“Ìtànṣán Ìmọ́lẹ̀ Ní Sànmánì Ojú Dúdú”
Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Germany
BÍ ÒPÌTÀN kan ṣe ṣàpèjúwe ìtàn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní sáà ìjọba Nazi nìyí. Ó jẹ́ níbi àfihàn àkọ́kọ́ fídíò tí ó gbé òtítọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ jáde náà, Jehovah’s Witnesses Stand Firm Against Nazi Assault, tí a ṣe ní Ibi Ìrántí Ravensbrück, ní Germany. Fídíò yí sọ ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ń wúni lórí nípa ìgboyà àti ìgbàgbọ́ tí àwọn 24 tí wọ́n la sáà ìjọba Nazi já, àti àwọn ògbógi 10 nínú ọ̀rọ̀ ìtàn àti ìsìn sọ.
Àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Ravensbrück ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà kan rí. Àwọn Ẹlẹ́rìí kan tí wọ́n là á já, tí ìjọba Nazi fi sẹ́wọ̀n ní ohun tí ó lé ní 50 ọdún sẹ́yìn, wá síbi àfihàn náà. Àwọn àti àwọn òpìtàn àti àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba rántí àwọn sáà ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ náà nígbà tí ìṣàkóso ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ ti ìjọba Nazi gbalẹ̀ jákèjádò Europe. Àwùjọ ènìyàn tí iye wọn tó 350 tẹ́tí sílẹ̀ sí ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń gbéni ró nípa ìwà títọ́ Kristẹni ti ọgọ́rọ̀ọ̀rùn Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n kú tìgboyàtìgboyà dípò kí wọ́n sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn.
Àwọn Ilé Iṣẹ́ Agbéròyìnjáde Ń Ṣàkíyèsí
A ṣe ìpàdé kan pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn ní hòtẹ́ẹ̀lì kan ní Berlin ní òwúrọ̀ ọjọ́ àfihàn àkọ́kọ́ náà, November 6, 1996. Àwọn oníròyìn wo àwọn àwòrán pélébé-pélébé láti inú fídíò náà, wọ́n sì tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé tí wọ́n sọ̀rọ̀ lórí ìjẹ́pàtàkì fídíò tuntun olótìítọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní sísọ ìtàn pàtàkì tí a kò mọ púpọ̀ nípa rẹ̀ náà. Ọ̀mọ̀wé Detlef Garbe, olùdarí Ibi Ìrántí Neuengamme, ṣàlàyé pé: “Kò yẹ kí a gba àwa—Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí—láyè láti gbàgbé ìtàn àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n ní àmì elésè àlùkò onígun mẹ́ta [àmì tí ó wà lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí nígbà náà]. Ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ ní sànmánì ojú dúdú ni èyí jẹ́.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí bíi mélòó kan tí wọ́n là á já, tí a rí nínú fídíò Stand Firm wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti sọ àwọn ìrírí wọn. Ọkàn wọn ha bà jẹ́ nítorí àwọn ìyà tí wọ́n jẹ́ bí? Ojú wọn tí ó tòrò mini, tí ó sì ń dán yinrin fi hàn pé wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀.
Lẹ́yìn àkókò ìbéèrè àti ìdáhùn, a ké sí àwọn oníròyìn wá síbi àfihàn àkọ́kọ́ fídíò olótìítọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Stand Firm, ní Ibi Ìrántí Ravensbrück, tí ó wà ní nǹkan bíi kìlómítà 64 sí ibẹ̀. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wọn ni wọ́n tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà.
Àfihàn Àkọ́kọ́ Náà
Ipò àyíká aláyọ̀ nínú gbọ̀ngàn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ṣe tí ó sún mọ́ Ibi Ìrántí Ravensbrück náà rọ́pò ìrísí ràkọ̀ràkọ̀ tí òfuurufú ní àti òjò tí ń fún wẹliwẹli ní ọjọ́ ìgbà ìwọ́wé títutù yí. Ọ̀jọ̀gbọ́n Jürgen Dittberner, tí ó jẹ́ olùdarí Àjọ Àgbówókalẹ̀fún àwọn ibi ìrántí Ravensbrück, Sachsenhausen, àti Brandenburg nígbà náà, sọ pé: “A gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún ìgboyà ìdánilójú ìgbàgbọ́ tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi hàn lábẹ́ ìjọba àjùmọ̀ní ti orílẹ̀-èdè. . . . A fi ìrántí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, tí wọn kò sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn, tí wọ́n sì ní láti jìyà tàbí kí wọ́n tilẹ̀ kú ní ìyọrísí rẹ̀, sí ipò iyì pátápátá.”
Angelika Peter, mínísítà ètò ẹ̀kọ́, ọ̀dọ́, àti eré ìdárayá fún Brandenburg, Germany, fi ìhìn iṣẹ́ kan, tí a kà, ránṣẹ́. Ó pòkìkí pé: “Ó ṣe pàtàkì pé kí a rántí ìdúróṣinṣin àwòfiṣàpẹẹrẹ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí.” Ọ̀mọ̀wé Sigrid Jacobeit, olùdarí Ibi Ìrántí Ravensbrück, sọ pé: “Mo ń fojú sọ́nà fún àfihàn àkọ́kọ́ yìí pẹ̀lú ìháragàgà àti ayọ̀. Mo rò pé, ọjọ́ pàtàkì kan ni òní jẹ́ fún gbogbo wa.”
Lẹ́yìn náà, wọ́n dín ìmọ́lẹ̀ kù láti bẹ̀rẹ̀ fídíò náà. Kì í ṣe àwọn olùlàájá láti orílẹ̀-èdè mẹ́jọ nìkan ni wọ́n wà níbẹ̀ fún ìṣẹ́jú 78, àmọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní àwùjọ pẹ̀lú tún finú wòye ìrírí ọlọ́rọ̀ ìbànújẹ́ náà àti ìjagunmólú apá aronilára yìí nínú ìtàn ilẹ̀ Germany. Ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ ènìyàn láti pa omijé mọ́ra bí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti ń sọ̀rọ̀ nípa àfihàn ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ lọ́nà àrà lábẹ́ àwọn ipò ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ bíburú jù lọ.
Lẹ́yìn tí àtẹ́wọ́ wàá-wòó náà wálẹ̀, òpìtàn Joachim Görlitz ka ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Ẹlẹ́rìí kan tí wọ́n pa ní Brandenburg. Görlitz ti rí ìwé náà ní ọ̀sẹ̀ méjì péré ṣáájú, nígbà tí ó ń ṣèwádìí ní Ibi Ìrántí àti Ibi Ìtọ́jú Àwọn Ìwé Ìlú Brandenburg, tí ó ṣe olùdarí rẹ̀. Ohùn rẹ̀ ń gbọ̀n bí ó ti ń ka àwọn ọ̀rọ̀ ọkùnrin Kristẹni olùṣòtítọ́ yìí tí ń fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níṣìírí láti rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ Olúwa wọn. Lẹ́yìn náà, Görlitz parí ọ̀rọ̀ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, lọ́kùnrin lóbìnrin, mo gbà gbọ́ pé fíìmù tí a ṣe yìí nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò kópa pàtàkì nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa.”
Òpìtàn Wulff Brebeck polongo pé, “nípasẹ̀ fíìmù yí, a ti fi búrùjí tuntun kan tí ó ṣe pàtàkì kún un—ohùn àwọn olùlàájá tí a kì í gbọ́ léraléra tó, àti . . . ohùn àwọn tí wọn kò là á já.” Ọ̀mọ̀wé Garbe fi kún un pé: “Ìwọ̀nyí jẹ́ ìrírí pàtàkì nípa àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí ìgbàgbọ́ wọn nínú Ọlọ́run àti ìgbẹ́kẹ̀lé wọn nínú àwọn ìlérí tí Bíbélì fúnni, fún ní okun láti dúró gbọnyin lákòókò ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ yẹn.”
Bí ìparí tí ó bá a mu wẹ́kú fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, lẹ́ẹ̀kan sí i, Àwọn Ẹlẹ́rìí bíi mélòó kan tí wọ́n là á já bá àwùjọ sọ̀rọ̀. Ó hàn kedere sí gbogbo ènìyàn pé àwọn Kristẹni aláìyẹhùn wọ̀nyí ṣì ní irú ìgbàgbọ́ lílágbára kan náà tí ó mú wọn dúró lákòókò tí wọ́n kojú ọ̀pọ̀ ìdánwò.
Láti ìgbà àfihàn àkọ́kọ́ náà, ó ti lé ní 340 àpilẹ̀kọ tí ó ti jáde nínú àwọn ìwé agbéròyìnjáde jákèjádò Germany nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti fídíò olótìítọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Stand Firm. Àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí rédíò bíi mélòó kan, tí wọ́n ṣe ọ̀kan ní ilé iṣẹ́ rédíò kan tí ó jẹ́ ti àpapọ̀ orílẹ̀-èdè, gbé àwọn ìròyìn dáradára pẹ̀lú.
Fídíò olótìítọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Stand Firm, yóò wà lárọ̀ọ́wọ́tó, ó kéré tán, ní èdè 24, níkẹyìn pátápátá. Bó bá yá, a óò tún ṣèmújáde ẹ̀dà kan ti iyàrá ìkàwé tí a yẹ̀ wò ṣàtúnṣe. Láti ìgbà tí fídíò náà ti jáde, àwọn olùkọ́ni tí iye wọn ń pọ̀ sí i ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo fídíò olótìítọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Stand Firm, gẹ́gẹ́ bí apá kan ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìlànà ẹ̀kọ́ wọn láti ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti ronú lórí àwọn ọ̀ràn pàtàkì-pàtàkì bí ẹ̀tanú, ìfòòró láti ọ̀dọ̀ ojúgbà ẹni, àti ohùn ẹ̀rí ọkàn.
Ní ayé tí ìkórìíra àti ìwà ọ̀dàlẹ̀ ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ yìí, ẹ wo bí ó ti bọ́ sákòókò tó pé kí a jẹ́ kí àwọn aráàlú mọ̀ nípa ìtàn ìwà títọ́ yìí! Lótìítọ́, ìyà tí àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ yìí jẹ kò já sí asán.—Hébérù 6:10.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ìpàdé pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn ní Berlin. Láti apá òsì: Ọ̀mọ̀wé Detlef Garbe; Simone Liebster àti Franz Wohlfahrt, tí wọ́n la ìpakúpa já; àti òpìtàn Wulff Brebeck