ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 5/8 ojú ìwé 26-27
  • Ijó Jíjó Ha Yẹ fún Àwọn Kristian Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ijó Jíjó Ha Yẹ fún Àwọn Kristian Bí?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ Ni Ijó Jíjó Jẹ́
  • Ijó Jíjó—Èyí Tí Ó Bójú Mu àti Èyí Tí Kò Bójú Mu
  • Bóyá Ó Bójú Mu Tàbí Kò Bójú Mu —Bí A Ṣe Lè Mọ̀
  • Ṣó Yẹ Kí N Máa Lọ Ságbo Ijó Alẹ́?
    Jí!—2004
  • Àwọn Èṣù Oníjó ní Yare
    Jí!—1998
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbádùn Ara Mi?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Àwọn Àṣà Ìbílẹ̀ àti Àwọn Ìlànà Kristẹni Wọ́n Ha Bára Mu bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 5/8 ojú ìwé 26-27

Ojú Ìwòye Bibeli

Ijó Jíjó Ha Yẹ fún Àwọn Kristian Bí?

Ọ̀ṢỌ́Ọ́RỌ́ ọkùnrin kan sọ̀rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ sí ìyàwó rẹ̀ létí nígbà tí ó ń dìde lórí ìjókòó rẹ̀, tí ó sì ń fi yàrá náà sílẹ̀ láti gba atẹ́gùn títura ní alẹ́ náà, pé: “Èmi kò lè wo eléyìí. Ó yẹ kí n jáde síta.” Ó tì í lójú.

Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló pe òun àti ìyàwó rẹ̀ sí ibi àpèjẹ kan. Àwọn tí ó pè wọ́n náà ti pinnu láti ṣe onírúurú eré fún wọn, ìyẹ́n sì ní àwọn obìnrin mẹ́ta tí wọn yóò jó nínú. Ó dà bí ẹni pé kò dààmú ọkàn àwọn òǹwòran yòókù. Ó ha lè jẹ́ pé ara rẹ̀ ti ń gbóná jù ni? Kì í ha ṣe pé àwọn oníjó náà kàn ń fi ayọ̀ inú wọn hàn ni, tí wọ́n sì ń gbádùn òmìnira ijó jíjó tí wọ́n ní? Jẹ́ kí a gbìyànjú láti lóye ohun tí ijó jẹ́ ní ojú ìwòye Kristian.

Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ Ni Ijó Jíjó Jẹ́

Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí àwọn ènìyàn ń gbà jùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀ ni nípa fífi ara ṣàpèjúwe tàbí ọ̀nà ìgbàṣarasí. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn àjèjì bá wà ní ilẹ̀ òkèèrè, ó ti ya ọ̀pọ̀ wọn lẹ́nu láti mọ̀ pé ọ̀nà ìgbàṣarasí kan tí wọ́n kà sí èyí tí kò já mọ́ nǹkan máa ń ní ìtumọ̀ tí ó yàtọ̀ níbẹ̀—bóyá kí ó tilẹ̀ jẹ́ èyí tí kò dára pàápàá. Ẹnì kan tí ó ti jẹ́ míṣọ́nnárì tẹ́lẹ̀ rí ní Solomon Islands, Malaysia, àti Papua New Guinea sọ pé: “Ní àwọn agbègbè kan, àwọn ọ̀nà ìgbàṣarasí kan ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ohun tí ó ní ìtumọ̀ ìbálòpọ̀ takọtabo. Fún àpẹẹrẹ, tí obìnrin kan bá jókòó sí ilẹ̀ẹ́lẹ̀, wọ́n kà á sí ohun tí kò bójú mu fún ọkùnrin kan láti dá a kọjá. Bákan náà ni ó jẹ́ ohun tí kò lọ́gbọ́n nínú fún obìnrin kan láti rin kọjá níwájú ọkùnrin kan tí ó jókòó sí ilẹ̀ẹ́lẹ̀. Nínú àwọn ọ̀ràn méjèèjì yìí, ó máa ń fún àwọn ènìyàn náà ní ìtumọ̀ abẹ́nú tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìbálòpọ̀ takọtabo.” Yálà a fura sí i tàbí a kò fura sí i, ọ̀nà ìgbàṣarasí wa ń sọ nǹkan. Kò yẹ kí ó yà wá lẹ́nu nígbà náà pé, jálẹ̀ ọ̀rọ̀ ìtàn, àwọn ènìyàn ti lo ijó jíjó gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ kan.

Gbogbo ìmọ̀lára tí ó bá wà ní inú ènìyàn ni ènìyàn lè fi hàn síta níbi ijó—láti orí ayọ̀ àti mùkúlúmùkẹ aláyẹyẹ, dé orí àjọ̀dún ààtò ìsìn àti ti ètò àṣà ìbílẹ̀. (2 Samueli 6:14-17; Orin Dafidi 149:1, 3) Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Oníjó máa ń bá àwọn òǹwòran sọ̀rọ̀ lọ́nà méjì, yálà nípa lílo ara àti ojú láti fi ìmọ̀lára tí ó wà nínú rẹ̀ hàn jáde pátápátá tàbí nípa èdè dídíjú ti fífi ara sọ̀rọ̀ àti fífí ara ṣàpèjúwe.” Nínú àwọn ijó kan, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ náà lè dà bí èyí tí ó ṣeé tètè lóye dáradára. Nínú irú àwọn ijó mìíràn, kìkì àwọn ọ̀mọ̀ràn díẹ̀ ló lè lóye èdè náà. Fún àpẹẹrẹ, níbi ijó alálọ̀ọ́yípo ìgbàlódé kan, tí ènìyàn bá fọwọ́ sí oókan àyà, ó túmọ̀ sí ìfẹ́, nígbà tí ó sì jẹ́ pé títọ́ka sí ìka ọwọ́ àlàáfíà kẹrin ń túmọ̀ sí ìgbéyàwó. Níbi orin aláré àwọn ará China, tí ènìyàn bá ń rìn yípo, ó túmọ̀ sí ìrìn àjò, nígbà tí ó sì jẹ́ pé, tí ènìyàn bá ń rìn yípo orí ìtàgé nígbà tí ó bá mú ọrẹ́ gbọọrọ kan lọ́wọ́, ó túmọ̀ sí pé ó ń gun ẹṣin; tí wọ́n bá fi àsíá dúdú dá orí ìtàgé, ó túmọ̀ sí ìjì, tí wọ́n bá sì lo èyí tí ó ní àwọ̀ búlúù, ó túmọ̀ sí afẹ́fẹ́ lẹlẹ. Nípa báyìí, àwọn ọ̀nà ìgbàṣarasí àti ìfaraṣàpèjúwe níbi ijó ń sọ nǹkan. Ṣùgbọ́n gbogbo ohun tí ó máa ń sọ ló ha bójú mu bí?

Ijó Jíjó—Èyí Tí Ó Bójú Mu àti Èyí Tí Kò Bójú Mu

Ijó jíjó lè jẹ́ irú eré ìnàjú àti eré ìmárale kan tí ń gbádùn mọ́ni. Ó lè jẹ́ ọ̀nà ìgbàfìmọ̀lára-ẹni-hàn kan tí ó mọ́ tí kò sì ní bojúbojú kankan, èyí tí ń tọ́ka sí bí a ṣe lè jẹ́ kí ara wa fi hàn pé a láyọ̀ nítorí pé a tilẹ̀ wà láàyè tàbí nítorí pé a mọrírì oore Jehofa. (Eksodu 15:20; Onidajọ 11:34) A lè gbádùn àwọn ijó alájùmọ̀jó àti àwọn ijó ìbílẹ̀ kan. Nínú àkàwé ọmọ onínàákúnàá náà, Jesu tilẹ̀ tọ́ka sí ẹgbẹ́ àwọn oníjó kan, tí ó ṣe kedere pé wọ́n jẹ́ ìsọ̀wọ́ àwọn oníjó tí a óò sanwó fún, pé wọ́n jẹ́ apá kan àjọyọ̀ náà. (Luku 15:25) Nítorí náà, ó ṣe kedere pé, Bibeli kò dẹ́bi fún ijó jíjó fúnra rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ó kìlọ̀ fún wa pé kí a má ṣe jẹ́ kí ó ru àwọn èrò inú àti ìfẹ́ ọkàn burúkú sókè nínú wa. Nítorí èyí ló fi jẹ́ pé irú àwọn ijó jíjó kan lè jẹ́ èyí tí kò bójú mu, tí ó sì tilẹ̀ lè léwu fún ipò tẹ̀mí ẹnì kan pàápàá. (Kolosse 3:5) Láti ìgbà láéláé ni ijó jíjó ti jẹ́ ohun tí ó lè ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè, tí ó sì ṣeé lò fún àwọn ète tí ń pani lára, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.—Fi wé Matteu 14:3-11.

Elénìní wa, Satani Èṣù, mọ̀ pé pípa àwọn ọ̀nà ìgbàṣarasí ijó jíjó àti àwọn èrò inú tí kò bójú mu pọ̀ jẹ́ ohun èèlò lílágbára tí òún ní lọ́wọ́. (Fi wé Jakọbu 1:14, 15.) Ó mọ̀ dáradára nípa ìtànjẹ onítẹ̀ẹ́lọ́rùn ti ara tí ènìyàn máa ń ní nígbà tí ara bá ń yí àti bí ó ṣe lè mú kí èrò ìṣekúṣe ru sókè. Aposteli Paulu kìlọ̀ pé Satani ti múra láti tàn wá jẹ kí á “lè sọ èrò inú” wa “di ìbàjẹ́ kúrò ninu òtítọ́-inú ati ìwàmímọ́ tí ó tọ́ sí Kristi.” (2 Korinti 11:3) Ìwọ wo bí inú Èṣù yóò ti dùn tó bí a bá jẹ́ kí ọkàn wa di èyí tí ó há sínú ìrònú oníwà pálapàla nítorí wíwòran ijó jíjó tí kò bójú mu, tàbí tí àwa fúnra wá bá ń jó o. Inú rẹ̀ yóò tilẹ̀ wá dùn sí i bí a bá fi ìfẹ́ ọkàn wa tí a kò ṣàkóso hàn síta, tí a sì wá di ẹni tí ó fọrùn há páká àbájáde ìwà aláìbójúmu. Ó ti lo ọ̀nà ìgbàṣarasí àti ijó láti fi ṣe ìyẹn tẹ́lẹ̀ rí.—Fi wé Eksodu 32:6, 17-19.

Bóyá Ó Bójú Mu Tàbí Kò Bójú Mu —Bí A Ṣe Lè Mọ̀

Nítorí ìdí èyí, yálà àwọn ẹgbẹ́ ni ó ń jó ijó kan ní o, tàbí àwọn méjì, tàbí ẹnì kan ṣoṣo péré, bí ọ̀nà ìgbàṣarasí náà bá ń ru àwọn èrò tí kò tọ́ sókè nínú rẹ, ijó náà lè ṣèpalára fún ọ nìyẹn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má ṣèpalára fún àwọn ẹlòmíràn.

Àwọn kan ti ṣàkíyèsí pé níbi ọ̀pọ̀ ijó tí à ń jó lóde òní, àwọn méjì tí ń jó náà kì í tilẹ̀ fọwọ́ kan ara wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀rọ̀ fífọwọ́ kanra ha ni ohun tí à ń sọ níhìn-ín yìí bí? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Britannica yẹn ṣàkópọ̀ ọ̀rọ̀ náà nípa sísọ pé, “nǹkan kan náà ni àbájáde rẹ̀—ìtẹ́lọ́rùn ti ara nínú ijó jíjó àti níní ìmọ̀lára ìbálòpọ̀ nípa alábàájó ẹni, ì báà jẹ́ pé a dì mọ́ ọn tàbí a kàn rọra ń yọ́ ọ wò ni.” Ǹjẹ́ “níní ìmọ̀lára ìbálòpọ̀ nípa alábàájó ẹni” ha mọ́gbọ́n dání láìjẹ́ pé nínú ìdè ìgbéyàwó bí? Kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jesu pé “olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan lati ní ìfẹ́ onígbòónára sí i ti ṣe panṣágà pẹlu rẹ̀ ná ninu ọkàn-àyà rẹ̀.”—Matteu 5:28.

Yálà o fẹ́ láti jó tàbí o kò fẹ́ kù sọ́wọ́ rẹ. Ríronú lórí àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀ lé e yìí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti pinnu pẹ̀lú ọgbọ́n. Kí ni ète ijó yìí? Ojú wo ni àwọn ènìyàn fi ń wò ó? Kí ni àwọn ọ̀nà ìgbàṣarasí ijó náà ń tọ́ka sí jù lọ? Àwọn èrò àti ìmọ̀lára wo ni wọ́n ń ru sókè nínú mi? Ìfẹ́ ọkàn wo ni wọ́n ń ru sókè nínú alábàájó mi tàbí nínú àwọn tí ń wòran? Ó dájú pé ẹnì kan gbọ́dọ̀ ṣe bí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá ti sọ fún un, gẹ́gẹ́ bí ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ ọkọ tí a kọ́kọ́ mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀, ìyówù kí àwọn ẹlòmíràn ṣe.

Bibeli fi hàn pé Ẹlẹ́dàá fẹ́ kí a gbádùn àwọn ẹ̀bùn ẹwà, orin, àti ìrọ́síhìn-ín sọ́hùn-ún. Bẹ́ẹ̀ ni, gbádùn wọn—àmọ́ fi í sọ́kàn pé tí o bá ń jó, ara rẹ ń wí nǹkan. Rántí ìtọ́sọ́nà Paulu tí ó wà nínú Filippi 4:8 pé: “Ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́, ohun yòówù tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, ohun yòówù tí ó jẹ́ òdodo, ohun yòówù tí ó jẹ́ mímọ́níwà, ohun yòówù tí ó dára ní fífẹ́, ohun yòówù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòówù tí ó bá wà, ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọnyi rò.”

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]

Picture Fund/Ìyọ̀ọ̀da onínúure, Museum of Fine Arts, Boston

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́