Adágún Victoria—Òkun Ńlá Tí Ilẹ̀ Yí Ká ní Áfíríkà
Láti Ọwọ́ Akọ̀ròyìn Jí! ní Kẹ́ńyà
NÍ ÀÁRÍN gbùngbùn ilẹ̀ Áfíríkà, ní ọdún 1858, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan dá rin inú ẹgàn kan tí a kò tíì ṣàyẹ̀wò rẹ̀ rí. Ìwọ̀nba àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ ìtọ́jú àyíká díẹ̀ ló wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìrìn àjò náà, bí àìsàn, àárẹ̀, àti àìdájú sì ti ń bá a fínra, ó rọ àwọn tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ láti tẹ̀ síwájú. John Hanning Speke ń wá ohun pàtàkì kan tí kò rọrùn láti rí—orísun odò Náílì.
Àwọn ọ̀rọ̀ tí Speke ti gbọ́ nípa omi ńlá kan tí ilẹ̀ yí ká, èyí tí àwọn olówò ẹrù ará Arébíà pè ní Ukerewe, ló sún un làkàkà láti la aginjù tó jọ pé kò lópin náà já. Níkẹyìn, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tí wọ́n ti ń rìn, àwùjọ àwọn arìnrìn-àjò kékeré náà rí ohun kíkàmàmà kan. Wọ́n rí òkun ńlá kan tí omi inú rẹ̀ kò níyọ̀, tí ó fẹ̀ dé ibi tí ojú lè rí mọ, tí ilẹ̀ yí i ká. Speke kọ̀wé lẹ́yìn náà pé: “Kò tún sí iyè méjì èyíkéyìí mọ́ lọ́kàn mi pé láti inú adágún tí mo kẹsẹ̀ bọ̀ náà ni odò pàtàkì yẹn, tí a ti sọ onírúurú nǹkan nípa orísun rẹ̀, tí ọ̀pọ̀ olùṣàwárí ti ń wá kiri, ti ṣàn wá.” Ó sọ ohun tí ó ṣàwárí náà ní orúkọ ọbabìnrin tó wà lórí oyè ní England nígbà náà—Victoria.
Orísun Odò Náílì
Lónìí, adágún tí ń jẹ́ orúkọ yẹn ṣì lókìkí gẹ́gẹ́ bí adágún olómi tí kò níyọ̀ tí ó tóbi ṣìkejì lágbàáyé—Adágún Superior, tó wà ní Àríwá Amẹ́ríkà, nìkan ló tóbi jù ú lọ. Bíi dígí gbígbórín kan tí ń kọ mànà nínú oòrùn ganrínganrín ibi ìlà agbedeméjì òbìrí ayé, ìtẹ́jú Adágún Victoria, tí ó jọ dígí náà, jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ta lé lẹ́gbẹ̀tàdínláàádọ́ta lé mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [69,484] kìlómítà níbùú lóròó. Níwọ̀n bí ìlà agbedeméjì ayé ti gba góńgó òkè rẹ̀ kọjá, tí ó sì wà láàárín apá ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn Àfonífojì Great Rift, ọ̀pọ̀ jù lọ lára rẹ̀ wọ inú Tanzania àti Uganda, ní ààlà ilẹ̀ Kẹ́ńyà.
Odò Kagera tó wà ní Tanzania, tí omi inú rẹ̀ ń wá láti àwọn òkè ńlá ní Rwanda, ni lájorí ibi tí omi ń gbà ṣàn wá sínú adágún náà. Àmọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ lára omi tí ń ṣàn wọnú Victoria ló jẹ́ omi òjò tí ń gbára jọ ní àyíká náà, tí àpapọ̀ rẹ̀ lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [200,000] kìlómítà níbùú lóròó. Ibì kan ṣoṣo tí omi ń bá ṣàn jáde wà ní Jinja, ní Uganda. Ibí yìí ni omi náà ti ṣàn lọ síhà àríwá, ó sì lọ di odò Náílì Funfun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Adágún Victoria nìkan kọ́ ni orísun Odò Náílì, ó ń ṣiṣẹ́ bí ìkudù ńlá kan, tí ń jẹ́ kí omi aláìníyọ̀ máa ṣàn lọ láìdúró, kí ó sì ní àwọn ohun abẹ̀mí nínú títí lọ dé Íjíbítì.
Ìgbésí Ayé Lórí Adágún Náà
Ọkọ̀ ọ̀pẹẹrẹ kan, tí ìgbòkun rẹ̀ funfun, tí ń fẹ́ lẹlẹ jọ ìyẹ́ labalábá nínàró kan, kọjá lórí òkun náà. Afẹ́fẹ́ ojoojúmọ́ tí ń wá láti ilẹ̀ àgbègbè náà gbá ọkọ̀ ojú omi kékeré náà lọ sí àárín gbùngbùn adágún náà. Nígbà tó máa fi di ọ̀sán, afẹ́fẹ́ náà yíwọ́ padà, ó sì gbé e padà sí ibi tó ti wá. Àwọn tí ń pẹja nínú omi yìí ti ń ṣe ohun kan náà bọ̀ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún.
Àwọn abúlé àti abà, tí wọ́n fi ewéko aláwọ̀ ilẹ̀ ṣe òrùlé ilé wọn, yí adágún Victoria ká. Ẹja ni lájorí oúnjẹ àwọn ará abúlé tí ń gbé àyíká Náílì, adágún náà ni wọ́n sì gbára lé fún ìpèsè oúnjẹ òòjọ́ wọn. Kí oòrùn tó ràn ni apẹja kan máa ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Àwọn ọkùnrin náà ń gbọ́n omi kúrò nínú ọkọ̀ ọ̀pẹẹrẹ wọn tí omi gba ibi tí ó dálu lára rẹ̀ wọlé, wọ́n sì ń gba ojú omi tí ìkùukùu bò náà lọ. Pẹ̀lú orin lẹ́nu, wọ́n ń tukọ̀ lọ síbi tí ó jindò gan-an, wọ́n sì ń ta ìgbòkun ọkọ̀ wọn tó ti gbó. Àwọn obìnrin sì ń wo bí àwọn ọkọ̀ ojú omi kéékèèké náà ṣe ń lọ síbi tí ó jọ pé ilẹ̀ òun òfuurufú ti pàdé tí wọn kò fi rí wọn mọ́ láti etíkun. Láìpẹ́, wọ́n yí padà nítorí pé iṣẹ́ pọ̀ nílẹ̀ tí wọ́n fẹ́ ṣe.
Bí àwọn ọmọdé ṣe ń ṣeré nínú omi tí kò jìn náà, tí wọ́n sì ń ta omi ni àwọn obìnrin ń fọ aṣọ, wọ́n ń pọnmi mímu nínú adágún náà. Níkẹyìn, wọ́n parí iṣẹ́ ní etí omi náà. Àwọn obìnrin pàǹtèté omi sórí gẹngẹ, wọ́n pọn ọmọ, wọ́n fa àwọn apẹ̀rẹ̀ aṣọ tí wọ́n ti fọ̀ lọ́wọ́ méjèèjì, wọ́n sì ń fẹ̀sọ̀ lọ sílé. Nílé, wọ́n ń bójú tó àwọn oko àgbàdo àti ti ẹ̀wà kéékèèké, wọ́n ń ṣa igi ìdáná, wọ́n sì ń fi àpòpọ̀ ìgbẹ́ màlúù àti eérú tún àwọn ilé wọn oníbàmùbàmù ṣe. Lọ́nà jíjìn ní etíkun náà, àwọn obìnrin ń lo òye wọn láti fi àwọn fọ́nrán hun okùn nínípọn àti apẹ̀rẹ̀ tí ó jojú ní gbèsè. A ń gbúròó àáké lára igi ńlá kan tí àwọn ọkùnrin mélòó kan fi ń gbẹ́ ọkọ̀.
Bí ọjọ́ ti ń rọ̀, ojú àwọn obìnrin tún yí sójú òkun fífẹ̀, tí omi rẹ̀ kò níyọ̀ náà. Ṣóńṣó orí àwọn ìgbòkun funfun náà tí ó yọ níbi tí ó jọ pé ilẹ̀ òun òfuurufú ti pàdé yóò jẹ́ àmì fún wọn pé àwọn ọkùnrin ti ń padà bọ̀. Wọ́n máa ń fojú wá a, pẹ̀lú ìháragàgà láti rí àwọn ọkọ wọn àti àwọn ẹja tí wọn óò kó bọ̀.
Ní gbogbo etí adágún náà àti àwọn erékùṣù rẹ̀, àwọn àwùjọ kéékèèké wọ̀nyí ń gba àwọn àlejò tí ń jíṣẹ́ àlàáfíà fún wọn. Wọ́n ń dé gbogbo abúlé àti abà, yálà ní fífẹsẹ̀rìn tàbí ní wíwọ ọkọ̀ ọ̀pẹẹrẹ. Onírẹ̀lẹ̀ ni àwọn ènìyàn náà, wọ́n sì ń fẹ́ láti fetí sílẹ̀. Inú wọn tún ń dùn láti ka àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí a tẹ̀ ní èdè Nilotic àti Bantu tí wọ́n ń sọ.
Àwọn Ohun Abẹ̀mí Inú Omi
Ó lé ní irínwó irú ọ̀wọ́ ẹja tó wà nínú Adágún Victoria, tí a kò sì lè rí àwọn kan lára wọn níbòmíràn lágbàáyé. Èyí tó wọ́pọ̀ jù lọ ni irú ọ̀wọ́ kan tí ń jẹ́ èpìyà. Àwọn ẹja kéékèèké, aláwọ̀ mèremère wọ̀nyí ní àwọn orúkọ àfijúwe bí ẹlẹ́yìn ọwọ́ iná, aláwọ̀ osùn fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, àti ẹlẹ́nu àkèré Kisumu. Àwọn èpìyà kan ní ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ tí wọ́n máa ń gbà dáàbò bo àwọn ọmọ wọn. Bí ewu bá ń bọ̀, ìyá ẹja yóò la ẹnu rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ kéékèèké yóò sì rọ́ síbi ààbò tí ó ṣí sílẹ̀ náà. Lẹ́yìn tí ewu náà bá kọjá, yóò kàn tún pọ̀ wọ́n ni, wọn óò sì máa bá ti wọn lọ bí ti tẹ́lẹ̀.
Adágún Victoria ni onírúurú ẹyẹ òkun tí ó rẹwà fi ṣe ilé. Àwọn ẹyẹ grebe, àgò, àti anhinga ń lúwẹ̀ẹ́ lábẹ́ omi, wọ́n sì ń fọgbọ́n sọ ẹja jẹ pẹ̀lú àgógó wọn ṣóńṣóṣóńṣó. Àwọn ẹyẹ crane, wádòwádò, àkọ̀, àti spoonbill ń rìn níbi tí kò jìn nínú omi, wọ́n ń dúró sójú kan láìmira bí wọ́n ti ń gbẹ́sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, ní fífi sùúrù dúró kí ẹja tí kò fura kan kọjá níbi tí wọ́n ti lè rọ́wọ́ bà á. Àwọn òfú ń fò ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ bí ọkọ̀ òfuurufú glider aláyà-fífẹ̀. Bí ọ̀wọ́ wọn bá ń lúwẹ̀ẹ́, wọ́n máa ń yí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ẹja po, wọn óò wá fi àgógó wọn ńlá tó dà bí apẹ̀rẹ̀ wọ́ wọn pọ̀. Ẹyẹ idì ajẹja, tòun ti ìyẹ́ rẹ̀ lílágbára, lọba lójú òfuurufú. Tí ó bá gbéra kúrò lórí ẹ̀ka igi kan tí ó yọrí sókè omi, yóò fò fẹ̀rẹ̀ tagbáratagbára lọ sílẹ̀ dòò tí ìyẹ́ rẹ̀ líle gba-n-di yóò sì mú afẹ́fẹ́ dún ṣìì, yóò sì gbé ẹja lójú adágún náà láìsí ìyọnu. Àwọn ẹyẹ ẹ̀gà aláwọ̀títàn ń gbé àárín àwọn ewé òrépèté dídí tí ó yí adágún náà ká, a sì ń gbọ́ igbe ẹyẹ hornbill nínú igbó igi bọn-ọ̀n-ní ní etídò lọ́hùn-ún.
Ní ọwọ́ òwúrọ̀ àti ìrọ̀lẹ́, híhan tí ń rinlẹ̀ tí àwọn erinmi máa ń han máa ń lọ jìnnà ré kọjá adágún píparọ́rọ́ náà. Tí ọjọ́ bá kanrí, wọ́n máa ń sùn sí etíkun, wọ́n sì máa ń fara jọ àfọ́kù àpáta aláwọ̀ eérú, tí ara rẹ̀ ń dán, tí ìdajì ara rẹ̀ wà nínú omi tí kò jìn. Ìgbà gbogbo ni àwọn ènìyàn àyíká adágún náà máa ń ṣọ́ra gidigidi nípa ọ̀nì líléwu inú odò Náílì. Díẹ̀ lára àwọn ẹ̀dá afàyàfà bíbanilẹ́rù wọ̀nyí ṣì wà ní àwọn ibi jíjìnnà nínú Adágún Victoria, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ni àwọn ènìyàn ti pa.
Omi Tí A Ń Yọ Lẹ́nu
Iye ènìyàn tó wà ní Áfíríkà ti pọ̀ sí i lẹ́yìn tí John Speke kọ́kọ́ rí adágún Victoria. Ó lé ní ọgbọ̀n mílíọ̀nù ènìyàn tí ń gbé àwọn etíkun adágún náà tí wọ́n wá gbára lé omi rẹ̀ tí kò níyọ̀ láti máa fi gbọ́ bùkátà wọn. Ní àwọn ìgbà tó ti kọjá, àwọn apẹja ládùúgbò gbára lé pípẹja lọ́nà àbáláyé. Pẹ̀lú ìgèrè lọ́wọ́, àwọ̀n tí wọ́n fi òrépèté ṣe, ìwọ̀, àti ọ̀kọ̀, wọ́n ń mú ohun tí wọ́n nílò. Lónìí tí a ń lo ọkọ̀ ojú omi afìwọ̀kẹ́ja àti àwọ̀n tí a fi ń mú ẹja lórí tí ó lè lọ jìnnà, kí ó sì kó ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ tọ́ọ̀nù ẹja nínú ibú omi, ìpẹjalápajù ń fewu wu àjọṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn.
Mímú àwọn irú ọ̀wọ́ ẹja wá láti ilẹ̀ òkèèrè ti ṣokùnfà àìwàdéédéé àjọṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn tí ó ti ba pípa ẹja jẹ́ ládùúgbò náà. Òṣíbàtà, oríṣi ewéko líléfòó kan tó máa ń yọ òdòdó aláwọ̀ àlùkò tí ó rẹwà, ń dá kún aburú tó ń ṣẹlẹ̀ sí adágún náà. Ewéko tí wọ́n mú wá láti Gúúsù Amẹ́ríkà náà ń yára hù débi tí ó fi kún bo ibi púpọ̀ ní etí adágún náà àti itọ́ rẹ̀, kì í sì í jẹ́ kí àwọn ọkọ̀ ojú omi akẹ́rù, ọkọ̀ ojú omi akérò, àti àwọn ọkọ̀ ọ̀pẹẹrẹ ti àwọn tí ń pẹja nínú omi náà lè gúnlẹ̀ sí etíkun àti èbúté. Pípa igbó àgbègbè adágún náà run, títú ìdọ̀tí dànù, àti ìgbékalẹ̀ ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ lápapọ̀ ń wu ọjọ́ iwájú adágún náà léwu.
Ǹjẹ́ Adágún Victoria yóò rù ú là? A ti ń ṣàṣàrò lórí ìbéèrè yẹn, kò sì sí ẹni tí ọ̀nà tí a óò gbà yanjú ìṣòro rẹ̀ dá lójú. Àmọ́, Adágún Victoria jẹ́ ohun àdánidá tí ó ṣeé ṣe kí ó máa wà nìṣó lórí ilẹ̀ ayé lẹ́yìn tí Ìjọba Ọlọ́run bá mú àwọn tí “ń run ilẹ̀ ayé” kúrò.—Ìṣípayá 11:18.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Ẹja Tí Ń Jẹ Adágún Náà Run
Òróró pọ̀ lára rẹ̀, ó ní ìwọra oúnjẹ, ó máa ń tètè pamọ rẹpẹtẹ, ó sì máa ń gùn tó ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà. Kí ni nǹkan náà? Ẹja lates niloticus! Ẹja ńlá oníwọra oúnjẹ, tí a kó wá sínú Adágún Victoria ní àwọn ọdún 1950 yìí, tí a mọ̀ níbi gbogbo sí ẹja ńlá perch odò Náílì, ti jẹ́ àgbákò fún àyíká náà. Láàárín ogójì ọdún, ó ti pa nǹkan bí ìdajì lára irínwó irú ọ̀wọ́ ẹja tí Ọlọ́run dá sínú adágún náà jẹ ráúráú. Ìpalápalù yìí ti fewu wu orísun oúnjẹ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ará àdúgbò tí wọ́n gbára lé àwọn ẹja èpìyà kéékèèké, àti àwọn ẹja inú odò náà mìíràn fún bíbọ́ àwọn ìdílé wọn. Àwọn ẹja kéékèèké wọ̀nyí ló tún jẹ́ kí àrùn máà sí nínú odò náà. Àwọn kan lára wọn máa ń jẹ òkòtó tí ń fa àrùn àtọ̀sí ajá tí gbogbo ènìyàn ń bẹ̀rù náà, ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ṣèrànwọ́ láti mú kí àwọn tí àrùn náà ń ṣe dín kù. Àwọn mìíràn ń jẹ àwọn èèhọ̀n àti àwọn ewédò mìíràn tí apá kò ká mọ́ nísinsìnyí. Apá tí kò ká híhù kọjá ààlà yìí ti fa kí afẹ́fẹ́ oxygen dín kù nínú omi náà nítorí ewéko jíjẹrà. Pẹ̀lú ìwọ̀nba àwọn ẹja tí Ọlọ́run dá sínú omi náà tí yóò palẹ̀ ìdọ̀tí yìí mọ́, àwọn “àyíká tí kò ti sí ohun abẹ̀mí,” nítorí tí kò sí afẹ́fẹ́ oxygen nínú omi náà, ti pọ̀ sí i, àwọn ẹja púpọ̀ sí i sì ń kú. Nítorí tí ẹja perch inú Náílì tí ebi máa ń fìgbà gbogbo pa kò fi bẹ́ẹ̀ rí àwọn ẹja jẹ mọ́, ó ti yíjú sí orísun oúnjẹ tuntun—àwọn ọmọ òun fúnra rẹ̀! Ẹja tí ń jẹ adágún náà run ti ń pilẹ̀ ewu jíjẹ ara rẹ̀ run nísinsìnyí!
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 25]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
UGANDA
KẸ́ŃYÀ
TANZANIA
ADÁGÚN VICTORIA
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Wíwàásù ní etí Adágún Victoria
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ẹ̀gà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]
Àwọn òfú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Àwọn lékeléke
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]
Ọ̀nì odò Náílì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]
Wádòwádò tó bà sẹ́yìn erinmi