Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Ní Láárí
BÍ Ọ̀RÀN bá di ti ọmọ títọ́, ibi gbogbo ni ọ̀pọ̀ òbí ń yíjú sí fún àwọn ojútùú tí ń bẹ lárọ̀ọ́wọ́tó nínú ilé wọn ní ti gidi. Àìníye ìdílé ní Bíbélì, àmọ́ ńṣe ni eruku ń bò ó níbi ìkówèésí dípò kí wọ́n lò ó ní títọ́ ọmọ.
Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ní ń ṣiyè méjì lónìí nípa lílo Bíbélì gẹ́gẹ́ bí amọ̀nà nínú ìgbésí ayé ìdílé. Wọ́n kà á sí ìwé tí kò bágbà mu, tí a gbé karí àṣà àtijọ́, tàbí tí ó le koko jù. Ṣùgbọ́n àyẹ̀wò àìlábòsí yóò fi hàn pé Bíbélì jẹ́ ìwé tó gbéṣẹ́ fún àwọn ìdílé. Ẹ jẹ́ kí a wo bí ó ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀.
Àyíká Yíyẹ
Bíbélì sọ fún bàbá pé kí ó máa wo àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “àwọn àgélọ́ igi ólífì yí tábìlì [rẹ̀] ká.” (Orin Dáfídì 128:3, 4, NW) Àwọn kògbókògbó igi kéékèèké kò ní dàgbà di igi eléso láìsí ìtọ́jú àfìṣọ́raṣe, láìfún wọn ní ọ̀rá, ilẹ̀, àti ọ̀rinrin tí ó yẹ. Bákan náà, títọ́mọ lọ́nà aláṣeyọrí ń gba iṣẹ́ àti àbójútó. Àwọn ọmọ nílò àyíká gbígbámúṣé, kí wọ́n lè dàgbà di géńdé.
Èròjà àkọ́kọ́ fún irú àyíká bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́—láàárín àwọn tọkọtaya àti láàárín àwọn òbí àti àwọn ọmọ. (Éfésù 5:33; Títù 2:4) Ọ̀pọ̀ mẹ́ńbà ìdílé nífẹ̀ẹ́ ẹnì kíní kejì, ṣùgbọ́n wọn kò rí ìdí láti sọ irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ jáde. Bí ó ti wù kí ó rí, ronú ná pé: Ǹjẹ́ o lè sọ ní tòótọ́ pé o bá ọ̀rẹ́ kan sọ̀rọ̀ bí o bá kọ àwọn lẹ́tà, tí o kò kọ àdírẹ́sì sára wọn, tí o kò lẹ sítáǹpù mọ́ wọn, tàbí tí o kò fi wọ́n ránṣẹ́ sí i? Bákan náà, Bíbélì fi hàn pé ìfẹ́ tòótọ́ ju ìmọ̀lára tí ń ta ọkàn àyà jí lásán lọ; ó ń fi ara rẹ̀ hàn nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe. (Fi wé Jòhánù 14:15 àti Jòhánù Kíní 5:3.) Ọlọ́run fi àpẹẹrẹ lélẹ̀, ó sọ ìfẹ́ rẹ̀ fún Ọmọkùnrin rẹ̀ jáde pé: “Èyí ni Ọmọkùnrin mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti fi ojú rere tẹ́wọ́ gbà.”—Mátíù 3:17.
Ìgbóríyìnfúnni
Báwo ni àwọn òbí ṣe lè fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn sí àwọn ọmọ wọn? Láti bẹ̀rẹ̀, máa wa ohun dídára. Ó rọrùn láti rí àṣìṣe àwọn ọmọdé. Àìdàgbàdénú wọn, àìnírìírí wọn, àti ìmọtara-ẹni-nìkan wọn yóò fara hàn lọ́nà púpọ̀, lójoojúmọ́. (Òwe 22:15) Ṣùgbọ́n wọn yóò ṣe ọ̀pọ̀ ohun rere lóòjọ́. Èwo ni ìwọ yóò pàfiyèsí sí? Ọlọ́run kì í nú ẹnu mọ́ àwọn àṣìṣe wa, ṣùgbọ́n ó ń rántí àwọn ohun rere tí a ṣe. (Orin Dáfídì 130:3; Hébérù 6:10) A gbọ́dọ̀ máa bá àwọn ọmọ wa lò lọ́nà kan náà.
Ọ̀dọ́mọkùnrin kan sọ pé: “Fún gbogbo ìgbésí ayé mi nílé, n kò lè rántí ìgbà kankan tí a gbóríyìn fún mi—yálà nítorí àṣeyọrí nínú ilé tàbí ní ilé ẹ̀kọ́.” Ẹ̀yin òbí, ẹ má ṣe ṣá àìní pàtàkì tí àwọn ọmọ yín ní yìí tì! A gbọ́dọ̀ máa gbóríyìn fún gbogbo àwọn ọmọ déédéé nítorí àwọn ohun rere tí wọ́n ń ṣe. Ìyẹn yóò dín ewu pé kí wọ́n “sorí kodò” bí wọ́n ṣe ń dàgbà, ní níní ìdánilójú pé kò sí ohun tí wọ́n lè ṣe tí yóò dára tó kù.—Kólósè 3:21.
Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀
Ọ̀nà dídára mìíràn láti fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ọmọ rẹ ni láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn inú Jákọ́bù 1:19 pé: “Yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” Ìwọ ha máa ń lu àwọn ọmọ rẹ lẹ́nu gbọ́rọ̀, kí o sì tẹ́tí sí ohun tí wọ́n ní láti sọ ní gidi bí? Bí àwọn ọmọ rẹ bá mọ̀ pé kí àwọn tó parí ọ̀rọ̀ pàápàá, ìwọ yóò bá àwọn wí, tàbí pé inú yóò bí ọ bí o bá mọ ìmọ̀lára àwọn ní gidi, wọ́n lè má sọ àwọn ìmọ̀lára wọn jáde. Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá mọ̀ pé ìwọ yóò tẹ́tí sí àwọn ní tòótọ́, ó túbọ̀ ṣeé ṣe pé wọn yóò finú hàn ọ́.—Fi wé Òwe 20:5.
Síbẹ̀síbẹ̀, bí wọ́n bá fi ìmọ̀lára tí ìwọ mọ̀ pé kò tọ̀nà hàn ńkọ́? Ṣé àkókò láti fìbínú dáhùn, láti báni wí, tàbí láti jẹni níyà nìyẹn? A gbà pé àwọn ìbújáde ọmọdé mélòó kan lè mú kí ó ṣòro láti “lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” Ṣùgbọ́n, tún gbé àpẹẹrẹ ti Ọlọ́run àti àwọn ọmọ rẹ̀ yẹ̀ wò lẹ́ẹ̀kan sí i. Òun ha dá àyíká ìbẹ̀rù oníjìnnìjìnnì kan sílẹ̀, kí ẹ̀rù lè máa ba àwọn ọmọ rẹ̀ láti sọ ìmọ̀lára wọn ní gidi fún un bí? Rárá! Orin Dáfídì 62:8 (NW) sọ pé: “Ẹ gbẹ́kẹ̀ lé [Ọlọ́run] ní gbogbo ìgbà. Ẹ tú ọkàn àyà yín jáde níwájú rẹ̀. Ọlọ́run jẹ́ ibi ìsádi fún wa.”
Nítorí náà, nígbà tí Ábúráhámù dààmú nípa ìpinnu Ọlọ́run láti pa àwọn ìlú ńlá Sódómù àti Gòmórà run, kò lọ́ra láti sọ fún Bàbá rẹ̀ ọ̀run pé: “Kò ṣeé ronú kàn nípa rẹ pé o ń gbé ìgbésẹ̀ ní irú ọ̀nà yí . . . Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé kì yóò ha ṣe ohun tí ó tọ́ bí?” Jèhófà kò fìkanra bá Ábúráhámù wí; Ó tẹ́tí sí i, Ó sì fọkàn rẹ̀ balẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 18:20-33, NW) Ọlọ́run ní sùúrù, ó sì ṣe pẹ̀lẹ́ lọ́nà gbígbàfiyèsí, kódà nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ bá sọ àwọn ìmọ̀lára tí kò ṣeé dá láre tàbí tí kò bọ́gbọ́n mu jáde pàápàá.—Jónà 3:10–4:11.
Lọ́nà kan náà, àwọn òbí ní láti ṣẹ̀dá àyíká kan, tí àwọn ọmọ kò ti ní bẹ̀rù láti sọ àwọn ìmọ̀lára wọn inú lọ́hùn-ún jáde, bí ó ti wù kí ìwọ̀nyí máa dani láàmú tó. Nítorí náà, bí ọmọ rẹ bá bú jáde láìsí ìmọ̀lára ìbínú, tẹ́tí sí i. Kàkà kí o fìbínú bá a wí, jẹ́wọ́ ìjóòótọ́ ìmọ̀lára ọmọ náà, kí o sì wádìí ohun tó fà á. Bí àpẹẹrẹ, o lè wí pé: ‘Ó jọ pé inú ń bí ọ sí lágbájá. Ǹjẹ́ o fẹ́ láti sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún mi?’
Kíkápá Ìbínú
Ó dájú pé kò sí òbí tí ó ní sùúrù tó Jèhófà. Àwọn ọmọ sì lè tán àwọn òbí wọn ní sùúrù. Bí inú bá ń bí ọ sí àwọn ọmọ rẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, má ṣe dààmú pé èyí ń sọ ọ́ di òbíkóbìí. Nígbà kọ̀ọ̀kan, ìbínú rẹ yóò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ gan-an. Ìbínú Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sí àwọn ọmọ rẹ̀, kódà, àwọn kan tí ó ṣọ̀wọ́n sí i gidigidi, máa ń lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. (Ẹ́kísódù 4:14; Diutarónómì 34:10) Síbẹ̀síbẹ̀, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kọ́ wa pé kí a máa kápá ìbínú wa.—Éfésù 4:26.
Báwo? Nígbà míràn, ó máa ń ṣàǹfààní pé kí o yí kókó ọ̀rọ̀ náà pa dà, kí ìbínú rẹ lè ráyè rọlẹ̀. (Òwe 17:14) Sì rántí pé, Ọmọdé ni! Má ṣe retí kí ó hùwà bí àgbàlagbà tàbí kí ó ronú bíi géńdé. (Kọ́ríńtì Kíní 13:11) Lílóye ìdí tí ọmọ rẹ fi ń hùwà lọ́nà kan lè mú kí ìbínú rẹ rọ̀. (Òwe 19:11) Má ṣe gbàgbé ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ tí ó wà láàárín ṣíṣe ohun kan tí ó burú àti jíjẹ́ ènìyàn búburú. Pípe ọmọ kan ní ọmọ burúkú lè mú kí ọmọ náà ronú pé, ‘Èé ṣe tí òun tilẹ̀ fi ń gbìyànjú láti ṣe ohun tí ó dára?’ Ṣùgbọ́n bíbá ọmọdé kan wí tìfẹ́tìfẹ́ yóò ran ọmọ náà lọ́wọ́ láti ṣe dáradára nígbà míràn.
Pípa Ìwàlétòlétò àti Ọ̀wọ̀ Mọ́
Ọ̀kan lára àwọn ìpèníjà ńlá tí àwọn òbí ń kojú ni kíkọ́ àwọn ọmọ láti wà létòlétò, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fúnni. Nínú ayé ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ òde òní, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń ṣe kàyéfì nípa bóyá ó tilẹ̀ tọ́ láti pààlà fún àwọn ọmọ wọn lọ́nàkọnà. Bíbélì dáhùn pé: “Ọ̀pá àti ìbáwí àfitọ́nisọ́nà ni ohun tí ń fúnni ní ọgbọ́n; ṣùgbọ́n ọmọdékùnrin tí a jọ̀wọ́ rẹ̀ sílẹ̀ fàlàlà yóò máa kó ìtìjú bá ìyá rẹ̀.” (Òwe 29:15, NW) Àwọn kan ń yẹra fún ọ̀rọ̀ náà, “ọ̀pá,” ní ríronú pé ó túmọ̀ sí ọ̀nà ìjọmọdéníyà kan. Àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ èdè Hébérù fún “ọ̀pá” tọ́ka sí ọ̀pá ìtìlẹ̀ kan, irú èyí tí olùṣọ́ àgùntàn kan ń fi darí àwọn àgùntàn rẹ̀—kì í ṣe láti fi lù wọ́n.a Nítorí náà, ọ̀pá ń ṣojú fún ìbáwí.
Nínú Bíbélì, láti báni wí nípìlẹ̀ túmọ̀ sí láti kọ́ni. Ìdí nìyẹn tí ìwé Òwe fi sọ ní ìgbà mẹ́rin pé, ‘fetí sílẹ̀ sí ìbáwí.’ (Òwe 1:8; 4:1; 8:33; 19:27) Ó yẹ kí àwọn ọmọ kẹ́kọ̀ọ́ pé ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ń mú ẹ̀san rere wá, ṣíṣe ohun búburú sì ń mú àbájáde búburú wá. Ìjẹniníyà lè ṣèrànwọ́ láti tẹ ìbáwí nítorí ìwà búburú mọ́ni lọ́kàn, lọ́nà kan náà tí ẹ̀san rere—bí ìgbóríyìnfúnni—lè gbà tẹ ìwà rere mọ́ni lọ́kàn. (Fi wé Diutarónómì 11:26-28.) O dára kí àwọn òbí fara wé àpẹẹrẹ Ọlọ́run nígbà tí ó bá kan ọ̀ràn ìjẹniníyà, nítorí tí ó sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé òun yóò nà wọ́n “dé ìwọ̀n tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Jeremáyà 46:28, NW) Ọ̀rọ̀ líle díẹ̀ ti tó láti mú kí àwọn ọmọ kan hùwà títọ́. Àwọn mìíràn nílò ọwọ́ líle díẹ̀. Ṣùgbọ́n nínani “dé ìwọ̀n tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu” kì yóò ní ohunkóhun tí ó lè ṣe ọmọ kan níjàǹbá ti ìmọ̀lára tàbí ti ara nínú láé.
Ìbáwí tí ó wà déédéé gbọ́dọ̀ ní kíkọ́ àwọn ọmọ nípa àwọn ààlà àti òpin nínú. A la ọ̀pọ̀ lára àwọn wọ̀nyí lẹ́sẹẹsẹ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bíbélì kọ́ni ní ọ̀wọ̀ fún àwọn ààlà tí ó yí ohun ìní ara ẹni ká. (Diutarónómì 19:14) Ó pààlà tí ó ṣeé rí, tí ó mú kí ó ṣàìtọ́ láti nífẹ̀ẹ́ sí ìwà ipá tàbí láti mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ẹlòmíràn ní ìjàǹbá. (Orin Dáfídì 11:5; Mátíù 7:12) Ó pààlà ìbálòpọ̀, ní dídẹ́bi fún ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan. (Léfítíkù 18:6-18) Ó tilẹ̀ tún sọ nípa àwọn ààlà ara ẹni àti ti ìmọ̀lára, ní kíkà á léèwọ̀ fúnni láti pe ẹnì kan lórúkọ burúkú tàbí bíbú èébú. (Mátíù 5:22) Kíkọ́ àwọn ọmọ nípa àwọn òpin àti ààlà wọ̀nyí—nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ àti àpẹẹrẹ—ṣe kókó láti ṣẹ̀dá àyíká ìdílé gbígbámúṣé.
Kókó pàtàkì míràn fún pípa ìwàlétòlétò àti ọ̀wọ̀ mọ́ nínú ìdílé sinmi lé mímọ ipa ẹni nínú ìdílé. Nínú ọ̀pọ̀ ìdílé lónìí, irú ipa bẹ́ẹ̀ kò ṣe kedere tàbí pé ó dojú rú. Nínú àwọn mìíràn, òbí kan yóò tú kẹ̀kẹ́ àwọn ìṣòro kàǹkàkanka sílẹ̀ fún ọmọdé kan, àwọn ìṣòro tí ọmọdé náà kò tóótun láti bójú tó. Nínú àwọn mìíràn, wọ́n fàyè gba àwọn ọmọdé láti di mọ́gàjí kéékèèké, tí ń ṣe ìpinnu fún ìdílé lódindi. Irú ìyẹn kò tọ́, ó sì ń pani lára. Àwọn òbí ní àìgbọdọ̀máṣe láti pèsè ohun tí àwọn ọmọ wọn kéékèèké ṣaláìní—yálà ní ti ara, ní ti ìmọ̀lára, tàbí ní ti ẹ̀mí—kì í ṣe iṣẹ́ àwọn ọmọ láti pèsè fún àwọn òbí. (Kọ́ríńtì Kejì 12:14; Tímótì Kíní 5:8) Ṣàgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ ti Jékọ́bù, tí ó ṣàtúnṣe sí bí ìdílé rẹ̀ lódindi àti àwọn alábàárìn rẹ̀ ṣe ń yára rìn tó, kí ó má baà ni àwọn ọmọ kéékèèké lára. Ó mọ ibi tí agbára wọn mọ, ó sì gbégbèésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 33:13, 14.
Bíbójútó Àwọn Àìní Tẹ̀mí
Kò sí ohun tí ó ṣe pàtàkì ju ipò tẹ̀mí lọ fún àyíká ìdílé gbígbámúṣé. (Mátíù 5:3) Àwọn ọmọdé ní agbára púpọ̀ fún ipò tẹ̀mí. Ìbéèrè pọ̀ lẹ́nu wọn: Èé ṣe tí a fi wà? Ta ló ṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé àti àwọn ẹranko, igi, òkun tí ó wà níbẹ̀? Èé ṣe tí ènìyàn fi ń kú? Kí ní ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Èé ṣe tí àwọn ohun búburú fi ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn rere? Ó jọ pé àwọn ìbéèrè náà kò lópin. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn òbí ló máa ń yàn láti má ronú nípa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀.b
Bíbélì rọ àwọn òbí láti lo àkókò ní fífún àwọn ọmọ wọn ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tẹ̀mí. Ó ṣàpèjúwe irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ ní lílo àwọn ọ̀rọ̀ ọlọ́yàyà gẹ́gẹ́ bí ìjíròrò tí ń bá a lọ láàárín àwọn òbí àti àwọn ọmọ. Àwọn òbí lè máa kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá jọ ń rìn, tí wọ́n jọ jókòó nínú ilé, nígbà tí wọ́n fẹ́ sùn—nígbàkigbà tó bá ṣeé ṣe.—Diutarónómì 6:6, 7; Éfésù 6:4.
Bíbélì ṣe ju dídámọ̀ràn irú ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ lọ. Ó pèsè àwọn ohun ìkọ́ni tí ìwọ yóò nílò pẹ̀lú. Àbí, báwo ni ìwọ yóò ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè tí àwọn ọmọdé ń béèrè tí a mẹ́nu bà lókè? Àwọn ìdáhùn náà wà nínú Bíbélì. Wọ́n ṣe kedere, wọ́n fani lọ́kàn mọ́ra, wọ́n sì fúnni ní ìrètí gidigidi nínú ayé aláìnírètí yìí. Èyí tí ó tún sàn ju ìyẹn lọ ni pé níní ọgbọ́n Bíbélì lè fún àwọn ọmọ rẹ ní ìtìlẹ́yìn lílágbára jù lọ, ìtọ́sọ́nà dídájú jù lọ nínú àwọn àkókò ìdàrúdàpọ̀ òde òní. Fi ìyẹn fún wọn, wọn yóò sì ní láárí ní gidi—nísinsìnyí àti ní ọjọ́ iwájú.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Jí!, September 8, 1992, ojú ìwé 26 àti 27.
b A pilẹ̀ ṣe ìwé náà, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ni, ó sì ní ọ̀pọ̀ ìtọ́sọ́nà gbígbéṣẹ́ láti inú Bíbélì lórí ìgbéyàwó àti ọmọ títọ́ nínú. Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ló ṣe é jáde.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]
Wá ọ̀nà kan tí o fi lè máà gbóríyìn pàtó fún ọmọ rẹ déédéé
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]
Bí A Ṣe Lè Ran Àwọn Ọmọdé Lọ́wọ́ Láti Ní Láárí
• Pèsè àyíká aláàbò fún wọn, nínú èyí tí wọ́n ti ń nímọ̀lára pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn, a sì nílò àwọn
• Máa gbóríyìn fún wọn déédéé. Máa ṣe pàtó
• Jẹ́ olùtẹ́tísílẹ̀ rere
• Jáwọ́ lára ọ̀ràn nígbà tí ìbínú bá ru sókè
• Fi àwọn ààlà àti òpin ṣíṣekedere, tí ó wà déédéé lélẹ̀
• Mú kí ìbáwí bá àìní ọmọ kọ̀ọ̀kan mu
• Má ṣe retí ju bí ó ṣe yẹ lọ lọ́dọ̀ ọmọ rẹ
• Bójú tó àwọn àìní tẹ̀mí nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 10]
Tipẹ́tipẹ́ Ṣáájú
ÀWỌN ìlànà inú Bíbélì ran àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì ìgbàanì lọ́wọ́ láti gbádùn ipò ìgbésí ayé ìdílé tí ó ga lọ́lá gan-an ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká lọ. Òpìtàn Alfred Edersheim sọ pé: “Ní ti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí Ísírẹ́lì ká, kò jọ pé a lè sọ pé ìgbésí ayé ìdílé kankan wà, tàbí pé ìdílé wà, ní bí a ti lóye àwọn èdè ọ̀rọ̀ náà sí.” Bí àpẹẹrẹ, láàárín àwọn ará Róòmù ìgbàanì, òfin fún bàbá ní agbára láìkùsíbìkan nínú ìdílé. Ó lè ta àwọn ọmọ rẹ̀ sí oko ẹrú, kí ó mú kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ bí alágbàṣe, tàbí kí ó tilẹ̀ pa wọ́n pàápàá—tí ohun kankan kò sì ní tẹ̀yìn rẹ̀ yọ.
Àwọn ará Róòmù kan rò pé àwọn Júù jẹ́ ènìyàn àrà ọ̀tọ̀ nítorí bí wọ́n ṣe ń bá àwọn ọmọ wọn lò ní jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Ní gidi, òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Róòmù ní ọ̀rúndún kìíní náà, Tacitus, kọ àkọsílẹ̀ onírìíra kan nípa àwọn Júù, ní sísọ pé àṣà ìbílẹ̀ wọn jẹ́ “ìdorí-àṣà-kodò àti akóni-nírìíra nígbà kan náà.” Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í to “àwọn àṣà ìbílẹ̀” bẹ́ẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ. Ó fi kún un pé: “Ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ láàárín wọn láti pa ọmọ èyíkéyìí tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí.”
Bíbélì pèsè ìlànà tí ó ga lọ́lá púpọ̀ gan-an. Ó kọ́ àwọn Júù pé àwọn ọmọ ṣe iyebíye—ní gidi, a gbọ́dọ̀ wò wọ́n bí ogún kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fúnra rẹ̀—kí a sì bá wọn lò lọ́nà bẹ́ẹ̀. (Orin Dáfídì 127:3) Ó ṣe kedere pé ọ̀pọ̀ lára wọn tẹ̀ lé irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Kódà èdè wọn ń fi irú èyí hàn. Edersheim ṣàkíyèsí pé, yàtọ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, èdè Hébérù ìgbàanì ní ọ̀rọ̀ mẹ́sàn-án fún àwọn ọmọdé, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan ń tọ́ka sí àwọn ìpele ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ìgbésí ayé. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ kan wà fún ọmọ tí ó ṣì wà lẹ́nu ọmú, òmíràn sì wà fún èyí tí a ti já lẹ́nu ọmú. Fún àwọn ọmọ tí ó fi díẹ̀ dàgbà jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọ̀rọ̀ kan wà tí ó fi hàn pé àwọn wọ̀nyí ti ń fẹsẹ̀ múlẹ̀, wọ́n sì ti ń lágbára. Fún àwọn èwe tí ó túbọ̀ dàgbà sí i, ọ̀rọ̀ míràn wà tí ó túmọ̀ ní olówuuru sí ‘jíjá ara ẹni gbà dòmìnira.’ Edersheim wí pé: “Dájúdájú, àwọn tí wọ́n ṣọ́ ìgbésí ayé ọmọdé jinlẹ̀ débi tí wọ́n fi ń fún ìgbésẹ̀ ìdàgbà kọ̀ọ̀kan lórúkọ tó fi bó ṣe rí hàn gbọ́dọ̀ ti ní ìsopọ̀ onífẹ̀ẹ́ni pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn.”