ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 7/22 ojú ìwé 14-17
  • Kòtò Àfonífojì Ńlá Náà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kòtò Àfonífojì Ńlá Náà
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Adágún Kòtò Náà
  • Àwọn Ẹranko Lónírúurú Rẹpẹtẹ
  • Àwọn Alákòókiri Nínú Kòtò Náà
  • Adágún Victoria—Òkun Ńlá Tí Ilẹ̀ Yí Ká ní Áfíríkà
    Jí!—1998
  • “Ilẹ̀ Kan Tí Ó Dára Tí ó Sì Ní Àyè Gbígbòòrò”
    Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà
  • Dúró sí “Àfonífojì Àwọn Òkè Ńlá”
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
Jí!—1997
g97 7/22 ojú ìwé 14-17

Kòtò Àfonífojì Ńlá Náà

Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Kenya

YÀRÀ ńlá kan ni, kòtò kan tí ó gbòòrò lójú ilẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí a fi lè rí i láti ojú òṣùpá! Ó lọ láti Àfonífojì Jọ́dánì ní ìhà àríwá ilẹ̀ Ísírẹ́lì títí dé Mòsáḿbíìkì—6,400 kìlómítà tó ṣàrà ọ̀tọ̀—ó la púpọ̀ lára ìnà òró kọ́ńtínẹ́ǹtì ilẹ̀ Áfíríkà já.

Ní 1893, onímọ̀ nípa ilẹ̀ ayé àti àwọn ohun alààyè inú rẹ̀ náà, J. W. Gregory, tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Scotland, ṣèwádìí kíkúnrẹ́rẹ́ àkọ́kọ́ nípa ohun àrà inú ìṣẹ̀dá yìí. Gregory fòye mọ̀ pé kì í ṣe omi àti ẹ̀fúùfù tí ń gbá ilẹ̀ dà nù ló wa yàrà ńlá náà, bí kò ṣe “nípasẹ̀ àpáta tí ó rì lódindi nígbà tí ilẹ̀ tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ wà digbí láìmira.” (Fi wé Orin Dáfídì 104:8.) Ó pe àfọ́kù kíkàmàmà tí ó wà lójú ilẹ̀ ayé yìí ní Kòtò Àfonífojì Ńlá.

Títí di òní, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kò tí ì lóye àwọn ipá abẹ́lẹ̀ tí ó ṣẹ̀dá àfonífojì yí ní ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rúndún sẹ́yìn. Síbẹ̀síbẹ̀, onírúurú nǹkan tí a lè rí nínú rẹ̀ ń fa ènìyàn lọ́kàn mọ́ra. Apá ti ilẹ̀ Áfíríkà lára Kòtò Àfonífojì Ńlá náà, tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Etiópíà, ní ọ̀kan lára àwọn ibi ẹlẹ́rù jẹ̀jẹ̀ jù lọ lójú ilẹ̀ ayé, Ìjinkòtò Danakil (tí a tún mọ̀ sí Orígun Mẹ́ta ti Afar). Ìjìnwọnú oníyọ̀ ńlá yìí fara ti Òkun Pupa, ó sì jẹ́ aṣálẹ̀ tí ó fẹ̀ ní 150,000 kìlómítà níbùú lóròó. Ilẹ̀ ibí yìí jìn ní 120 mítà sísàlẹ̀ ojú òkun. Ìdíwọ̀n ìgbóná òun ìtutù lè lọ sókè dé ìwọ̀n kíkọyọyọ ti 54 lórí òṣùwọ̀n Celsius. Láti ibẹ̀ ni kòtò náà ti wọnú àwọn ibi gíga ti Etiópíà—tí ó ga ní ìwọ̀n 1,800 mítà lókè ìtẹ́jú òkun, níbi tí ṣóńṣó orí àwọn òkè ńláńlá ti ga tó 4,300 mítà. Àwọn igbó kìjikìji dídí bo àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ibi gíga ọlọ́ràá wọ̀nyí, wọ́n sì ń pèsè omi fún ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ odò, bíi Náìlì Aláwọ̀ Búlúù. Bí kòtò náà ti ń lọ síhà gúúsù sínú ẹ̀ka ìhà ìlà oòrùn rẹ̀, ó ń gòkè, ó sì ń sọ̀ lọ́nà gbígbàfiyèsí.

Àwọn òkè ayọnáyèéfín gíga tí ó ní onírúurú ìrísí àti ìtóbi àti àwọn kòtò kéékèèké tí ó pẹ̀ka ni ó fara kọ́ra lọ léteetí Kòtò Àfonífojì Ńlá náà. Nínú kòtò ìhà ìwọ̀ oòrùn, àwọn àsokọ́ra òkè ńláńlá ayọnáyèéfín kóra jọ, wọ́n sì di àwọn àfarakọ́ra òkè ńlá Ruwenzori àti Virunga tí ó wà gátagàta ní àwọn ẹnu ààlà Rwanda, Zaire, àti Uganda. Àwọn òkè kan ṣì ń fi àmì ìgbòkègbodò ooru abẹ́lẹ̀ hàn, tí wọ́n sì ń rú èéfín àti ìṣàn àpáta yíyòrò gbígbóná jáde. Nítòsí kòtò ìhà ìlà oòrùn, àwọn òkè ayọnáyèéfín ìgbàanì bíi Kilimanjaro àti Òkè Ńlá Kenya ga fíofío tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé láìka bí oòrùn ibi ìlà agbedeméjì òbìrí ayé ṣe ń mú hanhan tó sí, òjò dídì ló máa ń bo orí wọn. Àwọn orísun omi gbígbóná tí ń tú oruku àti omi tí ó gbóná kọjá ààlà jáde pẹ̀lú wà káàkiri ìnà Àfonífojì Kòtò náà, tí ń jẹ́rìí sí pákáǹléke tí ó ṣì wà nísàlẹ̀ lábẹ́ ojú ilẹ̀ lọ́hùn-ún.

Síwájú sí i níhà gúúsù, ní Tanzania, ilẹ̀ pápá ńlá kan bá àfonífojì náà pààlà. A ń pè é ní siringet lédè Masai, ọ̀rọ̀ kan tí ó túmọ̀ sí “àyè títẹ́jú gbalasa.” Lọ́nà tí ó sàn jù, a mọ̀ ọ́n sí Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Serengeti, ọ̀pọ̀ agbo ẹran ìgbẹ́ ni ewéko pápá rẹ̀ tí ó pọ̀ yanturu ń pèsè oúnjẹ fún. Ibí ni àgbàyanu ìṣíkiri èsúró gnu ti máa ń wáyé—ìṣẹ̀lẹ̀ àrímáleèlọ kan ní tòótọ́!

Àwọn Adágún Kòtò Náà

Níhà ìlà oòrùn Kòtò Àfonífojì Ńlá náà ní Áfíríkà ni ọ̀wọ́ àwọn adágún kan wà, tí ó ní iyọ̀. Àwọn kẹ́míkà wọ̀nyí ti ṣàn wá láti àwọn àgbègbè olókè ayọnáyèéfín tàbí wọ́n ti wọnú àwọn adágún náà nípasẹ̀ àwọn ìgbòkègbodò ayọnáyèéfín abẹ́ ilẹ̀. Àwọn adágún kan, bí Adágún Turkana ní àríwá Kenya, ní ìwọ̀n èròjà oníyọ̀ díẹ̀ nínú. Adágún Turkana tí ó wà láàárín aṣálẹ̀ dídá páropáro, tí ó jẹ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà níbùú lóròó, máa ń ní àwọ̀ ewéko tí ó ṣá nígbà míràn, inú rẹ̀ sì ni àwọn ọ̀nì tí ó pọ̀ jù lọ lágbàáyé ń gbé. Àwọn adágún bí Adágún Magadi ní Kenya àti Adágún Natron ní Tanzania ní iyọ̀ nínú tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ di ìṣùpọ̀ sódà tí eruku bò. Kí ni èrèdí rẹ̀? Àìsí ọ̀nà àbájáde kan tí ó lè fọ iyọ̀ náà lọ. Ọ̀pọ̀ jù lọ omi náà ń lọ nípa ìfàgbẹ, tí ń fi àgbájọ ńlá àwọn èròjà mineral sílẹ̀. Ìwọ̀nba ẹranko mélòó kan ló lè wà láàyè nínú àwọn omi kíkorò ti àwọn adágún onísódà ti Kòtò Àfonífojì náà. Bí ó ti wù kí ó rí, àyàfi kan tí ó gbàfiyèsí ni ti àwọn ẹlẹgẹ́ ẹyẹdò flamingo aláwọ̀ osùn tí ń lọ láti adágún onísódà kan sí òmíràn, tí ń jẹ àwọn èèhọ̀n tí kò ṣeé fojú lásán rí, tí ń gbé inú àwọn omi onísódà. Àwọn ẹyẹdò flamingo máa ń kóra jọ síhìn-ín ní àràádọ́ta ọ̀kẹ́, tí wọ́n wá ń dà bí òkun ohun alààyè tí ó ní àwọ̀ osùn.

Ohun mìíràn tí ó tún ń gbé inú àwọn omi tí a lè kà sí aṣekúpani wọ̀nyí ni àwọn ẹja tín-tìn-tín kan tí a ń pè ní tilapia grahami. A sábà máa ń rí ẹja tí èròjà oníyọ̀ kò rí gbé ṣe yìí nítòsí ibi àbáyọ ooru lábẹ́ omi, níbi tí omi ti máa ń gbóná tó bẹ́ẹ̀ tí kò bára dé láti fọwọ́ kàn án. Síbẹ̀, ẹja tíntínní yìí ń gbébẹ̀ ní jíjẹ èèhọ̀n inú adágún náà.

Iye kéréje kan péré lára àwọn adágún ìhà ìlà oòrùn kòtò náà ló ní omi aláìníyọ̀. Adágún Naivasha, ní Kenya, jẹ́ ọ̀kan. Ó wà ní 1,870 mítà lókè ìtẹ́jú òkun, omi rẹ̀ mímọ́ gaara sì jẹ́ ibùgbé fún onírúurú ẹja àti fún ọ̀wọ́ àwọn erinmi tí ń yáàrùn. Ní gbogbo bèbè rẹ̀ ni àwọn àgbègbè òrépèté àti àwọn ewéko odò títutù yọ̀yọ̀ wà, tí oríṣiríṣi irú ọ̀wọ́ ẹyẹ jíjojúnígbèsè tí ó lé ní 400 ń gbé inú wọn. Adágún Naivasha dára ní wíwò bí ó ti wà níbi tí igi acacia aláwọ̀ ìyeyè ti wà ní ọwọ́ ẹ̀yìn rẹ̀, tí àwọn àsokọ́ra òkè ńláńlá sì yí i ká.

Nínú kòtò àfonífojì náà ni omi aláìníyọ̀ tí ó tóbi jù lọ ṣìkejì lágbàáyé, Adágún Victoria, wà. Omi rẹ̀ bo àwọn etíkun Kenya, Uganda, àti Tanzania, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orísun Odò Náílì. Síwájú níhà gúúsù, omi Adágún Tanganyika jìn ní 1,440 mítà. Èyí ni adágún tí ó jinlẹ̀ jù lọ ṣìkejì lágbàáyé.

Àwọn Ẹranko Lónírúurú Rẹpẹtẹ

Kòtò Àfonífojì Ìlà Oòrùn Áfíríkà ní onírúurú rẹpẹtẹ ohun alààyè nínú. Àwọn ẹfọ̀n, àgùnfọn, ẹranko rhinoceros, àti erin jẹ́ díẹ̀ lára àwọn ẹranko afọ́mọlọ́mú ńláńlá tí ń yan fanda kiri láìsí ìdíwọ́ nínú àyè tí kò láàlà, inú igbó náà. Ní àwọn àgbègbè gbígbẹ tí kò lómi, a lè rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà, ẹtu oryx, àti àwọn ẹyẹ ògòǹgò. Àwọn ẹtu ọlọ́láńlá ń fò sókè fíofío bí wọ́n ṣe ń sáré la ilẹ̀ pápá náà já. Àwọn ológbò abàmìtótòtó bí àmọ̀tẹ́kùn àti ẹranko cheetah ń ṣọdẹ ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ gbalasa náà, a sì lè sábà máa gbọ́ bí kìnnìún ọlọ́láńlá ṣe ń bú ramúramù lóru. Ìnàkí orí òkè ńlá tí ó ṣọ̀wọ́n náà máa ń gbé òkè lórí àsokọ́ra òkè ńláńlá ti Virunga. Nísàlẹ̀ pátápátá lọ́hùn-ún, ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀ kòtò náà, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìrò rọra ń kọjá lọ ní ojú ilẹ̀ gbágungbàgun náà, tí wọ́n ń wá àwọn kòkòrò, àwọn hóró, àti àwọn àkekèé kiri. Àwọn idì àti igún lílágbára, tí wọ́n ní apá kíkàmàmà ń fò nínú afẹ́fẹ́ lílọ́wọ́ọ́wọ́ọ́, tàbí ìgbì afẹ́fẹ́ gbígbóná, bí wọ́n ti ń fò sókè láìlo ìyẹ́. Àwọn ẹyẹ touraco, ẹyẹ barbet, ẹyẹ hornbill, àti ayékòótọ́ tí wọ́n jojú ní gbèsè ń gbé ilẹ̀ títẹ́ pẹrẹsẹ tí ó ní àwọn igi tí kò fi bẹ́ẹ̀ ga. Àwọn aláǹgbá ní oríṣiríṣi ìrísí, ìtóbi, àti àwọ̀ ń sá káàkiri, bíi pé iná ń jó wọn lẹ́sẹ̀.

Àwọn Alákòókiri Nínú Kòtò Náà

Kòtò Àfonífojì Ìlà Oòrùn Áfíríkà náà jẹ́ ibùgbé àdánidá fún ọ̀pọ̀ ẹ̀yà tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ti aṣálẹ̀ tán, tí ń da ẹran, tí wọ́n sì ń ṣí kiri. Wọ́n jẹ́ alágbára ènìyàn tí ó máa ń bẹ́ gìjàgìjà nígbà tí wọ́n bá ń rìn lọ́nà kan náà tí àwọn aláṣìíkiri ará Áfíríkà ń gbà rìn. Ní àwọn àgbègbè tí òjò ti ṣọ̀wọ́n, odindi abúlé sábà máa ń kẹ́rù, wọ́n sì máa ń kó lọ ní wíwá ibùjẹ tuntun fún àwọn ohun ọ̀sìn wọn. Láìsí ìwé àṣẹ ìrìn àjò tàbí àṣẹ ìwọ̀lú, wọ́n ń ré kọjá àwọn ààlà orílẹ̀-èdè tí a kò sàmì sí náà láìsí ìdíwọ́, ó sì jọ pé wọ́n ti dágunlá sí ìlọsíwájú tí ń lọ níbòmíràn àti àwọn ọ̀nà ìgbésí ayé mìíràn. Ní àwọn àgbègbè jíjìnnà wọ̀nyí, ìgbésí ayé kì í yára lọ ní kánmọ́kánmọ́. Yíyọ àti wíwọ̀ oòrùn la fi ń ṣírò àkókò. Iye ràkúnmí, ewúrẹ́, màlúù, tàbí àgùntàn tí ẹnì kan bá ni, tàbí iye ọmọ tí ń bẹ lágbo ilé rẹ̀ ni a fi ń díwọ̀n bí ó ṣe lọ́lá tó.

Wọ́n kọ́ àwọn ilé wọn lọ́nà rírọrùn, ṣùgbọ́n tí ó fi ọgbọ́n ìhùmọ̀ hàn. Wọn ń tẹ àwọn ẹ̀ka igi, wọ́n sì ń so wọ́n pọ̀ láti ní ìrísí ilé olórùlé rìbìtì. Lẹ́yìn náà ni wọ́n wá ń fi kóóko tí a hun pọ̀, awọ ẹran, tàbí ẹrẹ̀ tí a pò pọ̀ mọ́ ìgbẹ́ màlúù bò ó níta. Irú ilé bẹ́ẹ̀ sábà máa ń ní iná ìseǹkan, àhámọ́ kékeré kan fún àwọn ẹran ọ̀sìn, àti bẹ́ẹ̀dì kan tí ó lè jẹ́ awọ ẹran kan lásán. Iná tí wọ́n dá sí ààrò ń fi èéfín kún inú ilé náà, kì í jẹ́ kí eṣinṣin tàbí ẹ̀fọn wà nínú ilé. Lọ́pọ̀ ìgbà, abúlé kan tàbí àwùjọ ìdílé kan yóò kọ́ ilé olórùlé rìbìtì wọn kéékèèké nínú agbo kan tí a kó àwọn ẹ̀ka igi ẹlẹ́gùn-ún tí kò ṣeé gba àárín wọn kọjá yí po, láti dáàbò bo àwọn ẹran ọ̀sìn wọn lọ́wọ́ àwọn ẹran ìgbẹ́ rírorò lóru.

Jákèjádò Kòtò Àfonífojì Ńlá náà ni a ń rí onírúurú ènìyàn tí ìrísí ojú, èdè, àti àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ síra ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀yà wọn àti ibi tí wọ́n ń gbé. Ìgbàgbọ́ ìsìn pẹ̀lú yàtọ̀ púpọ̀. Àwọn kan ti tẹ́wọ́ gba ẹ̀sìn Ìsìláàmù; àwọn mìíràn tẹ́wọ́ gba ìsìn Kristẹni aláfẹnujẹ́. Ọ̀pọ̀ ló gba ohun asán gbọ́, tí wọ́n sì ní ìtẹ̀sí láti sọ pé àwọn agbára tí ó ju ti ẹ̀dá lọ ló fa ohunkóhun tí wọn kò lè lóye. Ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́, ipá àtòdewá ti ń dé ọ̀pọ̀ lára àwọn àgbègbè jíjìnnà náà nípasẹ̀ àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ń pèsè ẹ̀kọ́ àti ìṣègùn.

Kò yani lẹ́nu pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pẹ̀lú ń sapá láti kàn sí àwọn alágbára aláṣìíkiri wọ̀nyí. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ń retí láti sọ wọ́n di ojúlùmọ̀ ìlérí Bíbélì nípa àkókò kan tí ẹnì kankan kì yóò ní láti máa wá ọ̀nà àtigbọ́bùkátà nínú ilẹ̀ yíyan. Bíbélì wí pé: “Aginjù àti ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà, pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ yóò sì kún fún ìdùnnú, yóò sì yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí sáfúrónì.” (Aísáyà 35:1, NW) Ní báyìí ná, Kòtò Àfonífojì Ńlá náà ṣì jẹ́ ohun àfiṣèrántí kan ní ti ìjónírúurú agbára ìṣẹ̀dá tí Olùṣẹ̀dá ohun gbogbo, Jèhófà Ọlọ́run, ní.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 14]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÍSÍRẸ́LÌ

ÍJÍBÍTÌ

SAUDI ARABIA

Òkun Pupa

YEMEN

Ìyawọlẹ̀ Omi ti Aden

ERITREA

SUDAN

UGANDA

RWANDA

BURUNDI

ZAIRE

ZAMBIA

MALAWI

DJIBOUTI

ETIÓPÍÀ

SOMALIA

KENYA

TANZANIA

MÒSÁḾBÍÌKÌ

[Credit Line]

Mountain High Maps® Copyright © 1995 Digital Wisdom, Inc.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Serengeti, ìṣẹ̀lẹ̀ àrímáleèlọ tòótọ́ kan máa ń wáyé—àgbàyanu ìṣíkiri ẹtu “gnu”

[Credit Line]

Nísàlẹ̀: © Index Stock Photography and John Dominis, 1989

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ẹyẹdò “flamingo” ń kóra jọ, bí òkun ohun alààyè tí ó ní àwọ̀ osùn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá àwọn ènìyàn tí ń gbé inú Kòtò Àfonífojì náà ṣàjọpín ìhìn iṣẹ́ Bíbélì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́