Ẹ̀yin Alàgbà—Ẹ Kọ́ Àwọn Ẹlòmíràn Láti Gbé Ẹrù Náà
NÍNÚ àwọn ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé, a nílò àwọn ọkùnrin tó lè sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ní kánjúkánjú. Ohun mẹ́ta pàtàkì ló sọ ọ̀ràn yìí di kánjúkánjú.
Èkíní, Jèhófà ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun yóò sọ “ẹni kékeré . . . di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè.” (Aísáyà 60:22) Nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀, ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù kan àwọn ọmọlẹ́yìn tuntun tó ti ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà láàárín ọdún mẹ́ta sẹ́yìn. A ń fẹ́ àwọn ọkùnrin tó ṣeé fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́, tí yóò ran àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi wọ̀nyí lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú di Kristẹni tó dàgbà dénú.—Hébérù 6:1.
Èkejì, ó ti di dandan kí àwọn kan tó ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà fún ọ̀pọ̀ ọdún dín ẹrù iṣẹ́ tí wọ́n ń gbé nínú ìjọ kù nítorí ọjọ́ ogbó tàbí àìlera.
Ẹ̀kẹta, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni onítara tí wọ́n jẹ́ alàgbà ló ń sìn báyìí gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn tàbí mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn tàbí mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ó di dandan kí wọ́n já lára ẹrù iṣẹ́ wọn nínú ìjọ àdúgbò sílẹ̀, kí wọ́n lè ráyè bójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ yòókù.
Báwo la ṣe lè kájú àìní tó jẹ́ kánjúkánjú yìí láti rí àwọn ọkùnrin tó tóótun púpọ̀ sí i? Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ló máa yanjú ọ̀ràn yìí o. Bíbélì rọ àwọn Kristẹni alábòójútó pé kí wọ́n kọ́ “àwọn olùṣòtítọ́ . . . , tí àwọn, ẹ̀wẹ̀, yóò tóótun tẹ́rùntẹ́rùn láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn.” (2 Tímótì 2:2) Láti dáni lẹ́kọ̀ọ́ túmọ̀ sí láti kọ́ ẹnì kan, kí onítọ̀hún lè jẹ́ ẹni yíyẹ, ẹni tó tóótun, tàbí ẹni tó dáńgájíá. Ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn alàgbà ṣe lè kọ́ àwọn arákùnrin mìíràn tó tóótun.
Ẹ Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jèhófà
Ó dájú pé Jésù Kristi jẹ́ ‘ẹni yíyẹ, tó tóótun, tó sì dáńgájíá’ nínú iṣẹ́ rẹ̀—kò sì yẹ kíyẹn yà wá lẹ́nu! Nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run alára ló kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. Kí ló mú kí ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí gbéṣẹ́ tó bẹ́ẹ̀? Jésù mẹ́nu kan kókó mẹ́ta, nínú Jòhánù 5:20, pé: “Baba [1] ní ìfẹ́ni fún Ọmọ, ó sì [2] fi gbogbo ohun tí òun fúnra rẹ̀ ń ṣe hàn án, yóò sì fi [3] àwọn iṣẹ́ tí wọ́n tóbi ju ìwọ̀nyí hàn án.” Ṣíṣàyẹ̀wò kókó wọ̀nyí lọ́kọ̀ọ̀kan yóò jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun tí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wé mọ́.
Kíyè sí ohun tí Jésù kọ́kọ́ sọ, ó ní: “Baba ní ìfẹ́ni fún Ọmọ.” Láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìgbà ìṣẹ̀dá ni àjọṣe tó gbámúṣé ti wà láàárín Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀. Ìwé Òwe 8:30 ṣàlàyé àjọṣe yẹn dáadáa, ó ní: “Nígbà náà ni mo [Jésù] wá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ [Jèhófà Ọlọ́run] gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́, mo sì wá jẹ́ ẹni tí ó ní ìfẹ́ni sí lọ́nà àkànṣe lójoojúmọ́, tí mo ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà.” Ó dá Jésù lójú hán-únhán-ún pé Jèhófà “ní ìfẹ́ni sí [òun] lọ́nà àkànṣe.” Jésù kò sì pa ayọ̀ rẹ̀ mọ́nú nígbà tó ń ṣiṣẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Bàbá rẹ̀. Ẹ ò rí i pé ó máa ń dára gan-an tí àjọṣe tímọ́tímọ́, tó tún gbámúṣé bá wà láàárín àwọn Kristẹni alàgbà àtàwọn tí wọ́n ń dá lẹ́kọ̀ọ́!
Kókó kejì tí Jésù mẹ́nu kàn ni pé Bàbá “fi gbogbo ohun tí òun fúnra rẹ̀ ń ṣe hàn án.” Èyí kín ọ̀rọ̀ tó wà nínú Òwe 8:30 lẹ́yìn pé Jésù “wá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́” Jèhófà nígbà dídá ọ̀run òun ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Àwọn alàgbà lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ títayọ yìí nípa ṣíṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, kí wọ́n máa fi bí wọ́n ṣe lè ṣe ojúṣe wọn lọ́nà tó dáńgájíá hàn wọ́n. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn nìkan ló nílò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé. Àwọn arákùnrin olóòótọ́ wọ̀nyẹn tí wọ́n ti ń nàgà fún ipò alábòójútó fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣùgbọ́n tí a kò tíì yàn ńkọ́? (1 Tímótì 3:1) Ó yẹ kí àwọn alàgbà fún irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ ní ìmọ̀ràn tó ṣe pàtó, kí wọ́n lè mọ ibi tí wọ́n máa ṣiṣẹ́ lé lórí.
Fún àpẹẹrẹ, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan lè jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán, tí kì í fi nǹkan falẹ̀, tó sì máa ń fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ tá a bá yàn fún un. Ó tún lè jẹ́ olùkọ́ tó dáńgájíá. Ó lè jẹ́ ẹni tó ń forí fọrùn ṣe fún ire ìjọ. Àmọ́, ó lè má mọ̀ pé ọwọ́ tí òun fi ń mú àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ òun ti le jù. Bẹ́ẹ̀ rèé, ó yẹ kí alàgbà ní “ìwà tútù tí ó jẹ́ ti ọgbọ́n.” (Jákọ́bù 3:13) Ǹjẹ́ kò ní dára kí alàgbà kan bá ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà sọ̀rọ̀, kó ṣàlàyé ìṣòro náà fún un láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, kí ó tọ́ka sí àwọn àpẹẹrẹ kan pàtó, kí ó sì fún un ní àwọn àbá tó gbéṣẹ́ kí ó bàa lè ṣàtúnṣe? Bí alàgbà náà bá rọra “fi iyọ̀ dun” ìmọ̀ràn rẹ̀, ó ṣeé ṣe kó tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Kólósè 4:6) Ṣùgbọ́n o, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà á túbọ̀ mú kí iṣẹ́ alàgbà náà rọrùn bí ó bá fetí sí ìmọ̀ràn tá a bá fún un, láìjanpata.—Sáàmù 141:5.
Nínú àwọn ìjọ kan, àwọn alàgbà ń fún àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó mọ́yán lórí láìdáwọ́dúró. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń mú àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó tóótun dání nígbà tí wọ́n bá fẹ́ lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó ń ṣàìsàn tàbí àwọn àgbàlagbà. Èyí á jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà túbọ̀ mọ iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ṣe. Àmọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lè ṣe láti túbọ̀ máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.—Wo àpótí tó wà nísàlẹ̀ yìí, tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ohun Tí Àwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Lè Ṣe.”
Kókó kẹta tó mú kí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Jésù múná dóko ni pé Jèhófà ro ti ọjọ́ iwájú mọ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó fún un. Jésù sọ pé Bàbá yóò fi “àwọn iṣẹ́ tí wọ́n tóbi ju ìwọ̀nyí” han Ọmọ rẹ̀. Ìrírí tí Jésù ní nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ kó ṣeé ṣe fún un láti ní àwọn ànímọ́ tí yóò wúlò fún un nígbà tó bá ń ṣe àwọn iṣẹ́ tí a ó yàn fún un lọ́jọ́ iwájú. (Hébérù 4:15; 5:8, 9) Fún àpẹẹrẹ, ẹ wo iṣẹ́ bàǹtà-banta tí Jésù máa tó gbà—ìyẹn iṣẹ́ jíjí ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù èèyàn tó ti kú báyìí dìde, kí ó sì ṣèdájọ́ wọn!—Jòhánù 5:21, 22.
Nígbà táwọn alàgbà bá ń fún àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lónìí, ó yẹ kí wọ́n máa ro ti ọjọ́ iwájú. Ó lè dà bíi pé àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tá a ní báyìí ti tó. Àmọ́ ṣé wọ́n á ṣì tó nígbà tá a bá dá ìjọ tuntun kan sílẹ̀? Ṣé wọ́n á ṣì tó tá a bá dá ọ̀pọ̀ ìjọ sílẹ̀? Láàárín ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, ó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ìjọ tuntun tá a dá sílẹ̀ kárí ayé. Ẹ ò rí i pé iye àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tá a nílò láti bójú tó ìjọ tuntun wọ̀nyí á pọ̀ gan-an ni!
Ẹ̀yin alàgbà, ṣé ẹ ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà nípa níní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí ẹ̀ ń dá lẹ́kọ̀ọ́? Ṣé ẹ ń fi ọ̀nà tí wọ́n á gbà ṣe iṣẹ́ wọn hàn wọ́n? Ṣé ẹ ń ro ti ọjọ́ iwájú? Títẹ̀lé àpẹẹrẹ bí Jèhófà ṣe kọ́ Jésù yóò yọrí sí ìbùkún ńláǹlà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀.
Ẹ Má Bẹ̀rù Àtigbéṣẹ́ Lé Àwọn Ẹlòmíì Lọ́wọ́
Àwọn alàgbà tó dáńgájíá, tó ti mọ́ lára láti máa dá gbé ọ̀pọ̀ ẹrù iṣẹ́ wíwúwo, lè máà fẹ́ gbé ọ̀pá àṣẹ lé àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Wọ́n lè ti gbìyànjú rẹ̀ rí, kí ó jẹ́ pé ńṣe ló forí ṣánpọ́n. Wọ́n lè wá tìtorí ìyẹn ní ẹ̀mí náà pé, ‘Bí o bá fẹ́ iṣẹ́ àṣeyanjú, àfi kó o yáa ṣe é fúnra rẹ.’ Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ irú ẹ̀mí yìí bá ìfẹ́ Jèhófà mu, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú Ìwé Mímọ́, pé kí àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní ìrírí gba ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ àwọn tó ní ìrírí?—2 Tímótì 2:2.
Inú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ò dùn rárá nígbà tí ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n jọ ràjò, ìyẹn Jòhánù Máàkù, padà sílé ní Panfílíà nígbà tí wọ́n ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́. (Ìṣe 15:38, 39) Àmọ́ Pọ́ọ̀lù kò torí ìyẹn ṣíwọ́ fífún ẹlòmíì ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́. Ó tún yan ọ̀dọ́kùnrin mìíràn, ìyẹn Tímótì, ó sì kọ́ ọ níṣẹ́ míṣọ́nnárì.a (Ìṣe 16:1-3) Ní Bèróà, àwọn míṣọ́nnárì náà fojú winá àtakò gbígbóná janjan, tó le débi pé, ohun tó máa dáa jù lọ ni kí Pọ́ọ̀lù fibẹ̀ sílẹ̀. Ìyẹn ló jẹ́ kó fi ìjọ tuntun yìí síkàáwọ́ Sílà, arákùnrin tó dàgbà dénú, àti síkàáwọ́ Tímótì. (Ìṣe 17:13-15) Ó dájú pé Tímótì rí ẹ̀kọ́ púpọ̀ kọ́ lára Sílà. Nígbà tó yá, tí Tímótì tóótun láti gba ẹrù iṣẹ́ púpọ̀ sí i, Pọ́ọ̀lù rán an lọ sí Tẹsalóníkà kó lọ gbé ìjọ tó wà níbẹ̀ ró.—1 Tẹsalóníkà 3:1-3.
Ọ̀ràn iṣẹ́ nìkan kọ́ ló pa Pọ́ọ̀lù àti Tímótì pọ̀. Ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tún wà láàárín wọn. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí ìjọ Kọ́ríńtì, ó pe Tímótì, tó ń ronú àtirán lọ síbẹ̀, ní ọmọ òun “olùfẹ́ ọ̀wọ́n àti olùṣòtítọ́ nínú Olúwa.” Ó wá fi kún un pé: “[Tímótì] yóò sì rán yín létí àwọn ọ̀nà tí mo gbà ń ṣe nǹkan ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.” (1 Kọ́ríńtì 4:17) Tímótì lo ẹ̀kọ́ tó gbà lọ́dọ̀ Pọ́ọ̀lù, ó tóótun láti ṣe àwọn iṣẹ́ tá a yàn fún un. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ arákùnrin ni wọ́n ti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, alàgbà, tàbí alábòójútó arìnrìn-àjò tó dáńgájíá pàápàá, nítorí pé wọ́n jàǹfààní nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn àgbà ọkùnrin tó bìkítà, tí wọ́n ní ìfẹ́ àtọkànwá sí wọn, irú èyí tí Pọ́ọ̀lù ní sí Tímótì.
Ẹ̀yin Alàgbà, Ẹ Máa Kọ́ Àwọn Ẹlòmíràn!
Láìsí àní-àní, àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà 60:22 ń nímùúṣẹ lónìí. Jèhófà ń sọ “ẹni kékeré . . . di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè.” Bí orílẹ̀-èdè náà yóò bá máa bá a lọ ní jíjẹ́ “alágbára ńlá,” ó gbọ́dọ̀ wà létòlétò. Ẹ̀yin alàgbà, ẹ ò ṣe ronú àwọn ọ̀nà míì tẹ́ ẹ tún lè gbà kọ́ àwọn ọkùnrin tó ti ṣe ìyàsímímọ́ tí wọ́n sì tóótun láti gbẹ̀kọ́? Kí ẹ rí i dájú pé gbogbo ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ló mọ àtúnṣe tó yẹ kí wọ́n ṣe kí wọ́n lè máa tẹ̀ síwájú. Àti ẹ̀yin arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi, ẹ jẹ́ kí gbogbo ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ń ṣe fún yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ṣe yín láǹfààní. Ẹ lo gbogbo àǹfààní tẹ́ ẹ bá ní láti fi kún ìmọ̀, òye àti ìrírí yín. Dájúdájú, Jèhófà yóò bù kún irú ètò ìrànwọ́ onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀.—Aísáyà 61:5.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nígbà tó ṣe, Pọ́ọ̀lù tún bá Jòhánù Máàkù ṣiṣẹ́.—Kólósè 4:10.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30]
Ohun Tí Àwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Lè Ṣe
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kí àwọn alàgbà kọ́ àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, ohun púpọ̀ làwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lè ṣe láti túbọ̀ máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.
—Ó yẹ kí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ jẹ́ aláápọn, kí wọ́n sì ṣeé fọkàn tán lẹ́nu bíbójútó iṣẹ́ tá a yàn fún wọn. Ó tún yẹ kí wọ́n ní ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ tó jíire. Títí dé àyè kan, ìtẹ̀síwájú sinmi lórí bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí àti bá a ṣe ń fi ẹ̀kọ́ tá a ń kọ́ sílò.
—Nígbà tí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ bá níṣẹ́ nínú ìpàdé Kristẹni, kò sóhun tó burú nínú lílọ bá alàgbà kan tó tóótun pé kí ó fún òun ní àbá nípa bóun ṣe lè gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀.
—Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà tún lè ní kí alàgbà kan máa fọkàn bá a lọ bóun ṣe ń sọ ọ̀rọ̀ kan tá a gbé ka Bíbélì, kí ó sì fún òun ní ìmọ̀ràn tó máa jẹ́ kóun túbọ̀ ṣe dáadáa sí i.
Ó yẹ kí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa dìídì lọ gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn alàgbà, kí wọ́n tẹ́wọ́ gba irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀, kí wọ́n sì mú un lò. Bí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìlọsíwájú wọn yóò “fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.”—1 Tímótì 4:15.