ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 11/8 ojú ìwé 18-21
  • Wọ́n Mú Wa Ní Àmúdá Nígbà Ìrúkèrúdò Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Mú Wa Ní Àmúdá Nígbà Ìrúkèrúdò Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Kan
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìrúkèrúdò Náà Bẹ́ Sílẹ̀
  • Àwọn Tí Wọ́n Mú Ní Àmúdá Pọ̀ Sí I
  • Ìwà Ipá Náà Ń Pọ̀ Sí I
  • Ó Jọ Pé Ikú Rọ̀ Dẹ̀dẹ̀
  • Ṣíṣàjọ̀dún Ìṣe Ìrántí
  • Ìrírí Agbonijìgì Náà Dópin
  • Mò Ń retí Ìjọba Kan Tí “Kì í Ṣe Apá Kan Ayé Yìí”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Títan Irúgbìn Ìjọba Kálẹ̀ ní Gbogbo Ìgbà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Àbí Ohun Táa Pè Lójútùú Ló Ń Dá Kún Ìṣòro?
    Jí!—2001
  • Èmi Ògbóǹkangí Olóṣèlú Tẹ́lẹ̀ Di Kristẹni Tí Kò Dá Sí Ìṣèlú Mọ́
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 11/8 ojú ìwé 18-21

Wọ́n Mú Wa Ní Àmúdá Nígbà Ìrúkèrúdò Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Kan

NÍ NǸKAN bí agogo mẹ́ta ọ̀sán, ní ọjọ́ Saturday, March 30, 1996, èmi àti Edgardo Torres, pẹ̀lú Rubén Ceibel, gúnlẹ̀ sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Ẹlẹ́ṣọ̀ọ́ Gíga Jù Lọ ti Sierra Chica, ní ẹkùn ilẹ̀ Buenos Aires, Argentina. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kọ́ ọ láti gba nǹkan bí 800 ẹlẹ́wọ̀n, ọ̀daràn 1,052 tí a ti ṣèdájọ́ wọn ló wà nínú odi tí ó kún àkúnya yìí. Ẹ̀ṣẹ̀ wọ́n jẹ́ láti orí olè jíjà sí pípa ènìyàn léraléra. A ṣèbẹ̀wò lọ síbẹ̀ ni.

Ní ti Edgardo àti Rubén, ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ ìrìn àjò wọn sí ọgbà ẹ̀wọ̀n gbígbajúmọ̀ yìí ní àwọn ọjọ Saturday ni ó jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ àdúgbò ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n máa ń ṣèbẹ̀wò déédéé síbẹ̀ láti sọ àsọyé Bíbélì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n bíi 15. Ní tèmi, tí mo jẹ́ alábòójútó arìnrìn àjò kan, èyí jẹ́ àǹfààní ṣíṣọ̀wọ́n kan, níwọ̀n bí n kò tí ì ṣalága ìpàdé kankan nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n rí.

Ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ní òpó ilé túbú 12 tí wọ́n kọ́ ní ìrísí abẹ̀bẹ̀. Bí a ṣe wọnú ọgbà náà, a rí àwọn ẹlẹ́wọ̀n mẹ́rin lókèèrè tí wọ́n ń juwọ́ sí wa tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n wọ̀nyí ti tẹ̀ síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn dé orí dídi akéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, tí kò tí ì ṣèrìbọmi. Wọ́n tètè sìn wá lọ sí òpó ilé túbú 9, níbi tí a óò ti ṣe ìpàdé. Níbẹ̀, wọ́n ti kun iyàrá kan, wọ́n sì ti fi àwọn aṣọ ìkélé ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́, tí èyí sì fún un ní ìrísí tí ó gbayì.

Ìrúkèrúdò Náà Bẹ́ Sílẹ̀

Bí ó ti wù kí ó rí, ohun kan ṣàjèjì. Kìkì àwọn ẹlẹ́wọ̀n 12 péré ló wá dípò ẹni 15 tó sábà máa ń jẹ́. Ó ya gbogbo wa lẹ́nu. Ìpàdé náà bẹ̀rẹ̀ bí ó ṣe máa ń rí, pẹ̀lú orin àti àdúrà. Lẹ́yìn ìṣẹ́jú díẹ̀, ìró ìbọn kíkankíkan tí ìbúgbàù ọta ìbọn arọ̀jò ọta tẹ̀ lé gbọ̀n wá jìgìjìgì. Lẹ́yìn náà, a ń gbọ́ ariwo àti ìkétoto. Ìrúkèrúdò ọ̀tẹ̀ kan ló bẹ̀rẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn!

Àwọn ẹlẹ́wọ̀n mélòó kan tí wọ́n fi ohun ìjà tí ó jọ ọ̀bẹ dìhámọ́ra, tí wọ́n sì bo orí wọn ya wọ iyàrá ìpàdé wa. Ó yà wọ́n lẹ́nu láti rí wa—àlejò mẹ́ta! Wọ́n yára sìn wá gba ọ̀dẹ̀dẹ̀ kan tí èéfín bò. Àwọn tìmùtìmù tí ń jóná, àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ń sá kiri láìrójú ráyè, àti ẹ̀ṣọ́ kan tí ó fara pa wà ní ilẹ̀ẹ́lẹ̀. Iná tí bọ́m̀bù àtọwọ́dá kan dá sílẹ̀ bo ilé ẹ̀ṣọ́ gogoro tí ó wà ní àárín ilẹ̀ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Wọ́n kó wa lọ sí gbangba, wọ́n sì fipá mú wa láti dúró ní ibi tí ó fi nǹkan bí 50 mítà jìnnà sí ògiri. Nígbà tí a wo ọ̀kánkán tààràtà, a rí àwọn ọlọ́pàá àti àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn ògiri náà, tí wọ́n na ìbọn sí wa. Àwùjọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan, sá pamọ́ sẹ́yìn wa, wọ́n gbé ọ̀bẹ wọn sí wa lọ́rùn. Wọ́n ń lò wá gẹ́gẹ́ bí asà.

Àwọn Tí Wọ́n Mú Ní Àmúdá Pọ̀ Sí I

Wákàtí márùn-ún lẹ́yìn náà, lẹ́yìn tí oòrùn ti wọ̀, àwọn aṣáájú àwọn asòpàǹpá náà jẹ́ kí dókítà kan wọlé láti tọ́jú àwọn tí wọ́n fara pa. Wọ́n tún mú dókítà náà ní àmúdá. Níkẹyìn, ní nǹkan bí agogo mẹ́sàn-án alẹ́, wọ́n kó wa lọ sí ilé ìwòsàn ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Níbẹ̀ ni a ti dara pọ̀ mọ́ àwùjọ àwọn ẹ̀ṣọ́ kan tí wọ́n mú àwọn náà ní àmúdá. Nísinsìnyí, àwọn tí wọ́n ń jàjààgboro fipá mú gbogbo àwọn tí wọ́n mú ní àmúdá láti jẹ́ bí asà ní pípààrọ̀ ara wọn lọ́kọ̀ọ̀kan.

Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, wọ́n gba adájọ́ kan àti akọ̀wé rẹ̀ láyè láti lọ bá àwọn ajàjààgboro náà, nínú ìsapá láti yanjú ọ̀ràn náà nítùnbí-ǹ-nùbí. Ṣùgbọ́n rògbòdìyàn náà le sí i nígbà tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà tún mú àwọn méjèèjì ní àmúdá.

Ìjà ń ṣẹlẹ̀ lóòrèkóòrè ní gbogbo òru. A gbìyànjú láti sùn, ṣùgbọ́n ó jọ pé gbogbo àkókò tí a bá ti tòògbé lọ, ìkétoto gbígbalẹ̀kan yóò gbọ̀n wá jìgìjìgì jí lẹ́nu ìtòògbé wa. Lẹ́yìn náà, ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, ó tún to àkókò tiwa láti ṣe bí asà.

Ìwà Ipá Náà Ń Pọ̀ Sí I

Ní ọjọ́ Sunday, March 31, ọjọ́ kejì tí ìrúkèrúdò náà bẹ̀rẹ̀, ńṣe ni ọ̀ràn náà burú sí i. Àwọn aṣáájú àwọn asòpàǹpá náà kò lè gba ohun tí wọ́n béèrè fún. Èyí dá ìbínú àti ìwà ipá sílẹ̀. Àwùjọ àwọn ajàjààgboro bẹ̀rẹ̀ jàgídíjàgan, tí wọ́n ń ba ohunkóhun tí wọ́n bá rí jẹ́, wọ́n sì ń sun nǹkan. Wọ́n fi ìwà ipá àti ìpànìyàn yanjú àwọn awuyewuye tí ó ti wà nílẹ̀. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n bíi mélòó kan tí wọ́n kọ̀ láti dara pọ̀ nínú ìjààgboro náà ni wọ́n fìyà ikú jẹ. Wọ́n sun àwọn òkú kan nínú ààrò búrẹ́dì.

Oríṣiríṣi àhesọ àti ìròyìn títa kora nípa dídá wa sílẹ̀ tàn káàkiri inú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Ohun ayímọ̀láradà lójijì ló jẹ́ fún àwa tí wọ́n mú ní àmúdá. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n gbà wá láyè láti gbọ́ ìròyìn lórí tẹlifíṣọ̀n. Ó ṣe wá ní kàyéfì láti rí i bí ohun tí tẹlifíṣọ̀n ń sọ ṣe yàtọ̀ tó sí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ gangan. O ń kórẹ̀wẹ̀sì báni.

Báwo ni a ṣe kojú rẹ̀? A darí àfiyèsí sí gbígbàdúrà, kíka Bíbélì, àti bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìlérí Bíbélì nípa ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ kan. Ìyẹn ni àṣírí sí okun tẹ̀mí tí a ní lákòókò ìrírí agbonijìgì náà.

Ní ọjọ́ Monday, àwọn aṣáájú àwọn asòpàǹpá náà gbà láti bẹ̀rẹ̀ ìdúnàádúrà pẹ̀lú àwọn aláṣẹ. Ó jọ pé ìrúkèrúdò náà ń lọ sópin. Àwọn ajàjààgboro náà ń lo Edgardo àti àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n bíi mélòó kan gẹ́gẹ́ bí asà nígbà tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan bẹ̀rẹ̀ sí í yìnbọn síra wọn. Nínú ìdàrúdàpọ̀ tí ó tẹ̀ lé e, ní lílérò pé àwọn tí wọ́n ń mú ní àmúdá ni wọ́n ń yìnbọn fún, àwọn ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ sí í yin ìbọn wọn. Edgardo yèbọ́ láìfara gba àwọn ọta ìbọn tí ń yọ fìrìfìrì náà, ṣùgbọ́n wọ́n yìnbọn fún àwọn kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ tí wọ́n mú náà.

Ó Jọ Pé Ikú Rọ̀ Dẹ̀dẹ̀

Wọ́n kó àwa tí wọ́n mú ní àmúdá lọ sórí òrùlé láti fi han àwọn aláṣẹ pé a ṣì wà láàyè. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́pàá ń yìnbọn lọ kùrà. Èyí ru àwọn ajàjààgboro náà nínú. Gbogbo ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í lọgun nígbà kan náà. Àwọn kan ń kébòòsí pé: “Ẹ dúḿbú àwọn tí a mú ní àmúdá náà! Ẹ dúḿbú wọn!” Àwọn mìíràn ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ pé: “Kò tí ì yá! Ẹ jẹ́ kí a dúró ná!” Ó jọ pé ikú rọ̀ dẹ̀dẹ̀. Èmi àti Rubén wo ara wa bíi kí a sọ pé, ‘Ó tún di inú ayé tuntun.’ Lẹ́yìn náà, àwa méjèèjì gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́. Lọ́gán, a nímọ̀lára ìsinmẹ̀dọ̀ látinúwá àti àlàáfíà ọkàn, tí ó jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ Jèhófà nìkan ló ti lè wá lábẹ́ irú ipò náà.—Fílípì 4:7.

Lójijì, àwọn ọlọ́pàá dáwọ́ ìbọn yíyìn dúró, ọ̀kan lára àwọn aṣáájú àwọn asòpàǹpá náà dá ìpànìyàn náà dúró. Wọ́n pàṣẹ fún ọ̀dọ́ ẹlẹ́wọ̀n tí ó mú mi dání láti mú mi rìn lọ, rìn bọ̀ lórí òrùlé náà, gẹ́gẹ́ bí ìkìlọ̀ fún àwọn ọlọ́pàá. Ojora mú un gan-an. Níbẹ̀ gan-an, ó ṣeé ṣe fún mi láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò tí ó fọkàn àwa méjèèjì balẹ̀. Mo ṣàlàyé pé Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ní ń ṣokùnfà ìyà tí ẹ̀dá ènìyàn ń jẹ àti pé láìpẹ́, Jèhófà Ọlọ́run yóò fi òpin sí gbogbo irú ìjìyà bẹ́ẹ̀.—Ìṣípayá 12:12.

Nígbà tí wọ́n kó wa padà sí ilé ìwòsàn ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, a rí i pé ìpayà ti mú ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n mú ní àmúdà náà. A gbìyànjú láti ṣàjọpín ìgbàgbọ́ wa nínú ìlérí Jèhófà pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jùmọ̀ mú wa ní àmúdá. A bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ìrètí wa tí a gbé karí Bíbélì nípa ọjọ́ ọ̀la nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Àwọn kan lára àwọn tí wọ́n mú ní àmúdá náà bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe Jèhófà pẹ̀lú orúkọ rẹ̀. Dókítà náà fi ọkàn ìfẹ́ pàtàkì hàn, ó sì béèrè àwọn ìbéèrè pàtó bíi mélòó kan. Èyí ṣamọ̀nà sí ìjíròrò gígùn kan nínú Bíbélì ní lílo ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun.

Ṣíṣàjọ̀dún Ìṣe Ìrántí

Ọjọ́ Tuesday, ọjọ́ kẹrin tí wọ́n ti mú wa dè, ni àyájọ́ ikú Jésù Kristi. Ní ọjọ́ yẹn, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti àwọn olùfìfẹ́hàn jákèjádò ayé yóò pàdé pọ̀ láti ṣèrántí àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ní ìgbọràn sí àṣẹ Jésù. (Lúùkù 22:19) Àwa pẹ̀lú ṣètò láti ṣàjọ̀dún Ìṣe Ìrántí náà.

A yan igun kan iyàrá náà bí ibi àdálò. Kò sí àkàrà aláìwú bẹ́ẹ̀ ni kò sí wáìnì láti lò gẹ́gẹ́ bí ohun ìṣàpẹẹrẹ. Ṣùgbọ́n àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta gbádùn kíkọrin ìyìn sí Jèhófà, gbígbàdúrà, àti ṣíṣàyẹ̀wò àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa alẹ́ ti Jésù lò kẹ́yìn àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ míràn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ikú rẹ̀. A nímọ̀lára ìsúnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nípa tẹ̀mí, bí wọ́n ti ń ṣàjọ̀dún Ìṣe Ìrántí náà lákòókò kan náà, jákèjádò orílẹ̀-èdè náà.

Ìrírí Agbonijìgì Náà Dópin

Ipò àyíká àìfararọ, ẹ̀rù, àti àníyàn gbalẹ̀ láàárín ọjọ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó tẹ̀ lé e. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ lẹ́tà tí ó wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí àti àwọn ọ̀rẹ́, tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà jẹ́ kí a rí gbà, tù wá nínú. Ní àkókò kan, wọ́n tilẹ̀ gbà wá láyè láti kàn sí àwọn ìdílé wa nípasẹ̀ tẹlifóònù. Ẹ wo bí ó ti ń tuni lára tó láti gbọ́ ohùn wọn, kí a sì ka àwọn ọ̀rọ̀ onífẹ̀ẹ́ àti àníyàn wọn!

Ní ọjọ́ Saturday, ọjọ́ kẹjọ tí wọ́n ti mú wa dè, àwọn ajàjààgboro náà dórí àdéhùn kan pẹ̀lú àwọn aláṣẹ. Wọ́n sọ fún wa pé wọn óò dá wa sílẹ̀ ní ọjọ́ kejì. Ní ọjọ́ Sunday, April 7, ní agogo 2:30 ọ̀sán, a gbọ́ ìròyìn pé: “Ẹ ta mọ́ra, ìlọ yá!” Àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà ṣètò ‘ẹ̀ṣọ́ ẹ̀yẹ’ láti sìn wá jáde lómìnira! Bí a ti ń jáde kúrò ní ilé ìwòsàn náà, agbẹnusọ fún àwọn aṣáájú àwọn asòpàǹpá náà sún mọ́ Edgardo, ó sì wí pé: “Arákùnrin, ìhùwà yín wú mi lórí gan-an. Mo ṣèlérí pé láti ìsinsìnyí lọ, n óò máa lọ sí àwọn ìpàdé yín ọjọọjọ́ Saturday nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ṣebí ẹ óò ṣì máa ṣe àwọn ìpàdé náà, kódà lẹ́yìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ níhìn-ín yìí, àbí?” Edgardo rẹ́rìn-ín músẹ́, ó sì dáhùn pé: “Dájúdájú!”

Ìyàlẹ́nu kan ń dúró dè wá ní ìta. Kété tí a jáde nínú ilé náà, gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n pátápátá bẹ̀rẹ̀ sí í pàtẹ́wọ́ tọ̀yàyàtọ̀yàyà láti yẹ́ wa sí. Ọ̀nà yìí ni wọ́n ń gbà fi hàn pé kí a máà bínú nítorí ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Àkókò arùmọ̀lára sókè gbáà ni ó jẹ́. Kò sí iyè méjì pé ìhùwà wa láàárín ọjọ́ mẹ́sàn-án tí ó ti kọjá ti wú gbogbo wọn lórí, sí ìyìn Jèhófà.

Lóde ògiri ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, a pàdé àwọn ìdílé wa àti nǹkan bí 200 àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nípa tẹ̀mí. A gbá ara wa mọ́ra pẹ̀lú ìmọ̀lára ìdásílẹ̀ ńláǹlà. A ti là á já! Ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n mú ní àmúdá náà tọ aya mi wá, ó sì wí fún un pé: “Mo lérò pé Jèhófà ti dé inú ọkàn mí, ó sì fẹ́ kí n sin òun.”

Èmi, Edgardo, àti Rubén kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà àkànṣe pé Jèhófà lè mú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró, kódà lákòókò túláàsì líle koko jù lọ pàápàá. A ṣàlàyé bí ó ṣe jẹ́ àgbàyanu tó láti gbàdúrà sí Jèhófà, kí ó sì gbọ́ wa. Bíi ti onísáàmù náà, a lè sọ pé: “Èmi óò kókìkí rẹ, Olúwa; nítorí ìwọ ni o gbé mi lékè, tí ìwọ kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ mí, Olúwa Ọlọ́run mi, èmí kígbe pè ọ́, ìwọ́ sì ti mú mi lára dá. Olúwa, ìwọ́ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú: ìwọ́ sì pa mí mọ́ láàyè, kí èmi kí ó má baà lọ sínú ihò.” (Orin Dáfídì 30:1-3)—Gẹ́gẹ́ bí Darío Martín ṣe sọ ọ́.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]

Àwọn ẹlẹ́wọ̀n mélòó kan tí wọ́n fi ohun ìjà tí ó jọ ọ̀bẹ dìhámọ́ra, tí wọ́n sì bo orí wọn ya wọ iyàrá ìpàdé wa

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 20]

Àwọn ajàjààgboro náà ń lo Edgardo àti àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n mélòó kan gẹ́gẹ́ bí asà

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]

Àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà ṣètò ‘ẹ̀ṣọ́ ẹ̀yẹ’ láti sìn wá jáde lómìnira!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àwọn òjíṣẹ́ mẹ́ta tí wọ́n ṣèbẹ̀wò (láti apá òsì sí ọ̀tún): Edgardo Torres, Rubén Ceibel, àti Darío Martín

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́