Àwọn Èṣù Oníjó ní Yare
KÒ TÍ Ì pẹ́ tí ilẹ̀ mọ́, àmọ́ ooru ti bẹ̀rẹ̀ sí í mú gan-an. Bí a ti ń wo agbo àwọn ọkùnrin tí wọ́n rú dẹ́dẹ́ sí aṣọ ìbílẹ̀, a ṣe kàyéfì bí wọ́n ṣe lè mú ooru púpọ̀ jọjọ náà mọ́ra! A ń ṣèbẹ̀wò sí ìlú kékeré oníṣẹ́ àgbẹ̀ náà, San Francisco de Yare, Venezuela. Àwọn ọkùnrin tí wọ́n rú sí aṣọ náà ni Diablos Danzantes de Yare, Àwọn Èṣù Oníjó ní Yare.
Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ènìyàn Venezuela ló jẹ́ onísìn Kátólíìkì, wọ́n sì sọ pé àwọn gba Bíbélì gbọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, láti ìrandíran ni àwọn ijó olórìṣà tí ń ṣàgbéyọ àpẹẹrẹ ẹ̀mí èṣù ní kedere ti kó ipa pàtàkì nínú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àdúgbò. Kì í ṣe pé Ìjọ Kátólíìkì fàyè gba àwọn ijó náà nìkan ni, ó tún gbé e lárugẹ ní ti gidi. Bí ó ṣe rí nínú ọ̀ràn ti Àwọn Èṣù Oníjó ní Yare náà nìyẹn.
Lẹ́yìn tí a dé Yare, ẹnu yà wá láti rí i pé orílé-iṣẹ́ àdúgbò ti Ẹgbẹ́ Àwọn Ará ti Májẹ̀mú Mímọ́ Jù Lọ, tí ó jẹ́ ẹgbẹ́ kan nínú ìjọ Kátólíìkì, tún jẹ́ orílé-iṣẹ́ àwọn èṣù oníjó náà. Casa de Los Diablos (Ilé Èṣù) ni wọ́n ń pe ilé náà. Ọjọ́ Wednesday ni ọjọ́ ti a ń sọ yìí, àjọ̀dún Corpus Christi ti ìjọ Kátólíìkì ku ọ̀la, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ògbógi ayàwòrán ti tò síta ilé náà. Lójijì, ìró ìlù kan dún, àwọn ọkùnrin bíi mélòó kan tí wọ́n wọṣọ bí àwọn ẹ̀mí èṣù sì bẹ̀rẹ̀ sí í jó.
Aṣọ Àwọn Èṣù Oníjó
Oníjó kọ̀ọ̀kan wọ ẹ̀wù pupa, ṣòkòtò pupa, ìbọ̀sẹ̀ pupa, àti sálúbàtà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ki ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà, àgbélébùú, àti ohun ọ̀ṣọ́ ẹ̀yẹ Kátólíìkì sọ́rùn. Wọ́n so àgbélébùú mìíràn mọ́ ara aṣọ wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn mú ṣẹ́rẹ́ tí ó nírìísí eléṣù sọ́wọ́ kan, wọ́n sì mú àtòrì wẹ́wẹ́ sọ́wọ́ kejì. Àmọ́ èyí tó hàn kedere jù lọ ni agọ̀ ńlá, ràgàjì, aláwọ̀ oríṣiríṣi, tí ó ní àwọn ìwo, ojú kòǹgbàkòǹgbà, àti, lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn eyín tí ètè kò bò. Wọ́n rán aṣọ ìborùn pupa kan, tí ó gùn, mọ́ agọ̀ kọ̀ọ̀kan.
A gbọ́ pé oríṣiríṣi àwọn oníjó ló wà. Èyí tó jẹ́ olórí nínú wọn, capataz, tàbí alábòójútó, ni a tún mọ̀ sí diablo mayor, tàbí olórí èṣù. Ìwo mẹ́rin ni agọ̀ rẹ̀ ní. Ní gbogbogbòò ni wọ́n máa ń fẹ́ ẹ nítorí ipò gíga tó wà. Ìwo mẹ́ta ni igbákejì alábòójútó, tàbí segundo capataz, ní, ìwo méjì sì ni àwọn tí wọ́n jẹ́ oníjó lásán tí wọn kò ní ipò kankan ní. Díẹ̀ lára àwọn oníjó náà jẹ́ promesero, àwọn ènìyàn tí wọ́n ń pa ìlérí láti máa jó lẹ́ẹ̀kan lọ́dún fún iye ọdún mélòó kan pàtó, tàbí títí ìgbà tí wọ́n bá fi wà láàyè mọ́. Àwọn tí wọ́n gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ti dáhùn àdúrà pàtàkì kan ti àwọn gbà ni wọ́n sábà máa ń ṣe ìlérí yìí.
Ó Di Ṣọ́ọ̀ṣì
Nígbà tí ó di ọ̀sán, àwọn oníjó náà gbéra láti orílé-iṣẹ́ wọn, wọ́n sì forí lé ṣọ́ọ̀ṣì àdúgbò, láti lọ gba ìfọwọ́sí àlùfáà fún àwọn ibi yòó kù tí wọn óò dé. Àwọn èṣù oníjó náà pàdé àlùfáà ní ìta ṣọ́ọ̀ṣì. Wọ́n kúnlẹ̀ níbẹ̀ láti gba ìre rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n jó káàkiri àárín ìlú, nígbà míràn láti ojúlé dé ojúlé. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn onílé máa ń fi midinmí-ìndìn, ọtí, àti àwọn oúnjẹ mìíràn kí àwọn èṣù oníjó náà káàbọ̀. Gbogbo ọ̀sán ni wọ́n fi ṣe ìwọ́de yìí.
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí ìsìn Máàsì ṣe bẹ̀rẹ̀ ní ṣọ́ọ̀ṣì, àwọn oníjó náà tún pàdé ní Casa de Los Diablos. Wọ́n ń mi ṣẹ́rẹ́ wọn nígbà kan náà, láti ibẹ̀, wọ́n jó lọ sí itẹ́ òkú bí àwọn onílù ti ń lùlù. Wọ́n ti ṣe ojúbọ kan sí itẹ́ òkú náà, wọ́n sì júbà fún àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n ti kú. Lákòókò tí wọ́n ń ṣe ìrúbọ yìí, ọwọ́ ìlù fà. Lẹ́yìn náà, pẹ̀lú ìbẹ̀rù tí ó mú ìgbàgbọ́ nínú ohun asán lọ́wọ́, wọ́n fẹ̀yìn rìn jáde ní itẹ́ òkú náà, ní rírí i dájú pé àwọn kò kẹ̀yìn sí ojúbọ náà. Láti ibẹ̀, wọ́n forí lé ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n sì dúró kí ìsìn Máàsì parí.
Ìre Láti Ọ̀dọ̀ Àlùfáà
Lẹ́yìn ìsìn Máàsì, àlùfáà jáde síta, ó sì súre fún àwọn oníjó tí wọ́n kúnlẹ̀, tí wọ́n ti tẹrí ba, tí agọ̀ wọn rọ̀ sára aṣọ ìborùn wọn, èyí tí ó ṣàpẹẹrẹ bí ire ṣe ṣẹ́gun ibi. Àlùfáà náà jókòó ti olórí èṣù náà. Àwọn méjèèjì tẹ́tí sí ẹ̀jẹ́ àwọn promesero tuntun, tí wọ́n ṣàlàyé ìdí tí àwọn fi ń ṣèlérí láti jó, àti iye ọdún tí wọ́n fẹ́ fi jó.
Àwọn onílù bẹ̀rẹ̀ sí í yára lu ìlù wọn, àwọn èṣù oníjó náà sì gbéra nílẹ̀, wọ́n sì ń mi ara àti àwọn ṣẹ́rẹ́ wọn kikankikan tó fi bá ìlù tí wọ́n mú yá kánkán náà mu. Àwọn obìnrin pẹ̀lú jó, àmọ́ wọn kò wọ aṣọ èṣù. Wọ́n wọ yẹ̀rì pupa, ẹ̀wù funfun, wọ́n sì ta yálà ìrépé funfun tàbí pupa mọ́rí. Ní ìgbà kan láàárín ìwọ́de náà, àwọn kan lára àwọn èṣù oníjó náà gbé àwòrán baba ìsàlẹ̀ wọn sí èjìká wọn. Àwọn oníjó náà parí ìwọ́de wọn nípa títò lọ síwájú ṣọ́ọ̀ṣì kan, lẹ́yìn tí wọ́n ti lọ tẹrí ba fún àgbélébùú kan tí ó lókìkí ní ìlú náà.
Kì Í Ṣe fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Èyí ti jẹ́ ìrírí gbígbádùnmọ́ni fún wa gẹ́gẹ́ bí arìnrìn-àjò afẹ́. Nígbà tí a fi ṣèbẹ̀wò sí ìlú kékeré Yare, a kò lè mójú kúrò nínú àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú àwọn èṣù oníjó náà. Síbẹ̀, àwa gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, bíi ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà míràn tí wọ́n lé ní 70,000 ní Venezuela, kò dara pọ̀ mọ́ wọn nínú àjọ̀dún Àwọn Èṣù Oníjó ní Yare tàbí àwọn ìwọ́de tí ó jọ irú rẹ̀.
Kí ló dé tí a kò ṣe bẹ́ẹ̀? Nítorí pé a ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Èmi kò sì fẹ́ kí ẹ̀yin di alájọpín pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù. Ẹ̀yin kò lè mu ife Olúwa àti pẹ̀lú ife àwọn ẹ̀mí èṣù. Ẹ̀yin kò lè ṣalábàápín tábìlì Olúwa àti bákan náà tábìlì àwọn ẹ̀mí èṣù.” (Kọ́ríńtì Kíní 10:20, 21, New American Bible)—A kọ ọ́ ránṣẹ́.