ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 7/22 ojú ìwé 31
  • Àgbà Ayárasáré

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àgbà Ayárasáré
  • Jí!—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Cheetah—Ẹranko Ẹ̀yà Ológbò Tó Yára Jù Lọ
    Jí!—1997
  • Ohun Àgbàyanu Ni Ṣíṣílọ Àwọn Ẹranko Wildebeest
    Jí!—2003
  • Ọgbà Ẹranko—Ìrètí Ìkẹyìn Fún Àwọn Ẹran Ìgbẹ́ kẹ̀?
    Jí!—1997
Jí!—1996
g96 7/22 ojú ìwé 31

Àgbà Ayárasáré

Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyin Jí! ní Gúúsù Áfíríkà

TA LÓ jẹ oyè yìí? Cheetah, ẹranko tí ó yára jù lọ lágbàáyé tí ó bá ń sáré ibi tí kò jìnnà. Ẹranko cheetah kọ̀ọ̀kan ní bátànì àmì tóótòòtó ara tirẹ̀ tí ó yàtọ̀—òun ló mú orúkọ náà cheetah, tí ó wá láti inú ọ̀rọ̀ Sanskrit tí ó túmọ̀ sí “adíkálà” wá.

Àwọn kan sọ pé bí a bá kọ́kọ́ kófìri rẹ̀, ńṣe ló jọ pé ẹsẹ̀ nìkan ni gbogbo ara rẹ̀. Àwọn mìíràn sọ pé ẹ̀yin rẹ̀ tẹ̀ sínú, orí rẹ̀ sì kéré jù. Àmọ́ àwọn ànímọ́ wọ̀nyí ń ṣèrànwọ́ fún ẹranko cheetah. Àwọn ẹsẹ̀ ẹ̀yin rẹ̀ gígùn ń pèsè agbára ìgbérasọ, tí èyí sì ń jẹ́ kí ẹranko cheetah lè rìn lọ́nà fífani mọ́ra, kí ó sì máa sáré nínú ọlá ńlá. Ẹranko yìí sì lè yára sáré lóòótọ́! Níbi tí ilẹ̀ bá tẹ́jú, láàárín ìṣẹ́jú àáyá bíi mélòó kan, ẹranko cheetah kan lè sáré tó ìwọ̀n 110 kìlómítà ní wákàtí kan.

A ṣẹ̀da cheetah dáradára fún ìwọ̀n ìsáré gíga. Egungun ara rẹ̀ fífúyẹ́ ní nínú, egungun ẹ̀yìn aṣeétẹ̀síbísọ́hùn-ún ṣíṣàrà ọ̀tọ̀ tí ó lè ká, kí ó sì tú bí irin kíká atabọ̀n-ùn. A tún fi àyà jíjindò, ẹ̀dọ̀ fóró púpọ̀, ọkàn àyà lílágbára, ìrù tí ń pèsè ìwàdéédéé, àti ihò imú ńlá tí ń fàyè gba yíyára mí, jíǹkí ẹranko cheetah—tí gbogbo rẹ̀ ń ṣàlékún ìyára kánkán aláìlẹ́gbẹ́ ẹranko yìí. Bí ó ti wù kí ó rí, ìtújáde agbára ẹranko cheetah kì í wà fún ìgbà pípẹ́. Lẹ́yìn kìkì nǹkan bí 400 mítà lórí eré gidi, ó gbọ́dọ̀ dúró láti sinmi.

Àwọn ẹranko cheetah kì í sábà jẹ́ ewu fún ènìyàn. Ann van Dyk, tí ó ti ń sin àwọn ẹranko cheetah fún ọ̀pọ̀ ọdún, kọ sínú ìwé rẹ̀, The Cheetahs of De Wildt, pé: “Lẹ́yìn tí mo bá ti fún wọn lóúnjẹ tán, mo fẹ́ràn lílo àkókò díẹ̀ tó kù kí ilẹ̀ ṣú pẹ̀lú ìdílé àwọn ológbò mi. Ìmọ̀lára ìgbẹ́kẹ̀lé ti dàgbà láàárín wa, bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé a kò tù wọ́n lójú, mo mọ̀ pé wọn kò ní pa mí lára.”

Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ènìyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣe ẹranko cheetah ní jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ọdẹ ní Áfíríkà ṣojúkòkòrò awọ rẹ̀ ṣíṣàrà ọ̀tọ̀, ìtẹ̀lúdó sì ti pààlà sí àyè tí ẹranko cheetah ti lè sáré. Èyí ti dín iye àwọn ẹranko cheetah tí ó wà kù gidigidi. Ẹranko cheetah pọ̀ gan-an ní India ní àkókò kan, ó ti kú run níbẹ̀ ní 1952. A kò tún rí wọn mọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè kan tí wọ́n pààlà pẹ̀lú Mẹditaréníà ìhà ìlà oòrùn.

Ẹ wo bí a ti lè kún fún ọpẹ́ tó pé nínú ayé tuntun Ọlọ́run, àwọn ènìyàn oníwọra kò ní wu àwọn ẹranko léwu mọ́! (Aísáyà 11:6-9) Bóyá ní àkókò yẹn, ìwọ yóò ní àǹfààní àtirí àgbà ayárasáré tí a ṣẹ̀dá lọ́nà àgbàyanu yìí, ẹranko cheetah.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́