ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 7/22 ojú ìwé 21-23
  • Àwọn Ìlù Áfíríkà Ha Ń Sọ̀rọ̀ Ní Gidi Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìlù Áfíríkà Ha Ń Sọ̀rọ̀ Ní Gidi Bí?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Èdè Ìlù
  • Fífi Ìlù Ògìdì Ìgbó Sọ̀rọ̀
  • Àwọn Ìlù Tí Ń Sọ̀rọ̀ Dáradára Jù Lọ
  • “Ìlù Onígba-Ohùn”
    Jí!—2003
  • Àwọn Èṣù Oníjó ní Yare
    Jí!—1998
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1998
Jí!—1997
g97 7/22 ojú ìwé 21-23

Àwọn Ìlù Áfíríkà Ha Ń Sọ̀rọ̀ Ní Gidi Bí?

Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Nàìjíríà

NÍGBÀ ìrìn àjò rẹ̀ gba Odò Congo kọjá ní 1876 àti 1877, olùṣàwárí Henry Stanley kò láǹfààní púpọ̀ tó láti ronú lórí àǹfààní tí ó wà nínú lílu ìlù àdúgbò. Ní ti òun àti àwọn alájọrìnrìn-àjò rẹ̀, ìsọfúnni tí ìlù ní nígbà gbogbo jẹ́ ẹyọ ọ̀rọ̀ kan: ogun. Ìró wẹ́rẹ́ tí wọ́n bá ti gbọ́ túmọ̀ sí pé àwọn òǹrorò jagunjagun tí ó fi ọ̀kọ̀ dìhámọ́ra ń fẹ́ gbógun tì wọ́n.

Nígbẹ̀yìn pátápátá, ní àkókò tí ó túbọ̀ tura ni Stanley wá mọ̀ nípa àwọn ohun púpọ̀ míràn tí ìlù lè sọ yàtọ̀ sí kí ó peni fún ogun. Nígbà tí Stanley ń ṣàpèjúwe àwùjọ ìran kan tí ó gbé ẹ̀bá odò Congo, ó kọ̀wé pé: “[Wọn] kò tí ì máa lo ètò ìbánisọ̀rọ̀ oníná mànàmáná, àmọ́ bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n ní ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ kan tí ó gbéṣẹ́ dáradára bákan náà. Lílu àwọn ìlù wọn ńláńlá ní ìhà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ń lo èdè tí ó yé ẹni tí ó bá mọ̀ ọ́n bí ìgbà tí a fẹnu sọ̀rọ̀.” Stanley mọ̀ pé àwọn onílù ń jẹ́ iṣẹ́ tí ó ju ti ìpè ogun tàbí ijó lọ; àwọn ìlù lè gbé àwọn ìsọfúnni pàtó jáde.

A lè ṣe àgbàsọ irú àwọn ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ láti abúlé dé abúlé. A máa ń gbọ́ ohùn àwọn ìlù kan láti ibi tí ó jìn tó kìlómítà 8 sí 11, pàápàá bí ó bá jẹ́ lóru ni a lù wọ́n láti orí ọkọ̀ ojú omi kan tàbí láti orí òkè kan. Àwọn onílù tí ó wà lọ́nà jíjìn ń tẹ́tí sí i, wọ́n ń lóye rẹ̀, wọ́n sì ń tún àwọn ìsọfúnni náà lù ránṣẹ́ sí àwọn mìíràn. Arìnrìn-àjò ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, A. B. Lloyd, kọ̀wé ní 1899 pé: “Wọ́n sọ fún mi pé wọ́n lè fi ìsọfúnni kan ránṣẹ́ láti abúlé kan sí òmíràn, tí ó fi 100 ibùsọ̀ [160 kìlómítà] jìnnà síra, láìpé wákàtí méjì, mo sì gbà gbọ́ pé ó ṣeé ṣe dáadáa láàárín àkókò tí kò tó bẹ́ẹ̀.”

Àwọn ìlù ṣì ń kó ipa pàtàkì nínú fífi ìsọfúnni jíṣẹ́ títí wọ apá púpọ̀ nínú ọ̀rúndún ogún. Ìwé náà, Musical Instruments of Africa, tí a tẹ̀ jáde ní 1965, sọ pé: “A ń lo àwọn ìlù tí a fi ń sọ̀rọ̀ bíi tẹlifóònù àti tẹ́lígíráàmù. A ń fi onírúurú ìsọfúnni ránṣẹ́—láti kéde ìbímọ, ikú, àti ìgbéyàwó; àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ eré ìdárayá, ijó, àti àwọn ayẹyẹ imúniwẹgbẹ́; àwọn ìsọfúnni ìjọba, àti ogun. Nígbà míràn, a ń fi àwọn ìlù náà ṣe òfófó tàbí àwàdà.”

Ṣùgbọ́n báwo ni àwọn ìlù ṣe sọ̀rọ̀? Ní Europe àti àwọn ibòmíràn, a ń fi ìsọfúnni ránṣẹ́ lórí tẹ́lígíráàmù nípasẹ̀ ìgbì iná mànàmáná. A ń fún wóróhùn kọ̀ọ̀kan ní àmì tirẹ̀ kí a lè pe àwọn ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn ní wóróhùn kan lẹ́ẹ̀kan. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ènìyàn Àárín Gbùngbùn Áfíríkà kò ní èdè tí a ń kọ sílẹ̀, nítorí náà, àwọn ìlù náà kì í pe àwọn wóróhùn inú ọ̀rọ̀. Ọgbọ́n tó yàtọ̀ ni àwọn onílù ilẹ̀ Áfíríkà ń lò.

Èdè Ìlù

Àṣírí tí ó wà nínú gbígbọ́ ìlù sinmi lórí mímọ àwọn èdè Áfíríkà náà fúnra wọn. Ọ̀pọ̀ lára àwọn èdè Àárín Gbùngbùn àti Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà jẹ́ oníròó méjì ní ti gidi—sílébù kọ̀ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan tí a ń sọ ní ohùn kan lára àwọn ohùn ìpìlẹ̀ méjì, yálà ti òkè tàbí ti ìsàlẹ̀. Ìyípadà èyíkéyìí nínú ohùn yóò yí ọ̀rọ̀ pa dà. Bí àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ náà, lisaka, nínú èdè Kele ti Zaire. Ní fífi ohùn ìsàlẹ̀ pe sílébù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí “ọ̀gọ̀dọ̀ kékeré tàbí irà”; ní fífi ohùn ìsàlẹ̀-ìsàlẹ̀-òkè pe àwọn sílébù náà, ó túmọ̀ sí “ìlérí”; ní fífi ohùn ìsàlẹ̀-òkè-òkè pè é, ó túmọ̀ sí “májèlé.”

Àwọn ìlù ògìdì ìgbó ilẹ̀ Áfíríkà tí a fi ń fi ìsọfúnni ránṣẹ́ pẹ̀lú ní ohùn méjì, òkè àti ìsàlẹ̀. Bákan náà, nígbà tí a bá ń lu àwọn ìlù tí a fi awọ bò lójú láti fi ìsọfúnni ránṣẹ́, a máa ń lò wọ́n ní méjìméjì, tí ọ̀kan máa ń ní ohùn òkè tí èkejì sì ń ní ohùn ìsàlẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, onílù kan tí ó mọṣẹ́ dunjú máa ń fi ìsọfúnni ránṣẹ́ nípa ṣíṣe àfarawé ohùn àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú èdè tí a ń sọ náà. Ìwé náà, Talking Drums of Africa, sọ pé: “Ní gidi, èdè tí a pè ní ti ìlù yí jẹ́ èdè kan náà tí ẹ̀yà náà ń sọ.”

Dájúdájú, èdè oníròó ohùn méjì sábà máa ń ní ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tí ìró ohùn àti sílébù wọn dọ́gba. Bí àpẹẹrẹ, nínú èdè Kele, nǹkan bí 130 ọ̀rọ̀ orúkọ ló ní ìró ohùn (òkè-òkè) kan náà bíi ti sango (bàbá). Ó lé ní 200 tó ní ìró kan náà (ìsàlẹ̀-òkè) bíi ti nyango (ìyá). Láti yẹra fún ìdàrúdàpọ̀, àwọn onílù máa ń pèsè àwọn àyíká ọ̀rọ̀ fún irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, ní fífi wọ́n sí àárín àpólà ọ̀rọ̀ kúkúrú tí a mọ̀ dunjú, tí ó ní ìyàtọ̀síra púpọ̀ tó láti jẹ́ kí olùgbọ́ lóye ohun tí a ń sọ.

Fífi Ìlù Ògìdì Ìgbó Sọ̀rọ̀

Oríṣi ìlù kan tí a fi ń sọ̀rọ̀ ni ìlù ògìdì ìgbó tí a figi ṣe. (Wo àwòrán ní ojú ìwé 23.) A ń ṣe irú àwọn ìlù bẹ́ẹ̀ nípa gbígbẹ́ ihò sínú ìpórì igi kan. Kò sí awọ ní ojú rẹ̀ kankan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ihò méjì ni ìlù inú àwòrán náà ní, ọ̀pọ̀ ni ó ní ihò gígùn kan ṣoṣo. Bí o bá lu apá kan ihò náà, yóò mú ìró ohùn òkè jáde; bí o bá lu apá kejì, yóò mú ìró ohùn ìsàlẹ̀ jáde. Àwọn ìlù ògìdì ìgbó sábà máa ń gùn ní mítà kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè kúrú tó ìdajì mítà tàbí kí wọ́n gùn tó mítà méjì. Fífẹ̀ ojú rẹ̀ lè wà láàárín 20 sẹ̀ǹtímítà sí mítà kan.

Ohun tí a ń lo àwọn ìlù ògìdì ìgbó fún ju fífi ìsọfúnni ránṣẹ́ láti abúlé sí abúlé lọ. Òǹkọ̀wé Francis Bebey, ọmọ ilẹ̀ Cameroon, ṣàpèjúwe ipa tí àwọn ìlù wọ̀nyí ń kó nínú ìdíje ìjàkadì. Bí àwọn ẹgbẹ́ méjì ṣe ń múra láti kojú ní gbàgede abúlé, àwọn òmùjà yóò máa gbẹ́sẹ̀ ijó sí ìlù ògìdì ìgbó bí àwọn ìlù náà ṣe ń kì wọ́n. Ìlù àwọn apá kan lè máa polongo pé: “Òmùjà, ǹjẹ́ o bẹ́gbẹ́ rẹ pàdé rí? Ta ló tó láti bá ọ jà, sọ fún wa? Àwọn tí ò lágbára wọ̀nyí . . . rò pé àwọn lè fi [ẹni] tí ò lágbára kan tí wọ́n ń pè ní òmùjà kojú rẹ kí àwọn sì ṣẹ́gun . . . , ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó lè ṣẹ́gun rẹ láé.” Àwọn olórin ti ìhà kejì yóò lóye àwọn ìṣáátá apanilẹ́rìn-ín wọ̀nyí, wọn yóò sì yára fi ìlù pa òwe pé: “Ọ̀bọ kékeré . . . ọ̀bọ kékeré . . . ó fẹ́ gungi ṣùgbọ́n ẹni gbogbo ló rò pé yóò ṣubú. Àmọ́ ọ̀bọ kékeré lágídí, kò jẹ́ já bọ́ lórí igi, yóò gungi dókè, ọ̀bọ kékeré yìí.” Wọn yóò máa fi ìlù mú kí ìdíje ìjàkadì náà dáni lára yá jálẹ̀jálẹ̀.

Àwọn Ìlù Tí Ń Sọ̀rọ̀ Dáradára Jù Lọ

Àwọn ìlù aláfọwọ́fún tẹ̀ síwájú díẹ̀ sí i. Ìlù tí ẹ rí nínú àwòrán apá ọ̀tún ní ń jẹ́ dùndún; òun ni gbajúmọ̀ ìlù tí àwọn ẹ̀yà Yorùbá, láti Nàìjíríà, fi ń sọ̀rọ̀. Ìlù tí ó rí bí ìhùmọ̀ onígò tí ń ka wákàtí yìí ní ojú méjì tí a fi awọ ewúrẹ́ tí ó fẹ́lẹ́, tí a ti hu, sè. Wọ́n fi ọṣán so ojú méjèèjì pọ̀. Nígbà tí a bá fún àwọn ọṣán náà, ojú ìlù náà yóò le sí i tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi lè mú àwọn ohùn àárín ohùn orin mẹ́jọ tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ jáde. Nípa fífi kọ̀ǹgọ́ lù ú àti pípààrọ̀ bí ohùn rẹ̀ àti ìyára rẹ̀ ṣe le tó, onílù tí ó mọṣẹ́ dunjú lè ṣàfarawé ìròkèrodò ohùn ènìyàn. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn onílù kan lè “bá” àwọn onílù míràn tí ó gbọ́lù, tí ó sì lè fìlù sọ̀rọ̀, “jíròrò.”

Ní May 1976, àwọn ọ̀kọrin àgbàlá ọba Yorùbá kan ṣàfihàn arabaríbí agbára tí àwọn onílù ní láti fìlù báni sọ̀rọ̀. Àwọn kan tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láàárín àwùjọ sọ àwọn àṣẹ kan kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ fún ọ̀gá àyàn, tí ó wá ń fi ìlù pa àwọn àṣẹ náà lẹ́yìn náà fún ọ̀kọrin kan tí ó jìnnà sí àgbàlá náà. Ní dídáhùn sí àwọn àṣẹ tí a ń fi ìlù pa náà, ọ̀kọrin ọ̀hún ń lọ láti ibì kan sí òmíràn, ó sì ń ṣe ohunkóhun tí wọ́n pàṣẹ pé kí ó ṣe.

Kò rọrùn láti kọ́ bí a ṣe ń fi ìlù jẹ́ iṣẹ́. Òǹkọ̀wé I. Laoye sọ pé: “Lílu ìlù Yorùbá jẹ́ iṣẹ́ ọnà tí ó díjú, tí ó sì ṣòro, tí ń gba ọ̀pọ̀ ọdún láti kọ́. Kì í ṣe òye iṣẹ́ àfọwọ́ṣe àti ìmọ̀ ìró nìkan ni ó yẹ kí onílù náà ní, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó ní agbára ìrántí gidigidi ní ti ewì àti ìtàn ìlú náà.”

Ní àwọn ẹ̀wádún lọ́ọ́lọ́ọ́, àwọn ìlù Áfíríkà kò tún máa sọ̀rọ̀ púpọ̀ tó bí wọ́n ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì ní ipa pàtàkì kan tí wọ́n ń kó nínú ohùn orin. Ìwé náà, Musical Instruments of Africa, sọ pé: “Kíkọ́ láti fi ìlù sọ̀rọ̀ ṣòro púpọ̀; nítorí náà, iṣẹ́ ọnà yí ń yára pòórá ní Áfíríkà.” Ògbógi kan nípa ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀, Robert Nicholls, fi kún un pé: “Àwọn ìlù ńlá ti àtijọ́, tí ohùn wọn ń la ọ̀pọ̀ máìlì já, tí olórí iṣẹ́ wọn sì jẹ́ láti máa fi ìsọfúnni ránṣẹ́ ti ń kásẹ̀ nílẹ̀.” Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ènìyàn lóde òní rí i pé ó túbọ̀ rọrùn láti lo tẹlifóònù.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ìlù oníhò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ìlù tí Yorùbá fi ń sọ̀rọ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́