ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 9/8 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awò Awọ̀nàjíjìn Onírédíò Atàtagbà ní Gbalasa Òfuurufú
  • Tẹlifíṣọ̀n Àwọn Ọmọ Àfànítẹ̀tẹ́ Kẹ̀?
  • Ìṣòro Sísọ Ìsokọ́ra Alátagbà Internet Di Bárakú
  • Ìfilọ́lẹ̀ Ẹkùn Kò Gbéṣẹ́
  • Ní Ìrísí Arúgbó Kí O sì Kú Lọ́mọdé
  • Ewu Mànàmáná
  • Ìsoríkọ́ Àwọn Arúgbó
  • Àwọn Ikán Tí Ń Wa Kùsà Góòlù
  • Ìlànà Ìmọ̀wàáhù Lórí Tẹlifóònù Alágbèéká
  • ‘Àwọn Ohun Olómi Jíjáfáfá’
  • Ẹkùn! Ẹkùn!
    Jí!—1996
  • Fi Ọgbọ́n Lo Íńtánẹ́ẹ̀tì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ìsokọ́ra Alátagbà Internet—Èé Ṣe Tí O Ní Láti Ṣọ́ra?
    Jí!—1997
  • Béèyàn Ṣe Lè Sá fún Ewu Tó Wà Nínú Lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 9/8 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Awò Awọ̀nàjíjìn Onírédíò Atàtagbà ní Gbalasa Òfuurufú

Ìwé ìròyìn Science News sọ pé, láìpẹ́ yìí, Àjọ Sáyẹ́ǹsì Nípa Gbalasa Òfuurufú àti Sánmà fi awò awọ̀nàjíjìn onírédíò atàtagbà kan tí ó jẹ́ mítà mẹ́jọ ní ìwọ̀n ìdábùú òbírí ránṣẹ́ sínú gbalasa òfuurufú. Ohun àrà ọ̀tọ̀ inú awò awọ̀nàjíjìn tuntun yìí ni pé a tàtagbà rẹ̀ pẹ̀lú nǹkan bí 40 awò awọ̀nàjíjìn onírédíò atàtagbà lórí ilẹ̀ tí a gbé sí ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ayé. Ètò ìgbékalẹ̀ yí ni a mọ̀ sí Ibi Ìdúrówosánmà Atàtagbà sí Àwọn Ibi Jíjìnnà Síra Gan-an. Àwọn ìhùmọ̀ tí wọ́n jìnnà síra gan-an wọ̀nyí ń fa àwọn ìgbì òòfàmọ́ra onímànàmáná tí ń tú jáde láti orísun agbára rédíò ní gbalasa òfuurufú, bí àwọn ìṣẹ̀dá atànyinrin lójú ọ̀run àti àwọn ihò dúdú mọ́ra, wọ́n sì ń pa wọ́n pọ̀ láti gbé àwòrán kan ṣoṣo jáde. Bí ibi tí rédíò tí ń gba ìsọfúnni náà wà bá ṣe jìnnà tó ni àwọn ẹ̀yà àwòrán tí yóò gbé jáde náà yóò ṣe ketekete tó. Àyípoyípo awò awọ̀nàjíjìn yí yóò gbà á ní nǹkan bí 20,000 kìlómítà láti ibi tí ó ti jìnnà jù lọ lórí ilẹ̀ ayé. Awò awọ̀nàjíjìn tuntun tí ó wà ní gbalasa òfuurufú náà ń gbé àwọn àwòrán tí ìhànrekete wọn fi ìgbà 1,000 ju ti Awò Awọ̀nàjíjìn Gbalasa Òfuurufú ti Hubble tí a lè fojú rí lọ. Ìwé ìròyìn Science News sọ pé: “Bí agbára ìgbéjáde àwòrán yẹn ṣe tó, olùwosánmà kan tí ó wà ní Los Angeles lè rí hóró ìrẹsì kan ní Tokyo.”

Tẹlifíṣọ̀n Àwọn Ọmọ Àfànítẹ̀tẹ́ Kẹ̀?

Láti lè rí àyè ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì, àwọn òbí ọlọ́mọ kéékèèké tí ìṣòro ti bò mọ́lẹ̀, lè ní ìtẹ̀sí láti gbé àwọn ọmọ wọn jókòó ti tẹlifíṣọ̀n. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Parents ti sọ, èyí ń gbé àwọn ewu dìde sí ọmọ náà. Ó wí pé: “Àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ oníwà ipá,” títí kan ọ̀pọ̀ àwọn àwòrán apanilẹ́rìn-ín, “ni a ti fi hàn pé, láìsí iyè méjì, wọ́n ń ṣamọ̀nà sí ìwà jàgídíjàgan tí ń pọ̀ sí i, tí àwọn ọmọdé tí ń wo tẹlifíṣọ̀n ń hù.” Ní àfikún sí i, àwọn ìwádìí tí Dorothy Singer láti Yunifásítì Yale ṣe fi hàn pé, “sísọ tẹlifíṣọ̀n wíwò dàṣà kí ọmọ tó bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé tún ní í ṣe pẹ̀lú ìhùwà burúkú àti àwọn ìdíwọ́ nínú nínífẹ̀ẹ́ láti kàwé” tó bá yá. Singer dámọ̀ràn kí àwọn ọmọ ọlọ́dún kan máà máa wo tẹlifíṣọ̀n ju 30 ìṣẹ́jú lọ lójúmọ́. Ìṣòro mìíràn ni ti àwọn ìjàǹbá tí ó lè ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọmọ náà bá dá wà nídìí tẹlifíṣọ̀n. Òǹkọ̀wé Milton Chen sọ pé: “Ìṣẹ́jú kan péré ló gba ọmọ àfànítẹ̀tẹ́ kan tí ara rẹ̀ yá gágá, tí a kò bójú tó láti kó sínú ewu.” Ìwé ìròyìn Parents dábàá pé kí o gbé ọmọ rẹ àti àwọn ohun ìṣeré tí kò lè ṣèpalára bíi mélòó kan sínú àyè ìṣeré kan níbi tí ojú rẹ lè tó nígbà tí o bá ní láti gbọ́únjẹ ọ̀sán tàbí tí o ń bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù.

Ìṣòro Sísọ Ìsokọ́ra Alátagbà Internet Di Bárakú

Ìwé ìròyìn Canadian Medical Association Journal sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kí àbáyọrí tí ó kẹ́yìn nínú sànmánì onísọfúnni jẹ́ sísọ ìsokọ́ra alátagbà Internet di bárakú.” Ọ̀mọ̀wé Kimberly Young lo àwọn 496 tí ń lo ìsokọ́ra alátagbà Internet láìní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, tí a mọ 396 lára wọn bí ẹni tí ó ti sọ lílò ó di bárakú. Ìwádìí náà fi hàn pé àwọn ìyọrísí sísọ ìsokọ́ra alátagbà Internet di bárakú ní nínú, “àìbẹ́gbẹ́ṣe, ìjà nínú ìdílé, ìfìdírẹmi nílé ẹ̀kọ́, àpọ̀jù gbèsè, [àti] ìdádúró lẹ́nu iṣẹ́.” Ọ̀mọ̀wé Young sọ pé, ìṣòro náà “jẹ́ ìsọdibárakú gan-an bí ìmukúmu ọtí tàbí tẹ́tẹ́ títa láìníjàánu.” Ìwé ìròyìn náà fi kún un pé, “àwọn tí wọ́n ní kọ̀ǹpútà nílé ni wọ́n wà nínú ewu jù lọ.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnikẹ́ni ló lè kó sínú ìdẹkùn sísọ ìsokọ́ra alátagbà Internet di àṣejù, Ọ̀mọ̀wé Young sọ pé, “obìnrin ọlọ́jọ́ orí 40 sí 60 ọdún tí kò kàwé púpọ̀ ni a lè mú bí àpẹẹrẹ ẹni tí ó ti sọ ọ́ di bárakú.” Lára àwọn àmì ewu náà ni lílo àkókò tí ó túbọ̀ ń gùn sí i lórí ìsokọ́ra náà, àti “kíkọ àwọn ìgbòkègbodò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tàbí ti iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ẹni ṣíṣepàtàkì sílẹ̀” nítorí kí a lè lo ìsokọ́ra alátagbà Internet.

Ìfilọ́lẹ̀ Ẹkùn Kò Gbéṣẹ́

Ní 1973, wọ́n gbé Ìfilọ́lẹ̀ Ẹkùn kalẹ̀ ní Íńdíà láti ṣèdíwọ́ fún àkúrun àwọn ẹranko àpapọ̀ orílẹ̀-èdè náà. Ní àkókò yẹn, iye àwọn ẹkùn tí ó wà ní Íńdíà ti dín kù sí 1,827. Ìfilọ́lẹ̀ náà rí ìtìlẹ́yìn àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri àti àṣeyọrí tí ó gbàfiyèsí. Nígbà tí ó fi di 1989, iye àwọn ẹkùn Íńdíà ti pọ̀ ju 4,000 lọ. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní báyìí, ìwé ìròyìn India Today sọ pé, ẹkùn náà tún ti wà nínú ewu lẹ́ẹ̀kan sí i. A fojú díwọ̀n pé àwọn ẹkùn Íńdíà ti dín kù sí iye tí kò tó 3,000. Èé ṣe? Àwọn kan sọ pé, àwọn apẹran-láìgbàṣẹ ń pa ìpíndọ́gba ẹkùn kan lójoojúmọ́, ó kéré tán ni. A dá Ìfilọ́lẹ̀ Ẹkùn sílẹ̀ kí a lè dáàbò bo ológbò ńlá náà. Ṣùgbọ́n ó jọ pé kò lè ṣe ìyẹn. Ìròyìn náà sọ pé: “Àwọn aṣọ́gbó, tí a sábà ń yìnbọn fún, ń rẹ̀wẹ̀sì, wọn kò ní ohun èlò tí ó yẹ.” Ní ti ẹkùn, “ó ti wà ní bèbè àkúrun.”

Ní Ìrísí Arúgbó Kí O sì Kú Lọ́mọdé

Bí ìròyìn tí ó wà nísàlẹ̀ yí ti fi hàn, àwọn olùṣèwádìí gbà gbọ́ pé sìgá mímu lè mú kí ènìyàn yára darúgbó. Bí ìwé Lancet ti Britain ti sọ, ó ṣeé ṣe kí àwọn tí wọ́n ti ń mu sìgá fún ìgbà pípẹ́ hu irun funfun ní ìlọ́po mẹ́rin láìtọ́jọ́ kí wọ́n sì párí tàbí kí wọ́n máa párí díẹ̀díẹ̀ lọ́nà tí ó fi ìlọ́po méjì jù àwọn tí kì í mu sìgá lọ. Nígbà tí lẹ́tà ìròyìn UC Berkeley Wellness Letter ń ròyìn lórí èyí, ó tọ́ka pé ojú àwọn amusìgá túbọ̀ máa ń hunjọ, ó sì ṣeé ṣe kí eyín wọn yọ lọ́nà tí ó fi ìlọ́po méjì jù ti àwọn tí kì í mu sìgá lọ. Ìròyìn náà tọ́ka sí ìwádìí kan tí a ṣe láìpẹ́, tí a kọ sínú ìwé ìròyìn British Medical Journal tí ó fi hàn pé àǹfààní ìdajì péré ló wà fún àwọn ọkùnrin tó jẹ́ pé gbogbo àkókò ìgbésí ayé wọn ni wọ́n ti ń mu sìgá láti dàgbà di ẹni ọdún 73 ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn tí kì í mu sìgá. Ní àfikún sí i, ìwé ìròyìn Good Housekeeping sọ pé, “ó túbọ̀ ṣeé ṣe ní ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún fún àwọn tí kì í mu sìgá tí ń gbé pọ̀ pẹ̀lú àwọn amusìgá láti ní àrùn ọkàn àyà.”

Ewu Mànàmáná

Ìwé agbéròyìnjáde The Australian sọ pé: “Ìṣẹ̀lẹ̀ mànàmáná tí ó la ikú lọ ń ṣe lemọ́lemọ́ ju bí àwọn ènìyàn ti rò lọ.” Ìròyìn náà ṣàlàyé pé, mànàmáná ń pa ènìyàn márùn-ún sí mẹ́wàá ní Australia lọ́dọọdún, ó sì ń ṣokùnfà ìpalára tí ó lé ní 100. Phil Alford láti Ọ́fíìsì Ìsàsọtẹ́lẹ̀ Nípa Ojú Ọjọ́ ní Melbourne sọ pé, kì í fi bẹ́ẹ̀ sí ìkìlọ̀ tí ó pọ̀ tó tí yóò bá ṣẹlẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé “àwọn ènìyàn kan tí ó kù díẹ̀ kí mànàmáná kọ lù ti ròyìn pé àwọn ń nímọ̀lára pé irun àwọn ń nàró ṣánṣán.” Kí ó má baà kọ lù ọ́, Alford dámọ̀ràn pé kí o sá fún àrá sínú ilé kan tí ó fìdí múlẹ̀ gírígírí tàbí sínú ọkọ̀ ìrìnnà kan tí òkè rẹ̀ le, tí kò sún mọ́ àwọn ilé onípáànù.

Ìsoríkọ́ Àwọn Arúgbó

Ìwé agbéròyìnjáde Jornal do Brasil sọ pé: “Ìsoríkọ́ àwọn arúgbó ń fara hàn lọ́nà tí ó yàtọ̀ sí ti àwọn tí wọn kò dàgbà tó bẹ́ẹ̀.” Dípò fífarahàn bíi làásìgbò tàbí hílàhílo, irú ìsoríkọ́ bẹ́ẹ̀ ń “fi ìpàdánù agbára ìdáǹkanmọ̀ hàn—bí agbára ìrántí, agbára ìpọkànpọ̀, àti agbára ìrònú.” Síwájú sí i, gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Paulo Mattos láti Yunifásítì Àpapọ̀ Rio de Janeiro ti sọ, “àwọn arúgbó tí wọ́n sorí kọ́ ń fi ìmọ̀lára ẹ̀bi tí ó rékọjá ààlà hàn nípa àwọn ohun tí kò já mọ́ nǹkan kan. Wọ́n kì í lọ́kàn ìfẹ́ nínú ohun tí wọ́n ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ rí tàbí ohun tí ó ti máa ń mú wọn dunnú tẹ́lẹ̀ rí,” títí kan ìjíròrò. Ìròyìn náà sọ pé, nígbà míràn a máa ń ṣi irú àwọn àmì bẹ́ẹ̀ kà sí èyí tí ó wulẹ̀ jẹ́ apá kan ọjọ́ ogbó. Dókítà Mattos sọ pé, láti lè mọ irú àwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀ nínú ìhùwà kí a sì dá ìsoríkọ́ mọ̀, “ó ṣe pàtàkì gidigidi pé kí àwọn ènìyàn máa dé ọ̀dọ̀ àwọn mẹ́ńbà ìdílé tí wọ́n jẹ́ arúgbó déédéé.”

Àwọn Ikán Tí Ń Wa Kùsà Góòlù

Ní 1984, ará abúlé kan rí góòlù ní orílẹ̀-èdè Niger, tí ó wà ní Áfíríkà, ìrọ́gììrì lọ síbi tí yóò wá jẹ́ ibi àwárí góòlù tuntun náà mú kí àwọn awakùsà ti orílẹ̀-èdè púpọ̀ wá sí àgbègbè náà. Onímọ̀ nípa ilẹ̀ ayé àti àwọn ohun alààyè inú rẹ̀, tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Kánádà náà, Chris Gleeson, rántí pé, àwọn ọ̀làjú Áfíríkà ìgbàanì lo òkìtì ọ̀gán ikán láti wá góòlù kàn. Oríṣiríṣi irú ọ̀wọ́ ikán tí ń mọ òkìtì ọ̀gán ńláńlá tí àwọn kan ga ní mítà 1.8 àti mítà 1.8 ní ìwọ̀n ìdábùú òbírí wà ní Niger. Ìwé ìròyìn National Geographic ṣàlàyé pé, àwọn òkìtì ọ̀gán náà ń fẹ̀ sí i bí àwọn ikán náà ṣe ń walẹ̀—tí ó máa ń jìn tó mítà 75 nígbà míràn—bí wọ́n ti ń wá omi. Gleeson bu iyẹ̀pẹ̀ lára ọ̀pọ̀ àwọn òkìtì ọ̀gán pẹ̀lú ìrètí pé wọn óò jẹ́ kí ó mọ ibi tí yóò gbẹ́. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àpẹẹrẹ náà kò ní góòlù nínú, àmọ́ àwọn kan ní! Ó ṣàwárí pé, “Góòlù wà ní gbogbo inú òkìtì ọ̀gán èyíkéyìí tí ó bá ti ní góòlù nínú.” Ó jọ pé bí àwọn ikán náà ti ń walẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń wá omi, ohun yòó wù kí wọ́n bá pàdé ni wọ́n ń wà jáde, títí kan góòlù.

Ìlànà Ìmọ̀wàáhù Lórí Tẹlifóònù Alágbèéká

Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Far Eastern Economic Review ti sọ, dídé àwọn tẹlifóònù alágbèéká àtẹ̀bàpò ti tẹnu mọ́ àìní fún àwọn ọ̀nà ìmọ̀wàáhù àtijọ́ kan. Ògbógi oníṣòwò ará Hong Kong náà, Tina Liu, fúnni níṣìírí fífi ọ̀wọ̀ àti ìgbatẹnirò hàn fún ẹni tí ó wà ní ìhà kejì àti fún àwọn tí wọ́n lè yí ọ ká. Ó gbani nímọ̀ràn láti sọ̀rọ̀ ketekete àmọ́ láìpariwo, kí a má sì máa jẹun tàbí mu nǹkan bí a bá ń sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù. Liu tún dámọ̀ràn jíjẹ́ kí àwọn ìtẹniláago tí a ń dáhùn nígbà tí àwọn ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́ mọ níwọ̀n àti dídarí dídún àwọn ìtẹniláago síbòmíràn tàbí yíyí i síhà fífi ìgbọ̀nrìrì sọ fúnni nípa ìtẹniláago ní àwọn ibi bí ilé ìwòsàn, ibi ìkówèésí, àti àwọn gbọ̀ngàn àpéjọ. Ṣíṣèdíwọ́ ní àwọn àkókò àṣeyẹ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà nípa gbígba ìtẹniláago lè mú kí àwọn ọ̀rẹ́ tàbí àwọn ẹbí ronú pé o pa wọ́n tì. Ní ti jíjẹun níta, Liu sọ pé: “Ì bá dára kí ẹnì kan tí ń sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù nígbà tí ó gbé obìnrin jáde tètè parí ọ̀rọ̀ tí ń sọ náà kí iṣẹ́ rere tí ìdì òdòdó rẹ̀ ṣe tó forí ṣánpọ́n.”

‘Àwọn Ohun Olómi Jíjáfáfá’

Níwọ̀n bí a bá ti fi iná mànàmáná sára àwọn ohun olómi kan tí ó ní àwọn èérún tí kò silẹ̀ nínú rẹ̀, àwọn èérún náà ń di àwọn ìsokọ́ra kéékèèké, tí ń mú kí ohun olómi náà túbọ̀ máa fà mọ̀dẹ̀mọ̀dẹ̀. Ìṣẹ̀lẹ̀ agbàfiyèsí yìí ni a ń pè ní ipa ìyọrísí Winslow, tí a fi orúkọ Ọ̀mọ̀wé W. M. Winslow, tí ó ṣàwárí rẹ̀ ní 1940, pè. Láti ìgbà náà wá, àwọn ilé iṣẹ́ ọkọ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn mìíràn, títí kan Ọ̀mọ̀wé Winslow fúnra rẹ̀, tí ó jẹ́ ẹni ọdún 93 báyìí, ṣì ń ṣe ìwádìí lọ lórí àmúlò irú ‘àwọn ohun olómi jíjáfáfá’ kan lọ́nà tí ó gbéṣẹ́. Àwọn olùṣàyẹ̀wò ní Yunifásítì Ìpínlẹ̀ Michigan ní United States mọ̀ pé ṣokoléètì oníwàrà tí ó ti yọ́ ní àwọn ohun kan tí ó jọra pẹ̀lú ti ‘àwọn ohun olómi jíjáfáfá.’ Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti finú wòye ìṣeéṣe kan, nínú àṣeyẹ̀wò kan tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí, ọ̀pá ṣokoléètì kan tí ó ti yọ́ fẹ́rẹ̀ẹ́ le gbagidi pa dà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí a ṣí i pa yá sí ìgbì iná mànàmáná alágbára kan. ‘Ohun olómi jíjáfáfá’ mìíràn tí ó ní ògì àgbàdo tí kò silẹ̀ nínú kẹrosíìnì, wà lónírúurú láàárín ìlegbagidi mílíìkì àti ti bọ́tà bí a ti ń yí líle ọwọ́ ìgbì mànàmáná náà pa dà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́