Àpọ̀jù Ìsọfúnni
ÌSỌFÚNNI ti pọ̀ lápọ̀jù lọ́nà tí irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí ní ọ̀rúndún ogún yìí. Ìsọfúnni kún inú ayé dẹ́múdẹ́mú, yálà lórí rédíò tàbí tẹlifíṣọ̀n, lórí ìsokọ́ra alátagbà Internet, tàbí ní àwọn ọ̀nà míràn. Nínú ìwé rẹ̀, Data Smog—Surviving the Information Glut, David Shenk sọ pé: “Ó ti hàn pé àpọ̀jù ìsọfúnni jẹ́ ewu gidi. . . . Ní báyìí, a dojú kọ níní ìsọfúnni lánìíjù.”
Mú àpẹẹrẹ ìwé agbéròyìnjáde kan tí a mọ̀ dunjú. A gbọ́ pé ìsọfúnni tí ẹ̀dà kan ìwé agbéròyìnjáde The New York Times tí ó sábà máa ń jáde lọ́jọ́ kan lọ́sẹ̀ ń ní nínú pọ̀ ju gbogbo ìsọfúnni tí ẹnì kan tí a lè mú ṣàpẹẹrẹ ní ilẹ̀ England ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún ti lè ní jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ lọ. Àmọ́ ní àfikún sí àwọn ìwé agbéròyìnjáde ojoojúmọ́, àwọn ìwé ìròyìn àti àwọn ìwé lóríṣiríṣi lórí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ kókó ẹ̀kọ́ ń fi kún ìtúyáyá ìsọfúnni tí a ń mú jáde. Ẹgbẹẹgbàárùn-ún ìwé la ń tẹ̀ jáde lọ́dọọdún. Níwọ̀n bí ìsọfúnni lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sì ti ń di ìlọ́po méjì lọ́dún mẹ́fà-mẹ́fà, kò yani lẹ́nu pé àwọn ìwé àtìgbàdégbà lórí ìmọ̀ iṣẹ́ nìkan lé ní 100,000 lágbàáyé. Ìsokọ́ra alátagbà Internet sì ń mú kí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àkójọ ìsọfúnni wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn tí ń lo kọ̀ǹpútà.
Àwọn ìwé ìròyìn ńkọ́? Àwọn ìwé àtìgbàdégbà lórí ìṣòwò, àwọn ìwé ìròyìn àwọn obìnrin, àwọn ìwé ìròyìn àwọn ọ̀dọ́langba, àwọn ìwé ìròyìn eré ìdárayá òun eré ìnàjú—ní gidi, àwọn ìwé ìròyìn tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ lórí gbogbo kókó ẹ̀kọ́ àti ìfẹ́ ọkàn ẹ̀dá ènìyàn—ti kún inú ayé, tí gbogbo wọn sì ń béèrè àfiyèsí wa. Ipa tí olùpolówó-ọjà—tí a ṣàpèjúwe dáradára gẹ́gẹ́ bí “agbẹnusọ ohun asán”—ń kó ńkọ́? Òǹkọ̀wé Richard S. Wurman sọ nínú ìwé rẹ̀, Information Anxiety, pé: “Àwọn ilé iṣẹ́ ìpolówó-ọjà ń kó ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìpolówó tí ń fẹ́ ká wò wọ́n, ká gbọ́ wọn, ká fimú rùn wọ́n, ká sì fọwọ́ kàn wọ́n, bo àwọn ẹ̀yà ara ìmọ̀lára wa.” Wọ́n ń tẹpẹlẹ mọ́ ọn pé a nílò àwọn ọjà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gorí àtẹ, àwọn ọjà tí a mú bágbà mu, kí a lè “ní ohun ìní bíi ti Dàróṣà.”
Ará Australia tó jẹ́ afìṣemọ̀rònú òun olùṣèwádìí àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn náà, Ọ̀mọ̀wé Hugh MacKay, sọ pé, ‘ìsọfúnni ń bo ayé mọ́lẹ̀ jù, a sì ń ké sí àwọn ènìyàn láti bọ́ sí ọ̀nà tí ó yá jù lójú ọ̀nà márosẹ̀ ìfìsọfúnni-ránṣẹ́.’ Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀mọ̀wé MacKay ṣe rí i, ìṣòro náà ni pé ìtújáde ètò ìròyìn àti ọ̀rọ̀ tó ń lọ lórí rédíò àti tẹlifíṣọ̀n, pa pọ̀ mọ́ ìtújáde gbígbàfiyèsí ti lọ́ọ́lọ́ọ́ nípa ìsokọ́ra ìsọfúnni nípasẹ̀ kọ̀ǹpútà, ti yọrí sí ayé kan, níbi tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti ń hùwà pa dà sí ìsọfúnni tí ó jẹ́ pé ní gidi, ó sábà máa ń jẹ́ apá kan ìròyìn òkodoro òtítọ́ àti ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tí kì í ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn náà.
Kí Ni Ìsọfúnni?
Ìpìlẹ̀ ọ̀rọ̀ èdè Látìn náà, informare, ní èrò ṣíṣẹ̀dá nǹkan, lọ́nà kan náà tí amọ̀kòkò gbà ń fi amọ̀ ṣẹ̀dá nǹkan. Nítorí náà, àwọn ìtumọ̀ kan fún “sọ fúnni” jẹ́ “yí ìrònú pa dà,” tàbí “darí ìrònú tàbí kọ́ ìrònú lẹ́kọ̀ọ́.” Ọ̀pọ̀ jù lọ òǹkàwé lè rántí àkókò kan tí kò ì pẹ́ jù, tí ìsọfúnni wulẹ̀ jẹ́ àkọsílẹ̀ àwọn kókó ọ̀rọ̀ tàbí àwọn ìṣètò oníṣirò tí ń sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ fúnni nípa ta ni, níbo, kí ni, nígbà wo, tàbí báwo. Ìsọfúnni kò ní àwọn àkànlò èdè tàbí àkójọ ọ̀rọ̀ nígbà náà. Gbogbo ohun tí a ní láti ṣe nígbà náà ni kí a béèrè tàbí kí a wá a kàn fúnra wa.
Àmọ́ àwọn ọdún 1990 ti dé, aráyé sì ti tún ní àwọn ọ̀rọ̀ tuntun tó bá ìsọfúnni tan tó pọ̀ débi pé ìwọ̀nyí nìkan lè fa ìdàrúdàpọ̀. Nígbà tí àwọn kan nínú àwọn ọ̀rọ̀ àti èdè ọ̀rọ̀ wọ̀nyí bí “àṣejù ìháragàgà fún ìsọfúnni,” “ìyánnújù fún ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ,” àti “sànmánì onísọfúnni,” rọrùn, tí wọ́n sì ṣeé lóye níwọ̀nba tiwọn, àwọn mìíràn lè fa ìṣòro gidi. Lóde òní, ayé ti bọ́ sábẹ́ agbára àṣejù ìháragàgà fún ìsọfúnni—ìgbàgbọ́ pé ẹni tó bá ní ìsọfúnni púpọ̀ jù níkàáwọ́ ń jàǹfààní ju àwọn tí kò ní tó bẹ́ẹ̀ àti pé, ìsọfúnni kì í tún ṣe ọ̀nà sí àṣeyọrí kan mọ́, ṣùgbọ́n ó jẹ́ àṣeyọrí kan fúnra rẹ̀.
Ọ̀wààrà ìhùmọ̀ ìbánisọ̀rọ̀ tí ń dà jáde, bí ẹ̀rọ aṣàdàkọ ìsọfúnni, tẹlifóònù alágbèéká, àti kọ̀ǹpútà aládàáni, tí àwọn kan kà sí àmì àti ohun ìṣàpẹẹrẹ oríire ti sànmánì onísọfúnni, ní ń fún àṣejù ìháragàgà yí lókun. Òtítọ́ ni pé ìrọ̀rùn, ìyárakánkán, àti agbára kọ̀ǹpútà ti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún rírí ìsọfúnni gbà ju ti ìgbàkigbà rí lọ—tó bẹ́ẹ̀ tí Nicholas Negroponte, láti Ilé Ẹ̀kọ́ṣẹ́ Ìmọ̀ Ẹ̀rọ Massachusetts, fi sọ pé: “Lílo kọ̀ǹpútà kì í ṣe ọ̀ràn nípa kọ̀ǹpútà mọ́. Ọ̀ràn nípa gbígbé ìgbésí ayé ni.” Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, a ti buyì fún ìsọfúnni àti àwọn ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tí ń pèsè rẹ̀ ju bó ti yẹ lọ, kódà, a ń fi ọ̀wọ̀ onífọkànsìn fún un nínú àwọn ọ̀ràn kan, tí ó sì ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ olùfarajìn lápá ibi gbogbo lágbàáyé. Àwọn ìròyìn lórí tẹlifíṣọ̀n àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀rọ̀ tó ń lọ ni a ń tò sí ipò tó fẹ́rẹ̀ẹ́ bá òtítọ́ tí kò ṣeé sẹ́ dọ́gba, nígbà tí omilẹngbẹ ọ̀rọ̀ tí kò ní láárí ń tú jáde nínú àwọn ètò ìjíròrò àti ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò fún àwọn àlejò pàtàkì lórí tẹlifíṣọ̀n, tí àwọn aláìfura àti sùẹ̀gbẹ̀ ènìyàn sì ń gbà á bẹ́ẹ̀ láìjanpata.
Ọ̀pọ̀ ènìyàn lónìí ní ń jìyà lọ́wọ́ “ìháragàgà fún ìsọfúnni” ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn nítorí pé sànmánì onísọfúnni ti yí ọ̀nà ìgbésí ayé àti ìṣiṣẹ́ wa pa dà. Kí tilẹ̀ ni ìháragàgà fún ìsọfúnni gan-an? Báwo lo ṣe lè mọ̀ bí ó bá ń nípa lórí rẹ? Ǹjẹ́ ohun kankan wà tí o lè ṣe nípa rẹ̀?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Àwòrán ilẹ̀ ayé ní ojú ìwé 3, 5, àti 10: Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.