ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 4/22 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Amusìgá Obìnrin Tí Ń Kú Ń Pọ̀ Sí I
  • Oògùn Líle ní Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Germany
  • Àwọn Arìnrìn Àjò Kíkàmàmà
  • “Ìgbìmọ̀ Àgbáyé Tí Kò Fí Bẹ́ẹ̀ Lẹ́mìí”
  • Àwọn Oyin Tí Ìgbóná Ara Wọn Ga
  • Àgbélébùú—Àmì Ìwà Ipá Ha Ni Bí?
  • Àwọn Kòkòrò Omi Yanjú Ìṣòro Náà
  • Gbígbójú Fo Ẹ̀ṣẹ̀ Dá
  • “Òǹtẹ̀ Ìka” Lórí Nǹkan Ọ̀ṣọ́
  • Ṣíṣọ́ra fún Iṣẹ́ Iná
  • “Ohun Tí Ó Lè Di Ewu”
  • Ọjọ́ Ọ̀la Wo Ló Wà fún Ẹyẹ Albatross?
    Jí!—1997
  • Ìpadàbọ̀ Ẹyẹ Funfun Títóbi Náà
    Jí!—1998
  • Sìgá—O Ha Máa Ń Kọ̀ Ọ́ Bí?
    Jí!—1996
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
Jí!—1996
g96 4/22 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Àwọn Amusìgá Obìnrin Tí Ń Kú Ń Pọ̀ Sí I

Ìwádìí kan tí wọ́n gbé jáde láìpẹ́ yìí nínú ìwé ìròyìn The Canadian Journal of Public Health ṣàwárí pé iye àwọn tí ń kú nítorí sìgá mímu láàárín àwọn obìnrin Kánádà ti lọ sókè láti orí 9,009 ní ọdún 1985 sí 13,541 ní ọdún 1991. Ìwádìí náà fojú díwọ̀n rẹ̀ pé àwọn obìnrin tí ó pọ̀ ju àwọn ọkùnrin lọ ni yóò kú nítorí sìgá mímu nígbà tí yóò bá fi di ọdún 2010, bí àṣà tí ó gbòde nísinsìnyí bá ṣì ń bá a lọ. Ní ọdún 1991, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ìwé agbéròyìnjáde The Toronto Star sọ, iye tí a fojú díwọ̀n sí 41,408 àwọn ènìyàn ló kú nítorí sìgá mímu (27,867 ọkùnrin àti 13,541 obìnrin). Dókítà Michael Thun ti Ẹgbẹ́ Ìgbógunti Jẹjẹrẹ ti America sọ pé, ní United States, àwọn tí ń kú nítorí jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró láàárín àwọn amusìgá obìnrin ti lọ sókè ní ìlọ́po mẹ́fà láàárín àwọn ọdún 1960 àti àwọn ọdún 1980. Ìwé agbéròyìnjáde The Globe and Mail ti Toronto, Kánádà, ròyìn pé, àwọn olùṣèwádìí parí ọ̀rọ̀ pé “sìgá mímu ni okùnfà ikú àìtọ́jọ́ ńlá kan ṣoṣo tí ó ṣeé ṣàkóso pátápátá ní United States.”

Oògùn Líle ní Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Germany

Ìwádìí kan tí a ṣe láàárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó ju 3,000 lọ ní ìhà àríwá Germany fi hàn pé lílo àwọn èròjà tí ń di bárakú ń tàn kálẹ̀ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ìwé ìròyìn Focus sọ, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlàjì lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún 17 tí wọ́n ti lo àwọn oògùn tí kò bófin mu fúnra wọn, ohun tí ó sì ju ìdá mẹ́ta lọ ló ṣì ń lò ó lọ́wọ́. Ọ̀jọ̀gbọ́n Peter Struck ṣàlàyé pé “ní ọ̀pọ̀ ilé ẹ̀kọ́ ní Hamburg, ènìyàn ń rí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún 16 sí ọmọ ọdún 17 tí wọ́n ń lọ láti orí lílo oògùn amóríyá, sórí oògùn apanilọ́bọlọ̀.” Àmọ́, èé ṣe tí oògùn lílò fi ń gbalẹ̀ sí i báyìí? Ọ̀jọ̀gbọ́n Klaus Hurrelmann sọ ìdí mẹ́ta tí àwọn èwe fi ń lo oògùn: ìgbésí ayé ti sú wọn, ó dà bí ẹni pé àwọn ènìyàn kò ka àṣeyọrí wọn sí, àti fífẹ́ tí wọ́n ń fẹ́ láti fara wé àwọn ojúgbà wọn.

Àwọn Arìnrìn Àjò Kíkàmàmà

Eyẹ albatross kan tí ń rìn gbéregbère kiri fo kìlómítà 26,000 ní ọjọ́ 72, seali aláwọ̀ eérú kan sì wẹ omi fún 5,000 kìlómítà ní oṣù mẹ́ta. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìdáàbòbò àwọn ẹranko ṣe àwárí agbára ìfarada nǹkan yíyani lẹ́nu yìí nígbà tí wọ́n so ẹ̀rọ agbésọfúnni rédíò pínníṣín kan mọ́ àwọn ẹyẹ albatross àti seali pàtó kan lára láti fi lè mọ ipa ìrìn wọn nípa ẹ̀rọ sátẹ́láìtì. Nígbà tí ó dé ibì kan, ẹyẹ albatross náà fo fún ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 3,000 kìlómítà ní ọjọ́ mẹ́rin lókè sánmà Òkun Ńlá Gúúsù Pacific. Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London sọ pé, seali náà wẹ omi tó 100 kìlómítà lóòjọ́, láti Scotland sí Erékùṣù Faeroe, ó sì fi agbára tí ó kàmàmà láti wẹ nínú alagbalúgbú omi òkun hàn. Kí ló fà ìrìn àjò àrìnbọ́lẹ́mìí tí àwọn méjèèjì rìn yìí? Ìròyìn náà sọ pé, wọ́n ń wá oúnjẹ kiri.

“Ìgbìmọ̀ Àgbáyé Tí Kò Fí Bẹ́ẹ̀ Lẹ́mìí”

Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ti oṣù October tí ó kọjá ròyìn pé: “Fún ọjọ́ mẹ́ta ní ọ̀sẹ̀ tí ó kọjá, àwọn aṣáájú tí ó wá láti gbogbo àgbáálá ilẹ̀ kórí jọ níbi àjọ̀dún 50 ọdún tí a dá Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀, kí wọ́n baà lè sọ àwọn ọ̀rọ̀ kàǹkà kàǹkà nípa ipò tí ayé wà.” Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣe kedere pé ohun èèlò pàtàkì kan sọnù lára “àwọn ọ̀rọ̀ kàǹkà kàǹkà” bí mélòó kan tí wọ́n sọ náà—òtítọ́. Ìwé agbéròyìnjáde Times sọ pé: “Bí àwọn òṣèlú ṣe máa ń ṣe níbi gbogbo, wọ́n ṣèlérí pé àwọn kò ní perí ẹlòmíràn fún àṣìṣe tí àwọ́n ṣe, tàbí kí àwọn dá a lẹ́bi.” Lẹ́yìn tí ìwé agbéròyìnjáde náà tí fa ọ̀rọ̀ àwọn aṣáájú orílẹ̀-èdè mẹ́jọ tí ọ̀rọ̀ wọn tako ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè wọn yọ, ìwé agbéròyìnjáde náà parí rẹ̀ nípa sísọ pé lájorí ìhìn iṣẹ́ wọn jẹ́: “Ẹ gbàgbé ohun tí mò ń ṣe, ẹ̀yin ayé; ẹ tẹ́tí sílẹ̀ sí ohun tí mò ń sọ.” Abájọ tí ìwé ìròyìn U.S.News & World Report fi pe Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní “ìgbìmọ̀ àgbáyé tí kò fi bẹ́ẹ̀ lẹ́mìí.”

Àwọn Oyin Tí Ìgbóná Ara Wọn Ga

Ìwé ìròyìn Science News ròyìn pé, àwọn oyin ilẹ̀ Japan máa ń gbèjà ara wọn lójú ìkọlù àwọn agbọ́n ńlá nípa fífi ooru ara wọn pa á. Gbàrà tí àwọn oyin bá ti lè fura sí i pé agbọ́n wà láyìíká, wọn yóò tan ọ̀tá wọn náà sínú ilé wọn, níbi tí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn òṣìṣẹ́ yóò ti gbéjà kò ó tí wọn yóò sì ṣù jọ mọ́ ọn. Ìwé ìròyìn náà sọ pé, nígbà tí ó bá yá, “àwọn oyin náà yóò máa kùn, wọn yóò sì jẹ́ kí ìgbóná ara gbogbo àwọn tí ó ṣù mọ́ ọn náà lọ sókè sí ìwọ̀n 47 lórí òṣùwọ̀n Celsius [ìwọ̀n 116 lórí òṣùwọ̀n Fahrenheit] tí ó lè fa ikú ní nǹkan bí 20 ìṣẹ́jú.” Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé àwọn oyin ilẹ̀ Japan ti lè fara da ìwọ̀n ìgbóná tí ó bá lọ sókè tó nǹkan bí ìwọ̀n 50 lórí òṣùwọ̀n Celsius, ọgbọ́n wọn yìí kì í pa wọ́n lára. Bí ó ti wù kí ó rí, kì í ṣe gbogbo àwọn agbọ́n ni ẹ̀tàn àwọn oyin máa ń mú. Níwọ̀n bí “20 sí 30 agbọ́n ti lè pa agbo oyin tí ó jẹ́ 30,000 ní wákàtí 3,” àwọn agbọ́n ńlá lè borí àwọn oyin nípa kíkórajọ pọ̀ láti kọlù wọ́n. Ìwé ìròyìn News náà sọ pé: “Tí ó bá ti di báyìí, wọn yóò gba gbogbo ilé wọn náà, wọn yóò sì kó ẹyin àti ìdin àwọn oyin náà.”

Àgbélébùú—Àmì Ìwà Ipá Ha Ni Bí?

Ìwé agbéròyìnjáde The Dallas Morning News ròyìn pé, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan ti ń gbé ìbéèrè dìde sí ìbójúmu lílo àgbélébùú gẹ́gẹ́ bí àmì ìsìn Kristian, nítorí ìbáṣepọ̀ tí ó ní pẹ̀lú ìwà ipá. Àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn náà ń fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa lo àwọn àmì tí ń fi ìgbésí ayé Jesu hàn, dípò èyí tí ń fi ikú rẹ̀ hàn. Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn, Catherine Keller, ti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìsìn ti Yunifásítì Drew ní Madison, New Jersey, U.S.A., sọ pé, àgbélébùú “ń gbé ìjọsìn ikú lárugẹ. Kò sí ẹni tí yóò fẹ́ kí àga ìpànìyàn tàbí okùn ìpànìyàn jẹ́ àmì ìgbàgbọ́ pàtàkì òun, ṣùgbọ́n ohun tí a óò máa lò nìyẹn bí ó bá jẹ́ pé ìjọba òde òní ló pa Jesu.”

Àwọn Kòkòrò Omi Yanjú Ìṣòro Náà

Ìwé agbéròyìnjáde Independent ti London ròyìn pé, kòkòrò omi lásán làsàn lè yanjú ìṣòro àwọn odò tí ó ti di eléèérí láàárín ìlú. Èyí ni iṣẹ́ ìṣàtúnṣe kan tí ń lọ lọ́wọ́ fi hàn. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè kó àwọn ẹja tí ń fi àwọn kòkòrò omi ṣe oúnjẹ tí wọ́n jẹ́ tọ́ọ̀nù 9.5 jáde kúrò nínú omi Ormesby Broad ní Norfolk, England. Èyí mú kí àwọn kòkòrò omi náà gbèrú, kí wọ́n sì jẹ àwọn èhù tí ń sọ adágún náà di eléèérí. Lẹ́yìn náà, àwọn ewéko míràn yóò hù jáde láti ara irúgbìn tí ó ti wà níbẹ̀ láìwúlò tẹ́lẹ̀, àti àwọn ẹyẹ, bíi coot àti ògbùgbú, sì padà wá. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọn yóò kó àwọn ẹja padà, wọ́n sì fojú díwọ̀n rẹ̀ pé gbogbo ìṣètò dídíjú àyíká náà ni yóò padà sí bí ó ti yẹ kí ó wà nígbà tí yóò bá fi tó ọdún márùn-ún. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìdáàbòbò àwọn ẹranko ní ilẹ̀ Europe ń fi tọkàntọkàn sọ ohun tí àbájáde iṣẹ́ yìí yóò jẹ́.

Gbígbójú Fo Ẹ̀ṣẹ̀ Dá

Ìwé ìròyìn Newsweek béèrè pé: “Kí ló tilẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀? Ẹ̀mí ìtara ṣàṣà tí ẹnì kọ̀ọ̀kan máa ń ní nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pòórá tán nínú àṣà tó lòde nísinsìnyí nínú ìsìn ilẹ̀ America.” Àwọn ọmọ ìjọ “kò fẹ́ láti gbọ́ ìwàásù tí ó lè ba iyì ara ẹni wọn jẹ́,” láàárín àwọn Kátólíìkì sì nìyí, “jíjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún àlùfáà déédéé ti di ìṣe àṣà ìsìn àtijọ́.” Ẹ̀rù ń ba àwọn àlùfáà tí ń bára wọn díje pé kí àwọ́n máà mú àwọn agbo àwọn bínú. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé, ọ̀pọ̀ “máa dá àwọn ìwà tí kò dára láwùjọ ‘tí ó jẹ́ ti gbogbogbòò’ lẹ́bi, irú bíi kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà [àti] ìfojútẹ́ḿbẹ́lú àwọn obìnrin. Ṣùgbọ́n ohùn wọn kì í já gaara tí ó bá di ti àwọn ọ̀ràn tí ó kan àwọn ènìyàn gbọ̀ngbọ̀n—irú bí ìkọ̀sílẹ̀, ìgbéraga, ìwọra àti jíjàgùdù fún ipò ọlá ẹni pẹ̀lú àṣejù.”

“Òǹtẹ̀ Ìka” Lórí Nǹkan Ọ̀ṣọ́

Àwọn obìnrin ilẹ̀ Britain ní ohun ọ̀ṣọ́ diamondi mílíọ̀nù 39 tí iye owó rẹ̀ tó nǹkan bí bílíọ̀nù 17.5 dọ́là, ní ọdọọdún ni àwọn olè sì ń jí èyí tí iye owó rẹ̀ tó mílíọ̀nù 450 dọ́là. Ọ̀pọ̀ àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí wọ́n ń sọnù lọ́nà yìí ni wọ́n kò lè tọpasẹ̀ wọn. Àwọn mẹ́tààlì olówó iyebíye tí wọ́n to àwọn diamondi náà sí lára ni wọ́n máa ń yọ́. Tí wọn yóò sì tún àwọn òkúta iyebíye náà tò. Bí ó ti wù kí ó rí, nísinsìnyí, nípa lílo kọ̀m̀pútà kan tí ń ṣàkóso ọ̀pọ̀ nǹkan, àwọn tí ń ṣe ohun ọ̀ṣọ́ yóò lè tẹ àléébù tí òkúta iyebíye kọ̀ọ̀kan ní sínú ìrántí kọ̀m̀pútà. Àwọn “òǹtẹ̀ ìka” wọ̀nyí ni ẹ̀rọ oníná kan tí ó máa ń dá àwọn àléébù òkúta kọ̀ọ̀kan mọ̀ lè dá mọ̀—kò sí òkúta méjì tí ó jọra. Ìwé agbéròyìnjáde The Sunday Times ti London ròyìn pé, kìkì ọ̀nà kan ṣoṣo tí àwọn olè lè gbà mórí bọ́ nínú ìṣètò ààbò yìí yóò jẹ́ láti tún òkúta náà gé, èyí sì jẹ́ iṣẹ́ kan tí ó máa ń ná ènìyàn lówó gan-an, tí ó sì tún máa ń dín ìníyelórí wọn kù.

Ṣíṣọ́ra fún Iṣẹ́ Iná

Ìròyìn Morbidity and Mortality Weekly Report (MMWR) sọ pé, àwọn oníṣẹ́ ìjọba ròyìn pé “ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 12,000 ènìyàn ni wọ́n ń tọ́jú lọ́dọọdún ní ẹ̀ka pàjáwìrì ti United States, nítorí àwọn èṣe tí ó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ iná.” Ìròyìn tí Ìgbìmọ̀ Tí Ń Rí Sì Ààbò Àwọn Òǹràjà kó jọ fún ọdún 1990 sí 1994, fojú díwọ̀n rẹ̀ pé ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún lára gbogbo àwọn èṣe tí ó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ iná náà ló jẹ èṣe ojú. Ìwé ìròyìn MMWR sọ pé, ìwọ̀nyí “lọ́pọ̀ ìgbà máa ń burú gan-an, wọ́n sì lè fa kí ojú má ṣiṣẹ́ dáradára mọ́, tàbí kí ó fọ́ pátápátá.” Ó tún ṣe pàtàkì, pẹ̀lú, láti mọ̀ pé ó ṣe kedere pé ojú àwọn tí ń wòran ń bàjẹ́ ju ojú àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ iná fúnra wọn lọ.

“Ohun Tí Ó Lè Di Ewu”

Ìwé ìròyìn Focus sọ pé, nǹkan bí ìpín 45 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ènìyàn tí ń gbé orílẹ̀-ayé nísinsìnyí ní ń gbé àwọn ìlú ńlá ńlá, nígbà tí yóò bá sì fi di ọdún 2000, a fojú díwọ̀n rẹ̀ pé ìdajì àwọn tí ń gbé ayé yóò máa gbé inú ìlú ńlá ńlá. Ọ̀pọ̀ lára àríwá ilẹ̀ Europe, Itali, àti ìhà ìlà oòrùn United States ló ní àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ tí ń gbé inú wọn, àwọn ibì kan ní China, Egipti, India, àti Gúúsù Áfíríkà sì ní àwọn ìlú ńlá ńlá tí àwọn ènìyàn kún fọ́fọ́ ní àárín àwọn àrọ́ko. Bí ó ti wù kí ó rí, àwòrán sátẹ́láìtì fi hàn báyìí pé kìkì ìpín 3 sí 4 nínú ọgọ́rùn-ún ilẹ̀ ayé ni àwọn ènìyàn kún fọ́fọ́. Ìwé ìròyìn Focus sọ pé, ṣùgbọ́n pẹ̀lú mílíọ̀nù 61 àwọn ènìyàn tí ń kó lọ sí àwọn ìlú ńlá ńlá lọ́dọọdún, pàápàá jù lọ ní àwọn apá ayé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, iye ènìyàn tí ń gbé àwọn agbègbè tí ènìyàn pọ̀ sí yìí ń lọ sókè nítorí pé “àwọn ìlú náà kò lè tètè gbèrú kíákíá bí iye àwọn ènìyàn ti ń gbèrú. Ipò ọ̀ràn náà jẹ́ ohun tí ó lè di ewu lọ́jọ́ iwájú.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́