ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 10/22 ojú ìwé 16-19
  • Agbára Láti Inú Òjò Dídì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Agbára Láti Inú Òjò Dídì
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ilẹ̀ Kan Tí Kò Ti Sí Omi
  • Láti Àwókù sí Òjò Dídì
  • Ìgbésí Ayé Nínú Àwọn Òkè
  • Bí Ìgbékalẹ̀ Náà Ṣe Tóbi Tí Ó Sì Lágbára Tó
  • Bí Ìgbékalẹ̀ Snowy Ṣe Ń Ṣiṣẹ́
  • Ṣé Agbára Tí Kò Léèérí Ni?
  • Àwọn Ibi Tí Ìṣòro Náà Ti Le Jù
    Jí!—1997
  • Ìgbésí Ayé Yàtọ̀ Ní—Ìsàlẹ̀ Lọ́hùn-ún
    Jí!—1997
  • Ìṣètò Ìpèsè Omi London—Apá Tuntun Kan
    Jí!—1996
  • Ṣé Omi Ń tán Lọ Láyé Ni?
    Jí!—2001
Jí!—1997
g97 10/22 ojú ìwé 16-19

Agbára Láti Inú Òjò Dídì

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ AUSTRALIA

ÒKÈ Australia, tí a ń pè ní ibi gíga jù lọ ní Australia nígbà míràn, fi ẹsẹ̀ kan sí ìpínlẹ̀ New South Wales, ó sì fi òmíràn sí ìpínlẹ̀ Victoria. Láàárín àwọn òkè wọ̀nyí ni Òkè Ńlá Snowy wà, tó jẹ́ orísun Odò Snowy. Bí ojú ilẹ̀ olókè gbágungbàgun yìí àti àwọn ẹlẹ́ṣin, tí ara wọn gba ìyà, tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ dó síbẹ̀, ṣe wọ A. B. (Banjo) Paterson lọ́kàn ló sún un kọ ewì “Ọkùnrin Tí Ó Wá Láti Inú Odò Snowy,” tí a wá fi ṣe sinimá níkẹyìn.

Bí ó ti wù kí ó rí, lóde òní, àwọn ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ eléwu tí gbajúmọ̀ ẹlẹ́ṣin náà ti kọjá jẹ́ ibi àsémọ́ omi tó jẹ́ ohun ìyanu ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ kan—Ìgbékalẹ̀ Ìfomipèsè-Agbára-Mànàmáná Òkè Ńlá Snowy. Ní 1967, Ẹgbẹ́ Àwọn Onímọ̀ Iṣẹ́ Ẹ̀rọ Nílẹ̀ America ka ìsokọ́ra dídíjú ti ọ̀nà omi, ọ̀nà abẹ́lẹ̀, ìsédò, àti ilé iṣẹ́ amúnáwá yìí sí “ọ̀kan lára àwọn ohun ìyanu méje ti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní.” Ìwọ yóò ha fẹ́ láti bẹ “ohun ìyanu” orí òkè yí wò bí? Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ kí a mọ ìdí tí a fi kọ́ ọ àti ẹni tí ó kọ́ ọ.

Ilẹ̀ Kan Tí Kò Ti Sí Omi

Lọ́nà yíyanilẹ́nu, ìfomipèsè-agbára-mànàmáná kò fìgbà kankan sí lọ́kàn àwọn tètèdé abulẹ̀dó tí ìyánhànhàn wọn ṣokùnfà Ìgbékalẹ̀ náà. Bí ọ̀dá ti ń dààmú àwọn àgbẹ̀ ọ̀rúndún kọkàndínlógún náà ní ẹkùn ilẹ̀ Murray òun Darling, tí ó jẹ́ àgbègbè tó ṣe pàtàkì jù lọ fún iṣẹ́ àgbẹ̀ ní Australia, wọ́n wulẹ̀ ń wá orísun ìpèsè omi tó túbọ̀ láyọ̀lé ni.

Wọ́n mọ ibi tí omi náà wà—ní Odò Snowy. Ṣùgbọ́n odò Snowy ti ya gba ìhà kejì òkè náà, níbi tó lẹ́tù lójú, wọ inú Òkun Tasman. Ó jọ ìfiṣòfò lásán. Bí a bá lè tún darí omi tútù, tó mọ́ gaara yìí, láti téńté orí òkè lọ́hùn-ún sí orísun àwọn odò Murray àti Murrumbidgee tí ń fà látìgbàdégbà, àwọn àgbẹ̀ yóò bọ́ lọ́wọ́ ọ̀dá lọ́nà kíkàmàmà. Èrò tí a fọkàn fẹ́ gidigidi ni.

Ní 1908, èrò náà fẹ́rẹ̀ẹ́ dòótọ́ tán nígbà tí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àpapọ̀ yan àgbègbè Canberra tó wà nítòsí gẹ́gẹ́ bí olú ìlú orílẹ̀-èdè Australia. Ǹjẹ́ ìfomipèsè-agbára-mànàmáná yóò kájú àìní ìlú ńlá tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ tẹ̀ dó yìí bí? Lẹ́ẹ̀kan sí i, a darí àfiyèsí sí Òkè Ńlá Snowy.

Onírúurú àbá—àwọn kan fún ìfomipèsè-agbára-mànàmáná àti àwọn mìíràn fún ìbomirinlẹ̀—ni wọ́n gbé kalẹ̀ tí wọ́n sì tún pa tì. Lẹ́yìn náà, ní 1944, wọ́n mú àbá ìgbékalẹ̀ ìbomirinlẹ̀ abánáṣiṣẹ́ kìíní wá, ó sì jèrè ìtẹ́wọ́gbà kíákíá. Ní 1949, ìjọba àpapọ̀ gbé Ìgbìmọ̀ Ìfomipèsè-Agbára-Mànàmáná Lókè Ńlá Snowy kalẹ̀ láti ṣiṣẹ́ lórí wíwéwèé ìgbékalẹ̀ alápá méjì náà àti kíkọ́ ọ.

Ṣùgbọ́n báwo ni orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọjú, tí ó jẹ́ oníṣẹ́ àgbẹ̀ ní gbogbogbòò, tí kò ní àwọn ògbógi tàbí àwọn òṣìṣẹ́ rẹpẹtẹ, ṣe lè kojú iṣẹ́ kan tí a kò ṣe èyí tí ó tóbi, tí ó sì díjú tó bẹ́ẹ̀ rí?

Láti Àwókù sí Òjò Dídì

Ìṣíwọ̀lú ni ojútùú náà. Bí ràbọ̀ràbọ̀ Ogun Àgbáyé Kejì kò ṣe tí ì tán lára Europe, ó jẹ́ ibi ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ìsọdahoro, àìríṣẹ́ṣe, àti àìrílégbé. Nítorí náà, pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, Australia ké sí ará Europe èyíkéyìí tó bá ní òye iṣẹ́ tí a nílò láti kọ̀wé béèrè fún iṣẹ́ níbi Ìgbékalẹ̀ náà.

Ẹgbẹẹgbàárùn-ún òṣìṣẹ́ láti nǹkan bí orílẹ̀-èdè 33 dáhùn pa dà nípa fífi àwókù Europe sílẹ̀ wá sí Australia. Wọn yóò jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́ta gbogbo òṣìṣẹ́ ibi Ìgbékalẹ̀ náà, wọn yóò sì yí ẹ̀yà ẹ̀dá ènìyàn tó wà ní Australia pa dà láéláé. Brad Collis sọ nínú ìwé rẹ̀, Snowy, pé: “Orílẹ̀-èdè kan tí àwọn olùdásílẹ̀ rẹ̀ . . . jẹ́ àwọn ará Britain fẹ́rẹ̀ẹ́ di orílẹ̀-èdè tí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kún inú rẹ̀ ní ọ̀sán-kan-òru-kan.” Collis ṣàfikún pé: “Wọ́n rán [àwọn ọkùnrin náà] lọ sínú òkè ńlá náà—àti ọ̀tá àti onígbèjà, aninilára àti ẹni tí a ni lára—pé kí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ pọ̀.” Bí wọn kò tilẹ̀ pawọ́ pọ̀ di alájọṣe ní ọ̀sán-kan-òru-kan, bí àkókò ti ń lọ, wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.

Ìgbésí Ayé Nínú Àwọn Òkè

Ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Ìgbékalẹ̀ náà, ìrìn àjò wọnú àwọn òkè náà kò yáni lára. Àwọn ọ̀nà títutùnini, tí ẹrẹ̀ pọ̀ níbẹ̀, tó ṣe gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, tó sì lọ́ kọ́lọkọ̀lọ, kì í mú kí ìrìn àjò náà yá, ó sì ń tánni ní sùúrù. Ní gidi, àwọn apá kan ojú ilẹ̀ náà wà lóòró gangan jù, wọ́n sì bani lẹ́rù tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹranko kangaroo pàápàá fi ṣọ̀wọ́n níbẹ̀! Abájọ tí Collis fi sọ nípa Ìgbìmọ̀ Snowy pé, “ó gbajúmọ̀ gẹ́gẹ́ bí àjọ àkọ́kọ́ lágbàáyé láti sọ lílo bẹ́líìtì ara ìjókòó di dandangbọ̀n.”

Àwọn ibùgbé kò sàn ju ojú ọ̀nà náà lọ—àwọn àgọ́ sójà tí a kò rẹ́ ilẹ̀ wọn! Níkẹyìn, àwọn ìlú ńlá oníbùdó àti alágọ̀ọ́ tó lé ní 100 ló rú yọ kíákíá lójijì lórí àwọn òkè náà. Ọ̀kan lára wọn, Cabramurra—tí kì í ṣe ìlú ńlá alágọ̀ọ́ mọ́—ń fi jíjẹ́ tí ó jẹ́ ìlú tí ó wà níbi gíga jù lọ ní Australia yangàn.

Bí o ti lè finú wò ó, ṣíṣiṣẹ́ àti sísùn lábẹ́ àwọn ipò ṣebóotimọ, oníhílàhílo báwọ̀nyí ń dán agbára ẹni láti fàyà rán ìṣòro wò dé góńgó. Afẹ́fẹ́ tí òjò dídì kéékèèké wà nínú rẹ̀ ń wọni lára déegun nígbà òtútù, ooru atánnilókun ti ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn mú kí gbogbo ìgbésẹ̀ jẹ́ ìsapá ńlá, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn eṣinṣin tí kò ṣeé fara dà sì ń bo àwọn ojú àti ẹ̀yìn tí òógùn ti bò. Ẹ wo bí àwọn ará Europe ti kórìíra eṣinṣin wọ̀nyẹn tó!

Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ló fara dà á. Bí ogun ti sọ wọ́n di aláìmikàn, tí wọ́n sì rọ́kú, wọ́n pinnu láti ṣàṣeyọrí nínú ìgbésí ayé wọn tuntun. Ọ̀pọ̀ nínú wọn wá kúndùn igbó ilẹ̀ Australia tó kún fún àwọn ẹranko àti ejò àrà ọ̀tọ̀ àti àwọn ẹyẹ tí ń dún kíkankíkan, tí wọ́n sì ń pariwo dípò kí wọ́n máa súfèé tàbí kí wọ́n máa ké ṣíoṣío. Láìpẹ́, a fi àwọn ilé abọ́ọ́dé tí a fi pákó kọ́ rọ́pò àwọn àgọ́, àwọn aya àti àwọn ọmọ sì dara pọ̀ mọ́ àwọn ọkùnrin náà.

Ṣùgbọ́n báwo ni wọn yóò ti ṣe ti èdè rẹpẹtẹ náà sí? Finú wòye àwọn ọkùnrin tí ń lo àwọn ẹ̀rọ ńláńlá àti àwọn ẹ̀rọ ìgbẹ́lẹ̀, tàbí tí wọ́n ń lo àwọn ohun abúgbàù láìlèjọsọ̀rọ̀ kó yéni! Ohun tó lè fa ìjàǹbá ni, nítorí náà, Ìgbìmọ̀ náà dá ẹ̀kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì lẹ́yìn iṣẹ́, lọ́fẹ̀ẹ́, sílẹ̀. Láti máa bá iṣẹ́ lọ, òṣìṣẹ́ gbọ́dọ̀ gbọ́ èdè dé àyè kan, nítorí náà, kò yani lẹ́nu pé àwọn òṣìṣẹ́ ń wá síbi ẹ̀kọ́ yìí dáradára!

Láìka ọ̀pọ̀ ìdènà sí, lẹ́yìn ọdún 25—1949 sí 1974—iṣẹ́ náà parí lákòókò láìsí àfikún iye tí a wéwèé fún un. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé 820 mílíọ̀nù dọ́là tí iṣẹ́ náà náni nígbà náà kò tó nǹkan bí a bá fi wé bí nǹkan ṣe rí lóde òní, kì í ṣe kèrémí nígbà náà, pàápàá, fún orílẹ̀-èdè kan tí ó ní mílíọ̀nù mẹ́jọ ènìyàn péré, tí ó sì ń tiraka lẹ́yìn ogun síbẹ̀ láti pa dà sí bí ìgbésí ayé ṣe rí tẹ́lẹ̀.

Láti ṣayẹyẹ àṣeyọrí náà, Ìgbìmọ̀ náà ń wéwèé lọ́wọ́ láti ṣe àjọ̀dún 50 ọdún ní 1999. Yóò ní ìtúnrarí gbogbo àwọn tó ṣiṣẹ́ lórí ìdáwọ́lé náà nínú—bí a bá tún lè rí wọn. Kọmíṣánnà lọ́wọ́lọ́wọ́ sọ pé: “Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣèrànwọ́ láti kọ́ ọ̀kan lára àwọn ohun ìyanu ti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ lágbàáyé, wọ́n sì yí ìtàn bí nǹkan ṣe rí ní Australia pa dà. A fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn.”

Bí Ìgbékalẹ̀ Náà Ṣe Tóbi Tí Ó Sì Lágbára Tó

Gẹ́gẹ́ bí ìwé pẹlẹbẹ náà, The Power of Water, ṣe sọ, “Ìgbékalẹ̀ náà gba ilẹ̀ 3,200 kìlómítà [1,200 ibùsọ̀] níbùú lóròó, ó sì ní àwọn ọ̀nà omi tó gùn ní 80 kìlómítà [50 ibùsọ̀], àwọn ọ̀nà abẹ́lẹ̀ tó gùn ní 140 kìlómítà [87 ibùsọ̀] àti àwọn ìsédò ńlá 16.” Àwọn ìsédò wọ̀nyí ń gba 7,000 bílíọ̀nù lítà omi—ìlọ́po 13 ti Sydney Harbor, tí ń gba nǹkan bí 530 bílíọ̀nù lítà—tí Ìsédò Eucumbene sì jẹ́ lájorí agbomiró rẹ̀. Àwọn ilé iṣẹ́ amúnáwá méjèèje, tí ó ti lò tó 6,400 bílíọ̀nù wákàtí ìmúnáwá tí a gbé lórí ìṣirò wáàtì, láàárín ọdún kan, lè pèsè tó ìpín 17 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo iná tí a nílò ní gbalasa ilẹ̀ Gúúsù Ìlà Oòrùn Australia, títí kan Sydney, Melbourne, àti Canberra.

Kò wọ́pọ̀ kí àwọn ẹ̀rọ ayíbírí náà máa ṣiṣẹ́ tọ̀sántòru, àyàfi ní àwọn àkókò tí ìwọ̀n tí a nílò bá pọ̀, tí àwọn ilé iṣẹ́ amúnáwá tí ń lo ooru gbígbóná bá ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́. Ìfomipèsè-agbára-mànàmáná dára ní pàtàkì fún ìṣètìlẹ́yìn nígbà tí ẹrù bá ń pa àwọn ilé iṣẹ́ amúnáwá yòó kù nítorí bí ó ṣe ń yára dáhùn pa dà sí ìlò tí ó lọ sókè lójijì—láàárín ìṣẹ́jú méjì sí mẹ́ta, bí a bá fi wé ọ̀pọ̀ wákàtí tí èyí tí ń lo èédú ilẹ̀ ń gbà, kó tó bẹ̀rẹ̀ sí í múná wá.

Bí Ìgbékalẹ̀ Snowy Ṣe Ń Ṣiṣẹ́

Ìgbìmọ̀ Snowy sọ pé, Ìgbékalẹ̀ náà “ta yọ ní ti pé òun ni ìgbékalẹ̀ omi tó díjú jù lọ, tó jẹ́ gbogbonìṣe, tó sì ní ọ̀pọ̀ ìgbomisí jù lọ lágbàáyé.” Ó ní apá alásokọ́ra méjì—ìṣàmúlò odò Snowy òun Murray àti ìṣàmúlò odò Snowy òun Tumut.

Ìṣàmúlò odò Snowy òun Murray ní ń darí omi Odò Snowy láti Ìsédò Island Bend gba ojú ọ̀nà abẹ́lẹ̀ àtòkèńlá-dókèńlá kan dé Ìsédò Geehi, tí òun náà ń gba omi láti Odò Geehi. Láti ibí ni omi náà ti ń dà yàà wọnú ilé iṣẹ́ amúnáwá Murray méjèèjì tó wà ní 820 mítà nísàlẹ̀. Nígbà kan náà, Ilé Iṣẹ́ Amúnáwá Guthega ń fa omi láti orísun odò Snowy nítòsí òkè ńlá gíga jù lọ ní Australia, Òkè Ńlá Kosciusko. Láti Guthega, omi náà ń dà sínú ìsokọ́ra ọ̀nà abẹ́lẹ̀ tó wà ní Island Bend. Ní ṣíṣàfikún gidigidi sí ìṣeéyípadà Ìgbékalẹ̀ náà, àwọn ọ̀nà abẹ́lẹ̀ mélòó kan, títí kan ọ̀nà abẹ́lẹ̀ Island Bend òun Ìsédò Eucumbene, fàyè gba ṣíṣànlọṣànbọ̀.

Níbi ìṣàmúlò odò Snowy òun Tumut, omi máa ń ṣàn láti Ìsédò Eucumbene, Ìsédò Tooma, Ìsédò Happy Jack, àti Ìsédò Tumut Pond lọ sísàlẹ̀ òkè gba àwọn ibi àsémọ́ omi àti ọ̀wọ́ ilé iṣẹ́ amúnáwá mẹ́rin kí ó tó tú dà sínú Odò Tumut, tó ń ṣàn lọ sínú odò Murrumbidgee. Nínú ìpín yìí ni ilé iṣẹ́ amúnáwá títóbi jù lọ náà, Tumut 3, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan ibi àsémọ́ omi rẹ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà lè gba ọkọ̀ bọ́ọ̀sì alágbèékà kan, wà!

Láàárín àwọn àkókò tí ìlò kò bá pọ̀, Ìgbékalẹ̀ náà tún ń fa omi lọ sókè láti Ìsédò Jindabyne sínú Ìsédò Eucumbene, àti láti ìsàlẹ̀ Ilé Iṣẹ́ Amúnáwá Tumut 3, tí ó tún máa ń ṣiṣẹ́ bí ilé iṣẹ́ afami, lọ sínú Agbomiró Talbingo. Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí a fi ń fagbára mànàmáná ṣòfò ní fífa omi lọ sókè? Lọ́nà yíyanilẹ́nu, ó jẹ nítorí èrè. Àwọn ẹ̀rọ tí ń tú omi náà ń lo agbára tí ń wá láti àwọn ilé iṣẹ́ amúnáwá tí ń lo ooru gbígbóná, tí kò wọ́nwó, nígbà tí ìlò rẹ̀ kò bá pọ̀. Lẹ́yìn náà, ní àkókò tí ìlò bá pọ̀, wọ́n ń tú omi náà, wọ́n sì ń ta agbára mànàmáná tó mú wá pa dà sínú àsokọ́ra àtagbà náà lọ́nà tí ń mérè wá. Ó dájú pé a ń tú gbogbo omi náà—tó lé ní 2,000 bílíọ̀nù lítà lọ́dọọdún—dà sínú àwọn ìsokọ́ra odò ìhà ìwọ̀ oòrùn láìgbowó.

Ṣé Agbára Tí Kò Léèérí Ni?

Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí pé omi jẹ́ dúkìá tí kì í ṣèbàjẹ́, tí ó sì ṣeé sọ dọ̀tun, láìní àwọn ẹ̀yà tí kò wúlò. Kò sí àwọn ilé èéfín àti ilé gogoro ìmúǹkantutù tí ó lè ba ìrísí òkè náà jẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ń lọ yọ̀ lórí yìnyín ibi ìṣeré olókè yí nígbà òtútù tàbí tí ń lọ gùnkè rẹ̀ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn fẹ́rẹ̀ẹ́ má mọ̀ nípa àwọn ọ̀nà tóóró àti ilé iṣẹ́ amúnáwá tó wà lábẹ́ wọn.

Síwájú sí i, bí ó bá jẹ́ àwọn ilé iṣẹ́ amúnáwá tí ń lo ooru gbígbóná ló ń pèsè agbára mànàmáná tí Ìgbékalẹ̀ yí ń pèsè, àfikún mílíọ̀nù márùn-ún tọ́ọ̀nù gáàsì carbon dioxide ni ì bá máa tú dà sáfẹ́fẹ́ lọ́dọọdún.

Síbẹ̀síbẹ̀, àyíká kò mórí bọ́ pátápátá láìfarapa, pàápàá, Odò Snowy. Bí a ti darí ọ̀pọ̀ omi rẹ̀, térétéré lásán ló ń ṣàn bí a bá fi wé bí ó ti rí látijọ́. Láfikún sí i, àwọn ìsédò ńláńlá Ìgbékalẹ̀ náà ti mú kí àwọn ilẹ̀ oko kan kún ya, àkúnya omi wọn sì ti mú kí ó di dandan láti ṣí àwọn ìlú Adaminaby àti Jindabyne nípò lọ síbòmíràn.

Yàtọ̀ sí ìyẹn, Ìgbékalẹ̀ Snowy ti ṣeé gbára lé lọ́nà àrà ọ̀tọ̀—ó jẹ́ ẹ̀rí sí ìmọ̀ràn tí kọmíṣánnà àkọ́kọ́ fún Ìgbìmọ̀ náà fúnni pé: “Ìfẹ́ inú rere àti ọ̀wọ̀ ń wá láti inú àṣeyọrí, kì í ṣe láti inú pípariwo-ẹnu.”

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 16]

Gbogbo fọ́tò tó wà lójú ìwé 16 sí 19: Snowy Mountains Hydro-electric Authority

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ìrísí Ilé Iṣẹ́ Amúnáwá Tumut 3, ilé iṣẹ́ tó tóbi jù lọ nínú Ìgbékalẹ̀ Snowy, láti òfuurufú

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àwọn òṣìṣẹ́ ti gbọ́dọ̀ fara da ipò ìgbésí ayé oníhílàhílo

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Láti jọ ṣiṣẹ́ bí àwùjọ òṣìṣẹ́ kan, àwọn òṣìṣẹ́ gbọ́dọ̀ kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Kíkọ́ Ìgbékalẹ̀ náà ní kíkọ́ àwọn ọ̀nà abẹ́lẹ̀ la àwọn òkè ńlá kọjá nínú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́