Àwọn Wádòwádò Aládé—Ẹyẹ Ológbe, Abijólẹ́sẹ̀, Aláwọ̀ Mèremère
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ KẸ́ŃYÀ
WÁDÒWÁDÒ aládé jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹyẹ rírẹwà jù lọ lágbàáyé. Ó jẹ́ ẹyẹ kan tó gbayì gan-an, tí ó ní àwọn àwọ̀ títayọ àti ìrísí kíkọyọyọ. Ó gùn ju mítà kan lọ, nínà ìyẹ́ rẹ̀ gbòòrò púpọ̀, ọrùn rẹ̀ gígùn ń dáni lọ́rùn, bíi ti àwọn oríṣi wádòwádò míràn.
Akọ àti abo wádòwádò aládé jọra. Lọ́nà fífanimọ́ra, àwọn ìyẹ́ dúdú ẹ̀yìn ẹyẹ náà ń bo àwọn ìyẹ́ apá funfun báláú tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ méjèèjì, tó wá di olómiwúrà nítòsí ìrù. Àwọn ìyẹ́ apá tó kù ní àwọ̀ ilẹ̀ bíi ti èso chestnut.
Ìrísí ojú wádòwádò aládé ń múni láyọ̀. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ máa ń ní àwọ̀ ìyeyè rẹ́súrẹ́sú, àwọn ìyẹ́ orí tó rí múlọ́múlọ́, tó láwọ̀ ẹ́bónì, tó wà ní àtàrí àti ọ̀fun, sì yí i ká. Àwọn ojú náà ní àwọ̀ òféfèé rírẹwà. Nígbà tí wádòwádò náà bá na ọrùn rẹ̀ sọ́ọ̀ọ́kán, jọ̀jọ̀ pupa bẹ́lẹ́jẹ́ kan tó gùn, tó wá láti ibi ìyẹ́ dúdú ọ̀fun rẹ̀, máa ń fì bí àsorọ̀ gbẹ̀dẹ̀ pípọ́n fòò. Èyí tí ń gbàfiyèsí jù lọ ni àrímáleèlọ ìdì ìyẹ́ orí rẹ̀ tí ó ṣe tọ́ọ́rọ́tọ́ọ́rọ́, tí ó lómi wúrà, tí ó para pọ̀ di adé gígúnrégé tó sì kàmàmà. Àwọn ìyẹ́ tíntìntín dídányanran wọ̀nyí máa ń dán bíi wúrà nígbà tí ìtànṣán oòrùn bá tàn sí wọn. Gbogbo àwọn àwọ̀ gbígbàfiyèsí, yíyàtọ̀síra wọ̀nyí para pọ̀ ṣọ̀kan sórí àwọn ẹsẹ̀ gígùn méjì, tó dúdú, tí kò tóbi.
Ìró wádòwádò aládé tí ń dún bí ìpè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìró mánigbàgbé ilẹ̀ Áfíríkà: O-wahng! O-wahng! O-wahng! Igbe tí ń dún sókè yí ṣeé gbọ́ níbi jíjìnnà gidigidi. Nígbà púpọ̀, wádòwádò méjì yóò ké pọ̀ bí wọ́n ṣe ń fò lọ sórí igi tí wọ́n ń wọ̀ sí tàbí tí wọ́n ń fò bọ̀ látibẹ̀. Ní àwọn àkókò kan láàárín ọdún, àwọn wádòwádò aládé máa ń pàdé pọ̀, wọ́n sì lè tó 30, tí wọn yóò máa mú ìró híhan tí kò bára dọ́gba, tí ń dùn létí, jáde.
Ìtọ́jú Òbí
Àwọn wádòwádò aládé máa ń fẹ́ ara wọn ní tọkọtaya jálẹ̀ ìgbésí ayé ni. Wọ́n wà ní ibi púpọ̀ ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà, ní pàtàkì, ní àwọn àgbègbè irà àti àbàtà, tí wọ́n ń kọ́ ìtẹ́ sí, tí wọ́n sì ti ń tọ́ àwọn ọmọ wọn. Ìtẹ́ náà máa ń jẹ́ ìtòjọ gegere koríko àti òrépèté tó ní ìrísí àrọ tó dà bíi pèpéle, tí abo náà ń yín ẹyin méjì tàbí mẹ́ta lé lórí, àwọn ẹyin aláwọ̀ ewé òun búlúù. Akọ àti abo náà ń pín ara wọn láti sàba lé àwọn ẹyin náà, wọ́n sì ń pamọ láàárín oṣù kan. Àwọn òbí ń pawọ́ pọ̀ bọ́ àwọn ọmọ wọn abìyẹ́ múlọ́múlọ́, wọ́n ń bójú tó wọn, wọn yóò sì dáàbò bo àwọn ọmọ wọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gúnyẹ̀ẹ́ láìbẹ̀rù.
Àwọn kòkòrò, àkèré, ejò kéékèèké, àti hóró, ni olórí oúnjẹ àwọn wádòwádò aládé. Wọ́n máa ń fi ẹsẹ̀ wọn gígùn, tó tín-ínrín, àti àtẹ́lẹsẹ̀ wọn tó fẹ̀, kilẹ̀, wọn óò sì yára ṣa ẹ̀dá kékeré èyíkéyìí tí ó bá sá jáde nínú koríko jẹ.
Ijó Alálọ̀ọ́yípo Àwọn Ẹyẹ
Onítara àti adánilárayá oníjó ni àwọn wádòwádò aládé. Bí wọ́n ti ń lu ìyẹ́ ńlá apá wọn rírẹwà, wọ́n ń gbéra sókè sínú afẹ́fẹ́ lóòró gangan, wọ́n sì wá ń balẹ̀ dòò bíi pé wọ́n rọ̀ mọ́ ìhùmọ̀ inú ọkọ̀ òfuurufú tí a fi ń balẹ̀ láìfarapa. Wọ́n ń fò síhìn-ín sọ́hùn-ún nínú ọlá ńlá, wọ́n ń sáré, wọ́n ń tọ sókè, wọ́n ń yí èkejì wọn po, wọ́n sì ń yára kanrí mọ́lẹ̀ léraléra, lọ́nà tí ń pani lẹ́rìn-ín. Ní nína àwọn ìyẹ́ apá wọn ńlá, wọ́n ń nàró tán, wọ́n sì ń ṣàfihàn àwọn àwọ̀ rírẹwà tí àwọn ìyẹ́ apá wọn ní.
Nígbà míràn, tọkọtaya kan yóò yí ọrùn wọn lọ́nà ẹlẹ́wà ọlá, wọn yóò sì máa wo ojú ara wọn. Bí wọ́n ti kọ àgógó síra wọn, wọn yóò dún ìdún jíjinlẹ̀ mélòó kan, ní ohùn ìsàlẹ̀, bíi pé wọ́n ń ṣelégbè ara wọn. Bí wọ́n ti ń pa dà sí ìnàró lẹ́ẹ̀kan sí i, wọ́n tún ń kò sí ijó alálọ̀ọ́yípo wọn.
Ìsapá Láti Máa Wà Nìṣó
Àwọn wádòwádò aládé ní àmúmọ́ra fún ẹ̀dá ènìyàn, ó sì rọrùn láti mú wọn sìn. Nítorí àwọ̀ àti ìrísí wọn jíjojúnígbèsè àti ijó wọn tí ń dáni lára yá, wọ́n lókìkí nínú àwọn ọgbà ẹranko, a sì máa ń fẹ́ fi wọ́n ṣe àwọn ilé ńlá àti àwọn ọgbà lọ́ṣọ̀ọ́. Níwọ̀n bí a ti nílò wọn tó bẹ́ẹ̀, kò yani lẹ́nu pé iye wọn ń dín kù. Àwọn wádòwádò aládé tún ń kojú ìṣòro nítorí yíyí tí a ń yí àwọn ilẹ̀ olómi pa dà di ibùgbé ènìyàn àti lílò tí a ń lo àwọn májèlé àti egbòogi apakòkòrò, tí ń ba àwọn adágún àti odò kéékèèké jẹ́.
Yóò bani nínú jẹ́ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé lọ́jọ́ kan, a kò rí wádòwádò aládé àrímáleèlọ mọ́, a kò sì gbúròó rẹ̀ mọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, Bíbélì ṣèlérí pé láìpẹ́, gbogbo ilẹ̀ ayé yóò di ọ̀tun. (Fi wé Pétérù Kejì 3:13.) Nígbà náà, gbogbo olùgbé ilẹ̀ ayé yóò ní inú dídùn láéláé nínú àgbàyanu iṣẹ́ ìṣẹ̀dá Olùṣẹ̀dá Ẹni Ọ̀run náà, Jèhófà Ọlọ́run, àti nínú àwọn ológbe, abijólẹ́sẹ̀, aláwọ̀ mèremère tí ó ṣẹ̀dá.