ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 5/15 ojú ìwé 3
  • Ààbò Tòótọ́ Góńgó Àléèbá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ààbò Tòótọ́ Góńgó Àléèbá
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹkùn! Ẹkùn!
    Jí!—1996
  • Ààbò Tòótọ́ Nísinsìnyí àti Títí Láé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • “Wulẹ̀ La Ojú Rẹ Kí O sì Wò Ó”
    Jí!—1997
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 5/15 ojú ìwé 3

Ààbò Tòótọ́ Góńgó Àléèbá

ARNOLD jẹ́ ọmọdé kan tí ó nífẹ̀ẹ́ ẹkùn ìṣeré rẹ̀ tí a fi aṣọ ṣe. Níbikíbi tí ó bá ń lọ, wọ́n jọ ń lọ ni—níbi eré, nídìí tábìlì oúnjẹ, lórí ibùsùn rẹ̀. Lójú tirẹ̀, ẹkùn náà ń pèsè ìtùnú, ààbò. Ní ọjọ́ kan, yánpọnyánrin bẹ́ sílẹ̀. Ẹkùn pòórá!

Bí Arnold ti ń sọkún, ìyá, bàbá, àti àwọn ẹ̀gbọ́nkùnrin rẹ̀ mẹ́ta bẹ̀rẹ̀ sí túlé wọn tí ó tóbi láti wá ẹkùn náà. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọ̀kan nínú wọ́n rí i nínú àpótí tábìlì. Dájúdájú, Arnold ni ó gbé e síbẹ̀, ó sì tí yára gbàgbé ibi tí ó wà. Wọ́n dá ẹkùn náà padà fún un, Arnold sì nu omijé rẹ̀ nù. Ó láyọ̀, ó sì nímọ̀lára ààbò lẹ́ẹ̀kan sí i.

Ẹ wo bí yóò ti dára tó, ká ní a lè yanjú gbogbo ìṣòro pẹ̀lú ìrọ̀rùn bẹ́ẹ̀—ní wẹ́rẹ́, bíi rírí ẹkùn ìṣeré nínú àpótí tábìlì! Bí ó ti wù kí ó rí, lójú ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn, ọ̀ran ààbò túbọ̀ jinlẹ̀, ó sì díjú púpọ̀ ju ìyẹn lọ. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ibi gbogbo ni àwọn ènìyàn ti ń ṣe kàyéfì pé, ‘Wọn yóò ha hu ìwà ọ̀daràn tàbí ìwà ipá sí mi bí? Mo ha wà nínú ewu pípàdánù iṣẹ́ mi bí? Ó ha dájú pé ìdílé mi yóò ní oúnjẹ púpọ̀ tó bí? Àwọn ẹlòmíràn yóò ha yẹra fún mi nítorí ìsìn mi tàbí ẹ̀yà ìbílẹ̀ mi bí?’

Iye àwọn ènìyàn tí wọ́n ṣàìní ààbò pọ̀ jọjọ. Gẹ́gẹ́ bí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti sọ, kì í ṣe ìtọ́jú ìṣègùn fún àwọn àrùn tí ó wọ́pọ̀ nìkan ní èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù mẹ́ta ṣaláìní, ṣùgbọ́n wọ́n ṣaláìní àwọn òògùn ṣíṣe kókó pẹ̀lú. Èyí tí ó ju bílíọ̀nù kan ènìyàn ń ráre nínú òṣì pátápátá. Bí wọ́n tilẹ̀ lè ṣiṣẹ́, èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù kan kò ríṣẹ́ tí ó níláárí ṣe. Iye àwọn olùwá ibi ìsádi ń pọ̀ sí i. Ní òpin 1994, nǹkan bí ìpín 1 nínú 115 ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé ní a ti fi agbára mú láti sá kúrò nílé wọn. A ti pa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ẹ̀mí run nítorí òwò òògùn líle tí ń mú 500 bílíọ̀nù dọ́là wọlé lọ́dún, èyí tí ó ṣokùnfà àìlóǹkà ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá. Ogun ń pa ẹ̀mí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ run. Ní 1993 nìkan, orílẹ̀-èdè 42 lọ́wọ́ nínú ìforígbárí gidi, nígbà tí àwọn 37 mìíràn nírìírí ìwà ipá ìṣèlú.

Ogun, òṣì, ìwà ọ̀daràn, àti àwọn ohun mìíràn tí ń wu ààbò ẹ̀dá ènìyàn léwu so kọ́ra wọn, wọ́n sì ń pọ̀ sí i ní iye. Kò sí ojútùú rírọrùn sí irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀. Ní tòótọ́, ẹ̀dá ènìyàn kì yóò yanjú wọn rárá.

Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli, kìlọ̀ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọmọ aládé, àní lé ọmọ ènìyàn, lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.” Nígbà náà, ta ni a lè gbẹ́kẹ̀ lé? Ẹsẹ ìwé mímọ́ yìí ń bá a lọ pé: “Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní Ọlọrun Jakobu fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, ìrètí ẹni tí ń bẹ lọ́dọ̀ Oluwa Ọlọrun rẹ̀: Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé, òkun àti ohun tí ó wà nínú wọn.”—Orin Dafidi 146:3-6.

Èé ṣe tí a fi lè gbẹ́kẹ̀ lé Jehofa láti mú ààbò wá sí ilẹ̀ ayé yìí? Ó ha ṣeé ṣe láti gbádùn ìgbésí ayé aláàbò, tí ó sì láyọ̀ nísinsìnyí bí? Báwo ni Ọlọrun yóò ṣe mú àwọn ohun tí ń dènà ààbò ẹ̀dá ènìyàn kúrò?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́