Ìpadàbọ̀ Ẹyẹ Funfun Títóbi Náà
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ JAPAN
ÀWỌN ọkùnrin náà yọgi dání, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lu àwọn ẹyẹ funfun tó jojú ní gbèsè náà pa lọ́kọ̀ọ̀kan. Àwọn ẹyẹ albatross ni. Àwọn ọkùnrin náà: Hanemon Tamaoki àti àwọn alájọṣe rẹ̀. Ibi tó ti ṣẹlẹ̀: Torishima, erékùṣù kan ní nǹkan bí 600 kìlómítà ní ìhà gúúsù Tokyo. Ó jẹ́ ní ọdún 1887.
Ọ̀pọ̀ ọdún ni Tamaoki ti fi wéwèé láti ṣe èyí. Àwọn ènìyàn ń wá àwọn ìyẹ́ múlọ́múlọ́ tí wọ́n máa fi ṣe mátírẹ́ẹ̀sì nílé àti lẹ́yìn odi, Torishima sì jẹ́ erékùṣù àdádó kan tí ó jẹ́ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹyẹ albatross tí ń wábẹ̀ wá pamọ déédéé nìkan ní ń gbébẹ̀. Lára wọn ní ẹyẹ albatross onírù ṣékélé, tí ó gba Tamaoki lọ́kàn gan-an. Òun ni ẹyẹ òkun tó tóbi jù ní Àríwá Ìlàjì Ayé. Ṣá wulẹ̀ ronú bí ìyẹ́ tó máa bo ara ẹyẹ ńlá tó tẹ̀wọ̀n kìlógíráàmù mẹ́jọ, tí apá rẹ̀ sì fẹ̀ ju mítà 2.5 lọ tó bá nà án tán ti máa pọ̀ tó! Ní àfikún sí i, ó rọrùn láti mú ẹyẹ yìí, bí a bá ń wu ú léwu pàápàá, kì í gbìyànjú láti sá.
Tamaoki kó àwọn òṣìṣẹ́ tó pọ̀ tó 300 lọ sí erékùṣù náà láti bá a pa àwọn ẹyẹ náà, kí wọ́n sì tu ìyẹ́ wọn. Wọ́n tẹ abúlé kan dó, wọ́n tún la ọ̀nà ọkọ̀ ojú irin kékeré kan tí wọn yóò máa fi kó àwọn òkú ẹyẹ náà. Wọ́n ṣe iṣẹ́ náà yọrí tó bẹ́ẹ̀ tí Tamaoki fi di ọlọ́lá rẹpẹtẹ láìpẹ́—lẹ́yìn tí ó ti pa nǹkan bí mílíọ̀nù márùn-ún ẹyẹ. Ìpaláparun náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé, nígbà tí òkè ayọnáyèéfín erékùṣù náà bú gbàù ní 1902, tí ó ba abúlé náà jẹ́, tí ó sì pa gbogbo àwọn tí ń gbé ibẹ̀, àwọn ènìyàn ronú pé ó jẹ́ “ègún tó wá nítorí pípa tí wọ́n pa àwọn ẹyẹ albatross.” Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ènìyàn tún wá àwọn ẹyẹ tó ṣẹ́ kù lọ ní ọdún kejì.
Ní nǹkan bí 1,500 kìlómítà sí ibẹ̀, ní Òkun Ìlà Oòrùn China, ní àwọn erékùṣù olókùúta tí kò lólùgbé láàárín Taiwan àti Okinawa, ọkùnrin kan tí ń jẹ́ Tatsushiro Koga, ti ń ṣe irú òwò tí ń mówó wọlé kan náà. Bí ti Tamaoki, Koga rí sí i pé òun yára pa àwọn ẹyẹ náà kíákíá. Níkẹyìn, ó kúrò ní erékùṣù náà ní 1900—ṣùgbọ́n ó ti pa nǹkan bí àádọ́ta ọ̀kẹ́ ẹyẹ albatross kó tó lọ.
Àbájáde Oníbànújẹ́ Tí Ìwọra Fà
Pípa tí wọ́n pa àwọn ẹyẹ wọ̀nyẹn run jẹ́ ọ̀ràn ìbànújẹ́ tí àbájáde rẹ̀ burú púpọ̀. Nínú oríṣiríṣi irú ọ̀wọ́ ẹyẹ albatross tó wà, mẹ́ta ló ń gbé Àríwá Òkun Pásífíìkì, tí ibi tí wọ́n ń gbé ní pàtàkì sì jẹ́ àwọn erékùṣù tí Tamaoki àti Koga ti piyẹ́ náà. Ó ṣe kedere pé, a kò mọ ibòmíràn tí ọ̀kan nínú wọn, ẹyẹ albatross onírù ṣékélé (Diomedea albatrus), ti ń pamọ lágbàáyé.
Ìgbà kan ti wà tí ẹyẹ albatross ti jẹ́ ohun àràmàǹdà gbáà lójú àwọn atukọ̀ ní gbalasa òkun. Àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu àti àwọn ìtàn àròsọ tí wọ́n ń sọ nípa òkun fi hàn pé ó jẹ àpẹẹrẹ ìṣáájú fún ẹ̀fúùfù, àti kùrukùru. Bí ó ti wù kí ó rí, kì í ṣe ìtàn àtẹnudẹ́nu pé àwọn apá ẹyẹ yìí tó gùn lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ ló ń jẹ́ kí ó lè máa fò láìlo ìyẹ́ láti ìkángun kan òkun kan sí ìkángun kejì láàárín ọjọ́ mélòó kan péré, tí ó sì ń na apá rẹ̀ láìlù ú nínú afẹ́fẹ́ fún àkókò tó pọ̀ jù. Bí ó ṣe lè máa fò lọ láìgbagbára, kí ó sì wà lójú òkun fún ìgbà pípẹ́ kò láfijọ.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹyẹ albatross lè fò láìlo ìyẹ́ lọ́nà tó jọjú nínú afẹ́fẹ́, ìrìn rẹ̀ kì í yá lórí ilẹ̀, ó sì ń ṣe ségesège. Àwọn apá rẹ̀ tó gùn jù àti ara rẹ̀ tó tóbi jù kì í jẹ́ kí ó lè yára gbéra. Èyí, ní àfikún sí ti pé kò ti kọ́ láti máa bẹ̀rù ènìyàn, mú kí ẹyẹ náà dùn mú. Nítorí ìyẹn ni àwọn ènìyàn ṣe fún un lórúkọ bí òmùgọ̀ ẹyẹ tàbí gọ̀ǹgọ̀ṣú.
Àwọn èèyànkéèyàn tí mímọ̀ pé òkú ẹyẹ albatross ń mówó wọlé ń sún ṣiṣẹ́ ń bá pípaláparun náà nìṣó tayọ̀tayọ̀. Ìwádìí kan fi hàn pé nígbà tí ó fi di 1933, àwọn ẹyẹ tó kù ní Torishima kò pé 600 mọ́. Ìjọba ilẹ̀ Japan fi bó ṣe ká wọn lára tó kéde pé àwọn ènìyàn kò gbọ́dọ̀ dé erékùṣù náà. Ṣùgbọ́n àwọn èèyànkéèyàn sáré lọ sí erékùṣù náà láti pa iyekíye ẹyẹ tí wọ́n bá lè pa kí òfin náà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Nígbà tó fi di 1935, gẹ́gẹ́ bí ògbógi kan ṣe sọ, 50 ẹyẹ péré ló kù. Níkẹyìn, wọ́n kéde pé ẹyẹ albatross onírù ṣékélé ti kú run. Ẹ wo irú àbájáde oníbànújẹ́ tí ìwọra ènìyàn fà! Ṣùgbọ́n ìyanu kíkàmàmà kan ń bọ̀.
Ìpadàbọ̀ Náà Bẹ̀rẹ̀
Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan ní January 1951, ọkùnrin kan tí ń gun orí àpáta Torishima gbọ́ ìró ẹyẹ kan tó já a láyà lójijì. Ojú tó gbé sókè báyìí, ẹyẹ albatross kan ló rí! Lọ́nà kan ṣáá, ẹyẹ albatross onírù ṣékélé ti là á já, ó sì ń pamọ lẹ́ẹ̀kan sí i ní Torishima. Bí ó ti wù kí ó rí, ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé ṣe fún àwọn ènìyàn láti dé ni àwọn ẹyẹ náà kọ́lé sí lọ́tẹ̀ yí. Ó sì jọ pé wọ́n ní ìfura ọ̀tun kan sí ènìyàn. Ẹ wo bí yóò ti mú inú àwọn olùfẹ́ àwọn ẹ̀dá àdánidá dùn tó!
Ìjọba ilẹ̀ Japan yára wá nǹkan ṣe kíákíá. Wọ́n gbin koríko pampas láti mú kí ilẹ̀ náà túbọ̀ dára sí i láti fi kọ́lé ẹyẹ, wọ́n sì fòfin de lílọ tí àwọn ènìyàn ń lọ sí Torishima. Wọ́n kéde pé ẹyẹ albatross jẹ́ ìṣúra orílẹ̀-èdè, ó sì di ẹyẹ kan tí a ń dáàbò bò lágbàáyé.
Láti 1976 wá, Hiroshi Hasegawa, láti Yunifásítì Toho, ní Japan, ti ń ṣèwádìí nípa àwọn ẹyẹ náà, ó sì ń ṣèbẹ̀wò sí erékùṣù náà nígbà mẹ́ta lọ́dún báyìí láti ṣàkíyèsí wọn. Ó sọ fún Jí! pé, nípa fífi òrùka tó ní àwọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ́dún kọ̀ọ̀kan sí ẹsẹ̀ àwọn ẹyẹ náà, òún ti rí i pé ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni àwọn ẹyẹ albatross onírù ṣékélé ń padà lọ síbi tí wọ́n ti ń pamọ láàárín ọdún mẹ́ta tàbí mẹ́rin láti pamọ. Wọ́n ń bẹ̀rẹ̀ sí pamọ nígbà tí wọ́n bá pé ọdún mẹ́fà, ẹyin kan ṣoṣo ni wọ́n sì ń yín nígbà kọ̀ọ̀kan. Nítorí náà, pẹ̀lú pé wọ́n ń wà láàyè ní ìpíndọ́gba 20 ọdún, ó ń gba àkókò púpọ̀ láti mú kí iye wọn pọ̀ sí i. Nínú 176 ẹyin tí wọ́n yé sí Torishima nígbà òtútù 1996/97, 90 péré ni wọ́n pa.
Kí ni àwọn ẹyẹ albatross ń fi àkókò tó kù ṣe? Hasegawa sọ pé a kò mọ púpọ̀ nípa èyí. Ó dájú pé wọ́n ń yẹra fún ilẹ̀ àti ènìyàn. Ǹjẹ́ àwọn ẹyẹ albatross máa ń tẹ̀ lé ọkọ̀ òkun, kí wọ́n sì máa bà lé wọn lórí? Gẹ́gẹ́ bí Hasegawa ṣe wí, ìtàn àtẹnudẹ́nu lásán tí kò sí ẹ̀rí tí ń tì í lẹ́yìn ni ìyẹn. Ó sọ pé, ó dá òun lójú pé “àwọn ẹyẹ albatross ti ilẹ̀ Japan kì í bà lé àwọn ọkọ̀ òkun lórí.” Ṣùgbọ́n ó ṣàfikún pé níbòmíràn lágbàáyé, “ó ṣeé ṣe kí àwọn ẹyẹ náà kan máa bà lé ọkọ̀ òkun lórí fún àkókò díẹ̀ bí a bá ń bọ́ wọn.” Wọ́n ń lo àkókò púpọ̀ jù lọ nídìí ohun tí wọ́n mọ̀ ṣe jù—kí wọ́n máa fò nínú afẹ́fẹ́ tó bá wọn lára mu, kí wọ́n sì máa dòòyì ká orí òkun gbalasa náà. Nígbà tó bá rẹ̀ wọ́n, wọ́n máa ń sùn lójú òkun. Wọ́n máa ń jẹ ẹranmi squid, ẹja afòbíẹyẹ, akàn, àti edé. A ń rí àwọn ẹyẹ tí Hasegawa ti ki òrùka sí lẹ́sẹ̀ déédéé ní Òkun Bering àti Ìyawọlẹ̀ Omi Alaska. Nígbà tó sì di 1985, kíkófìrí ẹyẹ albatross onírù ṣékélé kan ní etíkun California—ní ìgbà àkọ́kọ́ láàárín àkókò tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀rúndún kan—fa ìdùnnú gan-an láàárín àwọn olùṣọ́ ẹyẹ níbẹ̀.
Ọjọ́ Iwájú Ńkọ́?
Apá tó múni láyọ̀ ni pé, ẹyẹ albatross onírù ṣékélé ń pọ̀ sí i láìsọsẹ̀. Ní May tó kọjá, Hasegawa fojú díwọ̀n rẹ̀ pé iye tó wà “lé ní 900 tọmọtọmọ.” Ó ṣàfikún pé: “Nígbà tí ó bá fi di ọdún 2000, ó yẹ kí a ní iye tó lé ní 1,000 ní Torishima nìkan, wọn yóò sì máa bí ọmọ tó lé ní 100 lọ́dọọdún.” Ohun tó tún múni láyọ̀ ni pé, ní 1988, lẹ́yìn ọdún 88, a tún ri tí wọ́n ń pamọ ní Òkun Ìlà Oòrùn China. Àwọn ẹyẹ náà ti yan ilẹ̀ olókùúta ní àgbègbè tí a ń jà lé lórí, èyí tí ó yẹ kí ó mú kí wọ́n láàbò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn fún ìgbà díẹ̀.
A ti ń ṣàtúnṣe àwọn ìwà àìtọ́ tí a hù ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn díẹ̀díẹ̀. Àbí a ti ṣe é? Àwọn olùwádìí ń rí i nígbà púpọ̀ pé, nígbà tí àwọn bá mú àwọn ẹyẹ náà láti fi òrùka sí wọn lẹ́sẹ̀, jìnnìjìnnì máa ń mú wọn, wọ́n sì máa ń bì. Wọ́n máa ń pọ àwọn èérún ike, ohun tí a fi ń tanná ran sìgá tí a sì ń sọ nù, àti àwọn pàǹtírí mìíràn tí àwọn ènìyàn ti fi àìbìkítà dà sínú òkun, ibi tí àwọn ẹyẹ náà ti ń jẹun.
Ǹjẹ́ ìwà ìkà tí àwọn ènìyàn ń hù yóò tún ti ẹyẹ ńlá funfun náà sí bèbè ewu lẹ́ẹ̀kan sí i?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Torishima, ibùgbé àdánidá ẹyẹ “albatross” onírù ṣékélé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Àwọn apá gígùn, tó rí tẹ́ẹ́rẹ́, tí ẹyẹ “albatross” ní ló jẹ́ kí ó jẹ́ ẹyẹ tó mọ̀ fò láìgbagbára jù lọ lágbàáyé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Àwọn ẹyẹ “albatross” onírù ṣékélé ti ń padà dé sí Torishima