ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 9/22 ojú ìwé 15-17
  • Cheetah—Ẹranko Ẹ̀yà Ológbò Tó Yára Jù Lọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Cheetah—Ẹranko Ẹ̀yà Ológbò Tó Yára Jù Lọ
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹranko Ẹ̀yà Ológbò Yíyára
  • Ẹwà Alámì Tóótòòtó
  • Ìtọ́jú Tí Òbí Ẹranko Ẹ̀yà Ológbò Ń Fún Ọmọ
  • A Ń Dọdẹ Ọdẹ Náà
  • Àgbà Ayárasáré
    Jí!—1996
  • Kìnnìún—Olóólàajù Abigọ̀gọ̀ Ti Ilẹ̀ Áfíríkà
    Jí!—1999
  • Ahọ́n Ológbò
    Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
  • Ẹkùn! Ẹkùn!
    Jí!—1996
Jí!—1997
g97 9/22 ojú ìwé 15-17

Cheetah—Ẹranko Ẹ̀yà Ológbò Tó Yára Jù Lọ

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ KẸ́ŃYÀ

OORU náà ń mú ṣáá ní ọ̀dàn tí oòrùn ti ń mú hánhán náà. A tẹjú àwọn awò awọ̀nàjíjìn wa mọ́ agbo àwọn ẹtu tí ẹ̀gbẹ́ wọn tó nílà olómi wúrà ń dán nínú ìtànṣán oòrùn tí ń lọ wọ̀ náà. Lórí ilé ikán kan tí kò jìnnà, alákìíyèsí kan tún lúgọ, ó sì ń wo ìhà ọ̀dọ̀ àwọn ẹtu náà. Ó jẹ́ ẹranko ẹ̀yà ológbò alámì tóótòòtó kan pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀. Ó tẹ àwọn ojú rẹ̀ aláwọ̀ ìyeyè òun àwọ̀ ilẹ̀ mọ́ ìran náà. Lójijì, ó fa àwọn iṣan ara rẹ̀ ro, ó sì rọra dìde, ó forí lé ìhà agbo ẹran náà. Ó jọ pé àwọn ọmọ rẹ̀ mọ̀ pé àwọn ní láti dúró de ìpadàbọ̀ rẹ̀.

Tìṣọ́ratìṣọ́ra, ó tẹ̀ síwájú, ní fífi ara pa mọ́ sẹ́yìn ìgbẹ́ kéékèèké àti ìṣùpọ̀ èèhù koríko gígùn. Ó ń yọ́ mìrọ́ pẹ̀lú ìdánilójú. Bí ó ti dé nǹkan bí 200 mítà sí ohun ọdẹ rẹ̀, ó dúró lójijì. Ọ̀kan lára àwọn ẹtu náà ti gbójú sókè wo ìhà ọ̀dọ̀ rẹ̀; lẹ́yìn náà, ó tún ń jẹun lọ. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ó tún ń sún mọ́ wọn. Ó sún mọ́ àwọn ẹran tí kò fura náà tó 50 mítà kí ó tó pinnu láti sáré. Bí ìgbà tí a jáwọ́ irin lílọ́ kan lójijì, ó bẹ́ gìjà sínú ìmọ́lẹ̀ tí ń wọ̀ọ̀kùn lọ náà. Agbo àwọn ẹtu náà tú ká pẹ̀ẹ́, àmọ́ ẹranko ẹ̀yà ológbò náà kò mú ojú rẹ̀ kúrò lára ohun ọdẹ tó ń fojú sùn. Ó sáré la pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà já, ó sì ń sún mọ́ ẹtu tí ẹsẹ̀ rẹ̀ yá náà sí i.

Ẹranko tí ẹ̀rù bà náà bẹ́ síhìn-ín sọ́hùn-ún láti yẹ ẹni tí ń lé e sílẹ̀, ṣùgbọ́n àrékérekè ìyẹǹkansílẹ̀ rẹ̀ kò tó ìyára bíi mànàmáná ẹranko ẹ̀yà ológbò náà. Nígbà tí ó wà ní nǹkan bíi mítà kan sí ẹran ọdẹ rẹ̀, ó nawọ́ iwájú láti kọ ẹran ọdẹ tí ó fojú sùn náà lẹ́sẹ̀. Nígbà yẹn, ó yẹ̀ gẹ̀rẹ̀ ṣubú. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, a kò rí ẹtu náà mọ́.

Bí ó ti ń mí lókèlókè, ẹranko cheetah náà dẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́, ó dúró, ó jókòó, ó sì wo ìhà àwọn ọmọ rẹ̀ tí ebi ń pa. Mo wo ìyàwó mi tìyanutìyanu. A ṣẹ̀ṣẹ̀ fojú ara wa rí eré ẹsẹ̀ ẹranko cheetah yíyanilẹ́nu tán ni.

Ẹranko Ẹ̀yà Ológbò Yíyára

Ní tòótọ́, ẹranko cheetah lè sáré bí afẹ́fẹ́. Ó ṣòro láti gbà gbọ́ pé ó lè gbéra láti orí ìdúró, kí ó sì sáré dé orí ìwọ̀n nǹkan bíi kìlómítà 65 ní wákàtí kan láàárín ìṣẹ́jú àáyá méjì péré! Eré ẹsẹ̀ rẹ̀ lè pé ìwọ̀n 110 kìlómítà ní wákàtí kan! Òun ni ẹranko orí ilẹ̀ tí ó yára jù lọ. Ní ṣíṣe ìfiwéra, ẹṣin asáré kan lè fi díẹ̀ sáré kọjá ìwọ̀n kìlómítà 72 ní wákàtí kan, ajá ọdẹ kan sì lè sáré tó ìwọ̀n kìlómítà 65 ní wákàtí kan. Bí ó ti wù kí ó rí, ẹranko cheetah lè sá eré ní ìwọ̀n ìyára kíkàmàmà rẹ̀ fún ọ̀nà tí kò jìn nìkan.

Ẹranko cheetah kì í tóbi, ẹsẹ̀ rẹ̀ tín-ínrín, ó sì gùn, ẹ̀yìn rẹ̀ títẹ̀ sì ṣeé ká kò. Ìrù gígùn alámì tóótòòtó tí ẹranko cheetah ní ń mára rẹ̀ dúró bí ó ti ń bẹ́gbẹ̀ẹ́ wọ̀ ọ́ tí ó sì ń yí pa dà lórí ìwọ̀n eré gíga. Nígbà tí ó bá nà tán lórí eré, àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ lè fẹ̀ ju mítà mẹ́fà lọ. Ẹsẹ̀ rẹ̀ tí kò lẹ́gbẹ́ jẹ́ àrànṣe kan fún irú ìyárakánkán bẹ́ẹ̀; wọ́n jọ ti ajá ju ti ológbò lọ. Ó máa ń fi àwọn èékánná rẹ̀ wa ilẹ̀ mú láti ṣàfikún eré rẹ̀.

Ẹwà Alámì Tóótòòtó

Ó ṣe kedere pé ojú ẹranko cheetah jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ ó sì rẹwà. Àwọn ìlà tẹ́ẹ́rẹ́ dúdú méjì wá láti ojú sí igun ẹnu rẹ̀, tí ó mú kí ojú ẹranko ẹ̀yà ológbò náà ní ìrísí ìbànújẹ́, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jọ ti ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀. Irun ara rẹ̀ tí ó ní àmì tóótòòtó dídọ́gba délẹ̀, kò gùn, ó sì sábà máa ń ní àwọ̀ ilẹ̀ pípọ́n ní ara, ṣùgbọ́n tí ń jẹ́ funfun ní ikùn. Nígbà tí a bá bí wọn, àwọn ọmọ máa ń dúdú gan-an, wọ́n sì máa ń ní jọ̀jọ̀ ṣíṣù tí ó ní irun gígùn aláwọ̀ búlúù mọ́ eérú tí ó wà láti ibi ọrùn wọn lọ sí ibi ìrù wọn.

Ẹranko cheetah máa ń han gooro tàbí kí ó ké igbe ẹyẹ kan tí ń dún lọ kánrin. A lè gbọ́ igbe rẹ̀ yí ní ibi tó jìn tó kìlómítà méjì, ó sì ń fi igbe yìí bá àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ẹranko cheetah míràn sọ̀rọ̀.

Ìfùsì ẹranko cheetah ṣe pẹ̀lẹ́tù, ó sì fọkàn balẹ̀ bí a bá fi wé ti àwọn ẹranko ẹ̀yà ológbò bíi tirẹ̀ míràn, kìnnìún àti àmọ̀tẹ́kùn. Nígbà tí nǹkan bá tẹ́ ẹ lọ́rùn, ó máa ń kùn bí ológbò ńlá kan. Ó máa ń tètè mára bá ipò wíwàníbẹ̀ ènìyàn mu, a tilẹ̀ ti mú un sìn. Bí ó ti wù kí ó rí, ẹranko cheetah kì í ṣe ológbò. Bí ó bá dàgbà tán, ó ń tẹ̀wọ̀n kìlógíráàmù 45 tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, eyín rẹ̀ mímú àti àwọn èékánná rẹ̀ mú kí ó jẹ́ ẹranko líléwu—ọ̀kan tí ó yẹ kí a máa ṣọ́ra fún.

Wọn kì í bí ọdẹ ṣíṣe mọ́ ẹranko cheetah, ìyá rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ kọ́ ọ gidigidi láti ṣọdẹ. Bí a bá tọ́ ọmọ kan ní àhámọ́, kì yóò ní agbára láti gẹ̀gùn kí ó sì lé ohun ọdẹ rẹ̀ pa. Nígbà tí ìyá kan àti àwọn ọmọ rẹ̀ bá jùmọ̀ ń jẹun, wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ lálàáfíà, láìsí ìjìjàdù àti ìjà tí ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn kìnnìún tí ń jẹun. Kódà, ní àwọn ilẹ̀ gbígbẹ, àwọn ẹranko cheetah máa ń jẹ bàrà oníṣulára.

Bí àwọn ẹranko ẹ̀yà ológbò yí kì í ti í bẹ̀rù, tí wọ́n sì lálàáfíà tó ti ya àwọn tí ń rìnrìn àjò afẹ́ lọ sí àwọn ọgbà ohun alààyè ilẹ̀ Áfíríkà lẹ́nu. Ó wọ́pọ̀ láti rí ẹranko cheetah tó ti dàgbà dáradára tí ó dùbúlẹ̀ sí ìbòòji ọkọ̀ àwọn arìnrìn-àjò afẹ́, tàbí kí ó fò mọ́ ìbòrí ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà, kí ó sì máa ti inú díńgí wo àwọn èrò ọkọ̀ tí ẹnu yà, tí ó sì sábà máa ń bẹ̀rù náà.

Ìtọ́jú Tí Òbí Ẹranko Ẹ̀yà Ológbò Ń Fún Ọmọ

Abo ẹranko cheetah kan lè bí àwọn ọmọ tíntìntín tí ó tó mẹ́fà. Tìgboyàtìgboyà ló ń dáàbò bò wọ́n, tí ó sì ń pa wọ́n mọ́ dáradára, tí ó ń kó wọn kiri láàárín oṣù mélòó kan àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, láìka àwọn ìsapá àwọn ìyá ẹranko cheetah láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn sí, ó jọ pé kìkì nǹkan bí ìdámẹ́ta àwọn ọmọ náà ní ń dàgbà.

Bíbójútó ìdílé kan tí ó ní àwọn ọmọ ẹranko cheetah nínú kì í ṣe iṣẹ́ rírọrùn fún ìyá ẹranko cheetah náà. Wọ́n lágbára púpọ̀, wọ́n sì lè ṣeré kọjá ààlà. Àwọn ọmọ náà sábà máa ń yọ́ kẹ́lẹ́ dọdẹ ìrù ìyá wọn nígbà tó bá ń sinmi, wọn á sì máa fò mọ́ ọn bí ó ti ń jù ú lọ́nà tí àwọn ológbò fi ń jùrù. Bí wọ́n ti ń bá ara wọn jìjàkadì, tí wọ́n ń gé ara wọn jẹ, tí wọ́n sì ń lé ara wọn kiri, wọ́n sábà máa ń wà láìfura sí ewu àwọn aṣèparun tí ó yí wọn ká nígbà gbogbo.

A Ń Dọdẹ Ọdẹ Náà

Ó ṣeé ṣe kí ẹranko cheetah ní ọ̀pọ̀ ọ̀tá nínú igbó, títí kan àwọn kìnnìún, àmọ̀tẹ́kùn, àti pẹnlẹpẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ènìyàn ni ọ̀tá búburú jù lọ tí ẹranko cheetah ní. Irun ara rẹ̀ tí ó ní àmì tóótòòtó lọ́nà fífanimọ́ra níye lórí gan-an fún aṣọ, rọ́ọ̀gì, àti ohun ọ̀ṣọ́ àfiṣèrántí. A ti ń mú ẹ̀dá tí ẹsẹ̀ rẹ̀ yá yìí, tí a sì ń kọ́ ọ láti ṣọdẹ. Nítorí tí ẹranko cheetah kì í bímọ ní àhámọ́, a ti dọdẹ rẹ̀ dé òpin ibùgbé rẹ̀ láti rí ohun tí a nílò yí. Àìsí ibùgbé tún ti dógun mú ẹranko cheetah tó bẹ́ẹ̀ tí a fi ń rí i ní àwọn igbó àìro nìkan ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà nísinsìnyí.

Ní 1900, a fojú díwọ̀n pé 100,000 ẹranko cheetah ló wà ní orílẹ̀-èdè 44. Lónìí, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ kìkì 12,000 ló là á já ní orílẹ̀-èdè 26, tí ọ̀pọ̀ jù lọ jẹ́ ní Áfíríkà. A ń sapá láti dáàbò bo ẹranko ẹ̀yà ológbò rírẹwà alámì tóótòòtó yìí, síbẹ̀ iye rẹ̀ ń dín kù sí i.

Àwọn kan rò pé, ó ṣeé ṣe kí a má lè gba ẹranko cheetah lọ́wọ́ àkúrun. Bí ó ti wù kí ó rí, ó múni lọ́kàn yọ̀ láti mọ̀ pé àkókò kan ń bọ̀ tí ènìyàn yóò tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún un ní kíkún, láti bójú tó, kí ó dáàbò bò, kí ó sì “máa jọba lórí . . . ohun alààyè gbogbo tí ń rákò lórí ilẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ìgbà náà nìkan ni ìdánilójú kíkún yóò wà pé irú àwọn ẹranko ẹ̀yà ológbò rírẹwà bí ẹranko cheetah yóò mú inú àwọn olùgbé orí ilẹ̀ ayé dùn títí láé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́