Igi Gbígbẹ́—Iṣẹ́ Ọnà Àtayébáyé Ilẹ̀ Áfíríkà
Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Nàìjíríà
Ó PẸ́ tí ọwọ́ àwọn agbẹ́gilére ti ń dí ní Benin City, tí ó wà ní ibi tí a mọ̀ sí ìhà gúúsù Nàìjíríà báyìí. Ní 400 ọdún sẹ́yìn, Benin City jẹ́ olú ìlú ilẹ̀ ọba ẹkùn ilẹ̀ igbó kan tí ó lágbára, tí a sì ṣètò lọ́nà títayọ. Àwọn òpópó fífẹ̀, tí ó tọ́ gbọnrangandan, àwọn ilé tí ó wà létòlétò, àti àwọn ènìyàn ìlú náà tí wọ́n ní àpọ́nlé, tí wọ́n sì ń pòfin mọ́, ya àwọn olùbẹ̀wò láti Europe lẹ́nu. Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, Benin City gbèrú bí ọ̀kan lára àwọn ibùdó ìṣòwò àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù ní ìhà ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà.
Àwọn ọba tí ń jẹ tẹ̀ léra ló ṣàkóso ilẹ̀ ọba Benin. Tọkàntara ni àwọn ọba náà gbé iṣẹ́ ọnà lárugẹ. Wọ́n fi àwọn ère orí tí a figi gbẹ́, àwọn àwòrán ara ògiri kíkọyọyọ tí a fi idẹ dà, àti àwọn ojúlówó eyín erin tí a gbẹ́ ṣe ọ̀ṣọ́ jìngbìnnì sára ààfin kíkàmàmà tó wà ní Benin City. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ère ìgbàanì tí a fi igi gbẹ́ kò bọ́ lọ́wọ́ ìgbóguntì ọjọ́ orí àti àwọn ikán, ó ṣe kedere pé àwọn agbẹ́gilére ṣiṣẹ́ ribiribi ní ilẹ̀ ọba náà. Martins Akanbiemu tó jẹ́ alábòójútó Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí ti Orílẹ̀-Èdè ní Èkó kọ̀wé pé: “Ẹgbẹ́ àwọn agbẹ́gilére . . . ló jọ pé ó ti wà tipẹ́ jù lọ lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ fún Ọba.”
Ní 1897, ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Britain fipá gba Benin City, ó sì kó àwọn ìṣúra iṣẹ́ ọnà rẹ̀ tí kò ṣeé díye lé ní báyìí—iye wọn lé ní 2,000—lọ sí Europe. Nísinsìnyí, a kì í pàtẹ àgbájọ tó pọ̀ jù lọ lára iṣẹ́ ọnà Benin ìgbàanì ní Nàìjíríà, bí kò ṣe ní àwọn ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí ní London àti Berlin.
Igi Gbígbẹ́ Lóde Òní
Lóde òní, Benin City jẹ́ ìlú tí èrò ti ń wọ́ lọ wọ́ bọ̀ bí ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn ní Nàìjíríà. Síbẹ̀, àwọn àpẹẹrẹ ògo rẹ̀ àtijọ́ ṣì kù níbẹ̀. Wọ́n ti tún ààfin kọ́, ọba tó wà lórí oyè nísinsìnyí sì ń gbébẹ̀. O lè rí iyàrà jíjìn tí wọ́n wà yí ìlú ńlá ìgbàanì náà ká; bí o bá sì tẹ́tí sílẹ̀ dáradára, o lè gbọ́ kọ̀ kọ̀ kọ̀ tí ìró ẹyá rọra ń dún lára igi.
Ọkùnrin kan tí ń jẹ́ Johnson ti ń gbẹ́gi lére ní Benin City fún 20 ọdún. Ní àwọn ọ̀rúndún tó ti kọjá, àwọn orí tí a fi igi gbẹ́ àti àwọn tí a fi idẹ dà ni a fi ń rántí àwọn tí wọ́n ti kú; a ń fi wọ́n ṣe àwọn pẹpẹ ìjọsìn àwọn babańlá lọ́ṣọ̀ọ́. Ṣùgbọ́n àwọn orí tí Johnson ń gbẹ́ kò jọ àwọn tí a ń lò fún ìjọsìn tẹ́lẹ̀. Ọ̀ṣọ́ lásán la ń fi àwọn tí ó ń gbẹ́ ṣe.
Johnson ń gbẹ́gi ẹ́bónì, igi líle kan, tí ó dùn gbẹ́. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ọṣán inú igi náà nìkan ló ń lò. Ọṣán inú igi ẹ́bónì ti Nàìjíríà sábà máa ń dúdú kiríkirí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn igi kan máa ń ní ọṣán tí àwọ̀ míràn ń lú tàbí tí ó wà láàárín àwọ̀ eléérú sí dúdú. Ó máa ń lo ìhà ìta igi náà díẹ̀ nínú igi tí ó ń gbẹ́; èyí máa ń mú kí ó ní àwọ̀ pupa wíwuni, tí ń ṣàlékún àwọ̀ dúdú náà. Àpapọ̀ ẹ́bónì aláwọ̀ pupa àti aláwọ̀ dúdú ń dán gbinrin lọ́nà rírẹwà.
Igi ẹ́bónì pọ̀ ní Nàìjíríà. Nígbà tí wọ́n bá gé igi ẹ́bónì, wọ́n máa ń fi sílẹ̀ nínú igbó kí ó lè da omi ara rẹ̀ nù. Kódà, lẹ́yìn tí ó bá kó gẹdú ẹ́bónì náà dé ibi iṣẹ́ rẹ̀, Johnson máa ń jẹ́ kí igi náà túbọ̀ gbẹ sí í fún oṣù mélòó kan kí ó tó lò ó. Èyí ṣe pàtàkì, nítorí pé ìrísí igi tí kò bá gbẹ lè yí pa dà, kí ó sì sán.
Nígbà tí Johnson bá ṣe tán tí ó fẹ́ gbẹ́gi lére, ó ń fi ayùn gé ìpórì igi náà sí nǹkan bí 40 sẹ̀ǹtímítà ní gígùn. Lẹ́yìn tí ó bá ti dúró fún ọ̀sẹ̀ kan sí i láti rí i dájú pé ìpórì náà kò sán, Johnson yóò fi ẹfun sàmì bí orí tí ó fẹ́ gbẹ́ náà ṣe máa rí sára igi náà, yóò wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.
Lákọ̀ọ́kọ́, ó ń lo ẹyá pẹlẹbẹ, lẹ́yìn náà, ó ń lo ẹyá títẹ̀, ó sì wá ń lo ẹyá mímú. Lẹ́yìn ìyẹn, ó ń fi ayùn yùn ún. Ó wá ń fi ọ̀bẹ agbẹ́gilére gbẹ́ ẹ parí. Bí Johnson ṣe ń ṣiṣẹ́, ó ń pọkàn pọ̀ gidigidi sórí igi náà. Àìpọkànpọ̀ lè sọ ère náà di èyí tí ń rẹ́rìn-ín sódì tàbí tí ojú rẹ̀ kò gún.
Lẹ́yìn tí wọ́n bá parí gbígbẹ́ igi náà, àwọn ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ Johnson yóò fi oríṣiríṣi pépà ìdánǹkan dán an. Níkẹyìn, wọn ń fi ọ̀dà ìkungi tàbí ìkunbàtà kùn ún, wọ́n sì ń fi búrọ́ọ̀ṣì ìdánbàtà dán an. Ó ń gba ọjọ́ méjì láti fi igi gbẹ́ orí kan bí irú àwọn tí ó wà nínú àwòrán. Ó ń gba ọjọ́ mẹ́ta sí i láti dán an, kí a sì kùn ún.
Bí Johnson bá gbẹ́ ẹ tán, ó ń gbé e sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan fún oṣù mélòó kan kí ó lè rí i dájú pé kò sán. Bí igi náà bá ti gbẹ dáradára kí wọ́n tó gbẹ́ ẹ, kò ní sán. Bí ó tì sábà ń rí nìyẹn. Bí a bá sì rí ipa sísán kan, a óò dá ère náà pa dà síbi iṣẹ́, a óò dí àlàfo ibi tó sán náà, a óò dán an, a óò sì tún un kùn.
Kíkọ́ Iṣẹ́ Igi Gbígbẹ́
Johnson ní ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ mẹ́fà tí ọjọ́ orí wọn bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 10 sí 18. Àkọ́sẹ́yìn ni wọ́n ń kọ́ṣẹ́ igi gbígbẹ́ náà, láti iṣẹ́ tó kẹ́yìn sí iṣẹ́ àkọ́kọ́ gan-an. Lọ́nà yí, ohun tí ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ kọ́kọ́ ń kọ́ ni kíkun ère náà lọ́dà. Lẹ́yìn náà, ó ń kọ́ bí a ṣe ń dán an. Lẹ́yìn náà, a ń fi bí a ṣe ń lo ayùn hàn án. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ọjọ́ náà ń dé, tí ó ń mu ẹyá pẹlẹbẹ, tí ó sì ń gbẹ́ ègé igi tí a kò ì gbẹ́ ibikíbi lára rẹ̀ ṣáájú.
Johnson wí pé: “Gbogbo ènìyàn kọ́ ni ó lè jẹ́ agbẹ́gilére. Lákọ̀ọ́kọ́, o gbọ́dọ̀ ní ẹ̀bùn àdánidá àti agbára láti pọkàn pọ̀. O tún ní láti kọ́ bí o ṣe lè ní sùúrù bí o ṣe ń tẹ̀ síwájú àti bí o ṣe lè kojú àwọn ìkùnà rẹ. O tún nílò ìfaradà, nítorí pé, ó kéré tán, ó ń gba ọdún mẹ́ta láti mọ igi gbẹ́ dáadáa. Àmọ́, kò mọ síbẹ̀—ẹ̀kọ́ kíkọ́ kò lópin. O lè máa mọ̀ ọ́n ṣe sí i bí o ti ń fi dánra wò nígbà gbogbo.”
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ikán àti Agbẹ́gilére
Àwọn kan sọ pé ikán ló fa ìdàgbàsókè iṣẹ́ ọnà ilẹ̀ Áfíríkà. Agbẹ́gilére náà ṣe ọnà kan, ikán (pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ojú ọjọ́ mímóoru) sì bà á jẹ́, nígbà míràn, láàárín ọjọ́ mélòó kan! Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá, ikán ti ń mú kí ọwọ́ agbẹ́gilére máa dí. Ó ti jẹ́ àṣetúnṣe tí ń mú nǹkan sunwọ̀n: Ikán ń bà á jẹ́, agbẹ́gilére náà tún ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lọ́tun, ó sì ń ní àǹfààní láti mú òye iṣẹ́ rẹ̀ sunwọ̀n sí i, kí ó sì mú ọnà ìronúwòye tuntun jáde.
Ìwé náà, African Kingdoms, sọ pé: “Èbíbu àti àwọn ikán aláápọn ti mú àǹfààní tí àwọn iṣẹ́ tó lọ́jọ́ lórí ní láti nípa lórí iṣẹ́ àwọn ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn kúrò lọ́nà púpọ̀. Ní ìyọrísí rẹ̀, bí àìní ti ń wà léraléra fún àwọn iṣẹ́ tuntun ni àǹfààní títóbi ń wà fún àìjọra; ìṣàfarawé ń dín kù, ẹnì kọ̀ọ̀kan sì lè gbára lé òye iṣẹ́ àti ìronúwòye tirẹ̀.”
Àwọn kan sọ pé àjọṣe yìí, láàárín ikán àti agbẹ́gilére, la lè fi ṣàlàyé ìtayọlọ́lá iṣẹ́ ọnà, tó ti mú kí iṣẹ́ ọnà ilẹ̀ Áfíríkà lókìkí bẹ́ẹ̀. Nínú ìwé rẹ̀, Nigerian Images, ọ̀mọ̀wé William Fagg sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a . . . gbóṣùbà fún ikán, tí ó ṣe pé, bó ti wù kí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìgbòkègbodò rẹ̀ má ṣètẹ́wọ́gbà fún ènìyàn tó, ó ti ń bá agbẹ́gilére ilẹ̀ olóoru ní àjọṣe tí ń lọ láìdẹwọ́ tí ó sì ń méso jáde lọ́pọ̀ yanturu, láàárín ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún àti ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rúndún.”
[Credit Line]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Ọ̀mọ̀wé Richard Bagine
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Gbígbẹ́ ọnà kan:
1. yíyan igi tó dára jù lọ,
2. sísàmì orí tí a fẹ́ gbẹ́,
3. lílo ẹyá, 4. dídán an, 5. kíkùn ún