Àbójútó Ọmọ—Èrò Oníwọ̀ntúnwọ̀nsì Kan
NÍGBÀ púpọ̀, ìṣòro gidi náà máa ń dé lẹ́yìn ìkọ̀sílẹ̀, nínú ìjàkadì lórí ìfẹ́ni àti àbójútó ọmọ. Òwe náà, “ìjọ̀ngbọ̀n kò ṣeé nìkan fà,” kì í fìgbà gbogbo jóòótọ́. Òbí kan ṣoṣo tí ń fẹ́ kí gbogbo nǹkan rí bí òun nìkan ṣe ń fẹ́ lè máa fàjọ̀ngbọ̀n. Agbẹjọ́rò kan nípa ọ̀ràn ìdílé ní Toronto, Kánádà, sọ pé: “Nínú òfin ìdílé, ohun gbogbo ló kan ìmọ̀lára àti ìrònú àwọn ènìyàn.”
Kàkà kí àwọn òbí kan ronú lórí ohun tó ṣe ọmọ láǹfààní jù, wọ́n ń fa ìjọ̀ngbọ̀n lọ nípa pípẹjọ́ lórí àwọn ọ̀ràn kéékèèké. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ti gbìyànjú láti fẹ̀rí hàn pé a ní láti yí ẹ̀tọ́ àbójútó ọmọ pa dà nítorí pé òbí kejì jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, yóò sì du ọmọ náà ní ‘ọ̀nà ìgbésí ayé yíyẹ.’
Òbí tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí náà lè sọ ọ̀ràn ṣíṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí, Kérésìmesì, tàbí Halloween pàápàá di nǹkan bàbàrà. Àwọn kan lè ṣàwáwí pé kíkọ̀ tí ọmọ náà bá kọ̀ láti kí àsíá yóò pààlà sí ìbákẹ́gbẹ́ ọmọ náà àti ìbáwùjọṣe rẹ̀. Àwọn kan tilẹ̀ lè sọ pé bíbá tí ọmọ náà bá ń bá òbí náà jáde láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì lè ba ìrònú òun ìhùwà rẹ̀ jẹ́. Àwọn òbí kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí tilẹ̀ ti fẹ̀sùn kàn pé ìwàláàyè ọmọ náà yóò wà nínú ewu nítorí pé òbí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí náà kì yóò gbà pé kí ọmọ náà gbẹ̀jẹ̀ sára.
Báwo ni Kristẹni kan ṣe ń kojú ìṣòro irú àwọn àwáwí tó kan ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀? Ìdáhùn tí ń fìgbónára hàn—“fífi eegun ko eegun”—kò ní gbéṣẹ́. Bí a bá gbé ọ̀ràn náà lọ síwájú adájọ́ kan, òbí kọ̀ọ̀kan yóò ní àǹfààní láti sọ̀rọ̀ ká gbọ́. Ó ṣe pàtàkì jù láti fi ìmọ̀ràn Bíbélì sọ́kàn pé: “Kó ẹrù rẹ lọ sí ara Olúwa, òun ni yóò sì mú ọ dúró: òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ olódodo kí ó yẹ̀ láé.” (Orin Dáfídì 55:22) Nípa ṣíṣe àṣàrò lórí èyí àti nípa lílo àwọn ìlànà inú Bíbélì, pẹ̀lú ìrànwọ́ Jèhófà, àwọn òbí lè kojú ipò tó wù kó yọjú nípa ẹ̀tọ́ àbójútó ọmọ.—Òwe 15:28
Ìfòyebánilò
Kókó tó ṣe pàtàkì jù ni ohun tó ṣe ọmọ náà láǹfààní jù lọ. Bí òbí kan bá jẹ́ arinkinkin, ó lè pàdánù ẹ̀tọ́ àbójútó ọmọ, ó sì lè rí i pé a pààlà sí àǹfààní òun láti bẹ ọmọ wò pàápàá. Òbí tó gbọ́n máa ń hùwà lọ́nà alálàáfíà, ní fífi ìmọ̀ràn Bíbélì sọ́kàn pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. . . . Ẹ yàgò fún ìrunú . . . Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” (Róòmù 12:17-21) Ì báà jẹ́ nílé ẹjọ́, tàbí ní ọ́fíìsì agbẹjọ́rò, tàbí lọ́dọ̀ olùdíyelé ẹ̀tọ́ àbójútó ọmọ, ó yẹ kí àwọn òbí “jẹ́ kí ìfòyebánilò [wọn] di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.”—Fílípì 4:5
Alábàáṣègbéyàwó kan tí a kẹ̀yìn sí yóò gbìyànjú láti tan àwọn ẹlòmíràn jẹ nípa mímú àwọn ìṣòro aṣinilọ́nà tí ó jẹ́ àrògún lásán wọ ọ̀ràn náà. Ó bọ́gbọ́n mu láti má ṣe hùwà pa dà ju bó ṣe yẹ lọ sí àwọn ìsọ̀kò-ọ̀rọ̀-luni wọ̀nyí. Àwọn kókó tí àwọn alábàáṣègbéyàwó tí a bá kẹ̀yìn sí sábà ń lò láti dá yánpọnyánrin sílẹ̀ níbi ìgbẹ́jọ́ ẹ̀tọ́ àbójútó ọmọ ni ìlera, ìsìn, àti ẹ̀kọ́.—Òwe 14:22.
Ìfòyebánilò tún kan agbára láti ronú lórí àwọn kókó tó jẹ́ òótọ́, kí a sì ṣètò àdéhùn tí kò fì síbì kan. Òbí kankan kò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé lẹ́yìn ìkọ̀sílẹ̀ pàápàá, ọmọ náà ṣì ní òbí méjì. Àwọn òbí ti kọ ara wọn sílẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò kọ ọmọ náà sílẹ̀. Nítorí náà, bí kò bá jẹ́ pé ọ̀ràn náà kọjá ààlà, òbí kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ lómìnira láti ṣe bí òbí nígbà tí ọmọ náà ṣì jẹ́ tirẹ̀. Òbí kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ lè sọ èrò rẹ̀ àti ohun tí ó kà sí pàtàkì, kí ó sì jẹ́ kí ọmọ náà ṣàjọpín àwọn ìgbòkègbodò bíbófinmu ti òbí náà, ì báà jẹ́ ti ìsìn tàbí ti ohun mìíràn.
Ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò ohun tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ àbájáde irú ìgbẹ́jọ́ bẹ́ẹ̀: (1) àbójútó àjùmọ̀ṣe, (2) àbójútó àdáṣe, àti (3) ààlà lórí àǹfààní ìṣèbẹ̀wò. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín àbójútó àjùmọ̀ṣe àti àbójútó àdáṣe? Báwo ni o ṣe lè kojú ipò náà nígbà tí o bá pàdánù ẹ̀tọ́ àbójútó? Bí òbí kan bá jẹ́ ẹni tí a ti yọ lẹ́gbẹ́ ńkọ́?
Àbójútó Àjùmọ̀ṣe
Àwọn adájọ́ kan rò pé ó ṣe pàtàkì kí àwọn òbí méjèèjì àti ọmọ máa ríra. Wọ́n gbé ìrònú wọn karí àwọn ìwádìí tó fi hàn pé bí àwọn òbí bá lè ṣàjọpín ẹ̀tọ́ àbójútó ọmọ, yóò dín másùnmáwo àti ìpalára ti ìmọ̀lára tí ọmọ yóò ní lẹ́yìn ìkọ̀sílẹ̀ kù. Kàkà tí ọmọ ì bá fi rò pé òbí kan pa òun tì, yóò nímọ̀lára pé àwọn òbí nífẹ̀ẹ́ òun, ọ̀ràn àwọn ìdílé méjèèjì sì kan òun. Agbẹjọ́rò kan nípa ọ̀ràn ìdílé sọ pé: “Àbójútó àjùmọ̀ṣe jẹ́ ọ̀nà kan láti jẹ́ kí àwọn òbí méjèèjì kópa.”
Bí ó ti wù kí ó rí, Ọ̀mọ̀wé Judith Wallerstein, olùdarí àgbà Ibùdó fún Ìdílé Tí Ń Yí Pa Dà, ní Corte Madera, California, kìlọ̀ pé, láti mú kí àbójútó àjùmọ̀ṣe gbéṣẹ́, àwọn òbí gbọ́dọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀, kí ọmọ sì lè tẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún, kí ó sì lè máa wà ní ipò ọ̀rẹ́ sí àwọn ènìyàn. Àwọn ànímọ́ wọ̀nyí ṣe pàtàkì nítorí pé nínú àbójútó àjùmọ̀ṣe, àwọn òbí méjèèjì ṣì ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin síbẹ̀ láti ṣàjọpín ṣíṣe ìpinnu lórí àwọn ọ̀ràn pàtàkì tí ó kan ìlera, ẹ̀kọ́, ìtọ́nidàgbà lọ́nà ti ìsìn, àti ìgbésí ayé ọmọ wọn láàárín àwùjọ. Ṣùgbọ́n èyí ń gbéṣẹ́, kìkì bí àwọn òbí méjèèjì bá ń gba tẹni rò ní ríronú lórí ohun tó ṣe ọmọ náà láǹfààní jù lọ, kàkà kí ó jẹ́ lórí ohun tí ó ṣe àwọn fúnra wọn láǹfààní.
Àbójútó Àdáṣe
Ilé ẹjọ́ lè fún òbí tí ó bá rò pé ó lè pèsè fún àwọn àìní ọmọ náà lọ́nà sísànjù ní àbójútó àdáṣe láti bójú tó ọmọ. Adájọ́ lè pinnu pé kí òbí tí a fún ní ẹ̀tọ́ ṣíṣe àbójútó náà máa dá ìpinnu ṣe lórí àwọn ọ̀ràn pàtàkì tí ó bá kan ire ọmọ náà. Lọ́pọ̀ ìgbà, ilé ẹjọ́ ń dórí ìpinnu náà lẹ́yìn gbígbọ́ ohun tí àwọn olùdíyelé bá rí—àwọn wọ̀nyí sábà máa ń jẹ́ afìṣemọ̀rònú, oníṣègùn ọpọlọ, tàbí òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re.
Àwọn tí ń ṣagbátẹrù àbójútó àdáṣe rò pé ìṣètò náà túbọ̀ ń mú kí ọmọ lè fọkàn balẹ̀. Nígbà tí àwọn òbí kò bá lè jùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀, tàbí tí ó jọ pé wọn kò lè ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ adájọ́ ń yan ìṣètò ẹ̀tọ́ àbójútó yìí láàyò. Ó dájú pé, ìyẹn kò yọwọ́ òbí tí kò ní ẹ̀tọ́ àbójútó náà lára ìgbésí ayé ọmọ ọ̀hún. Ní gbogbogbòò, a máa ń fún òbí tí kò ní ẹ̀tọ́ àbójútó ní ẹ̀tọ́ ìṣèbẹ̀wò, àwọn òbí méjèèjì sì lè máa pèsè ìtọ́sọ́nà, ìfẹ́, àti ìfẹ́ni, tí ọmọ nílò nìṣó.
Àǹfààní Ìṣèbẹ̀wò
Kò yẹ kí àwọn òbí máa fojú wo ẹ̀tọ́ àbójútó ọmọ bí ohun tí ó ní “aṣẹ́gun” àti “olùpàdánù.” Àwọn òbí kẹ́sẹ járí, wọ́n sì “ṣẹ́gun” nígbà tí wọ́n bá rí i tí àwọn ọmọ wọn di àgbàlagbà tó dàgbà dénú, tó tóótun, tó ń jèrè ọ̀wọ̀. Àṣeyọrí nínú títọ́ ọmọ kò ní ohun kan ṣe ní tààrà pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àbójútó lábẹ́ òfin. Nípa títẹ̀lé àwọn ipò tí ilé ẹjọ́ fi lélẹ̀ nínú àwọn ọ̀ràn ẹ̀tọ́ àbójútó ọmọ, kódà, nígbà tí ó bá jọ pé àwọn wọ̀nyí kò tọ́ pàápàá, Kristẹni kan ń fi hàn pé òun “wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga.” (Róòmù 13:1) Ó tún ṣe pàtàkì láti rántí pé èyí kì í ṣe àkókò láti jìjàdù láti lè jèrè ìfẹ́ni tàbí ìdúrótini àwọn ọmọ rẹ nípa títẹ́ńbẹ́lú òbí kejì nínú ìgbìyànjú láti ba ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú wọn jẹ́.
Bíbélì ní ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn òbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nítorí àwọn ìdí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, wọn kò bá àwọn ọmọ wọn gbé. Bí àpẹẹrẹ, Ámúrámù àti Jókébédì, àwọn òbí Mósè, bí wọ́n ti ń gbégbèésẹ̀ tí yóò ṣe ọmọ wọn láǹfààní jù lọ, gbé e sínú áàkì kan tí ń léfòó ‘nínú koríko odò lẹ́bàá odò Náílì.’ Nígbà ti ọmọbìnrin Fáráò sì yọ ọmọ ọwọ́ náà, wọ́n di ìgbẹ́kẹ̀lé tí wọ́n ní nínú Jèhófà mú. A san ẹ̀san àǹfààní “ìṣèbẹ̀wò” fún àwọn ọlọgbọ́n àti olùṣòtítọ́ òbí wọ̀nyí, wọ́n sì lò ó lọ́nà gbígbéṣẹ́ láti tọ́ ọmọ náà ní ọ̀nà Jèhófà. Mósè dàgbà di ìránṣẹ́ títayọ kan fún Ọlọ́run òtítọ́.—Ẹ́kísódù 2:1-10; 6:20.
Àmọ́, bí ọ̀kan lára àwọn òbí náà bá jẹ́ ẹni tí a ti yọ lẹ́gbẹ́ ńkọ́? Òbí tó jẹ́ Kristẹni náà ha ní láti mú kí ọmọ náà wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún ìbẹ̀wò bí? Ipò ìbátan tẹ̀mí láàárín ẹni tí a yọ lẹ́gbẹ́ àti ìjọ Kristẹni nìkan ni ìgbésẹ̀ ìyọnilẹ́gbẹ́ nínú ìjọ yí pa dà. Ní gidi, ó já àwọn ìdè tẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ìbátan òbí sí ọmọ ṣì wà digbí. Òbí tó ní ẹ̀tọ́ àbójútó náà gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ ìṣèbẹ̀wò tí òbí tí a yọ lẹ́gbẹ́ náà ní. Bí ó ti wù kí ó rí, bí òbí tí kò ní ẹ̀tọ́ àbójútó náà bá wá jẹ́ ewu ojú ẹsẹ̀ tó gadabú fún ire ọmọ náà ní ti ara àti ti ìmọ̀lára, nígbà náà, ilé ẹjọ́ (kì í ṣe òbí tó ní ẹ̀tọ́ àbójútó) lè ṣètò pé kí ẹnì kẹta máa wà níbẹ̀ nígbà ìbẹ̀wò sọ́dọ̀ ọmọ náà.
Ìwọ Nìkan Kọ́
Ìgbẹ́jọ́ ìkọ̀sílẹ̀ àti awuyewuye ẹ̀tọ́ àbójútó ọmọ tó máa ń tẹ̀ lé e jẹ́ ìrírí tó máa ń tánni lókun ní ti ìmọ̀lára. Ìgbéyàwó kan tó bẹ̀rẹ̀ dáradára ti forí ṣánpọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìfinúrò, ìwéwèé, àti ìrètí àwọn tọkọtaya náà. Bí àpẹẹrẹ, àìṣòótọ́ nínú ìgbéyàwó àti ìfìyàjẹnijù lè fipá mú kí adúróṣinṣin ìyàwó kan wá ààbò fún ara rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ lábẹ́ òfin. Síbẹ̀, ìmọ̀lára ẹ̀bi àti àìdójúùlà lè máa wà nìṣó bí ó ṣe ń ronú lórí ohun tí ó dojú rú tàbí bí a ṣe ti lè bójú tó o lọ́nà tó túbọ̀ gbéṣẹ́ ṣáájú. Ọ̀pọ̀ tọkọtaya ń ṣàníyàn lórí bí àwọn ọmọ wọn yóò ṣe hùwà pa dà sí ìtúká ìdílé. Ìjìjàdù fún ẹ̀tọ́ àbójútó nílé ẹjọ́ lè di ìṣẹ̀lẹ̀ ayíǹkanpadà tegbòtigaga lójijì ní ti ìmọ̀lára, tí ń dán ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni nínú Jèhófà wò ní àfikún sí dídán ìdúróṣinṣin ẹni wò gẹ́gẹ́ bí òbí.—Fi wé Orin Dáfídì 34:15, 18, 19, 22.
Nígbà tí òbí aláìmọwọ́mẹsẹ̀ kan bá pinnu láti wá nǹkan ṣe nítorí ìfìyàjẹ-ọmọdé tàbí ìfìyàjẹ-alábàáṣègbéyàwó jù tàbí láti dáàbò bo ìlera rẹ̀ lọ́wọ́ ewu àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré láti ọ̀dọ̀ alábàáṣègbéyàwó kan tó jẹ́ aláìṣòótọ́, òbí aláìmọwọ́mẹsẹ̀ náà kò ní ìdí kankan láti nímọ̀lára ẹ̀bi tàbí láti rò pé Jèhófà kọ òun sílẹ̀. (Orin Dáfídì 37:28) Alábàáṣègbéyàwó tó jẹ́ aláìṣòótọ́ tàbí tí ń fìyà jẹni náà ló ti tẹ àdéhùn àjọṣe mímọ́ ti ìgbéyàwó lójú, tí ó sì “hùwà ẹ̀tàn” sí ẹnì kejì rẹ̀.—Málákì 2:14.
Máa bá a nìṣó láti “di ẹ̀rí ọkàn rere mú” níwájú ènìyàn àti Jèhófà nípa lílo àwọn ìlànà Bíbélì, fífi òótọ́ bá alábàáṣègbéyàwó rẹ tí o kẹ̀yìn sí lò, àti fífi hàn pé o ṣeé tẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún nínú àwọn àdéhùn àbójútó tí ẹ ṣe. “Ó sàn láti jìyà nítorí pé ẹ ń ṣe rere, bí ìfẹ́ inú Ọlọ́run bá fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀, ju kí ó jẹ́ nítorí pé ẹ ń ṣe ibi.”—Pétérù Kíní 3:16, 17.
Ní ti àwọn ọmọ, wọ́n nílò ìdánilójú pé ìtúká ìdílé náà kì í ṣe ẹ̀bi àwọn. Nígbà míràn, nǹkan kì í wulẹ̀ rí bí a ti wéwèé rẹ̀. Ṣùgbọ́n títẹ̀lé àwọn ìlànà inú Bíbélì lè mú kí ipa tí ìkọ̀sílẹ̀ ń ní rọjú nípa fífàyègba ìjíròrò tinútinú tí ń fòye hàn láàárín àwọn òbí àti àwọn ọmọ. Bí àpẹẹrẹ, a lè ṣe èyí nípa jíjẹ́ kí àwọn ọmọ kó ipa gidi nínú ìṣètò ìgbésí ayé ìdílé lẹ́yìn ìkọ̀sílẹ̀. Nípa jíjẹ́ onísùúrù àti onínúure, àti lílọ́kàn ìfẹ́ sí èrò àwọn ọmọ àti fífetísí ohun tí wọ́n bá ní láti sọ, o lè ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an láti mú ara bá àwọn ìṣètò ọ̀nà ìṣeǹkan àti ìgbésí ayé tuntun mu.
Àwọn Mìíràn Lè Ṣèrànwọ́
Àwọn òbí nìkan kọ́ ló lè ṣèrànwọ́ fún ọmọ kan tí ìdílé rẹ̀ tú ká. Àwọn mọ̀lẹ́bí, àwọn olùkọ́, àti àwọn ọ̀rẹ́ lè ṣètìlẹ́yìn kí wọ́n sì pèsè ìdánilójú fún àwọn ọmọ nínú ìdílé tí àwọn òbí ti kọra wọn sílẹ̀. Ní pàtàkì, àwọn òbí àgbà lè kópa gidigidi nínú mímú kí ọkàn àwọn ọmọ balẹ̀, kí wọ́n sì gbádùn ní ti ìmọ̀lára.
Àwọn òbí àgbà tí wọ́n jẹ́ Kristẹni lè pèsè ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tẹ̀mí àti àwọn ìgbòkègbodò gbígbámúṣé fún àwọn ọmọ, ṣùgbọ́n wọ́n gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún ìpinnu àwọn òbí nípa ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ìsìn, nítorí pé àṣẹ ti ìwà rere àti òfin láti ṣe ìpinnu wọ̀nyí jẹ́ ti àwọn òbí, kì í ṣe ti àwọn òbí àgbà.—Éfésù 6:2-4.
Bí àwọn ọmọ tí àwọn òbí wọn ti kọra wọn sílẹ̀ bá ní irú ìtìlẹ́yìn bẹ́ẹ̀, wọ́n lè la ìtúká ìgbéyàwó àwọn òbí wọn já. Wọ́n sì lè máa bá a lọ ní wíwo iwájú fún àwọn ìbùkún ayé tuntun ti Ọlọ́run, níbi tí gbogbo ìdílé yóò ti bọ́ lọ́wọ́ “ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́ [tí wọn] yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:21; Pétérù Kejì 3:13.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]
Ṣíṣàtúnṣe Àwọn Àṣìlóye
“Ahọ́n ọlọgbọ́n ń lo ìmọ̀ rere,” òbí kan tó jẹ́ Kristẹni sì ní àǹfààní gidi kan láti ṣàtúnṣe àwọn àṣìlóye tàbí ohun tí kò jóòótọ́ tán. (Òwe 15:2) Bí àpẹẹrẹ, ní ti àbójútó ìlera àwọn ọmọ wọn, “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fara mọ́ ìtọ́jú ìṣègùn àti iṣẹ́ abẹ,” ṣùgbọ́n níbi tí Ẹlẹ́rìí kan bá ti jẹ́ òbí tí a fún ní ẹ̀tọ́ àbójútó ọmọ, ó ní ẹ̀tọ́ sí ìjọ́hẹn fún oríṣi ìtọ́jú èyíkéyìí.a—The Journal of the American Medical Association.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fọwọ́ gidi mú ìsìn wọn, tí a gbé karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì. Èyí mú kí wọ́n jẹ́ bàbá, ìyá, ọmọ, ọ̀rẹ́, aládùúgbò, àti ọmọ ìbílẹ̀, tí ó dára jù. Àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni ń fi ìfẹ́ báni wí, wọ́n ń mú ọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ dàgbà, wọ́n sì ń fún àwọn ọmọ wọn ní ọ̀wọ́ àwọn ojúlówó ìlànà ní ìmúrasílẹ̀ fún ìgbésí ayé.b—Òwe 13:18.
Apá pàtàkì kan nínú títọ́ ọmọ dàgbà ni ẹ̀kọ́ ìwé, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ń fẹ́ kí àwọn ọmọ wọn ní èyí tí ó bá dára jù tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó.c—Òwe 13:20.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé pẹlẹbẹ náà, How Can Blood Save Your Life?, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
b Wo ìwé náà, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, orí 5 sí 7, 9, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
c Wo ìwé pẹlẹbẹ náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Òbí kan tó ní ẹ̀tọ́ àbójútó gbọ́dọ̀ fi sùúrù tẹ́tí sílẹ̀ nígbà tí ọmọ kan bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìbẹ̀wò òbí tí kò ní ẹ̀tọ́ àbójútó sọ́dọ̀ òun