Ọjọ́ Ọ̀la Wo Ló Wà fún Ẹyẹ Albatross?
Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní ilẹ̀ Britain
Ọjọ́ ọ̀la wo ló wà fún ẹyẹ albatross, ẹyẹ òkun títóbi jù lọ lágbàáyé? Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London sọ pé: “Kò dára rárá.” Ẹgbẹẹgbàárùn-ún wọn—àwọn olùwádìí, ará Australia fojú díwọ̀n iye tí ó pọ̀ tó 44,000—ni a ń pa lọ́dọọdún. Ní gidi, àwọn aláṣẹ kan rò pé, ọlọ́láńlá ẹyẹ albatross alárìnká náà, tí ó fẹ̀ tó mítà mẹ́ta nígbà tí ó bá na ìyẹ́ rẹ̀, yóò kú run láìpẹ́.
Lẹ́yìn tí àwọn ẹyẹ albatross bá ti tó fò, wọ́n máa ń lo ọdún méje léra ní òkun, tí wọ́n ń fò sókè láìlo ìyẹ́, tí wọ́n sì ń fo ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà láìlu apá, kódà tí wọ́n máa ń sùn nígbà tí wọ́n ń fò lọ lọ́wọ́. Àwọn ènìyàn kan gbà gbọ́ pé àwọn ẹyẹ náà lè ti lọ yí ayé po nígbà mélòó kan kí wọ́n tó pa dà sí ibi tí a ti bí wọn láti máa bímọ.
Ẹyẹ albatross má ń bí ọmọ kọ̀ọ̀kan lọ́dún kẹtakẹ́ta. Àmọ́ láàárín 20 ọdún tó kọjá, iye àwọn ẹyẹ albatross alárìnká tí ó wà ní Gúúsù Georgia ní Gúúsù Àtìláńtíìkì, àti àwọn tó wà ní Crozet, ní Òkun Íńdíà, ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dín kù dé ìdajì. Kí ni àwọn kan rò pé ó fa èyí? Fífi ìdẹ oníwọ̀ púpọ̀ pẹja ni.
Àwọn apẹja ń lo àwọn ìdẹ oníwọ̀ púpọ̀, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìwọ̀ lára, láti fi pa ẹja tuna ńlá. Wọ́n ń ju ìdẹ náà sódò láti ibi ìdí ọkọ̀ ìpẹja. Ẹranmi squid—olórí oúnjẹ ẹyẹ albatross—ni wọ́n fi ń ṣe ìjẹ ẹnu ìwọ̀ kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí ẹyẹ náà bá wálẹ̀ lójijì láti jẹ ẹranmi squid náà, ó máa ń gbé ìwọ̀ mì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ẹyẹ albatross tó jẹ̀wọ̀ náà ń bá ìdẹ wíwúwo náà wọmi, ó sì ń rì.
Láti dáàbò bo ẹyẹ albatross, a ti ṣàṣeyọrí ní fífún àwọn apẹja tuna mélòó kan níṣìírí láti máa dẹ ìdẹ wọn lóru, nígbà tí ẹyẹ náà kì í dẹdò. Àwọn apẹja tún ń wá ọ̀nà láti máa dẹ ìdẹ wọn láti abẹ́ ọkọ̀ wọn, kí àwọn ẹyẹ albatross má lè rí ìjẹ náà. A ti dá àwọn ọgbọ́n mìíràn títí kan lílo àwọn ìdẹ wíwúwo tí ó tètè ń rì àti oríṣi aṣọ́komásùn kan láti fi lé àwọn ẹyẹ náà dà nù.
Bí ó ti wù kí ó rí, kò sí àbójútó kankan lórí ọ̀nà tí àwọn apẹja gbà ń ṣiṣẹ́ ní òkun Gúúsù Àtìláńtíìkì tí ó ṣe salalu. Gẹ́gẹ́ bí ògbóǹtagí onímọ̀ nípa àwọn ẹyẹ òkun, Sandy Bartle, láti Ibi Ìkóhun Ìṣẹ̀ǹbáyé Sí ti New Zealand, ṣe sọ, àwọn apẹja níbẹ̀ “kò ṣe ohunkóhun láti ṣíwọ́ pípa àwọn ẹyẹ albatross.” Ní tòótọ́, ṣíṣeéṣe tí ó ṣeé ṣe kí ẹyẹ albatross ọlọ́láńlá kú run jẹ́ ẹ̀rí àfiṣàpẹẹrẹ àìkaǹkansí àti ìdágunlá ẹ̀dá ènìyàn.