ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 12/8 ojú ìwé 3-5
  • Kí Ló Ṣe Ọmọ Láǹfààní Jù?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Ṣe Ọmọ Láǹfààní Jù?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Yíyàn Tó Wà fún Àbójútó Ọmọ
  • Àwọn Ìbéèrè Tí A Lè Dojú Kọ
  • Àbójútó Ọmọ—Èrò Oníwọ̀ntúnwọ̀nsì Kan
    Jí!—1997
  • Àbójútó Ọmọ—Ìsìn Àti Òfin
    Jí!—1997
  • Ipa Tí Ìkọ̀sílẹ̀ Máa Ń Ní Lórí Àwọn Ọmọ
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
  • Ohun Mẹ́rin Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Ìkọ̀sílẹ̀
    Jí!—2010
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 12/8 ojú ìwé 3-5

Kí Ló Ṣe Ọmọ Láǹfààní Jù?

KÁ KỌ ara wa sílẹ̀ tàbí ká má kọ ara wa sílẹ̀? Ìbéèrè pàtàkì tó wà lọ́kàn ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ìgbéyàwó wọn kò láyọ̀ nìyẹn. Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, a kì í fojú rere wo ìkọ̀sílẹ̀, a tilẹ̀ ń bu ẹnu àtẹ́ lù ú ní tààrà, nítorí àwọn ìdí tí ó kan ìwà rere àti ìsìn. Àwọn òbí tí ìgbéyàwó wọn kò láyọ̀ pàápàá máa ń wà pọ̀ nìṣó nítorí àwọn ọmọ. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọ̀pá ìdíwọ̀n ayé yìí ti yí dà délẹ̀délẹ̀ ní àkókò lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí. Lóde òní, ìkọ̀sílẹ̀ ti ní ìtẹ́wọ́gbà níbi púpọ̀.

Síbẹ̀, láìka ìtẹ́wọ́gbà tí ìkọ̀sílẹ̀ ní sí, àwọn òbí, adájọ́, onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá, àti àwọn mìíràn, tí ń pọ̀ sí i, ń dàníyàn nípa ipa búburú tí ìkọ̀sílẹ̀ ń ní lórí àwọn ọmọdé. A ń gbọ́ àwọn èrò tí a ń sọ jáde nísinsìnyí pé ó yẹ kí a ṣọ́ra. Àwọn ẹ̀rí tí ń pọ̀ sí i ń fi hàn pé ìkọ̀sílẹ̀ lè ní ipa tí ń múni banú jẹ́ lórí ọmọ kan. A ń rọ àwọn òbí pé kí wọ́n máa ronú lórí ohun tí àbájáde ìkọ̀sílẹ̀ jẹ́ fún àwọn fúnra wọn àti fún àwọn ọmọ wọn. Onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá, Sara McLanahan, ti Yunifásítì Princeton, sọ pé, “láàárín ìpín méjì nínú mẹ́ta sí ìpín mẹ́ta nínú mẹ́rin àwọn ìdílé tó ṣe ìkọ̀sílẹ̀ ni ì bá túbọ̀ yọ̀ǹda àkókò sí i, kí wọ́n sì tún dà á rò, kí wọ́n lè mọ̀ bóyá ohun tó tọ́ ni wọ́n ń ṣe.”

Àwọn ìwádìí tí a ṣe ní lọ́ọ́lọ́ọ́ fi hàn pé àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọn ti kọra sílẹ̀ ló ń kojú ewu púpọ̀ jù lọ ní ti lílóyún nígbà ọ̀dọ́langba, kíkẹ́kọ̀ọ́ dààbọ̀, ìsoríkọ́, ṣíṣe ìkọ̀sílẹ̀ nínú ìgbéyàwó tiwọn náà, àti wíwọ ẹgbẹ́ àwọn tí ń gba ìrànwọ́ ohun amáyédẹrùn. Ní apá Ìwọ̀ Oòrùn ayé, ìkọ̀sílẹ̀ ń nípa lórí ìpín 1 nínú 6 àwọn ọmọdé. Nínú ìwé tí òpìtàn Mary Ann Mason kọ lórí àbójútó ọmọ ní United States, ó sọ pé: “Ó ṣeé ṣe ní ìwọ̀n ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún pé kí ọmọ kan tí a bí ní 1990 bá ara rẹ̀ lábẹ́ àṣẹ ilé ẹjọ́ nínú ẹjọ́ lórí ibi tí yóò gbé àti ọ̀dọ̀ ẹni tí yóò máa gbé.”

Ó bani nínú jẹ́ pé ìkọ̀sílẹ̀ kì í fòpin sí ìkóguntini, níwọ̀n bí àwọn òbí ti lè máa jà nìṣó nílé ẹjọ́ lórí àbójútó ọmọ àti ṣíṣe ìbẹ̀wò sọ́dọ̀ ọmọ, tí ó túbọ̀ ń fi kún másùnmáwo àwọn ọmọ wọn. Àwọn ìfojúkojú onímọ̀lára bí ọ̀tá nínú àyíká ilé ẹjọ́ yìí máa ń dán ìṣòtítọ́ àwọn ọmọ sí àwọn òbí wọn wò, ó sì sábà máa ń mú wọn rò pé àwọn kò ní olùrànlọ́wọ́, ó sì ń bà wọ́n lẹ́rù.

Ẹnì kan tó jẹ́ olùgbaninímọ̀ràn nípa ìgbésí ayé ìdílé sọ pé: “Ìkọ̀sílẹ̀ kì í gba àwọn ọmọdé lọ́wọ́ ewu. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó ń gba àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́ ewu.” Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, àwọn òbí lè yanjú àwọn ìṣòro tiwọn fúnra wọn nípa kíkọ ara wọn sílẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà kan náà, wọ́n lè ṣèpalára fún àwọn ọmọ wọn, tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n lo ìyókù ìgbésí ayé wọn ní sísapá láti wo ìpalára náà sàn.

Àwọn Yíyàn Tó Wà fún Àbójútó Ọmọ

Lójú ìkóguntini àti másùnmáwo ti ìmọ̀lára tó rọ̀ mọ́ títú ìbátan ìgbéyàwó ká, ó ṣòro gidigidi láti fikùn lukùn jíròrò àbójútó àwọn ọmọ lọ́jọ́ iwájú lọ́nà onípẹ̀lẹ́tù òun ìgbatẹnirò. Láti dín ìkora-ẹni-lójú láàárín àwọn òbí kù, kí a sì yẹra fún ìpenilẹ́jọ́ bí ọ̀tá, àwọn aláṣẹ kan pèsè ọ̀nà àfirọ́pò kan láti yanjú awuyewuye, bíi kí ẹlòmíràn kan, yàtọ̀ sí ilé ẹjọ́, dá sí ọ̀rọ̀ náà.

Bí a bá ṣe é dáradára, bíbánidásọ́rọ̀ ń yọ̀ǹda fún àwọn òbí náà láti ṣètò àdéhùn kan, dípò kí wọ́n fi ìpinnu ibi tí àwọn ọmọ yóò wà sọ́wọ́ adájọ́ kan. Bí bíbánidásọ́rọ̀ kò bá ṣeé ṣe, àwọn òbí náà lè ṣètò fún àbójútó àti ìbẹ̀wò nípasẹ̀ àwọn agbẹjọ́rò wọn. Ní gbàrà tí àwọn òbí náà bá ti fẹnu kò, tí wọ́n sì ṣàkọsílẹ̀ àdéhùn wọn, adájọ́ lè fọwọ́ sí àṣẹ kan tó ní àwọn ohun tí wọ́n fẹ́ nínú.

Nígbà tí àwọn òbí kò bá lè fẹnu kò lórí ètò àbójútó kan, ètò òfin ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè yóò pèsè ọ̀nà láti gbìyànjú rí sí i pé a dáàbò bo ire dídára jù lọ ti àwọn ọmọ náà. Ohun tí yóò jẹ adájọ́ náà lọ́kàn jù lọ ni àwọn ọmọ náà, kì í ṣe àwọn òbí. Adájọ́ yóò ṣàyẹ̀wò àwọn kókó tí ó tan mọ́ ọn, bí ohun tí àwọn òbí fẹ́, ìbátan tó wà láàárín ọmọ náà àti òbí kọ̀ọ̀kan, ohun tí ọmọ náà yàn láàyò, àti bí òbí kọ̀ọ̀kan ṣe lágbára tó láti pèsè àbójútó ojoojúmọ́. Adájọ́ yóò wá pinnu ibi tí ọmọ náà yóò gbé àti ọ̀dọ̀ ẹni tí yóò gbé, bákan náà ni yóò pinnu bí àwọn òbí náà yóò ṣe ṣètò àwọn ìpinnu pàtàkì nípa ọjọ́ ọ̀la ọmọ náà.

Nínú ìṣètò àbójútó àdáṣe, òbí kan lè ní àṣẹ láti dá ṣe àwọn ìpinnu. Nínú ìṣètò àbójútó àjùmọ̀ṣe, àwọn òbí méjèèjì gbọ́dọ̀ fohùn ṣọ̀kan lórí àwọn ìpinnu pàtàkì, bí ìtọ́jú ìṣègùn àti ẹ̀kọ́ ọmọ.

Àwọn Ìbéèrè Tí A Lè Dojú Kọ

Nígbà tí àwọn òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ń jẹ́jọ́ lórí àbójútó ọmọ, wọ́n tún gbọ́dọ̀ ronú lórí ohun tí yóò ṣe àwọn ọmọ náà láǹfààní jù lọ nípa tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, bí òbí tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí náà bá lòdì sí ìdálẹ́kọ̀ọ́ èyíkéyìí láti inú Bíbélì fún àwọn ọmọ ńkọ́? Tàbí bí òbí tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí náà bá wá jẹ́ ẹni tí a ti yọ lẹ́gbẹ́ nínú ìjọ Kristẹni ńkọ́?

Àwọn ipò àfinúrò wọ̀nyí lè túbọ̀ mú kí ṣíṣe ìpinnu lọ́jú pọ̀ fún àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni. Wọ́n ń fẹ́ hùwà lọ́nà ọgbọ́n àti ìgbatẹnirò, wọ́n sì tún ń fẹ́ máa ní ẹ̀rí ọkàn rere nìṣó níwájú Jèhófà, bí wọ́n ti ń ronú tàdúràtàdúrà lórí àwọn ohun tí yóò ṣe àwọn ọmọ náà láǹfààní jù lọ.

Nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a óò ṣàyẹ̀wò àwọn ìbéèrè bí ìwọ̀nyí: Ojú wo ni òfin fi ń wo ìsìn nígbà tí ó bá ń fúnni ní ẹ̀tọ́ àbójútó ọmọ? Báwo ni mo ṣe lè kojú ìpèníjà tí ẹjọ́ àbójútó ọmọ ń mú wá lọ́nà àṣeyọrí? Báwo ni mo ṣe lè kojú ìpàdánù ẹ̀tọ́ láti bójú tó àwọn ọmọ mi? Ojú wo ni mo ní láti fi wo àdéhùn àjùmọ̀-ṣàbójútó-ọmọ pẹ̀lú òbí kan tí a ti yọ lẹ́gbẹ́?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́