Ẹkùn! Ẹkùn!
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ÍŃDÍÀ
Ọ̀MỌ̀WÉ Charles McDougal, tí ó ti fi ọ̀pọ̀ ọdún kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹkùn ní Ọgbà Ẹranko Royal Chitwan ní Nepal, rántí pé: ‘Nígbà kan, mo ń rìn lọ ní òkè kékeré, tóóró kan. Bí mo ti ń lọ, ẹkùn kan ń bọ̀ láti ìhà kejì. A fẹ́rẹ̀ẹ́ pàdé tán lókè, àlàfo kékeré kan báyìí ló sì wà láàárín wa—nǹkan bí ìṣísẹ̀ 15.’ Ọ̀mọ̀wé McDougal dúró rigidi. Kàkà kí ó máa wo ẹkùn náà lójú ní tààràtà, èyí tí ẹkùn kan máa ń kà sí ìpèníjà, ó ń wò gba orí èjìká ẹkùn náà. Ẹkùn náà ba mọ́lẹ̀ síbẹ̀, ṣùgbọ́n kò múra ìgbéjàkoni kankan. Lẹ́yìn ìṣẹ́jú mélòó kan, Ọ̀mọ̀wé McDougal rìn sẹ́yìn díẹ̀. Ó sọ pé: ‘Mo wulẹ̀ yí padà, mo sì rìn padà lọ síbi tí mo ti wá.’
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún yìí, 100,000 ẹkùn ní ń bẹ ní ìlú ìbílẹ̀ wọn ní Éṣíà, tí ó ní nǹkan bí 40,000 tí ó wà ní Íńdíà nínú. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó fi di 1973, iye àwọn ẹ̀dá ọlọ́lá ńlá yìí tí ó kù lágbàáyé ti dín kù sí iye tí kò tó 4,000, ní pàtàkì, nítorí pé a ń dọdẹ wọn. Ẹkùn, ẹranko tí ó tóbi jù lọ nínú ẹ̀yà ológbò lórí ilẹ̀ ayé, ti wá sábẹ́ ewu ìparun láti ọwọ́ ènìyàn. Ṣùgbọ́n, ẹkùn ha ń wu àwọn ẹ̀dá ènìyàn léwu bí? Kí ni ológbò ńlá yìí jọ gan-an? Àwọn ìgbìyànjú láti gbà á lọ́wọ́ kíkú run ha ti kẹ́sẹ járí bí?
Ìgbésí Ayé Ìdílé Ẹkùn
Ọ̀pọ̀ ọdún àkíyèsí onísùúrù ti fún àwọn onímọ̀ ẹ̀dá nínú ipò àdánidá ní èrò tí ó túbọ̀ ṣe kedere nípa ìgbésí ayé ẹkùn. Ẹ jẹ́ kí a finú wòye pé a ń wo bí ìgbésí ayé ìdílé ẹkùn kan ṣe máa ń rí nínú igbó mèremère Ranthambhore, ní ìhà àríwá Íńdíà. Láti imú sí góńgó ìrù rẹ̀, akọ náà gùn tó mítà 3, ó sì tẹ̀wọ̀n tó nǹkan bí 200 kìlógíráàmù. Èkejì rẹ̀ jẹ́ nǹkan bí mítà 2.7, ó sì tẹ̀wọ̀n tó nǹkan bí 140 kìlógíráàmù.a Ọmọ ẹkùn mẹ́ta ń bẹ pẹ̀lú wọn, akọ kan àti abo méjì.
Ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù nínú igbó wọ̀nyí lè ju ìwọn 45 lọ lórí òṣùwọ̀n Celsius, ṣùgbọ́n ìdílé ẹkùn náà máa ń rí ìbòji lábẹ́ àwọn igi tí ó léwé lórí. Wọ́n sì lè gbádùn ìlúwẹ̀ẹ́ nínú omi tútù inú adágún kan nítòsí lọ́pọ̀ ìgbà. Pé àwọn ẹranko ẹ̀yà ológbò lè lúwẹ̀ẹ́ kẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ẹkùn fẹ́ràn omi! Ní ti gidi, a ti mọ̀ nípa wọn pé wọ́n ń lúwẹ̀ẹ́ ju kìlómítà márùn-ún lọ láìsinmi.
Ìtànṣán oòrùn ń la àwọn igi wọ̀nyẹn kọjá sára awọ ẹkùn dídán yanran, tí ó ní àwọ̀ omi ọsàn, ìyẹ́n sì ń mú kí ó jọ pé wọ́n ń dánná yẹ̀rìyẹ̀rì. Àwọn ìlà dúdú ara wọn a máa kọ mànà, àwọn ibi tó funfun lókè ojú wọn pẹ̀lú a máa tàn yanranyanran. Lẹ́yìn tí a ti wo àwọn ọmọ ẹkùn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fún ìgbà díẹ̀, a lè fi ìyàtọ̀ ìlà ara wọn àti àmì ojú wọn dá ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn mọ̀ yàtọ̀.
Ìdàgbà Ẹkùn
Nígbà tí àkókò ń tó bọ̀ fún ìyá ẹkùn náà láti bí àwọn ọmọ rẹ̀, ó wá ihò yíyẹ wẹ́kú kan tí ó fara sin dáadáa sínú ìgbẹ́ dídí. Láti ibẹ̀, ìdílé náà ń gbádùn wíwo pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan tí ó ní ihò omi kan tí àwọn ẹranko mìíràn ti máa ń mumi. Abo ẹkùn náà yan ọ̀gangan yìí kí ó lè máa dọdẹ oúnjẹ rẹ̀ láìjìnnà sí àwọn ọmọ rẹ̀.
Láti ìgbà ìbí wọn, àwọn ọmọ ẹkùn náà ń gba àfiyèsí púpọ̀. Ní gbogbo ìgbà tí wọ́n wà ní jòjòló, ìyá wọn ń fi ìkúùkù rẹ̀ gbá wọn mọ́ra, ó ń fi imú rò wọ́n lára, ó sì ń pọ́n wọn lára lá, bí ó ti ń rọra kùn hùnnùhùnnù. Nígbà tí àwọn ọmọ ẹkùn náà túbọ̀ dàgbà, wọ́n ń ṣe bojúbojú, wọ́n sì ń ja ìjàkadì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ẹkùn kò lè kùn lọ́nà ìṣàfihàn ìtẹ́lọ́rùn bíi ti àwọn ẹranko ẹ̀yà ológbò míràn, láti ìgbà tí wọ́n bá ti tó nǹkan bí ọmọ ọdún kan, wọ́n máa ń mí kanlẹ̀ pẹ̀lú ìbújáde ńlá, tí ó dún sókè ketekete nígbà tí ìyá wọn bá dé lẹ́yìn tí ó ti fi wọ́n sílẹ̀ fúngbà díẹ̀.
Àwọn ọmọ ẹkùn náà fẹ́ràn láti máa lúwẹ̀ẹ́, kí wọ́n sì máa ṣeré nínú omi pẹ̀lú ìyá wọn. Fojú inú wo abo ẹkùn náà bí ó ti jókòó ní gẹ́gẹ́rẹ́ etí adágún náà tí ó fi ìrù rẹ̀ sínú omi. Látìgbàdégbà, ó ń gbọn ìrù rẹ̀ sókè láti fi ta omi tútù sí ara rẹ̀ tó ti gbóná. Ní ti ìrù náà fúnra rẹ̀, àwọn ọmọ ẹkùn náà kò fìgbà kankan káàárẹ̀ gbígbìyànjú láti mú ìrù ìyá wọn bí ó ti ń jù ú síbí sọ́hùn-ún. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe pé abo ẹkùn náà ń bá àwọn ọmọ rẹ̀ ṣiré nìkan ni; ó tún ń kọ́ wọn lọ́gbọ́n àtifò mú nǹkan, tí wọn yóò máa lò lẹ́yìn ìgbà náà, nígbà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọdẹ. Àwọn ọmọ ẹkùn náà tún kíyànyán igi gígùn. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá tó nǹkan bí ọmọ oṣù 15, wọn yóò ti tóbi jù, wọn yóò sì wúwo jù láti gungi tìrọ̀rùntìrọ̀rùn.
Ojúṣe ti Bàbá
Títí di àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ ènìyán gbà pé ìyá ẹkùn máa ń dá nìkan tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà ni, àti pé bí akọ náà bá ráyè, yóò pa àwọn ọmọ náà. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ jù lọ ẹkùn. Bàbá ẹkùn náà máa ń wọgbó lọ fún àwọn àkókò gígùn, tí yóò máa wọ́ agbègbè ìpínlẹ̀ rẹ̀ tí ó fẹ̀ tó 50 kìlómítà níbùú lóròó. Ṣùgbọ́n ó tún máa ń bẹ ìdílé rẹ̀ wò. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè dara pọ̀ mọ́ abo ẹkùn náà àti àwọn ọmọ ẹkùn náà ní ṣíṣe ọdẹ, tí ó tilẹ̀ ń bá wọn pín nínú ẹran tí wọ́n bá pa. Akọ ọmọ ẹkùn tí ó túbọ̀ ya oníjàgídíjàgan lè kọ́kọ́ jẹ ìpín tirẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, bí ó bá fìwọra lé àwọn arábìnrin rẹ̀ sẹ́yìn pẹ́ jù, ìyá rẹ̀ yóò rọra tì í sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan tàbí kí ó tilẹ̀ ta á nípàá pàápàá láti fàyè gba àwọn abo ọmọ ẹkùn náà láti jẹ ìpín tí ó tọ́ sí wọn lára oúnjẹ náà.
Àwọn ọmọ ẹkùn máa ń gbádùn bíbá bàbá wọn fìrìgbọ̀n ṣeré. Ibi tí wọ́n yàn láàyò fún ṣíṣe èyí ni ihò omi tí ó wà nítòsí. Bàbá ẹkùn náà ń rọra ri ara rẹ̀ bọmi dé ibi orí rẹ̀. (Àwọn ẹkùn kì í fẹ́ kí omí ta sí wọn lójú!) Nígbà náà ni ó máa ń jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa fimú rò ó lára bí òun náà ti ń pọ́n ojú wọn lá. Ní kedere, wọ́n ní ìdè ìdílé lílágbára kán.
Ajẹ̀nìyàn Ni Wọ́n Bí?
Àwọn ìwé àti sinimá sábà máa ń fi àwọn ẹkùn hàn bí ẹ̀dá rírorò, oníjàgídíjàgan, tí ń gbá àwọn ènìyàn mú, tí ó sì ń gbógun tì wọ́n, tí ń ṣe wọ́n níṣekúṣe lẹ́yìn náà, tí ó sì ń jẹ wọ́n. Èyí kì í ṣe òótọ́ rárá. Gbogbo ẹkùn kọ́ ní ń jẹ̀nìyàn. Lọ́pọ̀ ìgbà, bí ẹkùn kan bá rí ènìyàn kan nínú igbó, ó máa ń yàn láti wulẹ̀ rọra yọ́ mẹ̀rẹ́n lọ. Ó dùn mọ́ni pé òórùn ènìyàn kò ń nípa kankan lórí ẹkùn.
Bí ó ti wù kí ó rí, lábẹ́ àwọn ipò kan, ẹkùn kan tí ebi ń pa lè di eléwu ní ti gidi. Bí ó bá ti pàdánù àwọn eyín rẹ̀ nítorí ọjọ́ ogbó, tàbí tí àwọn ènìyán bá ti pa á lára, ó lè má ṣeé ṣe fún un láti ṣọdẹ bí ó ti yẹ. Bákan náà, bí ibùgbé àwọn ènìyàn bá wọ ibùgbé àdánidá rẹ̀, àwọn ẹran ìjẹ ẹkùn lọ́nà àdánidá lè ṣọ̀wọ́n. Nítorí irú ìdí báwọ̀nyí, nǹkan bí 50 ènìyàn ni ẹkùn ń pa lọ́dọọdún ní Íńdíà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iye yìí kéré ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún sí iye àwọn tí ejò ń pa. Ìkọlù ẹkùn máa ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn ibi àbàtà ẹsẹ̀ odò Ganges.
Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀mọ̀wé McDougal ṣe sọ, àwọn ẹkùn kò léwu tó bí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyán ṣe rò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, yíyọ sí ẹkùn kan lójijì, ní ìsúnmọ́ pẹ́kípẹ́kí lè tanná ran ìkọlù kan, ó sọ pé “ẹkùn jẹ́ ẹranko jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, oníparọ́rọ́, tí ó sì ń séra ró gan-an. Ní bí ó ti sábà máa ń rí, bí o bá pàdé ẹkùn kan—tí o tilẹ̀ ti sún mọ́ ọn gan-an pàápàá—kì yóò gbógun tì ọ́.”
Ìkọlù kò wọ́pọ̀ láàárín àwọn ẹkùn. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́ ẹkùn kán lè rìn gbéregbère wọ agbègbè ìpínlẹ̀ ẹkùn míràn, kí ó sì pàdé akọ tó ni ibẹ̀. Ìkùn hùnnùhùnnù lílágbára, bíbú tí ń dáni níjì, àti ìfimúkomú líle kokó lè ṣẹlẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí akọ tí ó dàgbà jù náà bá ti fi àjùlọ hàn, èyí tí ó kéré náà sábà máa ń yí fi ẹ̀yìn lélẹ̀, tí yóò sì ká tọwọ́tẹsẹ̀ sófuurufú, láti fi hàn pé òún túúbá, ìkòlójú náà á sì parí.
Ọjọ́ Iwájú Ológbò Ńlá Náà
Kàkà kí ènìyán wà nínú ewu lọ́wọ́ ẹkùn, ènìyán ti fara hàn gbangba bí ewu gidi kan ṣoṣo tí ẹkùn dojú kọ. Ní báyìí, a ti ń sapá láti dáàbò bo ẹkùn lọ́wọ́ àkúrun. Ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè Éṣíà ti dá àwọn igbó ẹkùn sílẹ̀. Ní 1973, a ṣèfilọ́lẹ̀ ìsapá àrà ọ̀tọ̀ kan tí a pè ní Ìfilọ́lẹ̀ Ẹkùn ní Ọgbà Corbett Ti Orílẹ̀-èdè, ní ìhà àríwá Íńdíà. Owó àti ohun èlò rọ́ wọlé láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé fún Ìfilọ́lẹ̀ Ẹkùn. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n ya igbó ẹkùn 18 sọ́tọ̀ ní Íńdíà pẹ̀lú àròpọ̀ ilẹ̀ tí ó fẹ̀ ju 28,000 kìlómítà lọ níbùú lóròó. Nígbà tí ó fi di 1978, wọ́n ti to ẹkùn mọ́ àwọn ẹranko tí a ń wu léwu. Àwọn àbájáde rẹ̀ kàmàmà! Kí wọ́n tóó fòfin de ṣíṣọdẹ ẹkùn, àwọn ẹkùn ti di ẹranko tí ń fara pamọ́ tàbí tí ń jẹ lóru nìkan nítorí ìbẹ̀rù ènìyàn. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdún mélòó kan tí a fi dáàbò bò wọ́n, ẹkùn ti bẹ̀rẹ̀ sí í rìn kiri nínú àwọn igbó náà, tí wọ́n sì ń ṣọdẹ lọ́sàn-án gangan!
Síbẹ̀, ewú ṣì wà lórí ẹkùn: bíbéèrè tí àwọn ènìyàn yí ká ayé ń béèrè fún àwọn egbòogi ìbílẹ̀ Éṣíà tí a fi àwọn onírúurú ẹ̀yà ara ẹkùn ṣe. Fún àpẹẹrẹ, àpò egungun ẹkùn kán lè mú 500 dọ́là (U.S.) wọlé ní Íńdíà, nígbà tí a bá sì fi ṣe gbogbo ohun tí ó yẹ pẹ̀lú egungun rẹ̀, tí a sì gbé e dé ọjà ní Ìlà Oòrùn Jíjìnnà Réré, iye owó náà ti lọ sókè sí iye tí ó lé ní 25,000 dọ́là. Pẹ̀lú iye owó tí ó pọ̀ tó báyìí tí ó rọ̀ mọ́ ọn, ọ̀pọ̀ àwọn òtòṣì tí ń gbé àrọko ni a ń dẹ wò láti sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn apẹkùn láìgbàṣẹ láti fọgbọ́n yọ́ àwọn aṣọ́gbó sílẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, a ka àwọn ìsapá láti dáàbò bo ẹkùn sí aláṣeyọrí. Ṣùgbọ́n láti 1988 wá, ipò náà ti yí padà sí búburú. Lónìí, nǹkan bí ẹkùn 27 péré ní ń rìn kiri ní Ranthambhore, ní ìfiwéra pẹ̀lú 40 tó wà níbẹ̀ ní 20 ọdún sẹ́yìn. Ó si ṣeé ṣe kí iye ẹkùn lágbàáyé kéré tó 5,000!
Títí di ìparí ọ̀rúndún tó kọjá, àwọn ẹkùn àti ènìyán jùmọ̀ ń gbé ní ìṣọ̀kan dé ìwọ̀n kan ní Íńdíà. Wọn yóò ha tún lè ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ láé bí? Ní báyìí ná, igbe arùmọ̀lárasókè náà, “Ẹkùn! Ẹkùn!” ṣì lè túmọ̀ sí ìkófìrí ẹranko ẹ̀yà ológbò títóbi jù lọ lágbàáyé náà. A kò tí ì lè sọ bóyá àwọn ètò ìdáàbòbò yóò mú ààbò ẹkùn dájú lọ́jọ́ iwájú. Ṣùgbọ́n Bíbélì fi dá wa lójú pé lọ́jọ́ kan, gbogbo ayé yóò di párádísè kan bíi ti Ọgbà Édẹ́nì. Nígbà náà, àti ènìyàn àti àwọn ẹranko ìgbẹ́ bí ẹkùn yóò ṣàjọpín ilẹ̀ ayé ní àlàáfíà.—Aísáyà 11:6-9.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ẹkùn ilẹ̀ Siberia, ẹ̀yà irú ọ̀wọ́ tí ó tóbi jù lọ, lè tẹ̀wọ̀n tó 320 kìlógíráàmù, kí ó sì gùn tó mítà 4.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ẹkùn Funfun
Ẹkùn funfun ṣíṣọ̀wọ́n, tí ó jẹ́ ohun ìṣúra kan fún orílẹ̀-èdè Íńdíà, jẹ́ àbájáde apilẹ̀ àbùdá kan tí ìyípadà ti bá. Ní 1951, wọ́n rí akọ ọmọ ẹkùn funfun kan he ní Igbó Rewa ti Íńdíà. Láti inú mímú kí ó gun abo ẹkùn kan tí ó ní àwọ̀ wíwọ́pọ̀, ó mú àwọn ọmọ aláwọ̀ wíwọ́pọ̀ jáde. Bí ó ti wù kì ó rí, nígbà tí abo kan nínú àwọn ọmọ wọ̀nyí gùn pẹ̀lú àgbà akọ funfun náà, ó bí àwọn ọmọ ẹkùn funfun mẹ́rin. Ìbísí àfọgbọ́nṣe ti mú kí ó ṣeé ṣe fún àwọn ènìyàn ní àwọn ibi púpọ̀ láti rí ẹwà ṣíṣàrà ọ̀tọ̀ yìí ní àwọn ọgbà ẹranko wọn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àwọn ẹranko ẹ̀yà ológbò tí ń lúwẹ̀ẹ́ kẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Àwọn ẹkùn kò léwu tó bí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyán ṣe rò