ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 10/22 ojú ìwé 25-27
  • Èé Ṣe Tí Wọ́n Ń Fún Arákùnrin Mi Ní Gbogbo Àfiyèsí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èé Ṣe Tí Wọ́n Ń Fún Arákùnrin Mi Ní Gbogbo Àfiyèsí?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń Ṣe Ojúsàájú
  • Àìbánilò Lọ́gbọọgba—Ìṣègbè Ha Ni Bí?
  • Kíkọ́ Bí A Tí Ń Fòye Mọ̀
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kojú Ṣíṣe Ojúsàájú?
    Jí!—1997
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Túbọ̀ Mọ Àwọn Òbí Mi?
    Jí!—2010
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Jẹ́ Kí Àlàáfíà Máa Wà Láàárín Èmi àti Àbúrò Tàbí Ẹ̀gbọ́n Mi?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Òfin Yìí Ò Wa Pọ̀ Jù!
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 10/22 ojú ìwé 25-27

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Èé Ṣe Tí Wọ́n Ń Fún Arákùnrin Mi Ní Gbogbo Àfiyèsí?

“Ohun tó ń bí mi nínú ni pé nígbà tí àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò mi bá ṣe ohun tí kò dára, wọ́n máa ń fún wọn ní àfiyèsí púpọ̀—yálà wọ́n ṣe ohun tó dára tàbí ohun tí kò dára. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí mo ti ní ìtẹ̀sí ṣíṣègbọràn, wọ́n máa ń rí mi mú.”—Kay, ọmọ ọdún 18.a

“Wọ́n ń fún àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò mi ní àfiyèsí púpọ̀, wọ́n sì ń ṣe dáadáa sí wọn jù. Lọ́pọ̀ ìgbà, àfiyèsí èyíkéyìí tí mo ń rí gbà máa ń jẹ́ ìbáwí. Ọkàn mi yóò túbọ̀ balẹ̀ tí mo bá mọ̀ pé wọ́n máa ń bá àwọn náà wí.”—Ruth, ọmọ ọdún 15.

“Lójú mi, ó jọ pé wọ́n ń fún àwọn ẹ̀gbọ́n mi ní àǹfààní àti àfiyèsí púpọ̀.” —Bill, ọmọ ọdún 13.

LÁTI ọjọ́ tí wọ́n ti bí wa ni gbogbo wa ti nílò àfiyèsí àwọn òbí wa. Bí o bá sì lérò pé o kò rí ìwọ̀n tí ó tọ́ sí ọ gbà, lọ́nà tó ṣeé lóye, ó lè dùn ọ́, kí inú sì bí ọ. Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀, ní pàtàkì bí ó bá jọ pé ọmọ ìyá rẹ—èyí tó dàgbà jù lọ, èyí tó kéré jù lọ, èyí tí ìwà rẹ̀ dára jù lọ, tàbí èyí tí ń ṣàìgbọràn jù lọ pàápàá—ni wọ́n ń fún ní àfiyèsí ní gbogbo ìgbà. Ìmọ̀lára rẹ tilẹ̀ lè dà bíi ti Dáfídì nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Èmi ti di ẹni ìgbàgbé kúrò ní iyè bí òkú: èmi dà bí ohun èlò fífọ́.”—Orin Dáfídì 31:12.

Rírí i tí wọ́n ń fún ọmọ ìyá rẹ kan ní àfiyèsí tí ìwọ yóò fẹ́ kí ó jẹ́ tìrẹ lè dùn ọ́. Ṣùgbọ́n ó ha fi dandan túmọ̀ sí pé wọn kò nífẹ̀ẹ́ rẹ ni bí? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Nígbà míràn, wọ́n máa ń fún àwọn èwe ní àfiyèsí tí ó pọ̀ sí i nítorí pé wọ́n ní agbára ìlèṣeǹkan tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀ tàbí àwọn àkópọ̀ ìwà bí ọ̀rẹ́. Kenneth, ọmọ ọdún 11, sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpele ẹ̀kọ́ kẹta ni àbúrò mi, Arthur, wà, ó wà nínú ẹgbẹ́ àwọn akọrin ti ìpele ẹ̀kọ́ karùn-ún. Ó tún mọ̀ nípa eré ìdárayá àti ìṣirò dáradára. Ní gidi, ipò kíní ló ń gbà nínú gbogbo iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀. Nígbà míràn, mo máa ń rò pé àwọn ènìyàn fẹ́ràn rẹ̀ jù mí lọ, ṣùgbọ́n n kò jowú rẹ̀. Àmọ́, bóyá níwọ̀nba díẹ̀ ṣá.”

Bákan náà, àwọn èwe kan wà tó jọ pé àwọn ni àwọn òbí wọn máa ń lo èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àkókò lé lórí kìkì nítorí pé àwọn ni wọ́n dàgbà jù lọ—tàbí ni wọ́n kéré jù lọ. Bíbélì sọ nípa ọ̀dọ́kùnrin náà, Jósẹ́fù, pé: “Ísírẹ́lì sì fẹ́ Jósẹ́fù ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọ, nítorí tí í ṣe ọmọ ogbó rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 37:3, 4) Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, Todd, ọmọ ọdún 18, lérò pé wọ́n ń ṣe ojúsàájú fún ẹ̀gbọ́n òun nítorí pé òun ló dàgbà jù lọ. Ó rántí pé: “Nígbà kan, wọ́n ní kí a mú fọ́tò ọmọdé tí a fẹ́ràn jù lọ wá fún iṣẹ́ kan ní ilé ẹ̀kọ́. Ìwọ̀nba díẹ̀ ni àwọn tèmi tí mo rí, mo sì ṣàkíyèsí pé àwọn ti ẹ̀gbọ́n mi pọ̀ gan-an. Ó mú kí ń ṣe kàyéfì nípa ohun tó fà á”

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń fúnni ní àfiyèsí púpọ̀ sí i nítorí pé ọmọ kan ní ìṣòro—bóyá ìṣòro tí ìwọ kò mọ̀ nípa rẹ̀. Cassandra, tí ó ti pé ẹni ọdún 22 báyìí, ṣàlàyé pé: “Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún 16, ẹ̀gbọ́n mi ní ìṣòro kan. Kò dá a lójú bóyá òun fẹ́ láti sin Jèhófà ní ti gidi, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé òun ni àwọn òbí mi ń fún ní gbogbo àfiyèsí wọn. Ní ìgbà yẹn, n kò lóye ohun tó fà á. Mo lérò pé wọn kò bìkítà rárá nípa mi ni. Ó mú kí n nímọ̀lára ìbànújẹ́ àti ìṣátì—orí mi tún gbóná bákan ṣáá.”

Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń Ṣe Ojúsàájú

Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà míràn, àwọn òbí máa ń jẹ̀bi ṣíṣe ojúsàájú. Ìyá kan jẹ́wọ́ pé: “Mo mọ̀ pé ó ń dun ọmọdékùnrin mi, Paul, bí ó ti mọ̀ nípa ìfẹ́ tí a ní fún ọmọdébìnrin wa. Ó ti wí fún wa rí lójúkojú pé, ‘Gbogbo ìgbà tí Liz bá sọ ohun kan ni ẹ̀yin àti Dádì máa ń fojú bá ara yín sọ̀rọ̀.’ Lákọ̀ọ́kọ́, a kò mọ ohun tó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Nígbà tó yá, a wá mọ̀ pé a sábà máa ń fojú bá ara wa sọ̀rọ̀ pé, ‘ohun tó sọ yẹn mà tún dára o.’ Níwọ̀n bí ó ti bá wa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, a ti sapá gidigidi láti ma ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.”

Ṣùgbọ́n kí tilẹ̀ ni ó fà á tí àwọn òbí fi máa ń ṣe ojúsàájú? Ọ̀nà tí a gbà tọ́ àwọn fúnra wọn lè jẹ́ okùnfà kan. Fún àpẹẹrẹ, bí ìyá rẹ bá jẹ́ àbíkẹ́yìn, ó lè túbọ̀ fara mọ́ èyí tó kéré jù lọ lára àwọn ọmọ rẹ̀. Ó lè nítẹ̀sí láti máa gbè sẹ́yìn ẹni yẹn láìmọ̀. Tàbí òbí kan lè fẹ́ràn ọmọ kan tí ìwà òun pẹ̀lú rẹ̀ tàbí ohun tí òun pẹ̀lú rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí dọ́gba. Ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ ní ti Aísíìkì àti Rèbékà nípa àwọn ìbejì wọn náà, Jékọ́bù àti Ísọ̀, pé: “Àwọn ọmọdékùnrin náà sì dàgbà: Ísọ̀ sì ṣe ọlọgbọ́n ọdẹ, ará oko; Jékọ́bù sì ṣe ọ̀bọ̀rọ́ ènìyàn, a máa gbé inú àgọ́. Ísákì sì fẹ́ Ísọ̀, nítorí tí ó ń jẹ nínú ẹran ọdẹ rẹ̀: ṣùgbọ́n Rèbékà fẹ́ Jékọ́bù.”—Jẹ́nẹ́sísì 25:27, 28.

Kí ló yẹ kí o ṣe tí ó bá jọ pé àwọn òbí rẹ ń ṣojúsàájú fún ọ̀kan lára àwọn ọmọ ìyá rẹ?b O lè gbìyànjú láti bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nítùbí-ìnùbí, láìfẹ̀sùnkàn wọ́n. (Òwe 15:22) Nípa títẹ́tí sí wọn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, o lè wá lóye wọn. Èyí lè ṣèrànwọ́ láti mú kí ara rẹ balẹ̀. (Òwe 19:11) Ọ̀dọ́langba kan sọ pé: “Ọkàn mi dà rú gan-an pé Mọ́mì mi fẹ́ràn àbúrò mi ọkùnrin jù mí lọ. Nígbà tí mo bi í nípa rẹ̀, ó ṣàlàyé pé, nítorí pé, ó dà bíi Dádì, ni òun ṣe fẹ́ràn rẹ̀. Àti nítorí pé èmi dà bí òun ni Dádì ṣe sún mọ́ mi. Bákan náà, nítorí pé èmi àti òun rí bákan náà gan-an, a máa ń mú ara wa bínú. Àti nítorí pé bàbá mi àti àbúrò mi ọkùnrin rí bákan náà gan-an, wọ́n máa ń mú orí ara wọn gbóná. Nígbà tí ó ti ṣàlàyé fún mi bẹ́ẹ̀—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò dùn mọ́ mi tó bẹ́ẹ̀—mo lè gbà á.”

Àìbánilò Lọ́gbọọgba—Ìṣègbè Ha Ni Bí?

Bí ó ti wù kí ó rí, èé ṣe tí àwọn òbí kò kàn lè bá olúkúlùkù lò lọ́nà kan náà? Beth, tí ó ti pé ọmọ ọdún 18 báyìí, sọ pé: “Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún 13, mo lérò pé ó yẹ kí wọ́n bá èmi àti àbúrò mi ọkùnrin lò lọ́gbọọgba—ní bákan náà gẹ́lẹ́. Ṣùgbọ́n èmi nìkan ni wọ́n máa ń pariwo mọ́, tí òun sì máa ń mú gbogbo nǹkan jẹ. Ó sì máa ń lo àkókò púpọ̀ pẹ̀lú Dádì ní títún ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ṣe. Ó dà bíi pé ojúsàájú ni.”

Ṣùgbọ́n àìbánilò lọ́gbọọgba kò fi dandan jẹ́ ìṣègbè. Ṣàgbéyẹ̀wò bí Jésù Kristi ṣe bá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lò. Láìsí àní-àní, ó fẹ́ràn àwọn méjèèjìlá, síbẹ̀ ó pe mẹ́ta péré lára wọn láti ṣẹlẹ́rìí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àkànṣe kan, tí ó ní nínú, jíjí ọmọbìnrin Jáírù dìde àti ìyípadà ológo náà. (Mátíù 17:1; Máàkù 5:37) Síwájú sí i, Jésù ní àkànṣe ìbádọ́rẹ̀ẹ́ sísúnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí kan pẹ̀lú àpọ́sítélì Jòhánù. (Jòhánù 13:23; 19:26; 20:2; 21:7, 20) Èyí ha jẹ́ àìbánilò lọ́gbọọgba bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Ojúsàájú ha ni bí? Rárá. Ìdí ni pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù fẹ́ràn àwọn kan ní pàtàkì, kò fọwọ́ rọ́ àìní àwọn àpọ́sítélì tó kù sẹ́yìn.—Máàkù 6:31-34.

Lọ́nà kan náà, ó lè jẹ́ pé wọ́n ń fún ọ̀kan lára àwọn ọmọ ìyá rẹ ní àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ nítorí ẹ̀bùn àbínibí, àkópọ̀ ìwà, tàbí àìní rẹ̀ ni. Bí ó ṣe sábà máa ń rí, ó lè bíni nínú tí a bá ń rí èyí. Ṣùgbọ́n ìbéèrè náà ni pé, Wọ́n ha ń ṣá àwọn àìní rẹ tì bí? Nígbà tí o bá nílò ìmọ̀ràn, ìrànlọ́wọ́, tàbí ìtìlẹ́yìn àwọn òbí rẹ, wọ́n ha máa ń fẹ́ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, o ha lè sọ ní ti gidi pé wọ́n ń ṣègbè sí ọ bí? Bíbélì fún wa níṣìírí láti bá àwọn ẹlòmíràn lò “ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àìní wọn.” (Róòmù 12:13) Níwọ̀n bí ìwọ àti àwọn ọmọ ìyá rẹ ti jẹ́ ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ó ní onírúurú àìní, kò lè rọrùn fún àwọn òbí yìn láti máa báa yín lò lọ́nà kan náà nígbà gbogbo.

Beth, tí a ṣàyọlò ọ̀rọ̀ rẹ̀ níṣàájú, wá tipa bẹ́ẹ̀ mọ̀ pé ìbánilò lọ́gbọọgba kì í fìgbà gbogbo jẹ́ ẹ̀tọ́ ẹni àti pé ìbánilò lọ́nà títọ́ kì í fìgbà gbogbo dọ́gba. Ó wí pé: “Mo wá mọyì pé èmi àti àbúrò mi jẹ́ ẹni méjì yíyàtọ̀síra, wọ́n sì níláti bá wa lò lọ́nà yíyàtọ̀síra. Ní ríronú pa dà sẹ́yìn, n kò lè gbà gbọ́ pé n kò lóye ìyẹn nígbà tí n kò tí ì dàgbà tó báyìí. Mo ronú pé ó wulẹ̀ jẹ́ ohun kan nípa ọ̀nà tí ẹnì kan ń gbà wo nǹkan nígbà tí ó wà lọ́jọ́ orí yẹn ni.”

Kíkọ́ Bí A Tí Ń Fòye Mọ̀

Òtítọ́ ni, “ọ̀nà tí o ń gbà wo nǹkan” ní púpọ̀ láti ṣe pẹ̀lú bí o ṣe ń hùwà pa dà sí ipò rẹ. Bí awò ojú tí a pa láwọ̀, èrò ìmọ̀lára rẹ lè máà mú kí àwọn nǹkan ṣe kedere sí ọ. Àìní fún àfiyèsí àwọn òbí àti ìfọwọ́sí wọn ní ti èrò ìmọ̀lára sì lágbára. Àwọn olùṣèwádìí náà, Stephen Bank àti Michael Kahn, sọ pé: “Kódà bí àwọn òbí bá lè kógo já ní ti ohun àfọkànfẹ́ tí kò ṣeé ṣe náà, bíbá àwọn ọmọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n ní lò lọ́gbọọgba, ọmọ kọ̀ọ̀kan yóò máa wò ó pé àwọn òbí náà ń ṣojúsàájú fún ọmọ mìíràn.”

Fún àpẹẹrẹ, tún ronú nípa ohun tí àwọn èwe mẹ́ta tí a ṣàyọlò ọ̀rọ̀ wọn ní ìbẹ̀rẹ̀ sọ. Yóò jọ pé ipò wọn kò ṣíni lórí, àmọ́ kókó kan ni pé: Ọmọ ìyá kan náà ni wọ́n! Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń wòye pé wọ́n ń fún àwọn tó kù ní àfiyèsí púpọ̀ àti pé òun ni wọ́n ń ṣá tì! Nígbà náà, lọ́pọ̀ ìgbà ló máa ń jẹ́ pé ọ̀nà tí a ń gbà wo nǹkan máa ń kù díẹ̀ káàtó. Òwe 17:27 sọ pé: “Ọlọ́kàntútù sì ni amòye ènìyàn.” Jíjẹ́ ẹni tí ń fòye mọ̀ túmọ̀ sí jíjẹ́ ẹni tí ń wo nǹkan pẹ̀lú èrò títọ́ àti àìsí ẹ̀tanú, kí a máà gbé e karí èrò ìmọ̀lára. Ìfòyemọ̀ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ̀ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí yín lè máà bá gbogbo yín lò lọ́nà kan náà, wọ́n ní ire dídara jù lọ ti gbogbo yín lọ́kàn! Mímọ èyí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yẹra fún bíbínú, kí o sì bọkàn jẹ́.

Nígbà náà, bí ó bá jọ pé wọn kò fún ọ ní ìwọ̀n àfiyèsí tí ó tọ́ sí ọ ńkọ́? Kí ni o lè ṣe? A óò gbé èyí yẹ̀ wò nínú ìtẹ̀jáde Jí! kan nígbà míràn.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí lára àwọn orúkọ náà pa dà.

b Àpilẹ̀kọ kan tí yóò jáde nígbà míràn yóò jíròrò ọ̀rọ̀ nípa kíkojú ṣíṣe ojúsàájú lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ó lè jọ pé àìbánilò lọ́gbọọgba jẹ́ ojúsàájú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́