Àbójútó Ọmọ—Ìsìn Àti Òfin
NÍNÚ àwọn ẹjọ́ ìkọ̀sílẹ̀ àti àbójútó ọmọ, ìsìn lè jẹ́ kókó pàtàkì kan—tí ó tilẹ̀ díjú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìbéèrè bí ìwọ̀nyí lè yọjú.
Adájọ́ kan ha gbọ́dọ̀ gba ẹ̀rí tí ń sọ pé kò tọ́ sí òbí kan láti ṣàbójútó ọmọ kan nítorí pé òbí yẹn jẹ́ mẹ́ńbà ìsìn pàtó kan, ní pàtàkì, ìsìn kan tí àwọn tí ń ṣe é kò pọ̀? Adájọ́ kan ha gbọ́dọ̀ gba ẹ̀rí nípa àwọn ìgbàgbọ́ àti àṣà ìsìn àwọn òbí yẹ̀ wò kí ó lè pinnu lórí ìsìn tí òun rò pé yóò ṣàǹfààní jù fún ọmọ? Ó ha gbọ́dọ̀ wá pàṣẹ pé kí a tọ́ ọmọ náà dàgbà nínú ìsìn yẹn, kí ó sì fòfin de jíjẹ́ kí ọmọ náà mọ̀ nípa àwọn ìsìn míràn bí?
Lóde òní, àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i ń fẹ́ ẹni tí ìsìn rẹ̀ tàbí ìran rẹ̀ yàtọ̀ sí tiwọn. Nítorí náà, nígbà tí àwọn tọkọtaya wọ̀nyí bá kọ ara wọn sílẹ̀, ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ ti bá àwùjọ ìsìn méjì tan. Nígbà míràn, òbí kan tí ń ṣe ìkọ̀sílẹ̀ lè ṣẹ̀ṣẹ̀ yí dà sí ìsìn pàtó kan tí ó yàtọ̀ sí èyí tí òbí yẹn ti ń ṣe tẹ́lẹ̀. Dídarapọ̀ mọ́ ìsìn tuntun yẹn ti lè jẹ́ kókó tó mú kí ìgbésí ayé òbí yẹn fẹsẹ̀ múlẹ̀, tí ó sì ṣe pàtàkì gidigidi sí i, ṣùgbọ́n tí ó ṣàjèjì sí àwọn ọmọ. Nítorí náà, ìbéèrè míràn yọjú, Ilé ẹjọ́ ha lè kà á léèwọ̀ fún òbí náà láti má ṣe mú àwọn ọmọ lọ síbi ìsìn yí kìkì nítorí pé ó yàtọ̀ sí ìsìn tí àwọn òbí náà ti ń ṣe tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀?
Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí ṣòro. Wọ́n gba pé kí adájọ́ kan má wulẹ̀ ronú lórí àwọn ohun tí ọmọ náà nílò nìkan, ṣùgbọ́n lórí ohun tí yóò ṣe àwọn òbí láǹfààní, tí ó sì jẹ́ ẹ̀tọ́ wọn pẹ̀lú.
Àwọn Ẹ̀tọ́ Ṣíṣekókó ti Òbí àti Ọmọ
Òtítọ́ ni pé èrò ara ẹni tí àwọn adájọ́ ní nípa ìsìn lè nípa lórí wọn. Ṣùgbọ́n ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, kò jọ pé a óò ṣàìka àwọn ẹ̀tọ́ òbí tàbí ọmọ nípa ìsìn sí. Ó ṣeé ṣe kí àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ní àwọn àkọsílẹ̀ òfin tó kà á léèwọ̀ fún adájọ́ náà láti pààlà sí ẹ̀tọ́ ṣíṣekókó tí àwọn òbí ní láti bójú tó títọ́ ọmọ kan dàgbà, títí kan ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọmọ náà ní ti ẹ̀kọ́ ìwé àti ìsìn.
Bí ó ti yẹ, ọmọ kan lẹ́tọ̀ọ́ láti gba irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀. Kí adájọ́ kan tó lè dá sí ọ̀ràn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọmọ kan ní ti ìsìn lọ́nà bíbófinmu, ilé ẹjọ́ náà gbọ́dọ̀ gbọ́ ẹ̀rí dídánilójú pé “àwọn àṣà ìsìn pàtó kan jẹ́ ewu ojú ẹsẹ̀ àti ewu gígadabú fún ire ọmọ náà ní ti ara ìyára.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Àwọn àìfohùnṣọ̀kan nípa ìsìn lásán, tàbí ìkóguntini láàárín àwọn òbí nítorí ìsìn, kò tó láti dá dídá tí Ìjọba dá sọ́rọ̀ náà láre.
Ní Nebraska, U.S.A., ipò bíbọ́gbọ́nmu tí ìyá kan, tí ó jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, dì mú lórí awuyewuye ṣíṣe àbójútó ọmọ fi bí àwọn ohun tí òfin pèsè wọ̀nyí ṣe ń dáàbò bo àwọn òbí àti àwọn ọmọ hàn. Bàbá tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí náà kò fẹ́ kí ọmọbìnrin wọn máa lọ síbi ìsìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ilé ẹjọ́ kékeré kan fara mọ́ bàbá náà.
Ìyá náà wá pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Nebraska. Ìyá náà rojọ́ pé kò sí ẹ̀rí nípa ohun kankan tí ń wu ire ọmọ náà ní ti ara ìyára léwu lójú ẹsẹ̀ àti lọ́nà gígadabú nínú àwọn ìgbòkègbodò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìyá náà jẹ́rìí “pé wíwà níbi ìgbòkègbodò ìsìn àwọn òbí méjèèjì àti kíkópa nínú wọn yóò . . . fún ọmọ náà láǹfààní láti pinnu ìsìn wo ni yóò yàn láàyò nígbà tí ó bá dàgbà tó láti lóye.”
Ilé ẹjọ́ gíga náà yí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kékeré ọ̀hún pa dà, ó sì dájọ́ pé “ilé ẹjọ́ [kékeré] náà kò ṣe ìdájọ́ tó dára nípa pípààlà sí ẹ̀tọ́ ìyá tó fún un láṣẹ àbójútó ọmọ náà láti bójú tó títọ́ ọmọ rẹ̀ náà lọ́nà ti ìsìn.” Ó dájú hán-únhán-ún pé kò sí ẹ̀rí kankan pé lílọ tí ọmọ náà ń lọ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe é ní ìjàǹbá kankan.
Àwọn Ẹ̀tọ́ Òbí Tí A Kò Fún Ní Ẹ̀tọ́ Àbójútó
Nígbà míràn, àwọn òbí tí ó ti kọra wọn sílẹ̀ máa ń lo awuyewuye ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ìsìn bí ọ̀nà kan láti gba agbára ìdarí lórí àwọn ọmọ. Bí àpẹẹrẹ, nínú ẹjọ́ láàárín Khalsa òun Khalsa, tó wáyé ní ìpínlẹ̀ New Mexico, U.S.A., àwọn òbí méjèèjì ń ṣe ẹ̀sìn Sikh nígbà tí wọ́n jẹ́ tọkọtaya. Ṣùgbọ́n láìpẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n kọra wọn sílẹ̀, ìyá di ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í dí àwọn ọmọ lọ́wọ́ ṣíṣe ẹ̀sìn Sikh.
Ọ̀rọ̀ náà bí bàbá náà nínú, ó sì pẹjọ́ nínú ìgbìyànjú láti túbọ̀ ní àṣẹ láti darí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọmọ náà nípa ìsìn síhà ẹ̀sìn Sikh tí òun ń ṣe. Báwo ni ilé ẹjọ́ kékeré náà ṣe dáhùn pa dà sí ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ bàbá náà? Ó kọ ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ rẹ̀. Ilé ẹjọ́ kékeré náà pàṣẹ pé “nígbà tí àwọn ọmọ náà wà lọ́dọ̀ [rẹ̀], wọn kò lè kópa nínú ìgbòkègbodò ẹ̀sìn Sikh kankan nípa ìfínnúfíndọ̀ tàbí àìfínnúfíndọ̀, títí kan ìgbòkègbodò èyíkéyìí tí ó jẹ́ ti ṣọ́ọ̀ṣì, ìpàgọ́ ìsìn Sikh tàbí ilé àbójútó ọmọ wẹẹrẹ ti ìsìn Sikh èyíkéyìí.”
Bàbá náà pẹjọ́ sí Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ti New Mexico. Ilé ẹjọ́ gíga yìí fara mọ́ bàbá náà, ó sì yí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ kékeré náà pa dà. Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn náà wí pé: “Àwọn ilé ẹjọ́ gbọ́dọ̀ rọ̀ mọ́ ìlànà àìṣègbè láàárín àwọn ìsìn, kìkì níbi tí ẹ̀rí kedere tó sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ bá wà pé ewu wà lórí àwọn ọmọ náà sì ni wọ́n ti gbọ́dọ̀ dá sí ọ̀rọ̀ ẹlẹgẹ́ tí àkọsílẹ̀ òfin dáàbò bò yí. Ìkàléèwọ̀ nínú ọ̀ràn yí ń mú ewu pé àwọn ààlà tí ilé ẹjọ́ ń pa yóò tẹ òmìnira ìsìn tí òbí ní lójú láìbófinmu wá, tàbí pé a óò wò ó bíi pé ó ń ṣe bẹ́ẹ̀.”
Irú ìdájọ́ bẹ́ẹ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà tó ti fìdí múlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Òbí tí ń gba tẹni rò kan yóò ronú lórí àwọn ìlànà wọ̀nyí. Láfikún, òbí tó jẹ́ Kristẹni náà yóò baralẹ̀ ronú lórí pé ọmọ náà nílò láti ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn òbí méjèèjì, àti pé ọmọ náà ní iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti bọ̀wọ̀ fún ìyá àti bàbá lápapọ̀.—Éfésù 6:1-3.
Ìbánidásọ́rọ̀ Tí A Kò Ṣe Nílé Ẹjọ́
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdásí tí a kò ṣe nílé ẹjọ́ túbọ̀ jẹ́ ọ̀ràn ọlọ́rẹ̀ẹ́-sọ́rẹ̀ẹ́ ju ìgbẹ́jọ́ níwájú adájọ́ kan lọ, òbí kan kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú un. A lè fìdí àdéhùn àjùmọ̀ṣe tàbí ìpinnu èyíkéyìí tí a bá fẹnu kò sí nínú ìgbésẹ̀ ọ̀rọ̀ àbójútó yìí múlẹ̀ nípasẹ̀ àṣẹ ilé ẹjọ́ lẹ́yìn náà. Nítorí náà, yóò bọ́gbọ́n mu fún òbí kan láti bá ògbóǹtagí amòfin kan nípa ọ̀ràn ìdílé fikùn lukùn, láti rí i dájú pé a bójú tó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ àbójútó bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.
Òbí kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ fìṣọ́ra múra fún ìgbésẹ̀ ìbánidásọ́rọ̀ náà. Ìṣesí àti ìhùwàsí òbí kan nígbà ìgbésẹ̀ ìdásí náà lè nípa gidigidi lórí ohun tí àbájáde náà yóò jẹ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn òbí tí ń kọra wọn sílẹ̀ náà ń ti ìmọ̀lára bọ ìgbésẹ̀ ìkọ̀sílẹ̀ náà, débi tí wọ́n fi ń gbójú fo àwọn kókó pàtàkì dá: Kí ló ṣe ọmọ náà láǹfààní jù lọ? Kí ni ọmọ náà nílò kí ó lè dàgbà ní ti èrò orí, ní ti ìmọ̀lára, àti ní ti ara ìyára?
Rántí pé lójú òfin, kókó pàtàkì nínú ìbánidásọ́rọ̀ kì í ṣe ọ̀ràn ìyàtọ̀ ìsìn tàbí ti àwọn ọ̀ràn ara ẹni mìíràn, ṣùgbọ́n ó kan bí àwọn òbí ṣe lè fohùn ṣọ̀kan, kí wọ́n sì ṣe àdéhùn kan fún ire àwọn ọmọ náà. Ó ṣeé ṣe kí òbí kan kojú àwọn ẹ̀tanú ìsìn, tàbí àwọn mìíràn, àwọn ìbéèrè tí a kò retí, tàbí àwọn ìlọ́nífun tí a wéwèé láti dani láàmú àti láti dani lọ́kàn rú. A lè tú àìdójúùlà òbí kọ̀ọ̀kan fó tàbí kí a tilẹ̀ fẹ̀ ẹ́ lójú. Bí ó ti wù kí ó rí, bí àwọn tí ọ̀ràn kàn náà bá hùwà ìgbatẹnirò, wọ́n lè dé orí ìpinnu kan.
Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó ń jọ pé ìgbésẹ̀ ìbánidásọ́rọ̀ náà ń falẹ̀, ó sì ń tánni ní sùúrù. Ọ̀nà àbájáde kan tó kù ni ìpẹ̀jọ́ tí ń fẹ ọ̀rọ̀ lójú tó tún ní sísọ ọ̀ràn di ti gbogbo ayé lọ́nà tí ń mójú tini, ìnáwó gọbọi, àti ìyọrísí tí ń pa ọmọ náà lára, nínú. Ó dájú pé a kò fẹ́ ìyẹn rárá. Bí ó ti máa ń rí nínú gbogbo ọ̀ràn pàtàkì nínú ìgbésí ayé, òbí kan tó jẹ́ Kristẹni yóò fẹ́ láti kún fún àdúrà ní kíkojú ìgbésẹ̀ ìbánidásọ́rọ̀ náà, ní rírántí ìkésíni onímìísí náà láti “fi ọ̀nà rẹ lé Olúwa lọ́wọ́; gbẹ́kẹ̀ lé e pẹ̀lú; òun yóò sì mú un ṣẹ.”—Orin Dáfídì 37:5.
Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá lè rí ojútùú kankan, tí adájọ́ sì fún òbí kejì ní ẹ̀tọ́ àbójútó ọmọ ńkọ́? Tàbí bí ọ̀kan lára àwọn òbí tí ń kọra wọn sílẹ̀ náà bá jẹ́ ẹni tí a ti yọ lẹ́gbẹ́ nínú ìjọ Kristẹni ńkọ́? Bákan náà, ojú wo ló yẹ kí ẹnì kan fi wo àbójútó àjùmọ̀ṣe àti àbójútó àdáṣe? A óò jíròrò àwọn ìbéèrè wọ̀nyí àti àwọn ìlànà inú Bíbélì tí ó tan mọ́ wọn nínú àpilẹ̀kọ tí ó kàn.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn Ànímọ́ Pàtàkì Mẹ́ta
Adájọ́ ọ̀ràn ìdílé kan tí Jí! fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò sọ pé, lára àwọn ànímọ́ pàtàkì tí òun máa ń wò lára òbí kan ni àwọn mẹ́ta wọ̀nyí:
Ìgbatẹnirò—ìmúratán láti yọ̀ǹda fún òbí kejì láti dé ọ̀dọ̀ ọmọ náà bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó (bí kò bá ti ní wu ọmọ náà léwu ní ti ara tàbí ní ti ìwà)
Ìfòyemọ̀—wíwà lójúfò sí àwọn àìní ọmọ náà ní ti ìmọ̀lára
Ìkóra-ẹni-níjàánu—ìgbésí ayé inú ilé tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, tí yóò mú àyíká onífọkànbalẹ̀ wá, nínú èyí tí ọmọ náà ti lè ní láárí
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn Ìlànà Ìdájọ́
Nípa gbígbé àwọn ìlànà kalẹ̀, àwọn adájọ́ kan ti gbìyànjú láti ṣèdíwọ́ fún awuyewuye tí kò pọn dandan lórí ojú ìwòye òbí kan nípa ìsìn. Bí àpẹẹrẹ:
1. A gbọ́dọ̀ fún àjọṣe tó nítumọ̀ níṣìírí láàárín ọmọ kan àti àwọn òbí méjèèjì. Adájọ́ John Sopinka ti Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Ilẹ̀ Kánádà sọ pé a gbọ́dọ̀ yọ̀ǹda fún òbí kọ̀ọ̀kan “láti kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò tó ń mú kí a dá òbí náà mọ̀ fún ohun tí ó jẹ́ ní gidi [títí kan ṣíṣe ìsìn rẹ̀]. A kò retí pé kí òbí tí ń ṣèbẹ̀wò náà máa díbọ́n ohun tí kò jẹ́ tàbí kí ó máa hùwà ẹ̀tàn nígbà tí ó bá ń ṣèbẹ̀wò.”
2. Kíkàáléèwọ̀ fún òbí tí ń ṣèbẹ̀wò náà pé kí ó má fi ìgbàgbọ́ ìsìn rẹ̀ kọ́ ọmọ náà jẹ́ títẹ òmìnira ìsìn òbí náà lójú, àyàfi bí ó bá ṣe kedere, tí ẹ̀rí tó dájú sì wà pé ewu gidi ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí ọmọ náà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn adájọ́ ń kojú ẹrù iṣẹ́ wíwúwo nínú àwọn ẹjọ́ àbójútó ọmọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ẹnì kan tí ń báni dá sí ọ̀rọ̀ lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti yanjú èdèkòyédè wọn láìsí ìpẹ̀jọ́ tí ń gba àkókò