ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/01 ojú ìwé 8
  • “Mo Dúró Gbọn-in! Mo Dúró Gbọn-in! Mo Dúró Gbọn-in!”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Mo Dúró Gbọn-in! Mo Dúró Gbọn-in! Mo Dúró Gbọn-in!”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ipa Tí Àwọn Fídíò Tá A Fi Ń Jẹ́rìí Ń Ní Lórí Àwọn Èèyàn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • A Ṣètò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Láti Wàásù Ìhìn Rere
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Àwọn Onígboyà Olùpàwàtítọ́mọ́ Borí Inúnibíni Ìjọba Násì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ọ̀dọ́ Kan Tó Fi Ìsìn Rẹ̀ Yangàn
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 6/01 ojú ìwé 8

“Mo Dúró Gbọn-in! Mo Dúró Gbọn-in! Mo Dúró Gbọn-in!”

1 Ọ̀rọ̀ tí Kristẹni olùṣòtítọ́ kan tó la Ìpakúpa Rẹpẹtẹ náà já sọ yìí ń ṣe àsọtúnsọ ìpinnu ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn tó wà láàyè, àtàwọn tó ti kú, tí wọ́n dúró ti ohun tí wọ́n gbà gbọ́ láìka ìwà òǹrorò ìjọba Násì sí. (Éfé. 6:11, 13) Ìtàn amúniláyọ̀ nípa ìgboyà àti ìjagunmólú wọn ni a sọ nínú fídíò tí ń runi sókè náà, Jehovah’s Witnesses Stand Firm Against Nazi Assault. A rọ gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ pé kí wọ́n wò ó kí wọ́n sì ṣàjọpín èrò wọn nípa rẹ̀ àti bó ṣe rí lára wọn lẹ́ni kìíní kejì.

2 Jẹ́ kí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí ru ìrònú rẹ sókè: (1) Kí làwọn ìdí tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe fi ìgboyà kojú ìjọba Násì? (2a) Èrò tó yàtọ̀ síra wo ló wáyé nípa irú ìkíni kan, kí ló sì fà á? (2b) Báwo lèyí ṣe ní ipa lórí àwọn ìdílé Ẹlẹ́rìí? (3) Àwọn Ẹlẹ́rìí mélòó ni wọ́n rán lọ sí àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, kí ni wọ́n fi ń dá wọn mọ̀ níbẹ̀, báwo sì ni Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Gestapo ṣe hùwà sí wọn? (4) Kí làwọn ará wa kò ṣe tán láti ṣe láti lè gba òmìnira? (5a) Báwo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe fi ìgboyà sọ̀rọ̀ lòdì sí ìwà ìkà òǹrorò tí ìjọba Hitler hù, ìgbà wo ni wọ́n sì sọ̀rọ̀? (5b) Kí ni Hitler ṣe? (6) Báwo ni ìfìmọ̀ṣọ̀kan àwọn èèyàn Jèhófà ṣe gbẹ̀mí àwọn àti àwọn ẹlòmíràn là nípa ti ara àti nípa ti ẹ̀mí? (7) Orin Ìjọba náà wo ni wọ́n ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ kan? (8) Àpẹẹrẹ àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn èwe olùṣòtítọ́ wo ló ń sún ọ láti pa ìwà títọ́ rẹ sí Jèhófà mọ́ láìka ohun tó wù kí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ sí? (Tún wo ìwé1999 Yearbook, ojú ìwé 144 sí 147.) (9) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èrò wo ni fídíò yìí mú kí o ní nípa ọ̀ràn ṣíṣàìjẹ́ apá kan ayé?

3 Àpẹẹrẹ rere ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí a fi hàn nínú fídíò Stand Firm lè ran àwọn ọ̀dọ́, àní àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí pàápàá lọ́wọ́, kí wọ́n lè kojú àwọn ọ̀ràn pàtàkì bí àìrára gba nǹkan sí, ẹ̀mí ṣohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe, àti ẹ̀rí ọkàn. Bí o bá jẹ́ ọ̀dọ́ tó ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ girama tàbí ilé ẹ̀kọ́ gíga, ǹjẹ́ o lè jẹ́ kí àwọn olùkọ́ rẹ ní àǹfààní láti lo fídíò yìí ní kíláàsì? Bóyá o lè fi ẹ̀dà kan fídíò yìí lọ̀ wọ́n kí o sì ṣàlàyé pé ó jẹ́ ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ táwọn èèyàn kò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa rẹ̀ tàbí pé ó jẹ́ àkọsílẹ̀ kan tó ń kọni lẹ́kọ̀ọ́ ìwà rere.

4 Irin iṣẹ́ tó tayọ lọ́lá ni fídíò Stand Firm jẹ́ láti fi bí ẹ̀kọ́ Ọlọ́run ṣe ń pèsè agbára tẹ̀mí hàn wá láti ṣe ohun tí ń mú inú Ọlọ́run dùn nípa dídúró gbọn-in nínú ṣíṣe ohun tó bá ìlànà mu. (1 Kọ́r. 16:13) Ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́