Bí O Ṣe Lè Kojú Sànmánì Onísọfúnni
A GBỌ́DỌ̀ gbà pé ọ̀pọ̀ ẹ̀ka sànmánì onísọfúnni ti àwọn ọdún 1990 yóò máa mú ká hára gàgà nìṣó. A kò ní agbára tó bẹ́ẹ̀ láti darí àwọn kan nínú wọn. Níhà kejì, àwọn ìgbésẹ̀ kan wà tí a lè gbé láti mú púpọ̀ nínú irú ìháragàgà bẹ́ẹ̀ kúrò, bí kò bá tilẹ̀ jẹ́ gbogbo wọn. A wá lè sọ pé, wíwànìṣó nínú sànmánì onísọfúnni náà jẹ́ ìpèníjà kan, síbẹ̀ ó jẹ́ iṣẹ́ tí ń mérè wá.
Àwọn Olùgbàsọfúnni àti Àwọn Olùfúnni-Nísọfúnni
Yálà a ti pín ara wa sí ìsọ̀rí yìí tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, jálẹ̀ ìgbésí ayé wa, gbogbo wa jẹ́ olùgbàsọfúnni àti olùfúnni-nísọfúnni dé àyè kan. Bí ó ti wù kí ó rí, ọpọlọ wa ń gba ìsọfúnni, ó sì ń tú u palẹ̀ ní ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ọ̀nà kan jẹ́ ti àgbàyanu agbára tí ọpọlọ ní láti ṣàtúpalẹ̀ ìsọfúnni láìsí ìsapá àmọ̀ọ́mọ̀ṣe títí lọ.
Ọ̀nà mìíràn ni ìtúpalẹ̀ ìsọfúnni tó gba ìsapá àmọ̀ọ́mọ̀ṣe bíi ti ìgbà tí a bá ń jíròrò. A lágbára láti darí irú ìtúpalẹ̀ ìsọfúnni yìí gidigidi—gẹ́gẹ́ bí olùfúnni àti olùgbà. Nígbà tí ó bá kan ìjíròrò tí kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí, Bíbélì kìlọ̀ fún wa nípa àwọn tí “kì í ṣe aláìníṣẹ́ nìkan, ṣùgbọ́n olófòófó pẹ̀lú àti alátojúbọ àlámọ̀rí àwọn ẹlòmíràn, [tí] wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí kò yẹ kí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.” (Tímótì Kíní 5:13) Lọ́nà míràn, ṣọ́ra kí o má maa fi àkókò púpọ̀ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí tàbí ìsọfúnni líléwu. Máà jẹ́ irú ẹni tí mímọ ọ̀rọ̀ àhesọ tó dé kẹ́yìn jẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ nínú ìgbésí ayé. Èyí lè fi àkókò àti okun tó ṣeyebíye ṣòfò, ó sì lè mú kí àwa àti àwọn ẹlòmíràn máa hára gàgà. O lè pàdánù àǹfààní gbígba ìsọfúnni tó lè gbéni ró, tó sì ṣe pàtàkì ní tòótọ́, láti la ayé oníhílàhílo yí já, àti àǹfààní láti pín in kiri.
A máa ń ṣàtúpalẹ̀ ìsọfúnni tí a bá gbà nípa kíkàwé lọ́nà tó gba ìsapá àmọ̀ọ́mọ̀ṣe, nítorí náà, ó ń gba àkókò tó pọ̀ jù. “N kò lè dójú ìlà ohun tí mo ní láti kà!” jẹ́ ìdárò oníhàáragàgà tí a mọ̀ dunjú. Ǹjẹ́ o lérò pé o ní ohun púpọ̀ láti kà láìní àkókò púpọ̀ tó? Nítorí pé ìwé kíkà ń gba àkókò, a sábà máa ń pàdánù ọnà inú rẹ̀ àti ìgbádùn inú rẹ̀ nínú sànmánì onísọfúnni ojú ẹsẹ̀ yí. Àwọn ènìyàn tí ń jẹ́ kí tẹlifíṣọ̀n jẹ wọ́n lákòókò ti pọ̀ jù. Síbẹ̀, ìsọfúnni alákọsílẹ̀ ló jẹ́ ọ̀nà tó ṣì lágbára jù lọ láti mú agbára ìwòye ṣiṣẹ́, àti láti tàtaré àwọn ìsọfúnni, èrò, àti àbá.
Báwo ni a ṣe lè kojú rẹ̀ nígbà tí ọ̀pọ̀ ìwé tí a ní láti kà ń béèrè àfiyèsí wa, tí tẹlifíṣọ̀n, àwọn eré ìdárayá orí kọ̀ǹpútà, àti àwọn ohun ìnàjú mìíràn sì ń bá a díje? Fífarabalẹ̀ ṣe àṣàyàn ni ojútùú náà. Fífarabalẹ̀ ṣe àṣàyàn, ṣíṣe ìyàsọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ohun tí a gbọ́dọ̀ gbọ́, kí a rí, kí a sọ, tàbí kí a kà, àti títò wọ́n sí ipò bí wọ́n ṣe ṣe pàtàkì tó, lè mú ọ̀pọ̀ ìháragàgà fùn ìsọfúnni kúrò. A lè fara balẹ̀ ṣe àṣàyàn lọ́nà tó gbéṣẹ́ ní ìpele méjì.
Ǹjẹ́ A Nílò Àwọn Ọ̀ràn Tí Kò Ṣe Pàtàkì Tó Bẹ́ẹ̀?
Ohun tí àwọn ẹlòmíràn rò pé a nílò tàbí ohun tí agbára ìpolówó-ọjà ilé iṣẹ́ ìròyìn mú kí a gbà pé a nílò sábà máa ń kó ìdàrúdàpọ̀ bá èrò orí wa nípa àwọn àìní wa. Láti borí ìgbékalẹ̀ dídíjú ti ìsọfúnni yìí, tẹ̀ lé ìlànà náà pé: Mú un rọrùn! Richard S. Wurman sọ ọ́ báyìí: “Àṣírí tó rọ̀ mọ́ ṣíṣàtúpalẹ̀ ìsọfúnni ni pípààlà ìwọ̀n ìsọfúnni sí kìkì èyí tó tan mọ́ ìgbésí ayé rẹ . . . Mo gbà pé èrò tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ni pé bí ohun tí o lè yàn bá ṣe pọ̀ tó ni ìgbésẹ̀ yíyẹ tí o lè gbé pọ̀ tó, tí o sì lè lómìnira tó. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jọ pé àníyàn púpọ̀ sí i ni yíyàn púpọ̀ sí i ń fà.”
Nítorí náà, bí ó bá di ọ̀ràn ìwé kíkà àti wíwo tẹlifíṣọ̀n, ó dára kí o ṣe àyẹ̀wò àṣà rẹ. Bi ara rẹ léèrè pé: ‘Ó ha pọn dandan fún iṣẹ́ mi tàbí ìgbésí ayé mi? Ǹjẹ́ ní tòótọ́ ni mo gbọ́dọ̀ mọ gbogbo ọ̀ràn tí kò ṣe pàtàkì àti àhesọ nípa àwọn olókìkí ènìyàn tí wọ́n fẹnu jẹ́wọ́ pé wọ́n rẹwà lágbàáyé? Ìyípadà wo ni yóò wà nínú ìgbésí ayé mi bí n kò bá wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹlifíṣọ̀n yí, tí n kò ka ìwé yìí tàbí ìwé ìròyìn yẹn, tàbí tí n kò bá lo àkókò tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ láti ka ìwé agbéròyìnjáde?’ Àwọn kan ti lè ṣàtúpalẹ̀ àwọn ohun tí wọ́n ń kà àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹlifíṣọ̀n tí wọ́n ń wò, wọ́n sì ti da àwọn ohun tí ń há èrò inú wọn àti ilé wọn gádígádí nù. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ti pinnu láti sanwó sílẹ̀ fún ìwé agbéròyìnjáde ojoojúmọ́ kan ṣoṣo. Ó ṣe tán, ọ̀pọ̀ ìwé agbéròyìnjáde ló ń gbé ìròyìn kan náà. Àwọn ènìyàn kan ti béèrè ní pàtó pé kí a má maa kó ẹrù ìwé tí wọn kò fúnra wọn béèrè fún sínú àpótí ẹrù àfiránṣẹ́ wọn.
Ọkùnrin títóbilọ́lá jù lọ tí ó tí ì gbé ayé rí, Jésù Kristi ṣalágbàwí gbígbé ìgbésí ayé rírọrùn tí kò há gádígádí. (Mátíù 6:25-34) Ọ̀pọ̀ àṣà ilẹ̀ Éṣíà ló dábàá ìgbésí ayé rírọrùn, tó sì gbóríyìn fún un, ọ̀pọ̀ ènìyàn nínú àwọn àṣà ìbílẹ̀ ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ló sì gbà pé ó dára jù. Òǹkọ̀wé Duane Elgin sọ pé: “Láti túbọ̀ gbé ìgbésí ayé rírọrùn jẹ́ láti túbọ̀ gbé ìgbésí ayé tó ní ète nínú sí i, tí ìpínyà ọkàn láìnídìí sì kéré jọjọ.”
Ní báyìí, tí o ti to àwọn ìsọfúnni tí o ń gbà sí bí wọ́n ti ṣe pàtàkì tó fún àwọn àìní rẹ, ṣe ohun kan náà nípa àwọn ìfẹ́ ọkàn rẹ, nítorí pé ìfẹ́ ọkàn ní ń sún ẹ̀kọ́ kíkọ́ ṣiṣẹ́. Bí ó ti wù kí ó rí, ìṣòro tó wà níbí ni fífìyàtọ̀ sáàárín ohun tó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ gidi àti ohun tí o lè rò pé ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ kí o lè tẹ́ àwọn ẹlòmíràn lọ́rùn—bóyá àwọn tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́. Àmọ́ bí o bá lè wéwèé ìwé kíkà àti tẹlifíṣọ̀n wíwò tàbí kọ̀ǹpútà lílò lọ́nà kan náà tí o lè gbà wéwèé ìgbòkègbodò èyíkéyìí mìíràn, o máa rí i pé gbígbé e karí ojúlówó ìfẹ́ ọkàn lè fàyè gba gbígbé ìgbésí ayé alárinrin, láìsí ìdàníyàn tí kò pọn dandan.
Nítorí náà, báwo lo ṣe lè kojú ìháragàgà fún ìsọfúnni? Ó ṣeé ṣe kí o má lè mú un kúrò pátápátá, ṣùgbọ́n títẹ̀lé àwọn ìlànà rírọrùn díẹ̀ tí a ti mẹ́nu bà lè ṣèrànwọ́ gan-an. Jẹ́ kí ìsọfúnni tí o ń gbà mọ níwọ̀n, sì tò wọ́n ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí o nílò àti ìfẹ́ ọkàn rẹ. Àkókò ń bọ̀ tí gbogbo ohun tó díjú nínú ìgbésí ayé, títí kan ìháragàgà fún ìsọfúnni yóò di nǹkan àtijọ́, àmọ́ ní báyìí ná, fi àwọn ohun ìyanu ìmọ̀ ẹ̀rọ òde òní sí àyè tó yẹ wọ́n. Máa lò wọ́n bí ohun kan tó ń múni ṣàṣeyọrí ohun mìíràn. Má di ẹrú wọn, má sì jẹ́ kí jìnnìjìnnì wọn bò ọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ìsọfúnni tó wúlò yóò jẹ́ agbéniró, afúnni-níṣìírí, àti aláǹfààní, láìmú kí o máa hára gàgà.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]
Gbìyànjú Ṣíṣe Pàṣípààrọ̀
“Fagi lé ìlò ìsọfúnni orí tẹlifíṣọ̀n rẹ, . . . kí o sì ná iye [owó] kan náà lóṣù sórí ìwé dáradára kan tàbí méjì. Ìwé jẹ́ òdì kejì tẹlifíṣọ̀n: Wọ́n lọ́ra, wọ́n ń mú ọwọ́ ẹni dí, wọ́n ń fúnni ni ìmísí, wọ́n ń ta èrò orí jí, wọ́n sì ń sún agbára ìhùmọ̀ ẹni ṣiṣẹ́.”
“O tún lè ronú nípa dídín àkókò tí o ń lò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ lórí ìsokọ́ra alátagbà Internet kù sí wákàtí mélòó kan, tàbí ó kéré tán, kí o lo àkókò ìjíròrò orí ẹ̀rọ náà lọ́gbọọgba pẹ̀lú àkókò tí o fi ń kàwé.”—Data Smog—Surviving the Information Glut.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]
Jẹ́ Ọ̀gá, Kì Í Ṣe Ẹrú
“Pa tẹlifíṣọ̀n. Kò sọ́nà tó yá jù láti pa dà jèrè ìdarí lórí ìṣiṣẹ́ ìgbésí ayé rẹ, àlàáfíà ilé rẹ, àti àwọn ohun tí o ń ronú lé lórí ju kí o pa ohun èlò tí ó jẹ́ àyíká ìwàláàyè fún ọ̀pọ̀ jù lọ wa lọ. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ará Amẹ́ríkà ti ń ṣàwárí ìparọ́rọ́ ọkàn àyà àti ìlò agbára tó wà nínú títẹ bọ́tìnnì ìdarí ohun èlò sí PA, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ ti ọ̀pọ̀ wákàtí tí wọn kò fi ṣe nǹkan kan, tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń jèrè, tí wọ́n lè máa fi ṣe àwọn nǹkan mélòó kan tí wọn kò ti ní àkókò fún tẹ́lẹ̀.”—Data Smog—Surviving the Information Glut.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]
Ṣọ́ra fún Ìsọkọ́ra Alátagbà Internet
Àwọn ènìyàn oníwà-pálapàla ń lo Ìsọkọ́ra Alátagbà Internet fún ìlépa ìbálòpọ̀ lọ́nà òdì wọn àti láti gbìyànjú láti kàn sí àwọn alájọṣe tó múra tán tàbí àwọn òjìyà aláìmọwọ́mẹsẹ̀. Àwọn mìíràn ń lo Ìsọkọ́ra Alátagbà Internet láti gbé àwọn ète ara wọn lárugẹ. Àwọn apẹ̀yìndà pẹ̀lú ṣàgbékalẹ̀ ìsokọ́ra Web láti máa mú àwọn aláìfura.
Ó gba ìṣọ́ra gidigidi nígbà tí a bá ń lo Ìsọkọ́ra Alátagbà Internet, ó sì dájú pé ó yẹ kí àwọn òbí fara balẹ̀ ṣàbójútó èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ wọn tó bá ń lò ó. Òtítọ́ ni pé ọ̀pọ̀ orísun ìsọfúnni tó wúlò ló wà níbẹ̀, bí ibi ìkówèésí fún ìṣèwádìí, ibi àkójọ ìwé, àti àwọn ìkànnì ìròyìn. Bí àpẹẹrẹ, láìpẹ́ yìí ni Watchtower Society kéde ìsokọ́ra Web tirẹ̀ (http://www.watchtower.org), tí ó wúlò ní pípèsè ìsọfúnni tòótọ́ nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Síbẹ̀, ó yẹ kí a mọ̀ pé ọ̀pọ̀ agbára ìdarí eléwu ló wà níbẹ̀, títí kan àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè àti ìpẹ̀yìndà.
Kristẹni kan gbọ́dọ̀ fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sọ́kàn pé: “Nítorí náà, èyí ni mo ń wí tí mo sì ń jẹ́rìí sí nínú Olúwa, pé kí ẹ má ṣe máa bá a lọ mọ́ ní rírìn gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ti ń rìn nínú àìlérè èrò inú wọn . . . Níwọ̀n bí wọ́n ti wá ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere, wọ́n fi ara wọn fún ìwà àìníjàánu láti máa fi ìwà ìwọra hu onírúurú ìwà àìmọ́ gbogbo. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò kẹ́kọ̀ọ́ Kristi bẹ́ẹ̀.” (Éfésù 4:17-20) Bákan náà, “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tàbí ìwà ìwọra láàárín yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́; bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà tí ń tini lójú tàbí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn akóninírìíra, àwọn ohun tí kò yẹ, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀ ìdúpẹ́.” (Éfésù 5:3, 4) Ó yẹ kí a mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ìsokọ́ra Web ló jẹ́ àwọn ènìyàn tó ní èrò ìwà pálapàla àti èrò àbòsí ló gbé wọn kalẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìsokọ́ra tí ó sì lè ṣàìjẹ́ ti oníwà-pálapàla tàbí ti alábòsí, bí àwọn àwùjọ̀ chat, ló wulẹ̀ jẹ́ ìfàkókòṣòfò lásán. Yẹra fún gbogbo irú wọnnì!