Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́—Ilẹ̀kùn Ńlá Tí Ń Ṣamọ̀nà sí Ìgbòkègbodò
1 Jèhófà gbẹnu wòlíì Jeremáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ṣe ni èmi yóò . . . gbé àwọn olùṣọ́ àgùntàn dìde lórí [àwọn èèyàn mi] tí yóò ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn ní ti gidi; wọn kì yóò sì fòyà mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìpayà kankan kì yóò bá wọn mọ́, kì yóò sì sí ọ̀kankan tí yóò dàwátì.” (Jer. 23:4) Lónìí, àwọn kan ń ṣe irú iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn bẹ́ẹ̀ láàárín àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn alàgbà ìjọ ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ yìí. Bákan náà, àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n pọ̀ gan-an bí ìrì tí ń sẹ̀ ti fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (Sm. 110:3) Ká sòótọ́, ìjọ àwọn èèyàn Ọlọ́run ń jàǹfààní gan-an lára àwọn arákùnrin onírẹ̀lẹ̀ yìí! Bí iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí yìí ti ń tẹ̀ síwájú, a ṣì ń fẹ́ àwọn arákùnrin tó kúnjú òṣùwọ̀n tó máa yọ̀ǹda ara wọn láti sin àwọn ará.
2 A ti ṣe ètò dáradára kan láti fi dá àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ àpọ́n lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ ṣe ojúṣe tó pọ̀ sí i. Ètò yìí ni Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Láti ọdún 1987 tí a ti dá ilé ẹ̀kọ́ yìí sílẹ̀, àwùjọ akẹ́kọ̀ọ́ mọ́kàn-dín-ní-ẹgbẹ̀rún [999] la ti dá lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí iye wọn lé ní ẹgbẹ̀rún méjìlélógún [22,000] láti ogóje orílẹ̀-èdè ló sì wà nínú àwùjọ wọ̀nyí. “Ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò” ni ilé ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ fún àwọn arákùnrin wọ̀nyí.—1 Kọ́r. 16:9.
3 Ìdí Tí A Fi Dá Ilé Ẹ̀kọ́ Yìí Sílẹ̀: A dá Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ sílẹ̀ láti fi dá àwọn arákùnrin tó kúnjú òṣùwọ̀n lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè ṣe àwọn ojúṣe tó bá yẹ ní ṣíṣe níbikíbi tá a bá ti fẹ́ kí wọ́n ṣèrànwọ́ nínú ètò àjọ Ọlọ́run. Ilé Ẹ̀kọ́ yìí á jẹ́ kí wọ́n lè túbọ̀ ṣe àwọn ojúṣe wọn nínú ìjọ dáradára sí i, irú bíi fífi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù, bíbójútó agbo Ọlọ́run àti kíkọ́ ìjọ lẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn tí ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí bá ti parí, a máa ń rán àwọn kan pé kí wọ́n lọ ṣe aṣáájú ọ̀nà àkànṣe tàbí alábòójútó arìnrìn-àjò lórílẹ̀-èdè wọn tàbí nílẹ̀ òkèèrè. A máa ń rán àwọn mìíràn láti padà lọ ṣèrànwọ́ nínú ìjọ wọn tàbí ká rán wọn lọ sáwọn ibi tí wọ́n bá ti máa wúlò jù ní àgbègbè tí ẹ̀ka ọ́fíìsì ń bójú tó.
4 Nígbà ìdálẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́sẹ̀ mẹ́jọ yìí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀jinlẹ̀. Wọ́n á fara balẹ̀ gbé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ inú Bíbélì àtàwọn ohun tó jẹ́ ẹrù iṣẹ́ àwọn alábòójútó nínú ìjọ yẹ̀ wò. Bákan náà, wọ́n á tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìlànà tí àwa Kristẹni fi lè yanjú ìṣòro. Wọ́n tún máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Ìwé Mímọ́ fi kọ́ni lórí ọ̀ràn ṣíṣe àbójútó nínú ìjọ Ọlọ́run, ṣíṣe ìdájọ́ àti fífi àwọn ìlànà ètò àjọ sílò. Wọ́n máa ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ àkànṣe nípa béèyàn ṣe lè sọ̀rọ̀ níwájú àwùjọ, a sì máa ń ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ bí wọ́n ṣe lè tètè ní ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí.
5 Àwọn Tó Lè Wá Sílé Ẹ̀kọ́ Yìí: Ká sòótọ́, ó lójú àwọn tó lè wá sí ilé ẹ̀kọ́ yìí. Àwọn tó bá fẹ́ wá ti gbọ́dọ̀ jẹ́ alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún ọdún méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Gbogbo wọn ní láti jẹ́ àpọ́n, kí ọjọ́ orí wọn má ṣe dín ní ọdún mẹ́tàlélógún, kó má sì lé ní àádọ́ta ọdún. Wọ́n gbọ́dọ̀ lè ka ìwé lédè tá a fẹ́ fi ṣe ilé ẹ̀kọ́ náà, kí wọ́n lè kọ èdè náà sílẹ̀, kí wọ́n sì lè sọ ọ́ dáradára. Bákan náà, ara wọn gbọ́dọ̀ dá ṣáṣá, kó máà sí pé wọ́n ń fẹ́ àbójútó àrà ọ̀tọ̀ tàbí pé irú àwọn oúnjẹ kan pàtó ni wọ́n ń jẹ. Ìwé àwọn tó bá jẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé la máa ń kọ́kọ́ gbé yẹ̀ wò.
6 Àwọn tó bá yọ̀ǹda ara wọn láti wá sí ilé ẹ̀kọ́ yìí gbọ́dọ̀ múra tán láti sìn níbikíbi tá a bá ti fẹ́ kí wọ́n lọ ṣèrànwọ́. Láti ṣe èyí, wọ́n ní láti fìwà jọ wòlíì Aísáyà, ẹni tó fi tinútinú yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún iṣẹ́ pàtàkì kan, tó sọ pé: “Èmi nìyí! Rán mi.” (Aísá. 6:8) Aísáyà tún jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ẹ̀dá. Bákan náà, ìfẹ́ àwọn ará àti ìfẹ́ láti sìn wọ́n ló yẹ kó wà lọ́kàn àwọn tó bá fẹ́ wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, kì í ṣe pé kí wọ́n máa wá ipò ọlá. Lẹ́yìn tí àwọn arákùnrin wọ̀nyí bá ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ dáradára yìí, a retí pé kí wọ́n fi àwọn ohun tí wọ́n kọ́ sílò kó bàa lè ṣe àwọn ẹlòmíràn láǹfààní.—Lúùkù 12:48.
7 Àǹfààní Ilé Ẹ̀kọ́ Yìí: Ní gbogbo ọ̀sẹ̀ mẹ́jọ táwọn arákùnrin wọ̀nyí yóò fi kẹ́kọ̀ọ́ àkọ́jinlẹ̀, a ó ‘fi àwọn ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ àti ti ẹ̀kọ́ àtàtà bọ́’ wọn. (1 Tím. 4:6) Èyí á jẹ́ kí wọ́n lè ran àwọn tó wà nínú àwọn ìjọ àti àyíká tí wọ́n bá wà lọ́wọ́, kí wọ́n sì lè fún wọn níṣìírí. Àwọn tó gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti ṣèrànwọ́ gan-an fún àwọn ará ní ọ̀pọ̀ àgbègbè tí a rán wọn lọ. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ti ran àwọn ará lọ́wọ́ láti túbọ̀ máa jáde òde ẹ̀rí; wọ́n ti ran àwọn púpọ̀ sí i lọ́wọ́ kí wọ́n lè di aṣáájú ọ̀nà, pàápàá àwọn ọ̀dọ́; bákan náà, àwọn arákùnrin wọ̀nyí ń ṣèrànwọ́ gan-an fún ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tuntun tí wọ́n ń wá sí ìpàdé wa.
8 Ṣé alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó jẹ́ àpọ́n ni ọ́? Ṣé ọjọ́ orí rẹ ò dín ní ọdún mẹ́tàlélógún, ṣé kò sì ju àádọ́ta ọdún lọ? O ò ṣe rò ó wò bóyá wàá lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́? Ṣé ọ̀dọ́kùnrin tó ń ronú nípa àwọn ohun tó fẹ́ ṣe lọ́jọ́ iwájú nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni ọ́? O ò ṣe jẹ́ kí àwọn ohun kòṣeémánìí ní ìgbésí ayé tẹ́ ọ lọ́rùn, kó o má sì gba ohunkóhun láyè láti pín ọkàn rẹ níyà, kó bàa lè ṣeé ṣe fún ọ láti gba ẹnu “ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò” yìí wọlé? Èyí á jẹ́ kó o láyọ̀ gan-an, ọkàn rẹ á sì balẹ̀. Ká sòótọ́, àwọn tó lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ nìkan kọ́ ló ti jàǹfààní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí o, gbogbo ìjọ àwọn èèyàn Ọlọ́run kárí ayé ló ti ṣe láǹfààní.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]
Bí Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Yìí Ṣe Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Kan Lọ́wọ́
“Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí ti jẹ́ kí n túbọ̀ di ọ̀jáfáfá nínú iṣẹ́ ìwàásù, ó sì ti jẹ́ kí n túbọ̀ mọ bí mo ṣe lè fi ọgbọ́n lo Ìwé Mímọ́ láti fi bójú tó agbo Ọlọ́run.”
“Ilé ẹ̀kọ́ yìí ti jẹ́ kí n túbọ̀ ní ìgboyà láti ṣe àwọn ojúṣe mi nínú ìjọ.”
“Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìgbésí ayé mi ni ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí ti yí padà, títí kan èrò mi nípa ìṣàkóso Ọlọ́run àti ètò àjọ Ọlọ́run.”
“Ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí mo gbà jẹ́ kí n mọ̀ pé ó yẹ kí n yọ̀ǹda ara mi láti lọ sìn níbikíbi tí mo bá ti lè ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹlòmíràn.”