Brolga, Cassowary, Emu, àti Jabiru—Díẹ̀ Lára Àwọn Ẹyẹ Ṣíṣàrà Ọ̀tọ̀ ní Australia
Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Australia
NÍ LÍLO ẹsẹ̀ èékánná rẹ̀ bíbani lẹ́rù, ẹyẹ cassowary tí kò lè fò, tí a ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ tí ó léwu jù lọ lágbàáyé, lè tọ sókè, kí ó ta ìpá, kí ó sì fa nǹkan ya pẹ̀lú ipá gígadabú. Òmíràn tún fara jọ èyí, tí òun pẹ̀lú dìhámọ́ra dáradára, mọ̀lẹ́bí rẹ̀, ẹyẹ emu, kò nílò apá—ó yára bí ẹ̀fúùfù. Nígbà tí ẹyẹ brolga bá ń jó ijó oge, ó máa ń pòkìkí agbára ìmòye àrà ọ̀tọ̀ Ẹlẹ́dàá àti Olùṣètò Ijó Oge rẹ̀. Ẹyẹ jabiru sì jẹ́ àpẹẹrẹ iyì àti ìséraró ẹ̀dá abìyẹ́ ní ti odò wíwọ́, gíga, àti pípẹ́lẹ́ńgẹ́. Yálà idì abìrùṣíṣùpọ̀ náà ń fò tàbí ó ń ṣọ́ ohun kan tí ó pa, ó máa ń ṣàṣehàn ìrísí ọdẹ ojú òfuurufú aláìlábùkù rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹyẹ gíga lọ́lá wọ̀nyí jẹ́ ìyanu ìṣẹ̀dá ní tòótọ́. Nígbà náà, pẹ̀lú ìdùnnú ni a tọ́ka sí . . .
Ẹyẹ Cassowary Jíjojúnígbèsè —Olùṣàǹfààní fún Ẹgàn
Ẹyẹ ìhà gúúsù, tàbí ẹyẹ oníjọ̀jọ̀ méjì, cassowary, tí ó wọn 30 sí 60 kìlógíráàmù, tí ń gbé inú ẹgàn ìhà ìlà oòrùn àríwá Australia àti New Guinea jẹ́ ẹyẹ rírẹwà ṣùgbọ́n adánìkanrìn ni. Ó ga tó nǹkan bíi mítà méjì, abo rẹ̀ tóbi ju akọ lọ, àti pé—lọ́nà tí ó ṣàjèjì fún ẹyẹ kan—ó túbọ̀ láwọ̀ mèremère ju akọ, tí ó máa ń fọgbọ́n yẹra fún abo tí sáà àkókò gígùn bá ti kọjá lọ. Lẹ́yìn gígùn, abo náà máa ń yín ọ̀wọ́ ẹyin aláwọ̀ ewé títàn, ṣùgbọ́n lẹ́yìn náà, yóò wulẹ̀ rìn lọ, tí yóò sì fi akọ sílẹ̀ láti sàba lé wọn, kí ó sì bójú tó àwọn ọmọ. Yóò tún lọ gùn pẹ̀lú àwọn akọ mìíràn, tí yóò sì fi ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sílẹ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ́ ẹ̀yin láti bójú tó!
Bí ó ti wù kí ó rí, pípa igbó run ń ṣèparun fún àwọn ẹyẹ cassowary. Nínú ìgbìyànjú láti mú kí iye wọ́n pọ̀ sí i, Ibi Ààbò Ohun Alààyè ti Billabong, nítòsí Townsville, Queensland, ti ṣàgbékalẹ̀ ètò ìtọ́jú àwọn ẹyẹ tí a mú, èyí tí a pète láti máa dá àwọn ẹyẹ padà sínú igbó tí wọ́n bá ti dàgbà tó. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ajẹran-jewé ni àwọn ẹyẹ cassowary, ní pàtàkì, èso ni wọ́n máa ń jẹ, wọ́n sì máa ń gbé e mì lódindi ni. Nípa bẹ́ẹ̀, hóró èso irú ọ̀wọ́ irúgbìn tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún ni àwọn ẹyẹ náà máa ń gbé kiri nínú wọn láìdà, tí wọ́n sì máa ń fún wọn káàkiri inú igbó nínú ìgbẹ́ ẹyẹ tí ń já bọ́ láti òfuurufú gẹ́gẹ́ bí ààbò àti ajílẹ̀. Àwọn ògbógi ní ibi ààbò náà sọ pé èyí lè mú kí ẹyẹ cassowary jẹ́ irú ọ̀wọ́ tí àwọn ohun mìíràn fẹ̀yìn tì, ní ti pé bí òún bá kú run, ọ̀pọ̀ irú ọ̀wọ́ irúgbìn pẹ̀lú yóò kú run lọ́nà gbígbàfiyèsí. Ṣùgbọ́n ṣé ẹyẹ jẹ́ bí ewu sí ẹ̀dá ènìyàn bí?
Sí àwọn òmùgọ̀ tí wọ́n bá sún mọ́ ọn jù nìkan ni. Ní tòótọ́, àwọn ẹ̀dá ènìyàn ni wọ́n jẹ́ ewu sí àwọn ẹyẹ cassowary ju bí òún ṣe jẹ́ sí wọn lọ. Nínú ẹgàn tí ó ṣú dùdù, ẹyẹ náà máa ń ké igbe ṣíṣàjèjì kan tí ó rinlẹ̀, láti kìlọ̀ fún ọ pé òún wà nítòsí. Ṣègbọràn sí ìtanilólobó náà; má ṣe sún mọ́ ọn jù. Ó lè jẹ́ pé abẹ́ àwọn irúgbìn tí ó wà níbàǹbalẹ̀ ni yóò gbà jà, ní lílo ìbòrí, tàbí akoto rẹ̀ líle koránkorán, láti dáàbò bo orí rẹ̀. Ṣùgbọ́n tí a bá ká a mọ́, tàbí tí ó bá fara pa tàbí tí ó bá ń dáàbò bo ọmọ rẹ̀, ó lè kọluni bí a bá sún mọ́ ọn jù.
Ẹyẹ Emu—Alárìnká àti Ohun Àmì Ìṣàpẹẹrẹ Orílẹ̀-Èdè
Ẹyẹ emu tí ó bá cassowary tan gan-an, tí ó sì ga jù ú lọ díẹ̀, wà ní ibi púpọ̀ jù lọ ní àwọn agbègbè àrọ́ko Australia. Ní àwùjọ àwọn ẹyẹ, ògòǹgò nìkan ló tóbi jù ú lọ. Ẹyẹ emu tí ẹ̀rù tètè máa ń bà yìí ní ẹsẹ̀ gígùn, lílágbára, tí ó dáńgájíá láti máa bẹ́ ní ìwọ̀n ìyára nǹkan bí 50 kìlómítà ní wákàtí, ẹsẹ̀ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan sì ní èékánná mẹ́ta tí ó lè ṣèparun bíi ti ẹyẹ cassowary. Bí ó ti wù kí ó rí, láìdà bíi ti ìbátan rẹ̀ tí ń wà ní agbègbè kan ṣoṣo, ẹyẹ emu jẹ́ alárìnká tí ń fẹsẹ̀ palẹ̀ kiri, kì í sì í sábà ṣe jàgídíjàgan. Ohunkóhun ló lè jẹ—ìdin labalábá, ewé, àti àwọn ògbólógbòó bàtà pàápàá! Gbàrà tí abo ẹyẹ emu bá ti yín ẹyin rẹ̀ aláwọ̀ ewé kirikiri—tí ó sábà máa ń jẹ́ ẹyọ 7 sí 10, ṣùgbọ́n tí ó máa ń tó 20 lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan—ńṣe ni òun náà, máa n yanṣẹ́ fún akọ rẹ̀ láti sàba, kí ó sì ṣètọ́jú ọmọ bíi ti ẹyẹ cassowary.
Àwọn olùtẹ̀dó ará Europe fa ìnira fún ẹyẹ emu. Àwọn olùtẹ̀dó tètè pa á run ní Tasmania. Ní orí ilẹ̀ pẹ̀lú, nítorí pé ó kúndùn ọkà àlìkámà ni wọ́n ṣe kà á sí ayọnilẹ́nu, tí ó sì jìyà lọ́wọ́ àwọn apẹrangbẹ̀bùn. Síbẹ̀, lójú pé a ń pa wọ́n láìdáwọ́dúró, iye àwọn ẹyẹ emu fi agbára ìkọ́fẹpadà rẹ̀ hàn, gan-an débi pé ní Ìhà Ìwọ̀ Oòrùn Australia, wọ́n polongo ìgbógunti ẹyẹ náà lójúkojú ní ọdún 1932. Ìjọba ṣàmúlò ẹgbẹ́ ọmọ ogun àti àwọn àgbá arọ̀jò ọta ti Lewis méjì! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò gbajúmọ̀ nítorí agbára ìmòye rẹ̀, ẹyẹ emu borí ogun náà. “Ogun” náà jẹ́ ìfiniṣẹ̀sín ìtagbangba àti ìkójútìbáni ti ìṣèlú; ẹgbàárùn-ún ọta tí wọ́n lò pa kìkì ọgọ́rùn-ún bíi mélòó kan. Ṣùgbọ́n nínú ogun ìhalẹ̀mọ́ni tí wọ́n ṣè lẹ́yìn náà—ẹyẹ emu, ní ìdojúkọ ìkọlù alápá méjì ti àwọn ọdẹ apẹrangbẹ̀bùn ṣe sí àwọn ẹyẹ náà àti ìpèsè ohun ìjà lọ́fẹ̀ẹ́ fún àwọn àgbẹ̀, èyí tí ìjọba ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀—ẹyẹ emu kò lè kojú ìkọlù náà mọ́.
Bí ó ti wù kí ó rí, lákòókò yìí, ẹyẹ emu jẹ́ ohun àmì ìṣàpẹẹrẹ orílẹ̀-èdè. Wọ́n yàwòrán rẹ̀ tí ó kọjú sí ẹranko kangaroo kan pẹ̀lú ìyangàn lára àmì ìṣàpẹẹrẹ orílẹ̀-èdè Australia, ó sì ń fẹsẹ̀ palẹ̀ kiri igbó náà láìsí ìpalára. Ọ̀dá ni ó kórìíra jù lọ nísinsìnyí. Wọ́n tilẹ̀ máa ń bọ́ àwọn ẹyẹ emu, wọ́n sì máa ń fi wọ́n dọ́sìn ní ṣíṣàyẹ̀wò onírúurú àwọn àṣèmújáde: ẹran tí kò ní ọ̀rá nínú rárá; awọ nínípọn, tí ó lálòpẹ́; ìyẹ́; àti òróró tí a mú jáde lára ọ̀rá rírọ̀ bẹ̀tẹ̀bẹ̀tẹ̀ ọrùn ẹyẹ náà. Nítorí pé ọ̀rá ṣẹ̀gẹ̀dẹ̀ sí ibi kan pàtó yìí ni ẹran rẹ̀ kò ṣe ní ọ̀rá rárá.
Ṣé O Fẹ́ẹ́ Jó?
Bóyá o kò fẹ́ẹ́ jó, ṣùgbọ́n dájúdájú, ẹyẹ brolga fẹ́ẹ́ jó. Ìwé The Waterbirds of Australia sọ pé, ní “ilé ijó” wọn lẹ́bàá omi, “iyekíye [àwọn wádòwádò aláwọ̀ eérú wọ̀nyí], láti orí ẹyẹ méjì sí nǹkan bíi méjìlá, yóò tò bíi pé nídojúkọra, wọn óò sì bẹ̀rẹ̀ sí í jó. Wọ́n óò tẹ̀ sí iwájú lórí ẹsẹ̀ wọn bí àgéré pẹ̀lú apá tí wọ́n ṣí láàbọ̀, wọn óò sì máa mì lẹ̀ǹgbẹ̀. Ní títẹ orí wọn balẹ̀ àti gbígbé e sókè sódò, wọn óò máa gbésẹ̀ síwájú, wọn óò sì máa gbé e sẹ́yìn, wọn óò máa dún ìdún kọ̀kọ̀kọ̀kọ̀ àti bíi fèrè ní fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ẹyẹ kan yóò dúró, ní fífi orí rẹ̀ sẹ́yìn, yóò dún ìdún kàkàkí kíkankíkan. Àwọn ẹyẹ náà tún lè fò sókè díẹ̀, kí wọ́n sì padà sílẹ̀ pẹ̀lú apá fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ aláwọ̀ dúdú àti àwọ̀ eérú. Àwọn ẹyẹ Brolga ń fẹ́ àwọn èérún ewéko tàbí koríko sófuurufú, wọ́n sì ń gbìyànjú láti hán àwọn èérún náà tàbí kí wọ́n fi àgógó ṣá wọn, bí wọ́n ṣe ń bọ́ sílẹ̀.” Ó jẹ́ eré tí ń runi sókè, ní pàtàkì ní ríronú nípa ìtóbi ẹyẹ náà, tí ó ga ju mítà kan lọ, tí apá rẹ̀ sì fẹ̀ tó mítà méjì!
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ irú ọ̀wọ́ àwọn ẹyẹ ń tage lọ́nà gígọntiọ lákòókò tí wọ́n bá ń pamọ, ẹyẹ brolga, ọ̀kan lára àwọn ẹyẹ wádòwádò títóbi jù lọ, jẹ́ oníjó jálẹ̀ ọdún. Ní tòótọ́, a mú orúkọ rẹ̀ láti inú ìtàn àwọn Aborigine nípa gbajúmọ̀ obìnrin oníjó kan tí ń jẹ́ Buralga. Kò fara mọ́ àfiyèsí tí pidánpidán ẹlẹ́mìí èṣù kan ń fún un. Ìyẹn sì sọ ọ́ di wádòwádò ọlọ́láńlá kan.
Ẹyẹ Jabiru—Àkọ̀ Kan Ṣoṣo Tí Australia Ní
Ẹyẹ jabiru, tàbí àkọ̀ ọlọ́rùn dúdú, tí ó tún jẹ́ ẹyẹ tí ń gbé ilẹ̀ àbàtà, sábà máa ń lọ sí ìhà àríwá àti ìlà oòrùn etíkun, tí ó jẹ́ agbègbè olóoru ní Australia. (Irú ọ̀wọ́ ẹyẹ àkọ̀ tí ó yàtọ̀ ni ẹyẹ jabiru ti Gúúsù America.) Ẹyẹ jabiru tẹ́ẹ́rẹ́, tí ó jẹ́ 130 sẹ̀ǹtímítà ní gígùn, tí àwọ̀ rẹ̀ ń gbàfiyèsí ẹni, dá yàtọ̀ gedegbe láàárín ẹgbàágbèje àwọn ẹyẹ mìíràn tí ń gbé ilẹ̀ àbàtà. Tí ó bá ń wá ìjẹ nínú omi tí kò jìn púpọ̀, yóò ki àgógó rẹ̀ gígùn, tí ó lágbára sínú omi pẹ̀lú ipá gan-an débi pé ó ní láti ṣí apá rẹ̀ díẹ̀, kí ó lè dúró tiiri láti kápá ìwọ̀n ipá náà.
Ẹ sì wo bí àwọn apá náà ṣe lágbára tó! Bí ẹyẹ jabiru bá na àwọn apá rẹ̀ tí ó jẹ́ nǹkan bí mítà méjì láti ìkangun kan sí èkejì, tí ó sì na àwọn lájorí iyẹ́ rẹ̀ bí ìka, ńṣe ni yóò pa bìnàbìnà lọ sókè jẹ́ẹ́ títí tí yóò fi dà bí àgbélébùú kékeré kan lófuurufú. Ní tòótọ́, ẹyẹ jabiru, tí ń fi afẹ́fẹ́ ṣagbára, tí ó ní apá, ọrùn, àti ẹsẹ̀ gígùn tí ó yọ òjìji níwájú oòrùn pupa roboto tí ń wọ̀ ní agbedeméjì ayé, jẹ́ àmì ilẹ̀ àbàtà àríwá Australia tí a ṣìkẹ́.
Idì Abìrùṣíṣùpọ̀—Ọba Òfuurufú
Nítòsí ṣóńṣó orí òkè ńlá olókùúta kan ní Victoria, àti ní kíkojú ẹ̀fúùfù líle tí ó lé gbogbo àwọn ẹyẹ mìíràn kúrò lójú òfuurufú, idì abìrùṣíṣùpọ̀ kan ń ṣeré kiri ojú òfuurufú ní tirẹ̀. Òǹkọ̀wé David Hollands wòran ìfòkiri agbàfiyèsí tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo tí yóò wò láyé rẹ̀, ó wí pé: “Idì náà wà lókè níbẹ̀, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà kúrò lójú kan, ara sì tù ú gidigidi lójú gbalasa oníjì líle yìí. . . . Bí mo ti ń wò ó, ó wálẹ̀, ní pípa apá rẹ̀ mọ́ra láti já wálẹ̀ dòò. Fún ọgọ́rùn-ún mítà, ó já wálẹ̀ dòò, lẹ́yìn náà, àwọn apá rẹ̀ tún ṣí díẹ̀, èyí sì jẹ́ kí ó gbéra lọ sókè láti tún padà sí ibi tí ó ti ń já bọ̀ wálẹ̀. . . . Ó lọ́ bìrìpó, lẹ́yìn náà, ó fò lọ sókè gan-an [ó sì] tún ìlọ́bìrì náà ṣe léraléra, ní fífò lọ́nà àràbarà lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì náà, ó sì tún fò lọ sókè nínú àṣehàn tí ó wà pẹ́ títí, tí ó sì ń wúni lórí.”
Nítorí pé ó ní apá tí ó fẹ̀ ní mítà 2.5 àti ìrù ṣíṣù pọ̀ tí ó yàtọ̀ gedegbe, a kò lè ṣi ọba ẹyẹ ọlọ́láńlá, tí ó sì lágbára yìí mú fún ẹyẹ mìíràn ní ojú òfuurufú Australia. Àwọn èékánná rẹ̀ lè wa nǹkan mú ní ìwọ̀n agbára tí ó tó tọ́ọ̀nù mẹ́ta! Bí ó ti wù kí ó rí, fún ìgbà díẹ̀, ọ̀nà “yíyẹ” kan ṣoṣo láti rí idì abìrùṣíṣùpọ̀ jẹ́ nígbà tí wọ́n bá ń fi ìbọn dọdẹ rẹ̀. Bíi ti ìbátan rẹ̀, idì apárí ti America, tí wọ́n yìnbọn pa láìṣàánú láti dáàbò bo àwọn ilé iṣẹ́ ẹja salmon àti irun ẹranko, wọ́n ṣe inúnibíni sí idì Australia yìí nítorí pé ó máa ń pa ọ̀dọ́ àgùntàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ìwé Birds of Prey sọ pé: “Ìwọ̀nba díẹ̀ ni àwọn ẹyẹ ìfiṣèjẹ [ẹyẹ ẹran ọdẹ] tí wọ́n ṣe inúnibíni líle koko sí lágbàáyé bí wọ́n ti ṣe sí Idì Abìrùṣíṣùpọ̀ . . . Fún nǹkan bí 100 ọdún, a kà á sí aṣèpalára . . . , a sì san ẹ̀bùn owó fún ẹni tí a bá rí ẹ̀rí pe ó pa lára wọ́n.”
Bí ó ti wù kí ó rí, ni àwọn ọdún tó ti kọjá, wọ́n dáwọ́ ìgbéjàkò náà dúró. Lájorí oúnjẹ rẹ̀ wá jẹ́ òkété, àti lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ẹran ìbílẹ̀, tí ó ní nínú ẹranko wallaby tí ó tóbi jù ú lọ ní ìlọ́po méjì. Níkẹyìn, ìṣípayá yìí mú kí idì náà jèrè ìbádọ́rẹ̀ẹ́ àti ìdáàbòbò tí a fàṣẹ sí lọ́dọ̀ ènìyàn.
Lóòótọ́, ẹ wo bí àwọn ẹyẹ ṣe jẹ́ apá pàtàkì yíyani lẹ́nu, tí ó díjú, tí ó sì lẹ́wà tó nínú àjọṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn! Bópẹ́bóyá, a lè kẹ́kọ̀ọ́ èyí, ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń pẹ́ kí a tó rí ọgbọ́n yìí kọ́—lẹ́yìn tí ìwọra àti àìmọ̀kan bá ti ṣèpalára. Ṣùgbọ́n ẹ wo bí ó ti ń tuni nínú tó láti mọ̀ pé, bí a bá fiyè sílẹ̀ nísinsìnyí pàápàá, a lè gbádùn dídún kọ̀kọ̀kọ̀kọ̀, dídún ṣíoṣío, sísúfèé, híhan, dídún bíi fèrè, dídún ìdún pẹ́pẹ́yẹ, àti pípariwo ní òfuurufú, nínú ẹgàn, àti ní ilẹ̀ àbàtà pílánẹ́ẹ̀tì ẹlẹ́wà yìí!
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ẹyẹ “cassowary”
Ẹyẹ “brolga”
[Credit Line]
Apá òsì àti ìsàlẹ̀: Australian Tourist Commission (ATC); àárín lápá òkè àti apá ọ̀tún: Billabong Sanctuary, Townsville, Australia
[Àwọn Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Idì
Ẹyẹ “emu”
Ẹyẹ “jabiru”
[Credit Line]
Àwọn ọmọ idì àti orí emu: Graham Robertson/NSW National Parks and Wildlife Service, Australia; idì tí ń fò: NSW National Parks and Wildlife Service, Australia; emu àti ọmọ rẹ̀ àti jabiru: Australian Tourist Commission (ATC)
[Àwọn Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 15]
Apá òsì: Graham Robertson/NSW National Parks and Wildlife Service, Australia; apá ọ̀tún: Australian Tourist Commission (ATC); òkè: Billabong Sanctuary, Townsville, Australia