ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 11/22 ojú ìwé 18-20
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kojú Ṣíṣe Ojúsàájú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kojú Ṣíṣe Ojúsàájú?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kó Ahọ́n Rẹ Níjàánu!
  • Àìgbọràn Ọlọ́gbọ́n Àyínìke
  • Ewu Ìyara-Ẹni-Sọ́tọ̀
  • Ewu Ìlara
  • Èé Ṣe Tí Wọ́n Ń Fún Arákùnrin Mi Ní Gbogbo Àfiyèsí?
    Jí!—1997
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Fífi Ẹ̀gbọ́n Mi Ṣe Àwòkọ́ṣe Nínú Gbogbo Nǹkan?
    Jí!—2003
  • Kí Ni Kí N Ṣe Báwọn Òbí Mi Bá Ń Jà?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Kí Ni Kí N Ṣe Báwọn Òbí Mi Bá Ń Jiyàn?
    Jí!—2007
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 11/22 ojú ìwé 18-20

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kojú Ṣíṣe Ojúsàájú?

“Mo fi ọdún méjì ju arábìnrin mi lọ, ó sì ń gba gbogbo àfiyèsí náà. . . . Kò jọ pé ó tọ́ bẹ́ẹ̀.”—Rebecca.a

BÍ ÀFIYÈSÍ tí arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ ń rí gbà ṣe pọ̀ tó ni o ṣe lè rò pé a pa ọ́ tì tó. Bí o bá sì ní ọmọ ìyá tí ó ní àwọn agbára àrà ọ̀tọ̀ láti ṣe nǹkan, tàbí tí ó ní àwọn ìṣòro lílekoko, tàbí tí àwọn ohun tí ń gbàfiyèsí rẹ̀ tàbí ànímọ́ ìwà rẹ̀ bá ti àwọn òbí yín mu, ó lè ṣòro fún ọ gidigidi láti gba àfiyèsí kankan pàápàá! Bí o bá ṣe ń ronú nípa rẹ̀ sí i tó ni o lè máa nímọ̀lára ìpalára àti ìbínú sí i tó.b

Bí ó ti wù kí ó rí, Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ẹ dúró nínú ẹ̀rù, ẹ má sì ṣe ṣẹ̀; ẹ bá ọkàn yín sọ̀rọ̀ lórí ẹní yín, kí ẹ sì dúró jẹ́ẹ́.” (Orin Dáfídì 4:4) Nígbà tí ara rẹ bá gbẹ̀kan, tí inú sì ń bí ọ, ó túbọ̀ rọrùn fún ọ láti sọ ohun kan tàbí kí o ṣe ohun kan tí o lè wá kábàámọ̀ lẹ́yìn náà. Rántí bí ṣìbáṣìbo ṣe bá Kéènì nítorí ipò ojú rere tí arákùnrin rẹ̀, Ébẹ́lì, gbádùn pẹ̀lú Ọlọ́run. Ọlọ́run kìlọ̀ fún un pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ ba ní ẹnu ọ̀nà, lọ́dọ̀ rẹ ni ìfẹ́ rẹ̀ yóò máa fà sí, ìwọ ó sì máa ṣe alákòóso rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:3-16) Kéènì kùnà láti ṣàkóso àwọn ìmọ̀lára rẹ̀, ó sì yọrí sí ìjábá!

Lóòótọ́, ìwọ kò múra tán láti di apànìyàn bíi Kéènì. Síbẹ̀ náà, ṣíṣe ojúsàájú lè ru àwọn èrò búburú àti ìmọ̀lára búburú sókè nínú rẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ewu lè ba ní ẹnu ọ̀nà rẹ! Kí ni díẹ̀ lára wọn? Báwo ni o sì ṣe lè ṣàkóso ipò yí?

Kó Ahọ́n Rẹ Níjàánu!

Nígbà tí Beth jẹ́ ọmọ ọdún 13, ó rò pé àwọn òbí òun ń ṣojúsàájú sí arákùnrin òun, wọ́n sì ń hùwà sí òun lọ́nà tí kò tọ́. Ó wí pé: “Èmi àti Mọ́mì mi máa ń jágbe mọ́ ara wa, ṣùgbọ́n ìyẹn kò mú ire kankan wá. N kì í tẹ́tí sí ohun tí ó bá ń sọ, òun náà kì í sì í tẹ́tí sí ohun tí mo bá ń sọ, nítorí náà, a kò ṣàṣeyọrí kankan.” Bóyá ìwọ pẹ̀lú ti rí i pé jíjágbe-mọ́ra-ẹni wulẹ̀ máa ń mú kí ipò tí ó ti burú tẹ́lẹ̀ túbọ̀ burú sí i ni. Éfésù 4:31 sọ pé: “Kí ẹ mú gbogbo ìkorò onínú-burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú.”

O kò ní láti máa lọgun nítorí kí o lè sọ èrò rẹ. Lọ́nà kan, ìyọsíni onípẹ̀lẹ́tù máa ń dára jù. Òwe 25:15 sọ pé: “Ìpamọ́ra pípẹ́ ni a fi ń yí ọmọ aládé ní ọkàn pa dà, ahọ́n tí ó kúnná ní ń fọ́ egungun.” Nítorí náà, bí ó bá jọ pé àwọn òbí rẹ jẹ̀bi ṣíṣe ojúsàájú, má ṣe jágbe mọ́ wọn, má sì ṣe fẹ̀sùn kàn wọ́n. Wá àkókò tí ó wọ̀, sì wá bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà onípẹ̀lẹ́tù, tí ó lọ́wọ̀.—Fi wé Òwe 15:23.

Bí o bá ń pàfiyèsí sí bí àwọn òbí rẹ kò ṣe kúnjú òṣùwọ̀n, tàbí tí o ń gàn wọ́n nítorí “àìṣẹ̀tọ́” wọn, ìwọ yóò wulẹ̀ sọ wọ́n dàjèjì tàbí kí o mú kí wọ́n máa gbèjà ara wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, pàfiyèsí sí bí ohun tí wọ́n ṣe ṣe nípa lórí rẹ. (‘Ó ń dùn mí gan-an nígbà tí ẹ bá pa mí tì.’) Ó ṣeé ṣe kí wọ́n fọwọ́ gidi mú èrò rẹ. Bákan náà, “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́.” (Jákọ́bù 1:19) Ó lè já sí pé àwọn òbí rẹ ní àwọn ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láti fún ọmọ ìyá rẹ ní àfikún àfiyèsí. Bóyá ó ní àwọn ìṣòro tí ìwọ kò mọ̀ nípa wọn.

Ṣùgbọ́n, bí o bá ní ìtẹ̀sí láti fìbínú bú jáde, kí o sì sọ̀rọ̀ láìronújinlẹ̀ nígbà tí o bá ń bínú ńkọ́? Òwe 25:28 fi “ẹni tí kò lè ṣàkóso ara rẹ̀” wé ìlú ‘tí kò ní odi’; ó ṣeé ṣe kí àwọn ìsúnniṣe aláìpé tirẹ̀ fúnra rẹ̀ ṣẹ́gun rẹ̀. Ní ìdà kejì, agbára láti ṣàkóso ìmọ̀lára rẹ jẹ́ àmì okun gidi! (Òwe 16:32) Nígbà náà, èé ṣe tí o kò kúkú fi dúró di ìgbà tí ọkàn rẹ bá balẹ̀ kí o tó sọ èrò rẹ, bóyá kí o tilẹ̀ dúró di ọjọ́ kejì? O tún lè rí i pé ó ṣèrànwọ́ láti yẹra kúrò ní ipò náà, bóyá kí o nasẹ̀ lọ díẹ̀ tàbí kí o ṣe àwọn eré ìdárayá díẹ̀. (Òwe 17:14) Nípa fífi ètè rẹ mọ́ ètè, o lè yẹra fún sísọ ohun kan tí ń pani lára tàbí tí kò bọ́gbọ́n mu.—Òwe 10:19; 13:3; 17:27.

Àìgbọràn Ọlọ́gbọ́n Àyínìke

Ọ̀fìn míràn tí o ní láti yẹra fún ni àìgbọràn. Marie ọlọ́dún 16 kíyè sí i pé wọn kì í bá àbúrò òun ọkùnrin wí bí ó bá ń ṣèdíwọ́ níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ìdílé. Bí ohun tí ó jọ ṣíṣe ojúsàájú yìí ṣe já a kulẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ “ìdaṣẹ́sílẹ̀,” ó ń kọ̀ láti kópa nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ṣé ìwọ náà ti lo ọgbọ́n ìgbẹ́nudání, tàbí àfihàn ẹ̀mí àìfọwọ́-sowọ́pọ̀ rí, nígbà tí o bá rò pé ohun kan kò bẹ́tọ̀ọ́ mu?

Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, mọ̀ pé irú ìjìnlẹ́sẹ̀ ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ bẹ́ẹ̀ lòdì sí àṣẹ inú Bíbélì láti bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí rẹ, kí o sì ṣègbọràn sí wọn. (Éfésù 6:1, 2) Síwájú sí i, àìgbọràn ń jin ipò ìbátan ìwọ àti àwọn òbí rẹ lẹ́sẹ̀. Ó sàn kí o bá àwọn òbí rẹ jíròrò àwọn ìṣòro tí o ní. Òwe 24:26 tọ́ka sí i pé ẹni “tí ó bá ṣe ìdáhùn rere” ń jèrè ọ̀wọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Nígbà tí Marie bá ìyá rẹ̀ jíròrò ọ̀ràn náà, wọ́n wá lóye ara wọn, nǹkan sì bẹ̀rẹ̀ sí í dára sí i.

Ewu Ìyara-Ẹni-Sọ́tọ̀

Ọ̀nà míràn tí ko bójú mu láti yanjú ìṣòro ṣíṣe ojúsàájú ni fífàsẹ́yìn lọ́dọ̀ ìdílé rẹ tàbí wíwá àfiyèsí lọ́dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Cassandra nìyí: “Mo ya ara mi nípa kúrò lọ́dọ̀ ìdílé mi, mo sì yíjú sí àwọn ọ̀rẹ́ ayé tí mo ní ní ilé ẹ̀kọ́. Mo tilẹ̀ ní àwọn ọ̀rẹ́kùnrin, àwọn òbí mi kò sì mọ̀ nípa rẹ̀. Mo wá ní ìsoríkọ́ gidigidi, ẹ̀rí ọkàn mi sì dá mi lẹ́bi nítorí pé mo mọ̀ pé ohun tó tọ́ kọ́ ni mo ń ṣe. Mo fẹ́ láti bọ́ nínú ipò náà, ṣùgbọ́n n kò rí ọ̀nà tí mo lè gbà sọ fún àwọn òbí mi.”

Yíya ara rẹ sọ́tọ̀ lọ́dọ̀ ìdílé rẹ àti àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ léwu—ní pàtàkì, nígbà tí ara rẹ bá gbẹ̀kan tí o kò sì lè ronú lọ́nà tó ṣe kedere. Òwe 18:1 kìlọ̀ pé: “Ẹni tí ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò lépa ìfẹ́ ara rẹ̀, yóò sì kọjú ìjà ńlá sí ohunkóhun tí í ṣe ti òye.” Bí ó bá nira fún ọ láti bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀ ní àkókò yí, wá ọ̀rẹ́ kan tí ó jẹ́ Kristẹni, irú èyí tí a ṣàpèjúwe nínú Òwe 17:17 pé: “Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n arákùnrin ni a bí fún ìgbà ìpọ́njú.” Lọ́pọ̀ ìgbà ni ó ń rọrùn láti rí irú “ọ̀rẹ́” bẹ́ẹ̀ nínú àwọn mẹ́ńbà ìjọ.

Cassandra rí “ọ̀rẹ́” kan ní àkókò àìní rẹ̀: “Nígbà tí alábòójútó àyíká [òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò] bẹ ìjọ wa wò, àwọn òbí mi fún mi níṣìírí láti bá a ṣiṣẹ́. Òun àti ìyàwó rẹ̀ kò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ rárá, wọ́n sì ní ọkàn ìfẹ́ gidigidi nínú mi. Mo lè bá wọn sọ̀rọ̀ ní gidi. N kò nímọ̀lára pé wọn yóò dá mi lẹ́bi. Wọ́n mọ pé títọ́ tí a tọ́ ẹnì kan dàgbà gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni kò túmọ̀ sí pé ẹni náà jẹ́ pípé.” Ìṣírí àti ìmọ̀ràn adàgbàdénú tí wọ́n pèsè ni ohun tí Cassandra nílò gẹ́lẹ́!—Òwe 13:20.

Ewu Ìlara

Òwe 27:4 kìlọ̀ pé: “Ìbínú ni ìkà, ìrunú sì ni kíkún omi; ṣùgbọ́n ta ni yóò dúró níwájú owú?” Ṣíṣe ìlara àti jíjowú ọmọ ìyá tí a ń ṣojúsàájú sí ti sún àwọn èwe kan hùwà láìronújinlẹ̀. Obìnrin kan jẹ́wọ́ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, mo ní irun tó tín-ínrín, tí kò pọ̀, tó láwọ̀ ilẹ̀, arábìnrin mi sì ní irun gígùn jọ̀lọ̀mì, olómiwúrà, tó ń kàn án níbàdí. Bàbá mi sábà máa ń gbóríyìn fún irun rẹ. Ó máa ń pe arábìnrin mi ní ‘Rapunzel’ òun. Nígbà tí arábìnrin mí sùn lóru ọjọ́ kan, mo mú àlùmọ́gàjí ìgéṣọ màmá mi, mo yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ síbi bẹ́ẹ̀dì rẹ̀, mo sì gé irun púpọ̀ bí mo ṣe lè gé e tó.”—Ìwé Siblings Without Rivalry, láti ọwọ́ Adele Faber àti Elaine Mazlish.

Abájọ nígbà náà tí a fi ṣàpèjúwe ìlara nínú Bíbélì gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn “iṣẹ́” búburú “ti ẹran ara.” (Gálátíà 5:19-21; Róòmù 1:28-32) Bí ó ti wù kí ó rí, gbogbo wa ni a ní “ìtẹ̀sí láti ṣe ìlara.” (Jákọ́bù 4:5) Nítorí náà, bí o bá rí ara rẹ ní ipò pé o ń pète láti rí i pé ọmọ ìyá rẹ jìyà, o ń pète láti bà á jẹ́, tàbí láti rẹ̀ ẹ́ nípò wálẹ̀ lọ́nà míràn, ìlara lè máa “ba ní ẹnu ọ̀nà,” kí ó sì máa wá ọ̀nà láti ṣàkóso rẹ!

Kí ló yẹ kí o ṣe bí o bá rí i pé o ń ní irú èrò oníjàǹbá bẹ́ẹ̀? Kọ́kọ́ gbìyànjú láti gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí ó fún ọ ní ẹ̀mí rẹ̀. Gálátíà 5:16 sọ pé: “Ẹ máa rìn nípa ẹ̀mí ẹ̀yin kì yóò sì ṣe ìfẹ́ ọkàn ti ẹran ara rárá.” (Fi wé Títù 3:3-5.) Ó tún lè ṣèrànwọ́ pé kí o ronú jinlẹ̀ lórí ìmọ̀lára gidi tí o ní sí ọmọ ìyá rẹ. Ǹjẹ́ o lè sọ ní tòótọ́ pé o kò ní ìfẹ́ ẹni yẹn rárá—láìka ìkórìíra tí o ní sí bí? Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé “Ìfẹ́ kì í jowú.” (Kọ́ríńtì Kíní 13:4) Nítorí náà, kò jálẹ̀ láti máa ṣàṣàrò lórí àwọn ìrònú òdì, tí ń ru ìlara sókè. Gbìyànjú láti bá ẹni yẹn yọ̀ bí ó bá ń rí àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ gbà lọ́dọ̀ àwọn òbí yín.—Fi wé Róòmù 12:15.

Àwọn ìjíròrò tí o bá ń bá àwọn òbí rẹ ṣe tún lè wúlò lórí ọ̀ràn yí. Bí ó bá wá dá wọn lójú pé ó yẹ kí wọ́n fún ìwọ náà ní àfiyèsí sí i, èyí yóò túbọ̀ ràn ọ́ lọ́wọ́ láti borí èrò ìlara tí o ní sí àwọn ọmọ ìyá rẹ. Àmọ́, bí ipò inú ilé kò bá dára sí i, tí ṣíṣe ojúsàájú sì ń bá a lọ ńkọ́? Má ṣe bínú sí àwọn òbí rẹ, má ṣe jágbe mọ́ wọn, má sì ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí wọn. Gbìyànjú láti máa ní ìṣarasíhùwà wíwúlò, ti onígbọràn nìṣó. Bí ó bá pọn dandan, wá ìtìlẹ́yìn àwọn adàgbàdénú nínú ìjọ Kristẹni. Ju ohun gbogbo lọ, fà mọ́ Jèhófà Ọlọ́run tímọ́tímọ́. Rántí àwọn ọ̀rọ̀ onísáàmù náà pé: “Nígbà tí baba àti ìyá mi kọ̀ mí sílẹ̀, nígbà náà ni Olúwa yóò tẹ́wọ́ gbà mí.”—Orin Dáfídì 27:10.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí lára àwọn orúkọ náà pa dà.

b Wo àpilẹ̀kọ náà, “Èé Ṣe Tí Wọ́n Ń Fún Arákùnrin Mi Ní Gbogbo Àfiyèsí?” nínú ìtẹ̀jáde Jí!, October 22, 1997.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ṣíṣàlàyé pé o nímọ̀lára pé a pa ọ́ tì lè yanjú ìṣòro náà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́