Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Kí Ni Kí N Ṣe Báwọn Òbí Mi Bá Ń Jiyàn?
BÁWỌN òbí ẹ bá ń ṣe awuyewuye, kò sí bọ́rọ̀ náà ò ṣe ní kàn ẹ́. Ó ṣe tán, o fẹ́ràn wọn, àwọn náà lo sì ní gẹ́gẹ́ bí aláfẹ̀yìntì. Bó bá wá dà bíi pé àwọn méjèèjì ò lè ṣe kí wọ́n má tahùn síra wọn, kò sí ni kí àníyàn má gbà ẹ́ lọ́kàn. Kí ló tiẹ̀ ń fà á tó fi máa ń dà bíi pé èrò àwọn òbí ẹ kì í ṣọ̀kan nígbà míì?
Èrò Tí Ò Ṣọ̀kan
Jésù sọ pé nígbà tí ọkùnrin àti obìnrin kan bá fẹ́ra, wọ́n ti di “ara kan” nìyẹn. (Mátíù 19:5) Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé gbogbo ìgbà ni èrò bàbá rẹ àti ti màmá rẹ á máa ṣọ̀kan? Rárá o. Òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé kò séèyàn méjì èyíkéyìí tí èrò wọn ò ní máa yàtọ̀ síra lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n ì báà tiẹ̀ jẹ́ tọkọtaya tó mọwọ́ ara wọn jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Bí èrò àwọn òbí ẹ ò bá ṣọ̀kan, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ìgbéyàwó wọn ti fẹ́ tú ká o. Kò sí iyè méjì níbẹ̀ pé àwọn òbí ẹ ṣì fẹ́ràn ara wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè máa tahùn síra wọn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀, kí ló fà á tí wọ́n fi ń bára wọn jiyàn. Bóyá ohun tó kàn ṣẹlẹ̀ ni pé ojú tí wọ́n fi máa ń wo nǹkan yàtọ̀ síra. Gbogbo ìgbà náà kọ́ nìyẹn máa ń burú, bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í ṣe ẹ̀rí pé ìgbéyàwó wọn máa pàpà forí ṣánpọ́n.
Àpẹẹrẹ kan rèé: Ṣé ìwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ ti wo sinimá kan rí tó o sì wá rí i pé èrò tìẹ àti tiwọn ò ṣọ̀kan lórí ohun tẹ́ ẹ jọ wò? Irú ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀. Kódà, èrò àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ kòríkòsùn máa ń yàtọ̀ síra.
Ó lè jẹ́ pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn òbí ẹ gan-an nìyẹn. Bóyá ọ̀ràn gbígbọ́ bùkátà ìdílé ló jẹ àwọn méjèèjì lógún, tó sì wá jẹ́ pé ọ̀tọ̀ lojú táwọn méjèèjì fi ń wo bó ṣe yẹ kí wọ́n náwó; ó sì lè jẹ́ pé ó wu àwọn méjèèjì láti gba ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́, àmọ́ kí èrò wọn yàtọ̀ nípa ohun téèyàn lè kà sí fàájì; tàbí kó jẹ́ pé àwọn méjèèjì ń ṣàníyàn nípa bí ẹ̀yin ọmọ ṣe máa kẹ́sẹ járí nílé ìwé, àmọ́ kí èrò wọn nípa ọ̀nà tí wọ́n lè gbà ràn yín lọ́wọ́ yàtọ̀ síra. Ohun tá à ń sọ ni pé, wíwà ní ìṣọ̀kan ò túmọ̀ sí ṣíṣe nǹkan lọ́gbọọgba. Kódà, àwọn èèyàn méjì tí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan nítorí pé wọ́n ti di ẹran ara kan ṣì lè máa wo nǹkan lọ́nà tó yàtọ̀ síra.
Kí ló wá fà á táwọn òbí ẹ fi máa ń jẹ́ kí èdè àìyedè mú kí wọ́n máa bára wọn jiyàn? Kí ló fà á tí ohun tí ò ju ọ̀nà tẹ́lòmíì ń gbà wo nǹkan lọ fi lè mú kí ìjíròrò di iyàn jíjà ran-n-to?
Ọṣẹ́ Tí Àìpé Ń Ṣe
Kò sóhun méjì nídìí ọ̀pọ̀ awuyewuye tó ń wáyé láàárín àwọn òbí ju àìpé lọ. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Bí ẹnì kan kò bá kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, ẹni yìí jẹ́ ènìyàn pípé.” (Jákọ́bù 3:2) Aláìpé làwọn òbí ẹ, aláìpé sì nìwọ náà. Nígbà míì, gbogbo wa la máa ń sọ àwọn nǹkan tá ò jẹ́ ṣe, ìgbà míì sì wà táwọn ọ̀rọ̀ tá a bá sọ á gún àwọn èèyàn lára bí “àwọn ìgúnni idà.”—Òwe 12:18.
Bóyá o lè ti kíyè sí i pé ó máa ń ṣe ìwọ náà bẹ́ẹ̀ nígbà míì. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ o lè ronú kan ìgbà kan tó o fárígá fún ẹnì kan tẹ́ ẹ jọ mọwọ́ ara yín gan-an? Ó ṣeé ṣe kó o rántí. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Kíkẹ́a sọ pé: “Kò sẹ́ni tí èrò ẹ̀ kì í yàtọ̀ sí tẹlòmíì. Kódà, ó lè jẹ́ pé àwọn èèyàn tí mo fẹ́ràn jù lọ gan-an ni wọ́n á máa múnú bí mi jù lọ, bóyá nítorí pé mo ti ń retí ohun tó pọ̀ jù látọ̀dọ̀ wọn!” Àwọn tọkọtaya tó jẹ́ Kristẹni máa ń retí ohun tó pọ̀ látọ̀dọ̀ ara wọn, bó sì ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn, torí pé ìlànà kékeré kọ́ ni Bíbélì gbé kalẹ̀ fún wọn láti máa tẹ̀ lé. (Éfésù 5:24, 25) Níwọ̀n bí àwọn méjèèjì sì ti jẹ́ aláìpé, bó pẹ́ bó yá, wọ́n á ṣẹra wọn. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.”—Róòmù 3:23; 5:12.
Nítorí náà, kò sí ni kí àìgbọ́ra-ẹni-yé díẹ̀díẹ̀ má máa wáyé láàárín àwọn òbí rẹ. Kódà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé àwọn tó ti ṣègbéyàwó á ní “ìpọ́njú nínú ẹran ara,” èyí tí Bíbélì The New English Bible túmọ̀ sí, “ìrora àti ìbànújẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 7:28) Béèyàn bá ro ti gbogbo ohun tó ń bá pàdé lójoojúmọ́, bí ọ̀gá tó ṣòroó tẹ́ lọ́rùn, sún kẹrẹ fà kẹrẹ ọkọ̀, gbèsè àìròtẹ́lẹ̀, ó tó kí ara máa kan án bó bá padà délé.
Bó o bá ń fi sọ́kàn pé aláìpé làwọn òbí rẹ àti pé ìgbà míì wà tí nǹkan lè nira gan-an fún wọn, ìyẹn lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa fojú tó tọ́ wo awuyewuye tó bá wáyé láàárín àwọn méjèèjì. Marie wá rí i pé bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn. Ó sọ pé: “Ó dà bíi pé àwọn òbí mi ń bára wọn jiyàn báyìí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, mo sì máa ń wò ó nígbà míì pé àbí wọ́n ti sú ara wọn ni. Màá tún wá dà á rò pé, ‘Kí ni mo tiẹ̀ ń sọ ná? Ó ti pé ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tí wọ́n ti ṣègbéyàwó, iṣẹ́ ńlá sì ni fún wọn láti máa gbọ́ bùkátà ọmọ márùn-ún!’” Bóyá ìwọ náà lè firú “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì” bẹ́ẹ̀ hàn, kó o má rántí pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà fáwọn òbí ẹ láti bójú tó.—1 Pétérù 3:8.
Ohun Tó O Lè Ṣe
O lè gbà pé aláìpé làwọn òbí rẹ àti pé wàhálà ojoojúmọ́ lè mú kí nǹkan nira gan-an fún wọn. Síbẹ̀, ìbéèrè tá ò ní ṣaláì dáhùn báyìí ni pé, Kí lo lè ṣe bí wọ́n bá ń jiyàn? Gbìyànjú àwọn àbá wọ̀nyí wò:
◼ Máà dá sí i. (Òwe 26:17) Kì í ṣe iṣẹ́ ẹ láti di olùgbaninímọ̀ràn ìgbéyàwó fáwọn méjèèjì tàbí láti bá wọn yanjú èdè-àìyédè wọn. Bó o bá kó sí wọn láàárín, àfàìmọ̀ kọ́ràn náà má padà wá di tìẹ. Fúnkẹ́, ọmọ ọdún méjìdínlógún sọ pé: “Mo ti ṣe alàgàta fáwọn òbí mi rí, àmọ́ ṣe ni wọ́n máa ń sọ fún mi pé kí n máa dá sí i.” Jẹ́ káwọn òbí ẹ fọwọ́ ara wọn yanjú ìṣòro náà.
◼ Má ṣe jẹ́ kó ká ẹ lára ju bó ṣe yẹ lọ. (Kólósè 3:13) Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ti pé àwọn òbí ẹ máa ń jiyàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ò fi dandan túmọ̀ sí pé ìgbéyàwó wọn ti fẹ́ tú ká. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí awuyewuye tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín wọn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan máa mú ẹ bẹ̀rù láìnídìí. Fúnmi, tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún, sọ nípa àwọn òbí rẹ̀ pé: “Ká tiẹ̀ ni wọ́n jà, mo mọ̀ pé wọ́n ṣì fẹ́ràn ara wọn àtàwa ọmọ. Wọ́n á yanjú ẹ̀.” Bí èdè àìyedè bá sẹlẹ̀ láàárín àwọn òbí rẹ, ó ṣeé ṣe káwọn náà parí ẹ̀.
◼ Fohun tó ń gbé ẹ lọ́kàn sókè sínú àdúrà. Bí ohun kan bá ń gbé ẹ lọ́kàn sókè, má wulẹ̀ bò ó mọ́ra. Bíbélì sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.” (Sáàmù 55:22) Àdúrà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ gan-an ni. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn ará Fílípì pé: “Ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.”—Fílípì 4:6, 7.
◼ Gbọ́ tara ẹ. Kò bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn máa yọra ẹ̀ lẹ́nu lórí ohun tó kọjá agbára ẹ̀. Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò sí bí ò ṣe ní máa hàn lójú ẹ. Bíbélì sọ pé: “Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba.” (Òwe 12:25) Gbìyànjú láti mú àníyàn kúrò nípa kíkẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ tó lè gbé ẹ ró, kó o sì máa ṣe àwọn nǹkan tó gbámúṣe.
◼ Báwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kó yẹ kó o máa dá sí ìjà àwọn òbí ẹ, ó dájú pé o lè jẹ́ kí wọ́n mọ bọ́ràn náà ṣe rí lára ẹ. Wá àkókò tó wọ̀ láti tọ ọ̀kan lára wọn lọ. (Òwe 25:11) Fi “inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” bá wọn sọ̀rọ̀. (1 Pétérù 3:15) Má ṣe fẹ̀sùn kàn wọ́n. Ṣe ni kó o wulẹ̀ ṣàlàyé bọ́ràn náà ṣe rí lára ẹ.
O ò ṣe gbìyànjú àwọn àbá tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ jíròrò tán yìí wò? Ìsapá rẹ sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ ran àwọn òbí ẹ lọ́wọ́. Ká tiẹ̀ wá ní kò tu irun kan lára wọn, ọkàn ẹ á balẹ̀ pé bó ò tiẹ̀ lè yí ìwà àwọn òbí ẹ padà, o mọ ohun tó o lè ṣe bí wọ́n bá ń jiyàn.
Àwọn àpilẹ̀kọ láti inú ọ̀wọ́ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” wà nínú ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì náà www.watchtower.org/ype
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí padà.
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
◼ Kí ló máa ń fà á nígbà míì tó fi máa ń nira fáwọn òbí láti gbé láìjà láìta?
◼ Bí ìjà àwọn òbí ẹ bá ń yọ àbúrò ẹ lẹ́nu, kí ni wàá sọ fún un?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20]
Ọ̀RỌ̀ RÈÉ O Ẹ̀YIN ÒBÍ
Kò lè ṣe kí èdè àìyedè má máa wáyé nínú ìgbéyàwó. Ọwọ́ yín ni ọ̀nà tẹ́ ẹ máa gbà bójú tó o wà ṣá o. Kì í dùn máwọn ọmọ nínú báwọn òbí wọn bá ń bára wọn jiyàn. Nítorí náà, ohun tó gbèrò lọ̀ràn iyàn jíjà, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwòkọ́ṣe ló yẹ kí ìgbéyàwó yín jẹ́ fáwọn ọmọ torí ìgbà táwọn náà bá máa ṣègbéyàwó. (Òwe 22:6) Bí èdè àìyedè bá wáyé, ẹ ò kúkú ṣe lo àǹfààní yẹn láti wá àwọn ọ̀nà tó gbéṣẹ́ láti fi yanjú ẹ̀? Ẹ gbìyànjú àwọn àbá tó wà nísàlẹ̀ yìí:
Fetí sílẹ̀. Bíbélì sọ fún wa pé ká “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” (Jákọ́bù 1:19) Má ṣe pa kún èdè àìyedè nípa fífi “ibi san ibi.” (Róòmù 12:17) Bó bá tiẹ̀ dà bíi pé ọkọ tàbí aya rẹ ò fẹ́ láti fetí sílẹ̀, ìwọ ò ṣe fetí sílẹ̀ ńtìẹ.
Sakun láti ṣàlàyé dípò kó o máa wá àṣìṣe. Fohùn pẹ̀lẹ́ sọ fún ọkọ tàbí aya ẹ bí ìwà tó ń hù ṣe rí lára ẹ. (“Ó máa ń dùn mí bó o bá . . . ”) Má ṣe dẹ́bi fún ẹnì kejì ẹ, má sì ṣe wá àṣìṣe ẹ̀. (“O ò kà mí kún nǹkan kan.” “O kì í tẹ́tí sí mi.”)
Máa tètè jánu lórí ọ̀rọ̀. Ìgbà míì wà tó máa ń dáa kéèyàn jánu lórí ọ̀rọ̀ kan kó sì máa bá ìjíròrò náà lọ lẹ́yìn tí inú tó ń bí i bá ti wálẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ asọ̀ dà bí ẹni tí ń tú omi jáde; nítorí náà, kí aáwọ̀ tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀.”—Òwe 17:14.
Ẹ máa tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ara yín, kẹ́ ẹ sì tún máa tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn ọmọ yín bó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Ṣadé, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, sọ pé: “Nígbà míì, lẹ́yìn táwọn òbí mi bá ti bára wọn jiyàn tán, wọ́n á tọrọ àforíjì lọ́wọ́ èmi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin torí wọ́n mọ bó ṣe máa ń rí lára wa.” Ọ̀kan lára ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye jù lọ tó o lè fi kọ́ àwọn ọmọ ẹ ni bí wọ́n ṣe lè máa fìrẹ̀lẹ̀ sọ pé, “Mo tọrọ àforíjì.”
O lè ka púpọ̀ sí i lórí àwọn kókó yìí nínú Jí! January 8, 2001, ojú ìwé 8 sí 14, àti Jí! January 22, 1994, ojú ìwé 3 sí 12.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Má ṣe fẹ̀sùn kàn wọ́n. Ṣe ni kó o wulẹ̀ ṣàlàyé bọ́ràn bá ṣe rí lára ẹ