Pípa Ìsọ̀kan Mọ́ Láàárín Àwọn Alàgbà àti Ìránṣẹ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́
NÍ KÉTÉ lẹ́yìn Pentekosti 33 C.E., ipò pàjáwìrì dìde nínú ìjọ Kristian kan tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ dásílẹ̀. A ti fìdí ìṣètò kan múlẹ̀ láti bójútó àwọn opó tí wọ́n ṣaláìní. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn àkókò díẹ̀ “ìkùnsínú wà nínú àwọn Hellene sí àwọn Heberu, nítorí tí a ń ṣe ìgbàgbé àwọn opó wọn ní ìpínfúnni ojoojúmọ́.”—Iṣe 6:1.
Ìráhùn yìí dé etígbọ̀ọ́ àwọn aposteli. “Àwọn méjìlá sì pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn jọ sọ́dọ̀, wọ́n wí pé, Kò yẹ tí àwa ìbá fi ọ̀rọ̀ Ọlọrun sílẹ̀, kí a sì máa ṣe ìránṣẹ́ tábìlì. Nítorí náà, ará, ẹ wo ọkùnrin méje nínú yín, olórúkọ rere, ẹni tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ọgbọ́n, ẹni tí àwa ìbá yàn sí iṣẹ́ yìí.”—Iṣe 6:2, 3.
Èyí ṣàkàwé ìlànà ìṣètòjọ pàtàkì kan láàárín ìjọ Kristian. Àwọn ọkùnrin díẹ̀ tí wọ́n ṣeé fi ẹrù-iṣẹ́ lé lọ́wọ́ ni a lò láti bójútó àwọn ọ̀ràn ojoojúmọ́, nígbà tí àwọn yòókù bójútó àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí tí ó túbọ̀ wúwo. Èyí kò ṣàìní àpẹẹrẹ ìṣáájú. Ní Israeli ìgbàanì, Aaroni àti àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ ni a yànsípò láti ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà láti máa rú ẹbọ sí Ọlọrun. Bí ó ti wù kí ó rí, Jehofa pèsè ìdarísọ́nà pé kí àwọn ọmọ Lefi ràn wọ́n lọ́wọ́ nípa ‘pípa gbogbo ohun-èèlò àgọ́ àjọ mọ́.’ (Numeri 3:5-10) Bákan náà, lónìí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ ń ran àwọn alábòójútó lọ́wọ́.
Ipa-Iṣẹ́ Àwọn Alàgbà àti Ìránṣẹ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́
Ìwé Mímọ́ ṣe ìlàlẹ́sẹẹsẹ àwọn ẹ̀rí ìtóótun gíga fún àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́. (1 Timoteu 3:1-10, 12, 13; Titu 1:6-9) Wọn kìí ṣe abáradíje ṣùgbọ́n wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún góńgó kan náà—gbígbé ìjọ ró. (Fiwé Efesu 4:11-13.) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ìyàtọ̀ díẹ̀ wà nínú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe nínú ìjọ. Nínú 1 Peteru 5:2, a sọ fún àwọn alábòójútó pé: “Ẹ máa tọ́jú agbo Ọlọrun tí ń bẹ láàárín yín, . . . kìí ṣe àfipáṣe, bíkòṣe tìfẹ́tìfẹ́; bẹ́ẹ̀ ni kìí ṣe ọ̀rọ̀ èrè ìjẹkújẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn tí ó múra tán.” Wọn yóò jíhìn fún Ọlọrun nípa bí wọ́n bá ṣe bójútó ohun àfúnniṣọ́ mímọ́ ọlọ́wọ̀ yìí.—Heberu 13:17.
Àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ ńkọ́? Ìwé Mímọ́ kò béèrè pé kí wọ́n tóótun bíi ti àwọn alàgbà nínú agbára wọn láti kọ́ni. Ẹrù-iṣẹ́ wọn yàtọ̀ lọ́nà kan sí tí àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ alàgbà. Ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní C.E., kò sí iyèméjì pé àwọn nǹkan tí ara, tí a ń ṣe déédéé, tàbí àwọn nǹkan àfaraṣe wà tí ó béèrè àfiyèsí, tí ó ṣeéṣe kí ó ní nínú ríra àwọn nǹkan ti ara fún ṣíṣàdàkọ Ìwé Mímọ́ tàbí kí ó tilẹ̀ jẹ́ ṣíṣe àdàkọ náà gan-an.
Lónìí, àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ ń báa lọ láti mú onírúurú àwọn iṣẹ́ pàtàkì ṣe láàárín ìjọ, bíi bíbójútó àkáùntì ìjọ àti àgbègbè ìpínlẹ̀, pípín àwọn ìwé ìròyìn àti àwọn ìwé fúnni, àti pípa Gbọ̀ngàn Ìjọba mọ́. Àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ kan tí wọ́n ní agbára ìṣe ni a tilẹ̀ lè lò fún kíkọ́ni, nígbà mìíràn fún dídarí àwọn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, bíbójútó àwọn apá nínú Ìpàdé Iṣẹ́-Ìsìn, àti sísọ àwọn ọ̀rọ̀-àsọyé fún gbogbo ènìyàn.
Nígbà tí àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ bá ń ṣiṣẹ́ papọ̀ ní ìṣọ̀kan, àwọn àìní ìjọ—nípa tẹ̀mí àti ti ìṣètòjọ—ní a ń bójútó lọ́nà wíwàdéédéé. Nígbà náà ni àwọn mẹ́ḿbà ìjọ yóò láyọ̀, jẹ́ alágbára, tí wọn yóò sì máa sèso nípa tẹ̀mí. Rántí ohun tí Paulu kọ̀wé rẹ̀ sí àwọn ẹni àmì òróró ní Efesu: “Láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ara náà tí a ń so ṣọ̀kan pọ̀, tí ó sì ń fi ara mọ́ra, nípa gbogbo oríkèé ìpèsè, (gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ olúkúlùkù ẹ̀yà-ara ní ìwọ̀n tirẹ̀) ó ń mú ara náà bí síi fún ìdàgbàsókè òun tìkáraarẹ̀ nínú ìfẹ́.”—Efesu 4:16.
Àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ gbọ́dọ̀ làkàkà láti mú irú ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀ dàgbà, ìyẹn ni, ìfohùnṣọ̀kan, ìfìmọ̀ṣọ̀kan, ìfọwọ́sowọ́pọ̀, àti ìrẹ́pọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, irú ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀ kìí ṣàdéédéé wá. A gbọ́dọ̀ mú un dàgbà kí a sì dáàbòbò ó pẹ̀lú ìṣọ́ra.
Ohun tí Àwọn Alàgbà Lè Ṣe
Ìgbésẹ̀ ṣíṣe pàtàkì kan ni láti rántí pé ìbátan tí ó wà láàárín alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ kan kìí ṣe ti ọ̀gá sí ẹrú tàbí ti agbanisíṣẹ́ sí ẹni tí a gbàsíṣẹ́. Níbi tí ìṣọ̀kan tòótọ́ bá wà, àwọn alàgbà a máa wo àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọrun ẹlẹgbẹ́ wọn. (Fiwé 1 Korinti 3:6-9.) “Níti ọlá, ẹ máa fi ẹnìkejì yín ṣáájú,” ni Romu 12:10 wí. Àwọn alàgbà ń tipa báyìí yẹra fún fífọwọ́ mú àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ ní àwọn ọ̀nà kan tí ó lè mú kí ó dàbí ẹni pé wọ́n ń rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, tàbí sọ wọ́n di yẹpẹrẹ. Wọ́n ń fún ìdánúṣe gbígbámúṣé ní ìṣírí, dípò kí wọ́n fojú tẹ́ḿbẹ́lú rẹ̀. Fífi ọ̀wọ̀ bá àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ lò a máa mú àwọn ànímọ́ dídára jùlọ wọn gbèrú ó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbádùn iṣẹ́ wọn nínú ìjọ.
Àwọn alàgbà tún níláti ní in lọ́kàn pé iṣẹ́ tí a fi rán wọn láti ṣolùṣọ́ àgùtàn agbo Ọlọrun tí ó wà lábẹ́ àbójútó wọn kan àwọn arákùnrin tí wọ́n ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́. Lóòótọ́, irú àwọn ọkùnrin ẹlẹ́rù-iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ni a retí pé kí wọ́n jẹ́ Kristian tí ó dàgbàdénú. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù nínú agbo, wọ́n nílò àfiyèsí ara-ẹni láti ìgbà dé ìgbà. Àwọn alàgbà níláti lọ́kàn-ìfẹ́ jíjinlẹ̀ nínú ìdàgbàsókè tẹ̀mí wọn.
Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí aposteli Paulu pàdé ọ̀dọ́mọkùnrin náà Timoteu, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ó lóye ohun tí Timoteu lágbára láti jẹ́ ó sì “sọ ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ jáde pé kí ọkùnrin yii bá oun jáde lọ.” (Iṣe 16:3, NW) Timoteu ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alábàákẹ́gbẹ́ nínú ìrìn-àjò pẹ̀lú Paulu, ní gbígba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ṣíṣeyebíye gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí èyí. Họ́wù, ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà Paulu lè kọ̀wé sí ìjọ Kristian tí ó wà ní Korinti pé: ‘Mo rán Timoteu sí yín, ẹni tíí ṣe ọmọ mi olùfẹ́ àti olódodo nínú Oluwa, ẹni tí yóò máa mú yín rántí ọnà mi tí ó wà nínú Kristi, gẹ́gẹ́ bí mo ti ń kọ́ni nínú gbogbo ìjọ níbi gbogbo!’—1 Korinti 4:17.
Ẹ̀yin alàgbà, ẹ ha ti bẹ̀rẹ̀ síí lo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára tí ó ṣeéṣe kí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ nínú ìjọ yín mú dàgbà bí? Ẹ ha ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tẹ̀síwájú nípa fífún wọn ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ ara-ẹni nínú sísọ̀rọ̀ ní gbangba àti ìwádìíjinlẹ̀ nínú Bibeli? Ẹ ha ti késí àwọn tí wọ́n tóótun láti bá yín lọ nígbà ìbẹ̀wò olùṣọ́-àgùtàn? Ẹ ha ń bá wọn ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá bí? Nínú òwe Jesu nípa tálẹ́ǹtì, ọ̀gá náà sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùṣòtítọ́ pé: “O ṣeun, ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ rere àti olóòótọ́.” (Matteu 25:23) Ẹ̀yin pẹ̀lú ha jẹ́ ọlọ́làwọ́ níti yíyìn àti ṣíṣàyẹ́sí fún àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ tí wọ́n ń fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn bójútó iṣẹ́ àyànfúnni wọn ní ọ̀nà àtàtà bí? (Fiwé Owe 3:27.) Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn yóò ha ronú pé a kò mọrírì iṣẹ́ wọn bí?
Bákan náà ni ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tún ṣekókó fún ipò ìbátan iṣẹ́ ṣíṣe tí ó wà ní ìṣọ̀kan. (Fiwé Owe 15:22.) Iṣẹ́ ni a kò níláti yàn fúnni tàbí kí a gbà kúrò lọ́wọ́ ẹni lọ́nà kòdúrógbẹ́jọ́ tàbí ní ìdákúrekú. Àwọn alàgbà níláti fi tàdúrà-tàdúrà jíròrò lórí bí wọ́n ṣe lè lo agbára tí arákùnrin kan nínú ìjọ ní lọ́nà dídára jùlọ. (Fiwé Matteu 25:15.) Nígbà tí a bá yan iṣẹ́ kan fúnni, arákùnrin kan ni a níláti fún ní ìtọ́ni kínníkínní nípa ohun pàtó náà tí a ń retí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀. Owe 11:14 kìlọ̀ pé, “Níbi tí ìgbìmọ̀ kò sí, àwọn ènìyàn a ṣubú.”
Kò dára tó láti wulẹ̀ sọ fún arákùnrin kan láti tẹ́wọ́gba ẹ̀ka-iṣẹ́ àkáùntì, ìwé-ìròyìn, tàbí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ ìránṣẹ́ mìíràn. Nígbà mìíràn ìránṣẹ́ kan tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yanṣẹ́ fún máa ń gba ọ̀pọ̀ àwọn àkọsílẹ̀ tí kò péye tàbí pé pérépéré. Ẹ wo bí ìyẹn ti ń banilọ́kànjẹ́ tó! 1 Korinti 14:40 fúnni ní ìtọ́ni pé, “Ẹ máa ṣe ohun gbogbo tẹ̀yẹtẹ̀yẹ àti lẹ́sẹlẹ́sẹ.” Àwọn alàgbà níláti lo ìdánúṣe láti fún àwọn ará ní ìdálẹ́kọ̀ọ́, ní sísọ wọ́n dojúlùmọ̀ pẹ̀lú àwọn ìlànà ìṣe nǹkan nínú ìjọ kí àwọn fúnraawọn sì máa fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ ní títẹ̀lé irú àwọn ìlànà ìṣe nǹkan bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ó yẹ kí àwọn alàgbà ṣètò pé kí a ṣe ìṣirò owó àkáùntì ìjọ ní oṣù mẹ́ta-mẹ́ta. Fífojú tín-ín-rín irú ìṣètò pàtàkì bẹ́ẹ̀ lè yọrísí àwọn ìṣòro kí ó sì dín ọ̀wọ̀ tí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ ní fún àwọn ìtọ́ni nípa ìṣètòjọ kù.
Ṣùgbọ́n kí a sọ pé ó dàbí ẹni pé arákùnrin kan fi ìwà àìnáání hàn nínú ọ̀nà tí ó ń gbà bójútó iṣẹ́ àyànfúnni pàtàkì kan ń kọ́? Dípò mímú un kúrò lẹ́nu iṣẹ́ àyànfúnni rẹ̀ láìjáfara, àwọn alàgbà níláti jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú rẹ̀. Bóyá àìní ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí ó pọ̀ tó ní ìṣòro náà. Bí arákùnrin náà bá ń báa lọ láti máa ní ìṣòro nínú bíbójútó iṣẹ́ àyànfúnni rẹ̀, bóyá yóò ṣe dáradára nínú iṣẹ́ àyànfúnni mìíràn.
Àwọn alàgbà tún lè gbé ìṣọ̀kan lárugẹ nípa fífi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn hàn. Filippi 2:3 fún àwọn Kristian ní ìṣírí láti “máṣe fi ìjà tàbí ògo asán ṣe ohunkóhun: ṣùgbọ́n ní ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn kí olúkúlùkù ro àwọn ẹlòmíràn sí ẹni tí ó sàn ju òun tìkáraarẹ̀ lọ.” Alàgbà kan níláti tipa báyìí gbìyànjú láti fọwọ́sowọ́pọ̀ bí olùṣàbójútó èrò kan bá darí rẹ̀ láti jókòó sórí ìjókòó pàtó kan nínú gbọ̀ngàn, ní ṣísàìronú pé nítorí pé òun ti jẹ́ alàgbà, kò sí ìdí fún òun láti ṣègbọràn. Bóyá olùṣàbójútó èrò náà wulẹ̀ ń ṣiṣẹ́ lórí ìdámọ̀ràn náà láti jókòó ní àwọn apá ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú gbọ̀ngàn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó níláti rántí pé kò sí ìlànà kankan pé gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.a Bí kò bá sí ìdí fún un alàgbà kan yóò yẹra fún ṣíṣe ìyípadà àwọn ìpinnu lórí ọ̀ràn tí a ti yàn fún ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ kan.
Àwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ tí Wọ́n Ń Ṣiṣẹ́ Láti Wá Ìṣọ̀kan
Paulu sọ̀rọ̀ àkíyèsí pé, “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ awọn ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ níláti ní ìwà àgbà.” (1 Timoteu 3:8, NW) Wíwo iṣẹ́ àyànfúnni wọn lọ́nà tí ó ṣe pàtàkì—gẹ́gẹ́ bí apákan iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ wọn—ń ṣe púpọ̀ láti ṣèdíwọ́ fún pákáǹleke láti máṣe gbèrú. Bí ìwọ bá jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́, ìwọ ha ń fi ìtara ọkàn ṣe àwọn iṣẹ́ rẹ bí? (Romu 12:7, 8) Ìwọ ha ti fi aápọn lo araàrẹ kí o baà lè di ọ̀jáfáfá nínú bíbójútó àwọn iṣẹ́ rẹ bí? Ìwọ ha ṣeé fọkàntẹ̀ tí o sì ṣeé gbáralé bí? Ìwọ ha ń fi ẹ̀mí ìmúratán hàn nígbà tí ó bá di ti àwọn iṣẹ́ àyànfúnni bí? Ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ kan ní ilẹ̀ Africa kan ń bójútó àwọn iṣẹ́ àyànfúnni mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ìjọ. Kí ni ìṣarasíhùwà rẹ̀? Ó sọ pé, “Ó dára, ó wulẹ̀ túmọ̀sí iṣẹ́ àṣekára púpọ̀ síi, iṣẹ́ àṣekára kò sì lè pa ọ́.” Nítòótọ́, àwọn wọnnì tí wọ́n yọ̀ǹda araawọn ń gbádùn ayọ̀ tí ó pọ̀ jùlọ.—Iṣe 20:35.
Ìwọ pẹ̀lú lè ṣe púpọ̀ láti gbé ìṣọ̀kan lárugẹ nípa fífọwọ́sowọ́pọ̀ ní kíkún pẹ̀lú àwọn alàgbà. Heberu 13:17 sọ pé, “Ẹ máa gbọ́ ti àwọn tí ń ṣe olórí yín, kí ẹ sì máa tẹríba fún wọn: nítorí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ nítorí ọkàn yín, bí àwọn tí yóò ṣe ìṣirò, kí wọn kí ó lè fi ayọ̀ ṣe èyí, ní àìsí ìbànújẹ́, nítorí èyíyìí yóò jẹ́ àìlérè fún yín.” Nítòótọ́, àwọn alàgbà jẹ́ ènìyàn aláìpé, ó sì lè rọrùn láti rí àríwísí sí wọn. Síbẹ̀, ìṣarasíhùwà ṣíṣe òfíntótó a máa bí àìnígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé. Ó lè pa ayọ̀ rẹ̀ run kí ó sì nípa búburú lórí àwọn ẹlòmíràn nínú ìjọ. Aposteli Peteru tipa báyìí fúnni ní ìmọ̀ràn yìí pé: “Ẹ̀yin ìpẹ́ẹ̀rẹ̀, ẹ tẹríba fún àwọn àgbà. Àní gbogbo yín, ẹ máa tẹríba fún ara yín, kí ẹ sì fi ìrẹ̀lẹ̀ wọ ara yín ní aṣọ: . . . Nítorí náà ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọrun, kí òun kí ó lè gbé yín ga ní àkókò.”—1 Peteru 5:5, 6.
Irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ ṣe wẹ́kú ní pàtàkì nígbà tí o bá ronú pé a ti gbójúfò ọ́ dá níti àǹfààní iṣẹ́-ìsìn. Bóyá o ti “ń nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó,” ṣùgbọ́n a kò tíì yàn ọ́ sípò. (1 Timoteu 3:1, NW) Ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti pa “ẹ̀mí ìrònú ìdúródè” mọ́. (Ẹkun Jeremiah 3:24, NW) Dípò kí ó fi ìbínú hàn sí àwọn alàgbà—èyí tí ó dájú pé yóò sọ ipò ìbátan iṣẹ́ ṣíṣe rẹ di aláìlágbára—bi wọ́n bí àwọn àgbègbè kan bá wà nínú èyí tí o ti lè ṣe ìmúsunwọ̀n síi. Kò sí iyèméjì pé ìmúratán rẹ láti tẹ́wọ́gbà kí o sì fi ìmọ̀ràn sílò ni a óò rí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìdàgbà tẹ̀mí rẹ.
Ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Ọlọrun lè ran ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ kan lọ́wọ́ láti pa ìwàdéédéé rẹ̀ mọ́ bí ó bá ní agbára ìṣe àrà-ọ̀tọ̀ tàbí àwọn àǹfààní ti ẹ̀kọ́-ìwé àti ti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà. Ẹ wo bí ó ti lè jẹ́ ìdẹwò fún un tó láti gbìyànjú láti ta àwọn alàgbà yọ tàbí pe àfiyèsí sí àwọn agbára ìṣe tirẹ̀! Owe 11:2 rán wa létí pé “ọgbọ́n wà pẹ̀lú onírẹ̀lẹ̀.” Arákùnrin kan tí ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ mọ ibi tí agbára òun mọ. Ó ń múratán láti fi ìdákẹ́jẹ́ẹ́ ṣiṣẹ́ lábẹ́lẹ̀ àti láti lo òye rẹ̀ láti ti àwọn alàgbà lẹ́yìn. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tún lè ràn án lọ́wọ́ láti mọ̀ pé nígbà tí ó jẹ́ pé òun lè ní ìmọ̀ púpọ̀ ní ọ̀nà ti ayé, òye ṣì lè kù fún òun ní àwọn àgbègbè pàtàkì kan nínú ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ tẹ̀mí—àwọn ànímọ́ nínú èyí tí àwọn alàgbà ti lè yọrí-ọlá.—1 Korinti 1:26–2:13; Filippi 1:9.
Ní kedere, àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́ ń kó àwọn ipa ṣíṣekókó. Lápapọ̀ wọ́n lè ṣe púpọ̀ láti gbé gbogbo àwọn tí ń bẹ́ nínú ìjọ ró. Ṣùgbọ́n láti ṣe bẹ́ẹ̀ wọ́n gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ papọ̀ ní ìṣọ̀kan, “pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ gbogbo àti inútútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra, ẹ máa fi ìfẹ́ faradà á fún ẹnìkejì yín; kí ẹ sì máa làkàkà láti pa ìṣọ̀kan Ẹ̀mí mọ́ ní ìdìpọ̀ àlàáfíà.”—Efesu 4:2, 3.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Àwọn alàgbà ń wo àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́, kìí ṣe gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ọmọ-abẹ́ kan, bíkòṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ẹlẹgbẹ́ wọn