Ǹjẹ́ O Máa Ń Wo Ojú Pátákó Ìsọfúnni?
Àwọn alàgbà, àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àtàwọn míì tó ń bójú tó àwọn iṣẹ́ kan nínú ìjọ sábà máa ń wo ojú pátákó ìsọfúnni kí wọ́n lè mọ ìgbà tí wọ́n níṣẹ́. Ṣùgbọ́n, àwọn ìsọfúnni pàtàkì tó kan gbogbo wa nínú ìjọ tún máa ń wà níbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ o mọ ìgbà tí ìmọ́tótó Gbọ̀ngàn Ìjọba máa kan ìjọ tàbí àwùjọ rẹ? Ǹjẹ́ o mọ̀ bóyá alábòójútó àyíká tàbí ẹ̀ka ọ́fíìsì ti fi ìsọfúnni pàtàkì ránṣẹ́ sí ìjọ yín? Ǹjẹ́ o mọ àkòrí àsọyé ti ọ̀sẹ̀ yìí, kó o lè fi pe àwọn tí ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti wá gbọ́ àsọyé náà? Ṣé o mọ̀ bóyá wọ́n ti ṣe àwọn ìyípadà kan sí ìpàdé ìjọ tàbí àwùjọ tí wọ́n pín ẹ sí? A kì í ṣe ìfilọ̀ èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìsọfúnni yìí mọ́. Ó sì lè má ṣeé ṣe fún àwọn alàgbà láti sọ ọ́ fún gbogbo akéde lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Torí náà, ẹ jẹ́ ká fi kọ́ra láti máa lọ ka àwọn ìsọfúnni yìí lójú pátákó ìsọfúnni. Tá a bá ń ka àwọn ìsọfúnni tó wà níbẹ̀ déédéé, ohun gbogbo á lè máa ṣẹlẹ̀ “lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.”—1 Kọ́r. 14:40.