Ilé Ẹ̀kọ́ Kan Táwọn Tó Jáde Níbẹ̀ Ń Ṣe Àwọn Èèyàn Láǹfààní Jákèjádò Ayé
NÍNÚ ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ju ẹgbẹ̀rún méjìdínlọ́gọ́rùn-ún [98,000] lọ, èyí tó wà káàkiri ilẹ̀ tó lé ní igba, a lè rí àwọn èèyàn tí Jèhófà ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ láìfi ipò wọn tàbí ibi tí wọ́n ti wá pè. Olórí ìwé tó fi ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ ni Bíbélì, ìdí tó sì fi ń kọ́ wa ni kí olúkúlùkù wa lè máa tẹ̀ síwájú nínú ìmọ̀ Ọlọ́run nípa kíkọ́ ohun tí ìfẹ́ rẹ̀ jẹ́ àti nípa kíkọ́ bá a ṣe lè máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa. Àǹfààní ńláǹlà làwọn tó gba ẹ̀kọ́ yìí ń rí jẹ nínú ẹ̀. Wọ́n ń kọ́ àwọn ẹlòmíì ní ohun tí wọ́n kọ́, gẹ́gẹ́ bí Jésù Kristi ṣe pàṣẹ pé ká máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.—Mátíù 28:19, 20.
Yàtọ̀ sí ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó ń lọ lọ́wọ́ láwọn ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a tún ti dá àwọn ilé ẹ̀kọ́ pàtàkì-pàtàkì kan sílẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn ilé ẹ̀kọ́ náà ni Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Oṣù October ọdún 1987 la dá a sílẹ̀ nílùú Pittsburgh, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rìnlélógún tó lè sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ló wà nínú kíláàsì àkọ́kọ́ irú ẹ̀. Látìgbà náà wá, ilé ẹ̀kọ́ náà ti wà ní èdè mọ́kànlélógún. Ó sì lé ní orílẹ̀-èdè mẹ́tàlélógójì tó wà. Ní báyìí, ó ju àádọ́rùn-ún orílẹ̀-èdè lọ táwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó jẹ́ àpọ́n ti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ yìí. Báwọn akẹ́kọ̀ọ́ bá ti jáde ní ilé ẹ̀kọ́ tó máa ń gba ọ̀sẹ̀ mẹ́jọ yìí, a máa ń rán wọn lọ sìn níbi tí wọ́n bá ti nílò ìrànlọ́wọ́, yálà lórílẹ̀-èdè wọn tàbí lórílẹ̀-èdè míì. Nígbà tọ́dún 2005 fi máa parí, ó ti tó ẹgbẹ̀rún méjìlélógún [22,000] àwọn arákùnrin tó ti jáde nílé ẹ̀kọ́ yìí. Iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ń fi ìrẹ̀lẹ̀ ṣe láti mú kí ìtẹ̀síwájú bá gbogbo àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run tó sì ń ṣe àwọn míì láǹfààní ti mú èrè jìgbìnnì wá.—Òwe 10:22; 1 Pétérù 5:5.
Bí Wọ́n Ṣe Ṣètò Láti Lè Lọ Síbẹ̀
Ńṣe ni ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ ní láti gba ààyè ìsinmi níbi iṣẹ́ òòjọ́ wọn kí wọ́n tó lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Ìṣòro lèyí máa ń jẹ́ fún wọn nígbà míì. Ní ìpínlẹ̀ Hawaii, àwọn arákùnrin méjì kan tí wọ́n pè láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ yìí ní láti gba ààyè kúrò lẹ́nu iṣẹ́ olùkọ́ tí wọ́n ń ṣe. Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé Jèhófà á ran àwọn lọ́wọ́, wọ́n kọ lẹ́tà láti tọrọ ààyè, wọ́n sì ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi fẹ́ lọ sílé ẹ̀kọ́ náà àtàwọn àǹfààní tí wọ́n máa rí níbẹ̀. Wọ́n fún àwọn méjèèjì láàyè láti lọ.
Àwọn ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé táwọn Ẹlẹ́rìí kan bá tọrọ ààyè níbi iṣẹ́, èsì tí wọ́n máa fún wọn ni pé iṣẹ́ ti tán fún wọn nìyẹn tí wọ́n bá fi lè lọ. Síbẹ̀ wọ́n yàn láti lọ gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ ètò Jèhófà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn á mú kíṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ wọn. A rí lára àwọn wọ̀nyí táwọn tó gbà wọ́n síṣẹ́ tún pè padà sẹ́nu iṣẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti parí ilé ẹ̀kọ́ náà. A lè sọ pé báyìí ni ìpinnu tí wọ́n ṣe láti relé ẹ̀kọ́ náà ṣe lọ: Sọ fẹ́ni tó gbà ọ́ síṣẹ́, gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o sì fi ìyókù sílẹ̀ fún Jèhófà.—Sáàmù 37:5.
‘Àwọn Tí Jèhófà Kọ́’
Ìjìnlẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì ni wọ́n ń fọ̀sẹ̀ mẹ́jọ kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ náà. Àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà máa ń kọ́ bá a ṣe ṣètò àwa èèyàn Jèhófà láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, wọ́n sì tún máa ń kọ́ báwọn fúnra wọn ṣe máa jáfáfá sí i nínú lílo Bíbélì lóde ẹ̀rí, ní ìpàdé ìjọ àti láwọn àpéjọ.
Ẹnì kan tó ti jáde nílé ẹ̀kọ́ náà tó sì mọrírì ohun tó kọ́ níbẹ̀ kọ ọ̀rọ̀ yìí ránṣẹ́ sẹ́nì kan tí ò tíì lọ sílé ẹ̀kọ́ náà lákòókò yẹn, ó sọ sínú lẹ́tà yẹn pé: “Gbà bí mo ṣe sọ fún ẹ, wàá kọ́ babańlá ẹ̀kọ́ tó ò tíì kọ́ rí bó o bá débẹ̀. Ẹsẹ Bíbélì tó sọ pé ‘Jèhófà ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́’ á túbọ̀ wá nítumọ̀ sí i fún ẹ. Ohun tá a kọ́ níbẹ̀ tún ọkàn wa rọ, ó ń mú ká túbọ̀ lè fìwà jọ Kristi Jésù ká sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Wàá rí ohun tó ò tíì rí rí láyé ẹ nígbà tó o bá débẹ̀.”—Aísáyà 54:13.
Àwọn Oníwàásù, Olùṣọ́ Àgùntàn àti Olùkọ́
Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ilẹ̀ mẹ́tàdínlọ́gọ́fà [117] làwọn tó jáde ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti ń sìn. Lára àwọn ibi bẹ́ẹ̀ ni àwọn erékùṣù tó wà ní àgbègbè Òkun Àtìláńtíìkì, Caribbean àti Pàsífíìkì tó fi mọ́ èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà. Àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì ròyìn pé ẹ̀kọ́ tó jíire táwọn akẹ́kọ̀ọ́ kọ́ ń yọ lára wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, lẹ́nu iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn, àti nínú bí wọ́n ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ yìí mú kí wọ́n mọ Bíbélì lò dáadáa lóde ẹ̀rí. (2 Tímótì 2:15) Bí wọ́n bá ń dáhùn ìbéèrè lóde ẹ̀rí, lemọ́lemọ́ ni wọ́n máa ń tọ́ka sí ìwé Reasoning From the Scriptures,a wọ́n sì máa ń kọ́ àwọn akéde tó kù láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ìtara àwọn tó ti jáde ní ilé ìwé yìí ń ran àwọn míì, ìgbòkègbodò wọn sì ń fún àwọn ìjọ lókun.
Àwọn alàgbà ìjọ láǹfààní láti “máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run,” wọ́n ń ran àwọn ará lọ́wọ́ láti lè máa sin Ọlọ́run. (1 Pétérù 5:2, 3) Alàgbà kan sọ̀rọ̀ nípa ìṣètò náà pé: “A dúpẹ́ pé ẹ̀ka ọ́fíìsì rán àwọn arákùnrin tí wọ́n tí kọ́ dáadáa láti wá bá wa gbé ẹrù bíbójú tó agbo Ọlọ́run.” Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kan tó wà ní Ìpẹ̀kun Ìlà Oòrùn ayé sọ pé: “Aláàánú làwọn tó jáde ní ilé ẹ̀kọ́ yẹn. Wọ́n ṣiṣẹ́ ní àṣekára, gbogbo ìjọ ló sì bọ̀wọ̀ fún wọn gidigidi. Gbogbo ìjọ ló ń rí ìwà ìrẹ̀lẹ̀, ọ̀yàyà àti ìmúratán wọn, wọ́n sì mọrírì rẹ̀ gan-an. Tinútinú ni wọ́n fi máa ń yọ̀ǹda ara wọn, wọ́n sì máa ń fi tayọ̀tayọ̀ lọ sáwọn ìjọ míì tí wọ́n ti nílò olùṣọ́ àgùntàn.” (Fílípì 2:4) Irú àwọn ọkùnrin báyìí máa ń fún ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni bíi tiwọn lókun, wọ́n sì yẹ lẹ́ni tá à ń gbóṣùbà fún.—1 Kọ́ríńtì 16:18.
Láfikún sí i, àwọn olùkọ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ máa ń kọ́ àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ láti mọ àsọyé fún gbogbo èèyàn sọ dáadáa sí i. Bí ọ̀pọ̀ àwọn tó ti jáde níbẹ̀ ṣe ń fi ìmọ̀ràn àti àbá tí wọ́n rí gbà nílé ẹ̀kọ́ náà sílò, kì í pẹ́ tí wọ́n á fi dẹni tá a lè máa lò nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àyíká àti àgbègbè. Alábòójútó àyíká kan sọ pé àwọn tó jáde nílé ẹ̀kọ́ yìí máa ń “sọ àsọyé alárinrin wọ́n sì máa ń fi ìfòyemọ̀ gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀.”—1 Tímótì 4:13.
Lẹ́yìn tí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti wáyé lórílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà, tí wọ́n sì rán àwọn tó jáde níbẹ̀ lọ sìn ní pápá, ọ̀nà tí wọ́n ń gbà kọ́ni láwọn ìpàdé ìjọ ti yàtọ̀ gan-an. Àwọn alàgbà tí wọ́n rán jáde nílé ẹ̀kọ́ náà máa ń ṣèrànlọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn àti iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì ń tipa báyìí fún ìjọ lókun tẹ̀mí.—Éfésù 4:8, 11, 12.
Wọ́n Ń Mú Kí Ìjọ Ní Àbójútó Tó Tó
Ọ̀pọ̀ ibi ni wọ́n ti nílò àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ púpọ̀ sí i. Àwọn ìjọ kan ì bá máà ní alàgbà rárá tí kì í bá ṣe bí wọ́n ṣe rán àwọn tó jáde ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ sí wọn. Torí náà, ọ̀pọ̀ àwọn tó jáde nílé ẹ̀kọ́ yìí ni wọ́n ń rán sáwọn ibi tọ́rọ̀ wọn ti rí bẹ́ẹ̀.
Ọ̀pọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì ló ròyìn pé àwọn ọkùnrin yìí mọ “bí ètò Jèhófà ṣe ń ṣiṣẹ́ dáadáa,” “wọ́n ń fi ọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ wọn,” “wọ́n ń mú káwọn èèyàn túbọ̀ lóye ètò Jèhófà, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún un,” wọ́n ń “mú kí ẹ̀mí ọ̀yàyà máa gbilẹ̀ sí i nínú ìjọ, wọ́n sì ń mú kí ìgbàgbọ́ àwọn ará máa jinlẹ̀ sí i.” Ìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ yìí máa ń tẹ̀ lé ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọn kì í gbára lé òye ara wọn, wọn kì í sì í ṣe bí ẹní gbọ́n lójú ara wọn. (Òwe 3:5-7) Ìbùkún tẹ̀mí ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ́ fáwọn ìjọ tí wọ́n yàn wọ́n sí.
Àwọn Kan Ń Sìn Láwọn Ìpínlẹ̀ Àdádó
Àwọn kan lára àwọn tí wọ́n jáde nílé ẹ̀kọ́ yìí tí wọ́n yàn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ń lọ ran àwọn àwùjọ tó dá dúró lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ìjọ. Nígbà tí alàgbà kan ní ibi àdádó kan lágbègbè Guatemala ń dúpẹ́ fún ìrànlọ́wọ́ wọn, ó sọ pé: “Láti ogún ọdún ni mo ti ń ṣàníyàn nípa bá a ṣe máa kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù tó pọ̀ yìí. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti torí ọ̀ràn yìí gbàdúrà. Àwọn arákùnrin tí wọ́n lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ti gbẹ̀kọ́ tó yan-ran-n-tí lórí bá a ṣe ń sọ àsọyé àti bá a ṣe ń bójú tó ètò Jèhófà, inú mi sì dùn láti rí i pé wọ́n ti ń bójú tó ìpínlẹ̀ ìwàásù wa tìfẹ́tìfẹ́.”
Àwọn tó ti jáde nílé ẹ̀kọ́ yìí ti kọ́ bí wọ́n á ṣe ṣiṣẹ́ wọn bí iṣẹ́ láwọn ibi tí wọ́n ti ní láti rìn jìnnà lórí òkè kí wọ́n tó lè dé àwọn abúlé tó fọ́n ká gátagàta. Gbàrà tí wọ́n bá ti débẹ̀ ni wọ́n máa ń kó àwùjọ àdádó jọ, àní bó bá tiẹ̀ ṣòro fáwọn akéde míì láti dá àwùjọ bẹ́ẹ̀ sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Niger, alàgbà kan ní káwọn tó jáde nílé ẹ̀kọ́ yìí wá ran àwọn lọ́wọ́ torí ó gbà pé wọ́n á ṣe bẹbẹ lágbègbè ibi tóun ń gbé bí wọ́n bá débẹ̀. Ó lè rọrùn fáwọn tí kò níyàwó ju àwọn tó ní lọ láti lọ sìn bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe àti alábòójútó àyíká, pàápàá láwọn ibi àdádó. Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó ti di dandan fáwọn náà láti fara da ‘àwọn ewu odò, ewu dánàdánà, ewu nínú aginjù,’ àtàwọn ìnira míì, tó fi mọ́ àníyàn fáwọn ìjọ tí wọ́n ti ń sìn.—2 Kọ́ríńtì 11:26-28.
Wọ́n Ń Ṣàwọn Ọ̀dọ́ Láǹfààní
Bíbélì rọ àwọn ọ̀dọ́ pé kí wọ́n rántí Ẹlẹ́dàá wọn. (Oníwàásù 12:1) Àpẹẹrẹ àtàtà làwọn tó jáde ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ jẹ́ fáwọn ọ̀dọ́ Kristẹni. Lẹ́yìn táwọn méjì tó jáde ní ilé ẹ̀kọ́ yìí dé sí ìjọ kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, iye àkókò táwọn ará ń lò lóde ẹ̀rí di ìlọ́po méjì. Síwájú sí i, àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé, ìyẹn àwọn tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò, pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run di mọ́kànlá látorí méjì. Ohun tó sì sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìjọ nìyẹn.
Àwọn tó jáde nílé ẹ̀kọ́ yìí tún ti ran àwọn ọ̀dọ́kùnrin lọ́wọ́ láti ronú nípa lílọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Èyí sì ti mú káwọn kan tí kò tíì di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n ṣe máa láǹfààní yẹn. Ẹ̀ka ọ́fíìsì lórílẹ̀-èdè Netherlands pe àwọn tó jáde ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ní “àpẹẹrẹ táwọn ọ̀dọ́kùnrin tó ń ronú nípa ohun tí wọ́n máa fi ìgbésí ayé wọn ṣe lè tẹ̀ lé.”
Wọ́n Ń Sìn Láwọn Ìjọ Tí Wọ́n Ti Ń Sọ Èdè Àwọn Àjèjì
Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, akitiyan láti wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn ní èdè wọn ti légbá kan báyìí. Àwọn tó jáde ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ sábà máa ń kọ́ àwọn èdè míì, wọ́n sì máa ń lọ sìn láwọn ìpínlẹ̀ táwọn àjèjì tó wá gbé ìlú pọ̀ sí. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Belgium, wọ́n nílò oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run púpọ̀ sí i láti wàásù fáwọn tó ń sọ èdè Albanian, Páṣíà àti Rọ́ṣíà.
Àwọn tó jáde ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ló ń sìn bí alábòójútó àyíká, alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ láwọn ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè láwọn ilẹ̀ bí Amẹ́ríkà, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Ítálì, Jámánì, Mẹ́síkò àtàwọn ilẹ̀ mìíràn, wọ́n sì ń jàǹfààní wọn láwọn orílẹ̀-èdè yìí gan-an ni. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Kòríà ròyìn pé “ó lé ní igba lára àwọn tó ti jáde nílé ẹ̀kọ́ yìí tó ń ṣe bẹbẹ nínú ríran àwọn ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè lọ́wọ́.”
Wọ́n Ń Fi Ìrẹ̀lẹ̀ Ṣe Àwọn Iṣẹ́ Mìíràn
Yàtọ̀ sí pé àwọn tó ti jáde ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ń lọ sìn láwọn ìjọ àti àwùjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè, wọ́n tún ń sìn bí alàgbà, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti alábòójútó àyíká. Àwọn míì ò kọ̀ láti lọ sìn láwọn orílẹ̀-èdè míì, bóyá kí wọ́n lọ bójú tó iṣẹ́ tó ń fẹ́ àbójútó ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì kan. Àwọn tó mọ̀ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé nínú wọn lè yọ̀ǹda ara wọn láti kópa nínú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba.
Bí iye ìjọ àti àyíká ṣe ń pọ̀ sí i kárí ayé fi hàn pé a ó máa nílò àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò sí i ni. Ká bàa lè rẹ́ni máa ṣe iṣẹ́ yìí, àwọn kan lára àwọn tó jáde ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ máa ń lọ gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́sẹ̀-mẹ́wàá láti kọ́ iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò, lẹ́yìn náà wọ́n á di adelé alábòójútó àyíká tàbí kí wọ́n di alábòójútó àyíká. Nǹkan bí ẹ̀ẹ́dégbèje [1,300] àwọn tó ti jáde nílé ẹ̀kọ́ náà ló ń sìn bí alábòójútó arìnrìn-àjò láwọn orílẹ̀-èdè mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún [97]. Ní orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà, tá a bá fi gbogbo àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò tó wà níbẹ̀ dá ọgọ́rùn-ún, márùndínlọ́gọ́ta nínú wọn ló máa jẹ́ àwọn tó ti jáde ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Lórílẹ̀-èdè míì nílẹ̀ Áfíríkà, àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò ibẹ̀ ló jáde nílé ẹ̀kọ́ yìí.
Wọ́n ti rán ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn tó jáde nílé ẹ̀kọ́ yìí láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Ìpẹ̀kun Ìlà Oòrùn ayé, Kánádà, Ọsirélíà àti ilẹ̀ Yúróòpù láti lọ bójú tó àwọn ọ̀ràn kan pàtó tó ń fẹ́ àbójútó láwọn orílẹ̀-èdè míì. Lọ́nà yìí, kárí ayé ni wọ́n ti ń jàǹfààní ilé ẹ̀kọ́ náà.
Jèhófà ti lo Jésù Kristi Ọmọ rẹ láti yan àwọn oníwàásù, olùṣọ́ àgùntàn, olùkọ́ àtàwọn míì tó ń mú kí gbogbo àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba Ọlọ́run máa tẹ̀ síwájú láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Ǹjẹ́ ẹ̀rí wà pé àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣì máa pọ̀ sí i? Dájúdájú! Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó di dandan báyìí pé káwọn arákùnrin tó ti ya ara wọn sí mímọ́ wá bí wọ́n ṣe máa ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn púpọ̀ sí i. (Aísáyà 60:22; 1 Tímótì 3:1, 13) Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ máa ń mú káwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní àǹfààní láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i. Èrè ńláǹlà ló sì ń mú wá bá wọn àtàwọn ẹlòmíràn jákèjádò ayé.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ń mú kí àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run máa tẹ̀ síwájú jákèjádò ayé
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ṣó wu ìwọ náà láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ kó o lè ṣe àwọn míì láǹfààní?