ORÍ 32
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbádùn Ara Mi?
Fàmì sí òótọ́ tàbí irọ́ nínú àwọn gbólóhùn tó wà nísàlẹ̀ yìí.
Bí Bíbélì ṣe sọ . . .
Kò dáa kéèyàn máa ṣeré ìdárayá.
□ Òótọ́ □ Irọ́
Gbogbo fíìmù àtàwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n ni ò dáa.
□ Òótọ́ □ Irọ́
Gbogbo ijó ni ò dáa.
□ Òótọ́ □ Irọ́
O TI ṣe wàhálà ní gbogbo ọ̀sẹ̀. Kò síléèwé lópin ọ̀sẹ̀. O ti parí iṣẹ́ ilé, àmọ́ torí pé ọ̀dọ́ ni ẹ́, kò tíì rẹ̀ ẹ́ tó bẹ́ẹ̀. (Òwe 20:29) Nígbà tó o sì ṣe tán, o rí i pé ó yẹ kó o gbádùn ara ẹ.
Àwọn ojúgbà ẹ lè rò pé Bíbélì kì í jẹ́ kéèyàn gbádùn ara ẹ̀, pé ó sì máa ń káni lọ́wọ́ kò. Ṣóòótọ́ nìyẹn ṣá? Jẹ́ ká wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tá a béèrè lójú ìwé tó ṣáájú, ká sì wo ohun tí Bíbélì sọ gan-an nípa gbígbádùn ara wa.
● Kò dáa kéèyàn máa ṣeré ìdárayá.
Irọ́. Bíbélì sọ pé “ara títọ́ ṣàǹfààní.” (1 Tímótì 4:8) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “títọ́” nínú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù yìí túmọ̀ sí ‘bí eléré ìdárayá ṣe máa ń tọ́ ara ẹ̀.’ Ọ̀pọ̀ eré ìdárayá ló sì wà lóde òní, díẹ̀ lára wọn ni yíyọ̀ lórí yìnyín, gígun kẹ̀kẹ́, sísáré kúṣẹ́kúṣẹ́, eré tẹníìsì, bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá, bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá àti volleyball.
Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé a ò gbọ́dọ̀ ṣọ́ra rárá ni? Ó dáa, gbé àyíká ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà lókè yìí yẹ̀ wò. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ lẹ́tà sí ọ̀dọ́kùnrin tó ń jẹ́ Tímótì, ó sọ pé: “Ara títọ́ ṣàǹfààní fún ohun díẹ̀; ṣùgbọ́n fífọkànsin Ọlọ́run ṣàǹfààní fún ohun gbogbo, bí ó ti ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí àti ti èyí tí ń bọ̀.” Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù rán wa létí pé mímú inú Ọlọ́run dùn ló gbọ́dọ̀ jẹ wá lógún. Bó o bá fẹ́ rí i dájú pé ìfọkànsìn Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé ẹ, kódà nígbà tó o bá ń ṣeré ìdárayá, o lè bi ara ẹ láwọn ìbéèrè mẹ́ta tó wà nísàlẹ̀ yìí:
1. Báwo ni ewu tó wà nínú eré ìdárayá náà ṣe pọ̀ tó? Má kàn gbọ́kàn lé ọ̀rọ̀ àhesọ tàbí ohun táwọn ọ̀dọ́ tó fẹ́ràn eré ìdárayá ń sọ. Wádìí òkodoro òtítọ́. Bí àpẹẹrẹ, wádìí àwọn nǹkan bíi: Báwo lèèyàn ṣe lè ṣèṣe nídìí eré yẹn tó? Kí lèèyàn lè ṣe tí ò fi ní ṣèṣe? Kí lèèyàn gbọ́dọ̀ kọ́, kí ló sì gbọ́dọ̀ ní kó tó lè ṣeré yẹn láìṣèṣe? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣàṣà ni eré téèyàn lè ṣe tí ò ní ṣèṣe, ṣé olórí ìdí táwọn èèyàn fi ń ṣe eré yìí ni láti ṣàwọn ẹlòmíì léṣe tàbí láti pa wọ́n?
Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìwàláàyè jẹ́, òfin tí Ọlọ́run sì fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi hàn pé ìyà tó tóyà lòún máa fi jẹ ẹni tó bá ṣèèṣì pààyàn. (Ẹ́kísódù 21:29; Númérì 35:22-25) Ìdí nìyẹn táwọn èèyàn Ọlọ́run fi máa ń ṣe nǹkan tìsọ́ratìṣọ́ra. (Diutarónómì 22:8) Àwa Kristẹni òde òní náà gbọ́dọ̀ fi hàn pé a ka ẹ̀mí sí pàtàkì.
2. Ṣáwọn tó mọ àwọn ìlànà Ọlọ́run lẹ jọ máa ṣeré ọ̀hún? Bó o bá mọwọ́ eré ìdárayá kan dáadáa, àwọn tíṣà àtàwọn ojúgbà ẹ lè fẹ́ kó o dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ tó ń ṣojú iléèwé yín fún irú eré ìdárayá bẹ́ẹ̀. Ó sì lè máa wu ìwọ náà láti dara pọ̀ mọ́ wọn. Kristẹni ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Mark sọ pé: “Mi ò rò pé ó dáa káwọn òbí mi máa sọ pé kí n má dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ tó ń ṣojú iléèwé wa.” Àmọ́, dípò tí wàá fi máa gbìyànjú láti yí àwọn òbí ẹ lérò pa dà, gbé àwọn òótọ́ wọ̀nyí yẹ̀ wò: Ìgbà tẹ́ ẹ bá jáde iléèwé lẹ máa ń bẹ̀rẹ̀ ìdánrawò eré ìdárayá ọ̀hún. Bí wọ́n bá rí i pé o mọwọ́ eré ọ̀hún dáadáa, wọ́n á tún rọ̀ ẹ́ láti fàyè púpọ̀ sílẹ̀ fún bíbá wọn ṣeré yẹn. Bó bá sì jẹ́ pé ńṣe lo ò mọwọ́ ẹ̀ tó bó ṣe yẹ, wàá fẹ́ wáyè púpọ̀ sí i láti máa ṣe ìdánrawò kó o lè mọwọ́ ẹ̀ dáadáa. Yàtọ̀ síyẹn, kì í pẹ́ tẹ́yin ọmọ iléèwé tẹ́ ẹ jọ wà nínú ẹgbẹ́ yẹn á fi bẹ̀rẹ̀ sí bára yín ṣọ̀rẹ́ torí ẹ máa ní láti bára yín yọ̀ nígbà tẹ́ ẹ bá rọ́wọ́ mú, ẹ ó sì máa bára yín kẹ́dùn nígbà tẹ́ ò bá rọ́wọ́ mú.
Wá bi ara ẹ pé: ‘Bí mo bá bẹ̀rẹ̀ sí fàkókò mi ṣeré tó máa mú mi dọ̀rẹ́ àwọn ọ̀dọ́ tí ò mọ àwọn ìlànà Bíbélì, ṣéyẹn lè nípa rere lórí mi?’ (1 Kọ́ríńtì 15:33) ‘Kí làwọn nǹkan tí mo ti ṣe tán láti yááfì kí n lè wà nínú ẹgbẹ́ eré ìdárayá kan?’
3. Báwo leré yẹn ṣe máa gba àkókò mi tó, èló lá á sì máa ná mi? Bíbélì kọ́ wa pé ká “máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílípì 1:10) Kó o lè fi ìmọ̀ràn yìí sílò, bi ara ẹ pé: ‘Ṣé eré tí mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe yìí ò ní gba àkókò tí mo fi ń ṣe àwọn iṣẹ́ iléèwé tàbí tí mò ń lò fáwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run? Èló ni gbogbo owó tí mo máa ná sórí ṣíṣe eré ìdárayá yìí? Ṣé ẹ̀mí mi gbé nǹkan tí mo fẹ́ dáwọ́ lé yìí?’ Bó o bá dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fàwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì ṣáájú nígbèésí ayé ẹ.
● Gbogbo fíìmù àtàwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n ni ò dáa.
Irọ́. Bíbélì pàṣẹ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n “di ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ mú ṣinṣin, kí wọ́n sì “ta kété sí gbogbo oríṣi ìwà burúkú.” (1 Tẹsalóníkà 5:21, 22) Kì í ṣe gbogbo fíìmù àti ètò orí tẹlifíṣọ̀n ló tako ìlànà yìí.a
Kò sí àníàní pé lílọ wo fíìmù nílé sinimá jẹ́ ọ̀nà kan téèyàn lè gbà gbádùn ara ẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀. Leigh, ọmọbìnrin kan láti orílẹ̀-èdè South Africa sọ pé: “Bí fíìmù kan bá wù mí wò, ńṣe ni mo máa ń pe àwọn ọ̀rẹ́ mi lórí fóònù, bí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ wa tó kù sì ṣe máa gbọ́ nìyẹn.” Lọ́pọ̀ ìgbà, ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n bá fẹ́ fi fíìmù hàn ni irú àwọn bẹ́ẹ̀ máa ń fẹ́ lọ. Lẹ́yìn tí wọ́n bá sì ṣe tán, àwọn òbí wọn á lọ gbé wọn, gbogbo wọn á sì gba ilé oúnjẹ kan lọ láti gbádùn ara wọn.
Ó lè dà bíi pé nǹkan ìgbàlódé ni tẹlifíṣọ̀n àti fíìmù, àmọ́ ńṣe ló wulẹ̀ jẹ́ ọ̀nà tuntun táwọn èèyàn gbà ń sọ ìtàn, bí wọ́n ti ń ṣe látìgbà táláyé ti dáyé. Jésù ò kẹ̀rẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká sọ ìtàn tó wọni lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, àkàwé tó ṣe nípa aláàánú ara Samáríà wọ àwọn èèyàn lọ́kàn gan-an ni, ó kọ́ wọn láti máa fàánú hàn, wọ́n sì kọ́ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa hùwà.—Lúùkù 10:29-37.
Àwọn tó ń ṣe fíìmù lónìí náà ń fàwọn fíìmù wọn kọ́ àwọn èèyàn láwọn ẹ̀kọ́ tó ń darí ìgbésí ayé wọn àtàwọn ìwà tí wọ́n ń hù. Wọ́n máa ń gbìyànjú láti mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ẹni tí eré yẹn dá lé lórí, ì báà jẹ́ ọ̀daràn tó ń fìwà ipá ṣayé tàbí ẹni tágbára ń gùn. Bó ò bá ṣọ́ra, wàá fẹ́rẹ̀ẹ́ lè máa gbàdúrà pé kí ọ̀daràn yẹn ṣàṣeyọrí, kódà wàá máa wá àwíjàre pé kò sóhun tó burú nínú ìṣekúṣe tó ṣe tàbí ìwà burúkú tó hù! Kí lo lè ṣe tó ò fi ní kó sínú páńpẹ́ yìí?
Kó o tó yan fíìmù tàbí ètò orí tẹlifíṣọ̀n, bi ara ẹ pé: ‘Ṣé ètò yìí máa ràn mí lọ́wọ́ láti máa yọ́nú sáwọn èèyàn kí n sì máa ṣàánú wọn?’ (Éfésù 4:32) ‘Àbí ńṣe lá á jẹ́ kí n máa yọ̀ nítorí ìṣubú àwọn ẹlòmíì?’ (Òwe 17:5) ‘Ṣó máa jẹ́ kó ṣòro fún mi láti “kórìíra ohun búburú”?’ (Sáàmù 97:10) ‘Àbí tí mi ò bá ṣọ́ra, ńṣe ni màá máa bá “àwọn aṣebi” kẹ́dùn?’—Sáàmù 26:4, 5.
Àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń kọ sẹ́yìn àwọn àwo fíìmù àti ìpolówó wọn lè jẹ́ kó o mọ ohun tí fíìmù kan dá lé. Àmọ́, ṣọ́ra kó o máa lọ “ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀” láìronú jinlẹ̀. (Òwe 14:15) Kí nìdí? Èrò ọkàn ẹlòmíì ló máa ń wà nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń kọ sẹ́yìn àwo fíìmù. Wọ́n sì lè mọ̀ọ́mọ̀ yọ àwọn àwòrán tí ò dáa kúrò nínú fíìmù nígbà tí wọ́n bá ń polówó. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Connie ò tíì tó ọmọ ogún ọdún, ó sọ pé: “Mo ti wá rí i pé téèyàn bá mọ àwọn eléré tó kópa pàtàkì nínú fíìmù kan, ó ṣeé ṣe kéèyàn mọ ohun tí fíìmù ọ̀hún dá lé.”
Àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni tó ń fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù bíi tìẹ lè jẹ́ kó o mọ̀ tó bá yẹ kó o wo fíìmù kan. Àmọ́, má gbàgbé pé ohun táwọn èèyàn bá gbádùn nínú fíìmù ni wọ́n máa sọ fún ẹ. O ò ṣe kúkú béèrè ohun tó burú nínú fíìmù yẹn? Sọ ojú abẹ níkòó. Bí àpẹẹrẹ, ní kí wọ́n sọ fún ẹ bí ìwà ipá, ìṣekúṣe tàbí ẹ̀mí èṣù bá wà nínú ẹ̀. Ó tún máa dáa kó o gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn òbí ẹ. Vanessa sọ pé: “Mo máa ń lọ bá àwọn òbí mi fún ìrànlọ́wọ́. Bí wọ́n bá ní àwọn ò rí ohun tó burú níbẹ̀ ni mo máa ń lọ wò ó.”
Má fọwọ́ kékeré mú yíyan fíìmù tàbí ètò orí tẹlifíṣọ̀n o. Ìdí ni pé ohun tó o bá fi ń gbádùn ara ẹ ló máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ àtàwọn ohun tó o kà sí pàtàkì. (Lúùkù 6:45) Ohun tó o bá yàn máa jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn tó ò ń bá kẹ́gbẹ́, irú ọ̀rọ̀ tó o máa ń sọ àti ohun tó o fàyè gbà tó bá dọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀. Torí náà, yan ohun tó dáa!
● Gbogbo ijó ni ò dáa.
Irọ́. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì la òkun pupa kọjá tí wọ́n sì ti bọ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun Íjíbítì, Míríámù kó àwọn obìnrin jọ láti fi ijó yin Ọlọ́run. (Ẹ́kísódù 15:20) Nínú àkàwé tí Jésù náà sì sọ nípa ọmọkùnrin onínàákúnàá, ó ní wọ́n fi ‘orin àwọn òṣèré àti ijó’ yọ ayọ̀ ńláǹlà nítorí ọmọkùnrin wọn tó pa dà wálé.—Lúùkù 15:25.
Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn. Láwọn ìṣẹ̀dálẹ̀ kan, tọmọdé tàgbà ló máa ń gbádùn àtimáa fẹsẹ̀ rajó nígbà táwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ bá pàdé pọ̀. Àmọ́, ó yẹ ká máa ṣọ́ra. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò dẹ́bi fún ṣíṣe ayẹyẹ níwọ̀nba, ó kìlọ̀ pé “àwọn àríyá aláriwo” ò dáa. (Gálátíà 5:19-21) Wòlíì Aísáyà kọ̀wé pé: “Ègbé ni fún àwọn tí ń dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ kí wọ́n lè máa wá kìkì ọtí tí ń pani kiri, àwọn tí ń dúró pẹ́ títí di òkùnkùn alẹ́ tí ó fi jẹ́ pé wáìnì mú wọn gbiná! Háàpù àti ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín, ìlù tanboríìnì àti fèrè, àti wáìnì sì ní láti wà níbi àsè wọn; ṣùgbọ́n ìgbòkègbodò Jèhófà ni wọn kò bojú wò.”—Aísáyà 5:11, 12.
“Ọtí tí ń pani” àti orinkórin ló máa ń wà níbi àríyá bẹ́ẹ̀. Bí wọ́n bá ti bẹ̀rẹ̀ láàárọ̀, ó di òru kí wọ́n tó fibẹ̀ sílẹ̀. Tún ṣàkíyèsí ìwà àwọn tó máa ń gbádùn irú àríyá bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń hùwà bíi pé Ọlọ́run ò sí! Kò yẹ kó yà ẹ́ lẹ́nu nígbà náà pé Ọlọ́run ò fọwọ́ sí irú àwọn àríyá bẹ́ẹ̀.
Bí wọ́n bá pè ẹ́ síbi àríyá kan tí wọ́n ti máa jó, bi ara ẹ láwọn ìbéèrè bí: ‘Àwọn wo ló máa wà níbẹ̀? Irú èèyàn wo ni wọ́n? Ta ló máa dáhùn fún ohun tó bá ṣẹlẹ̀ níbẹ̀? Irú àbójútó wo ló máa wà níbẹ̀? Ṣáwọn òbí mi fọwọ́ sí i pé kí n lọ? Irú ijó wo ni wọ́n máa jó?’ Àwọn ijó kan wà tó máa ń ru ìfẹ́ ọkàn láti ní ìbálòpọ̀ sókè. Tẹ́nì kan bá ń jó irú ijó yẹn tàbí tó ń wò ó, ṣéèyàn lè sọ pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń “sá fún àgbèrè.”—1 Kọ́ríńtì 6:18.
Bó bá wá jẹ́ pé ibi tí wọ́n ti máa ń jó ijó alẹ́ ni wọ́n pè ẹ́ sí ńkọ́? Gbọ́ ohun tí ọ̀dọ́ kan tó ti máa ń lọ sílé ijó kó tó di Kristẹni sọ, Shawn lorúkọ ẹ̀, ó sọ pé: “Orinkórin ni wọ́n máa ń kọ, ijó tí wọ́n máa ń jó máa ń mú kí ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà níbẹ̀ ló ní ìdí kan pàtó tí wọ́n fi wá.” Shawn sọ pé ìdí ti wọ́n sì fi wá ni láti rí ẹnì kan bá sùn lẹ́yìn tí wọ́n bá kúrò nílé ijó. Lẹ́yìn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ Shawn lẹ́kọ̀ọ́, ó yí ọkàn ẹ̀ pa dà. Ìmọ̀ràn ẹ̀ ni pé: “Ilé ijó ò yẹ Kristẹni.”
Ìdí Tó O Fi Gbọ́dọ̀ Wà Lójúfò
Ìgbà wo lo rò pé àwọn ọ̀tá lè rí ọmọ ogun kan mú, ìgbà tó wà lójú ogun ni àbí ìgbà tó bá ń gbafẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé kò ní fura nígbà tó bá ń gbafẹ́, ìgbà yẹn sì lọwọ́ àwọn ọ̀tá lè tẹ̀ ẹ́. Bọ́ràn tìẹ náà ṣe rí nìyẹn, o máa ń wà lójúfò láti fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù nígbà tó o bá wà níléèwé tàbí níbi iṣẹ́. O máa ń tètè mọ̀ bí ohun tó lè ba àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ bá fẹ́ wáyé. Àmọ́, ìgbà tó o bá ń gbádùn ara ẹ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ ló ṣeé ṣe kó o ṣìwà hù.
Àwọn kan lára àwọn ojúgbà ẹ lè fàbùkù kàn ẹ́ torí pé o máa ń fẹ́ fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù nígbà tó o bá ń gbafẹ́. Ó tiẹ̀ lè jẹ́ àwọn ọ̀dọ́ táwọn òbí wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló máa rí sí ẹ. Àmọ́, irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ ti dá àpá sí ẹ̀rí ọkàn wọn, ó sì ti gíràn-án. (1 Tímótì 4:2) Wọ́n lè máa sọ pé tìẹ ti pọ̀ jù tàbí pé olódodo àṣelékè ni ẹ́. Dípò ti wàá fi jẹ́ káwọn ojúgbà ẹ sọ ẹ́ dà bí wọ́n ṣe dà, ìwọ ṣáà “di ẹ̀rí-ọkàn rere mú.”—1 Pétérù 3:16.
Ohun tó jà jù ni ojú tí Jèhófà fi ń wò ẹ́, kì í ṣe ojú táwọn ojúgbà ẹ fi ń wò ẹ́! Bó bá sì ti di pé àwọn ọ̀rẹ́ ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí bú ẹ torí pé ò ń tẹ̀ lé ẹ̀rí ọkàn ẹ, á dáa kó o wá àwọn ọ̀rẹ́ míì. (Òwe 13:20) Má gbàgbé pé ìwọ ni wàá máa ṣọ́ ọ̀nà tó o gbà ń hùwà, kódà nígbà tó o bá ń gbádùn ara ẹ pàápàá.—Òwe 4:23.
KA PÚPỌ̀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 37, NÍNÚ APÁ KÌÍNÍ ÌWÉ YÌÍ
Àwòrán tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe ti wá pọ̀ nígboro báyìí, kò sì ṣòro láti rí. Kí lo lè ṣe tó ò fi ní máa bá wọn wò ó?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo orí 36, nínú Apá Kìíní ìwé yìí, fún àlàyé síwájú sí i.
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Máa yọ̀, ọ̀dọ́kùnrin, ní ìgbà èwe rẹ, . . . kí o sì máa rìn ní àwọn ọ̀nà ọkàn-àyà rẹ àti nínú àwọn ohun tí ojú rẹ bá rí. Ṣùgbọ́n mọ̀ pé ní tìtorí gbogbo ìwọ̀nyí ni Ọlọ́run tòótọ́ yóò ṣe mú ọ wá sínú ìdájọ́.”—Oníwàásù 11:9.
ÌMỌ̀RÀN
Béèrè lọ́wọ́ àwọn òbí ẹ bóyá ẹ lè ṣètò àwọn àkókò kan lóṣù tẹ́ ó máa pa tẹlifíṣọ̀n kẹ́ ẹ lè jọ gbádùn ara yín gẹ́gẹ́ bí ìdílé.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Apá pàtàkì ni ijó àti orin jẹ́ nínú ìjọsìn tòótọ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.—Sáàmù 150:4.
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Bí wọ́n bá pè mí láti wá dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn tó ń ṣeré ìdárayá lẹ́yìn iléèwé, màá sọ pé ․․․․․
Bí mo bá ti rí i pé fíìmù témi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi ń wò kò dára, màá ․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Kí nìdí tí kò fi yẹ káwọn Kristẹni máa ṣeré ìdárayá tó léwu?
● Báwo lo ṣe lè mọ̀ bí fíìmù kan bá dáa?
● Irú ijó wo lo máa kà sí èyí tó bojú mu?
[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 269]
“Ijó máa ń wù mí jó, àmọ́ mo ti kọ́ láti máa fetí sí ìmọ̀ràn àwọn òbí mi. Mi ò jẹ́ kí ijó wá di nǹkan bàbàrà nígbèésí ayé mi.”—Tina
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 268]
Ìgbà tọ́mọ ogun bá ń gbafẹ́ ni ọwọ́ àwọn ọ̀tá lè tẹ̀ ẹ́, ìgbà tíwọ náà bá ń gbádùn ara ẹ ló ṣeé ṣe kó o ṣìwà hù