Àṣírí Oorun Ẹranko
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ KẸ́ŃYÀ
OORUN—a ń lo nǹkan bí ìdámẹ́ta ìgbésí ayé wa ní ipò ìsinmi yẹn. Láìṣe ìfàkókòṣòfò, ó jọ pé oorun kúnjú àwọn àìní pàtàkì mélòó kan ní ti ara àti ti ìrònú òun ìhùwà. A lè tipa bẹ́ẹ̀ wo oorun bí ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.—Fi wé Orin Dáfídì 127:2.
Kò yani lẹ́nu pé oorun tún kó ipa pàtàkì kan ní àwùjọ àwọn ẹranko. Ní gidi, ọ̀pọ̀ ọ̀wọ́ wọn ní ń foorun rẹjú ní àwọn ọ̀nà tí ń fani lọ́kàn mọ́ra, tí ó máa ń dáni lára yá nígbà míràn, tí ó sì ń ṣàjèjì lọ́pọ̀ ìgbà. Jẹ́ kí a wo àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ kan.
Àwọn Àgbà Nínú Oorun Sísùn
Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti rí kìnnìún kan tí ń sùn, tí ó tàkaakà, tí ó ká àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè nínú oòrùn ọ̀sán gangan ilẹ̀ Áfíríkà lè parí èrò sí pé ẹranko ẹ̀yà ológbò rírorò yí rí gẹ́lẹ́ bí ológbò ọ̀sìn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìrísí ń tanni jẹ. Òǹkọ̀wé ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún náà, Thomas Campion, kọ̀wé pé: “Ta ló tó láti lọ tọ́ kìnnìún tí ń sùn?” Bẹ́ẹ̀ ni, kódà kìnnìún alágbára náà nílò oorun—nǹkan bí 20 wákàtí lóòjọ́—kí ó baà lè kógo ìgbésí ayé ìdọdẹpẹran rẹ̀ já.
Tún gbé ẹranko tuatara yẹ̀ wò, ẹranko aṣesùẹ̀sùẹ̀ tí ó wà ní New Zealand, tó jọ aláǹgbá. Ó ń lo nǹkan bí ìdajì ọdún ní ipò ìrẹjú fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́. Kódà, ẹranko tuatara ń ṣe sùẹ̀sùẹ̀ gan-an débi pé ó máa ń sùn tí ó bá ń jẹun lọ́wọ́! Ṣùgbọ́n ẹ̀rí wà pé gbogbo oorun yẹn ń ṣe àwọn àǹfààní kan fún un, nítorí pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fojú díwọ̀n pé àwọn ẹranko tuatara kan lè lò tó 100 ọdún láyé!
Bíi ti Rip Van Winkle inú ìtàn àròsọ, àwọn ìṣẹ̀dá mìíràn pẹ̀lú máa ń sùn fún àkókò gígùn. Ọ̀nà tí púpọ̀ wọn ń gbà la ìgbà òtútù nini já nìyẹn. Ní ìmúrasílẹ̀, ẹranko náà máa ń kó ọ̀pọ̀ ọ̀rá jọ sínú ara, èyí yóò máa ṣe oúnjẹ fún un láàárín àkókò gígùn tó fi ń sùn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kí ni kì í jẹ́ kí ẹranko tí ń sùn náà gan paali? Bí ìwé Inside the Animal World ṣe ṣàlàyé, ọpọlọ ń ru àwọn ìyípadà oníkẹ́míkà sókè nínú ẹ̀jẹ̀ ẹranko náà, èyí ń ṣẹ̀dá irú adènà ìganpaali kan. Bí ìdíwọ̀n ooru ara ìṣẹ̀dá náà ṣe ń dín kù, tí ó kù díẹ̀ kí ó dé ìpele ìtutùnini, ìwọ̀n ìlùkìkì ọkàn àyà rẹ̀ yóò dín kù sí ìpele kíkéré sí ìwọ̀n ìlọkiri rẹ̀ gidi; bí ó ṣe ń mí yóò sì dín kù. Oorun àsùnwọra yóò tẹ̀ lé e, ó sì lè pẹ́ tó ọ̀sẹ̀ mélòó kan.
Wọ́n Ń Sùn ‘Bí Wọ́n Ti Ń Fò Kiri’ Kẹ̀?
Àwọn ẹranko kan máa ń sùn lọ́nà kan tí ó ṣàjèjì. Ṣàyẹ̀wò ẹyẹ òkun tí a ń pè ní tern dúdú. Tí ọmọ ẹyẹ tern dúdú kan bá fi ìtẹ́ rẹ̀ sílẹ̀, ó máa ń dorí kọ òkun, ó sì máa ń fò láìdábọ̀ fún ọdún mélòó kan tó tẹ̀ lé e! Níwọ̀n bí ìyẹ́ ara rẹ̀ kò ti lè dènà omi, tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò sì ní abẹ̀bẹ̀ bíi ti àwọn ẹyẹ tern míràn tí ó lè bà lórí omi, ẹyẹ tern dúdú ń yẹra fún rírì sínú òkun. Ó máa ń dọdẹ nípa sísáré mú ẹja kéékèèké lójú omi.
Àmọ́ ìgbà wo ló máa ń sùn? Ìwé náà, Water, Prey, and Game Birds of North America, sọ pé: “Ó jọ pé wọn kò lè sùn lójú òkun nítorí pé ìyẹ́ wọn yóò fa omi mu. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan sọ pé ó ṣeé ṣe kí àwọn ẹyẹ wọ̀nyí máa sùn bí wọ́n ti ń fò kiri.”
Ìfoorun-Ọ̀sán-Rajú Lábẹ́ Omi
Ǹjẹ́ àwọn ẹja máa ń sùn? Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia ti sọ, lára àwọn ẹ̀dá eléegun lẹ́yìn, “àwọn ẹ̀dá afàyàfà, àwọn ẹyẹ, àti àwọn ẹranko afọ́mọlọ́mú nìkan ní ń sun oorun gidi, bí bátànì ìgbì ìṣiṣẹ́ ọpọlọ tí ń yí pa dà.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ẹja máa ń gbádùn àwọn àkókò ìsinmi tí ó jọ ti sísùn—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ wọn kò lè pajú dé.
Àwọn ẹja kan máa ń fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ sùn; àwọn mìíràn, ní ìtàkaakà tàbí ní ìnàró. Àwọn ẹja pẹlẹbẹ kan, bí ẹja flounder, ń wà ní ìsàlẹ̀ omi nígbà tí wọ́n bá wà lójúfò. Tí wọ́n bá ń sùn, wọ́n máa ń léfòó ní ìwọ̀n tó fi íńṣì díẹ̀ kúrò nísàlẹ̀ odò.
Ẹja ayékòótọ́ aláwọ̀ mèremère ní àṣà àrà ọ̀tọ̀ kan tí ó máa ń dá kí ó tó sùn: Ó máa ń wọ “aṣọ àwọ̀sùn.” Bí àkókò ìsinmi rẹ̀ ti ń sún mọ́, o máa ń pọ kẹ̀lẹ̀bẹ̀, tàbí ikun tí ń bo gbogbo ara rẹ̀. Fún ète wo? Òǹkọ̀wé nípa ẹ̀dá náà, Doug Stewart, sọ pé: “A ronú pé ó jẹ́ nítorí kí àwọn adọdẹpẹran má lè rí [i] ni.” Yóò jáde nínú aṣọ rẹ̀ oníkun nígbà tó bá jí.
Bákan náà, àwọn séálì ní àṣà gbígbádùnmọ́ni kan tí wọ́n sábà máa ń dá kí wọ́n tó sùn. Wọ́n máa ń fẹ́ afẹ́fẹ́ sí ọ̀fun wọn bíi fèrè, tí wọn óò wá ṣẹ̀dá irú ẹ̀wù ààbò ojú omi àdánidá kan. Bí èyí ti ń gbé wọn léfòó, wọ́n lè sùn bí wọ́n ti léfòó gbọọrọ lójú omi, tí imú wọn sì yọ sókè omi fún mímí.
Wọn Kò Sùn Wọra
Dájúdájú, sísùn nínú igbó ń mú kí ọwọ́ àwọn adọdẹpẹran lè tètè tẹ ẹranko kan. Nítorí èyí, ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀dá ni kì í sùn wọra. Ọpọlọ wọn ń wà lójúfò dé ìwọ̀n àyè kan tí wọ́n bá ń sùn, èyí sì ń jẹ́ kí wọ́n lè hùwà pa dà sí ìró èyíkéyìí tí ó bá jẹ́ eléwu. Síbẹ̀, àwọn ìṣẹ̀dá mìíràn ń là á já nípa ṣíṣọ́ àyíká déédéé. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ẹyẹ tí ń sùn ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ máa ń la ojú kan lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, wọn óò sì wò kiri, bóyá ewu wà.
Agbo àwọn ẹtu tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà ní Áfíríkà pẹ̀lú máa ń bá ara wọn ṣọ́ àyíká tí wọ́n bá ń sinmi. Nígbà míràn, odindi agbo náà yóò nà gbọọrọ sílẹ̀, ní gbígbé orí wọn sókè lójúfò. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ẹranko kan yóò fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀, yóò sì sùn fọnfọn sílẹ̀ gbalaja. Lẹ́yìn ìṣẹ́jú bíi mélòó kan, òmíràn nínú agbo náà yóò tún ṣe bákan náà.
Bákan náà, àwọn erin máa ń sùn bí agbo kan. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn tí wọ́n ti dàgbà sábà máa ń wà ní ìdúró, wọn óò sì rẹjú fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, tí wọn óò sì máa la ojú wọn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n ń gbé àwọn etí wọn fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀, wọ́n sì ń nà wọ́n láti lè gbọ́ ìró ewu èyíkéyìí. Lábẹ́ ààbò àwọn olùṣọ́ ńláńlá wọ̀nyí, àyè gba àwọn ọmọ kéékèèké láti dùbúlẹ̀, kí wọ́n sì sùn wọra. Nínú ìwé rẹ̀, Elephant Memories, òǹkọ̀wé Cynthia Moss rántí rírí agbo kan tí gbogbo wọn sùn lọ pé: “Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn ọmọ kéékèèké, lẹ́yìn náà àwọn tí wọ́n dàgbà díẹ̀, níkẹyìn àwọn abo tí wọ́n dàgbà jù lọ, gbogbo wọn dùbúlẹ̀, wọ́n sì sùn lọ. Nínú ìtànṣán òṣùpá náà, wọ́n dà bí àwọn àpáta ńlá rìbìtì aláwọ̀ ràkọ̀ràkọ̀, àmọ́ ìhan-anrun wọn onífọ̀kànbalẹ̀ tí ó rinlẹ̀ já ìrísí náà nírọ́.”
A ṣì ní ohun púpọ̀ láti kọ́ nípa ọ̀nà tí àwọn ẹranko ń gbà sùn. Ṣùgbọ́n tí o bá ṣàgbéyẹ̀wò ìwọ̀nba ohun tí a mọ̀, kò ha sún ọ láti ronú nípa àgbàyanu ọgbọ́n Ẹni tí ó “dá ohun gbogbo” bí?—Ìṣípayá 4:11.