ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 1/8 ojú ìwé 5-9
  • Kí Ló Ń Fa Ìháragàgà fún Ìsọfúnni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Ń Fa Ìháragàgà fún Ìsọfúnni?
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Ìwà Ọ̀daràn Orí Kọ̀ǹpútà Ṣe Lè Kàn Ọ́
  • Àìgbọ́dọ̀máṣe Láti Ní Ìmọ̀ Púpọ̀ Tó
  • Ǹjẹ́ Púpọ̀ Túmọ̀ Sí Dídára Jù?
  • Ìfẹ̀rọ-Fúnni-Nísọfúnni Ńkọ́?
  • Ṣé O Ti Gbọ́ Nípa Ìbẹ̀rù Ẹ̀rọ?
  • Ìṣejáde Ha Sunwọ̀n Sí I Ní Gidi Bí?
  • Àpọ̀jù Ìsọfúnni
    Jí!—1998
  • Bí O Ṣe Lè Kojú Sànmánì Onísọfúnni
    Jí!—1998
  • Wíwà ní Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì Nínú Lílo Ìmọ̀ Iṣẹ́ Ẹ̀rọ Kọ̀ǹpútà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ǹjẹ́ Ẹ̀kọ́ Ò Ti Wá Pọ̀ Jù fún Ọmọ Èèyàn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Jí!—1998
g98 1/8 ojú ìwé 5-9

Kí Ló Ń Fa Ìháragàgà fún Ìsọfúnni?

“ÀLÀFO tí ń fẹ̀ sí i ṣáá láàárín ohun tí a mọ̀ àti ohun tí a rò pé ó yẹ kí a mọ̀ ló ń fa ìháragàgà fún ìsọfúnni. Ó jẹ́ ohun tó ṣókùnkùn síni láàárín àwọn ìsọfúnni tó wà àti ìmọ̀ tí a ní, ó sì ń wáyé nígbà tí ìsọfúnni kò bá kúnjú ohun tí a fẹ́ láti mọ̀ tàbí tí ó yẹ kí a mọ̀.” Ohun tí Richard S. Wurman kọ nínú ìwé rẹ̀, Information Anxiety nìyẹn. “Láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, àwọn ènìyàn kò mọ bí ohun tí wọn kò mọ̀ ṣe pọ̀ tó—wọn kò mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ni ohun tí àwọn kò mọ̀. Àmọ́ nísinsìnyí, àwọn ènìyàn ti wá mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ni ohun tí àwọn kò mọ̀, ìyẹn ló sì ń mú wọn hára gàgà.” Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa lè rò pé ó yẹ kí a mọ̀ ju bí a ti mọ̀ lọ. Bí ìsọfúnni sì ṣe ń tú yàà dé ọ̀dọ̀ wa, a ń ṣa ìwọ̀n ìsọfúnni díẹ̀díẹ̀ jọ. Àmọ́ nígbà púpọ̀, a kì í lè pinnu ohun tí ó yẹ kí a fi wọ́n ṣe. Nígbà kan náà, a lè rò pé gbogbo ènìyàn tó kù ló mọ̀ jù wá lọ, tí wọ́n sì lóye jù wá lọ. Nígbà yẹn ni a ń hára gàgà!

David Shenk ṣàlàyé pé àpọ̀jù ìsọfúnni ti di aṣèbàjẹ́ tí ń dá “ìdojúrú ìsọfúnni” sílẹ̀. Ó fi kún un pé: “Ìdojúrú ìsọfúnni ń ṣèdíwọ́; kì í fàyè sílẹ̀ fún àwọn sáà ìparọ́rọ́, ó sì ń dabarú ìpọkànpọ̀ tí a nílò gidigidi. . . . Ó ń kó wa sí másùnmáwo.”

Òtítọ́ ní pe ọ̀pọ̀ yanturu ìsọfúnni tàbí àpọ̀jù ìsọfúnni lè fa hílàhílo, àmọ́ bákan náà ló rí bí a kò bá ní ànító ìsọfúnni, tàbí èyí tó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ìsọfúnni tí a ní kò bá tọ̀nà. Ńṣe ló dà bíi níní ìmọ̀lára ìdáwà nínú iyàrá tó kún fún ọ̀pọ̀ ènìyàn. Bí John Naisbitt ṣe sọ ọ́ nínú ìwé rẹ̀, Megatrends, “a ń rì sínú agbami ìsọfúnni, ṣùgbọ́n ebi ìmọ̀ ń pa wá.”

Bí Ìwà Ọ̀daràn Orí Kọ̀ǹpútà Ṣe Lè Kàn Ọ́

Pípọ̀ tí ìwà ọ̀daràn orí kọ̀ǹpútà ń pọ̀ sí i jẹ́ okùnfà míràn. Ọ̀mọ̀wé Frederick B. Cohen sọ ìdààmú tó ní jáde nínú ìwé rẹ̀, Protection and Security on the Information Superhighway, pé: “Ilé iṣẹ́ FBI [Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Ìjọba Àpapọ̀] fojú bù ú pé lọ́dọọdún, a ń pàdánù owó tó pọ̀ tó bílíọ̀nù márùn-ún dọ́là sórí ìwà ọ̀daràn orí kọ̀ǹpútà. Lọ́nà tí ó ṣòro láti gbà gbọ́, ìyẹn wulẹ̀ jẹ́ apá kékeré kan nínú ìṣòro ńlá kan ni. A ti ń kófà àwọn àìkúnjú-òṣùwọ̀n nínú àwọn ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ láti rọ́wọ́ mú nídìí ìdúnàádúrà, láti bani jẹ́, láti ṣẹ́gun nínú ìforígbárí ológun, àti láti mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn pàápàá.” Láfikún sí èyí ni ìdààmú tí a ń ní nípa bí àwọn ọmọdé ṣe ń láǹfààní láti wo àwọn ìran arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè lórí kọ̀ǹpútà—ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti títojúbọ àṣírí ẹlòmíràn.

Àwọn aláìtẹ̀lélànà olùfarajin-kọ̀ǹpútà ń mọ̀ọ́mọ̀ fi àṣẹ ìdarí burúkú tí ń ba ìsọfúnni inú kọ̀ǹpútà jẹ́ sínú àwọn ìgbékalẹ̀ kọ̀ǹpútà, wọ́n sì ń dá ìṣòro sílẹ̀. Àwọn ọ̀daràn olùṣàgbékalẹ̀ ètò orí kọ̀ǹpútà ń já wọnú ìgbékalẹ̀ abánáṣiṣẹ́ láìbófinmu, wọ́n sì ń gba ìsọfúnni àṣírí nípa àwọn ẹlòmíràn, kódà wọ́n ń jíni lówó nígbà míràn. Irú àwọn ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀ lè ní ipa amúnibanújẹ́ lórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ń lo kọ̀ǹpútà aládàáni. Ìwà ọ̀daràn orí kọ̀ǹpútà jẹ ewu kan fún ìṣòwò àti ìjọba.

Àìgbọ́dọ̀máṣe Láti Ní Ìmọ̀ Púpọ̀ Tó

Dájúdájú, ó yẹ kí gbogbo wa ní ìmọ̀ púpọ̀ tó, àmọ́, kò fi dandan túmọ̀ sí pé níní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìsọfúnni ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ní gidi, nítorí ọ̀pọ̀ nǹkan tí a ń wò bí ìsọfúnni kò ju àwọn kókó tàbí àkójọ ọ̀rọ̀ lásán tí a kò tí ì tò pọ̀ dáadáa, tí kò ní ṣe pẹ̀lú ìrírí tí a ní. Àwọn kan tilẹ̀ dábàá pé dípò tí a fi ń pe ìṣẹ̀lẹ̀ yí ní “àpọ̀jù ìsọfúnni,” ì bá sàn ká máa pè é ní “àpọ̀jù àkójọ ọ̀rọ̀,” tàbí lọ́nà tó túbọ̀ fi àìnígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé hàn, “àpọ̀jù àìnísọfúnni.” Bí alálàyé ètò ọrọ̀ ajé náà, Hazel Henderson, ṣe rí i sí ni pé: “Ìsọfúnni fúnra rẹ̀ kò mú kí a ní ìmọ̀. A kò lè ṣàlàyé ohun tó jẹ́ ìsọfúnni òdì, àìnísọfúnni, tàbí ìtànkálẹ̀ èrò lásán nínú àyíká tí ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde ti pọ̀ jaburata yìí. Pípọkànpọ̀ sórí ìsọfúnni lásán ti yọrí sí àpọ̀jù ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù èérún ìsọfúnni tí kò kún, tó wà lẹ́yọlẹ́yọ, láìnítumọ̀, dípò kó jẹ́ àwárí òye tuntun tó nítumọ̀.”

Joseph J. Esposito, ààrẹ Àjọ Ìṣejáde Ìwé Agbédègbẹ́yọ̀ Ilẹ̀ Britain, fìṣọ́ra ṣe ìdiwọ̀n yí pé: “Èyí tó pọ̀ jù nínú ìsọfúnni inú Sànmánì Onísọfúnni ló jẹ́ àfiṣòfò; ariwo lásán ni. Orúkọ náà, Àpọ̀jù Ìsọfúnni bá a mu gẹ́lẹ́; àpọ̀jù náà ń dí wa lọ́wọ́ gbígbọ́ ohunkóhun tó bó ṣe yẹ. Bí a ò bá lè gbọ́, a ò lè mọ̀.” Orrin E. Klapp ṣe àlàyé pé: “Mo rò pé kò sẹ́ni tó mọ bí àgbélẹ̀rọ ṣe pọ̀ tó nínú àwọn ìsọfúnni tí ará ìlú ń gbọ́, tó jọ pé ó ń sọ nǹkan fúnni, àmọ́ tí kò sọ ohunkóhun fúnni ní gidi.”

Láìsíyèméjì, o lè rántí pé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ tí o gbà nílé ẹ̀kọ́ jẹ́ láti mọ àwọn kókó ọ̀rọ̀ kí o lè yege nínú ìdánwò. Lọ́pọ̀ ìgbà ni o kọ́ àwọn kókó ọ̀rọ̀ lákọ̀ọ́sórí nígbà tí ìdánwò kù sí dẹ̀dẹ̀. Ǹjẹ́ o rántí bí o ṣe kọ́ àwọn déètì jàn-ànrànjan-anran sórí nínú ẹ̀kọ́ nípa ìtàn? Mélòó nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àti déètì wọ̀nyẹn ni o lè rántí nísinsìnyí? Ǹjẹ́ àwọn kókó ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn kọ́ ọ láti ronú, kí o sì dé orí ìpinnu tó fọgbọ́n yọ?

Ǹjẹ́ Púpọ̀ Túmọ̀ Sí Dídára Jù?

Bí a kò bá baralẹ̀ ṣàkóso rẹ̀, ìfarajìn láti gba àfikún ìsọfúnni lè náni lọ́pọ̀ àkókò, oorun, ìlera, àti owó pàápàá. Bí níní ìsọfúnni púpọ̀ sí i tilẹ̀ ń fúnni ní yíyàn púpọ̀ sí i, ó lè mú kí ẹni tí ń wá ìsọfúnni náà máa ṣàníyàn, ní dídààmú lórí bóyá òun ti ṣàyẹ̀wò gbogbo ìsọfúnni tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó, kí òun sì tú wọn palẹ̀. Ọ̀mọ̀wé Hugh MacKay kìlọ̀ pé: “Ní gidi, ìsọfúnni kì í ṣe ọ̀nà sí ìlanilójú. Nínú ara rẹ̀, ìsọfúnni kò tànmọ́lẹ̀ sórí ìtumọ̀ ìgbésí ayé wa. Ìwọ̀nba ni ohun tí ìsọfúnni lè ṣe nínú gbígba ìmọ̀. Ní tòótọ́, bíi ti àwọn ohun ìní mìíràn, ó lè jẹ́ ìdènà fún ọgbọ́n. A lè mọ àmọ̀jù, lọ́nà kan náà tí a lè gbà ní àníjù.”

Nígbà púpọ̀, láfikún sí bí ìsọfúnni púpọ̀ jaburata tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó lónìí ṣe ń dẹ́rù pa àwọn ènìyàn, ìjákulẹ̀ tí wọ́n ń ní nídìí gbígbìyànjú láti sọ ìsọfúnni di ohun tó yéni, tó nítumọ̀, tó sì kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ní tòótọ́ tún ń dẹ́rù pa wọ́n. A ti gbọ́ pé a lè “dà bí ẹnì kan tí òùngbẹ ń gbẹ ṣùgbọ́n tí a ní kí ó máa fi ìdérí ìka bomi mu láti ẹnu ẹ̀rọ omi panápaná. Bí ìsọfúnni tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ṣe pọ̀ tó àti ọ̀nà tí a sábà máa ń gbà fi fúnni ti mú kí púpọ̀ nínú rẹ̀ máà wúlò fún wa.” Nítorí náà, a ní láti pinnu ìsọfúnni tí ó tó lórí ìníyelórí àti ìwúlò rẹ̀ fún àwa fúnra wa, kì í ṣe lórí bí ó ti pọ̀ tó ní iye.

Ìfẹ̀rọ-Fúnni-Nísọfúnni Ńkọ́?

Èdè ọ̀rọ̀ míràn tó tún wọ́pọ̀ lónìí ni “ìfẹ̀rọ-fúnni-nísọfúnni.” Èyí tọ́ka sí fífi ìsọfúnni ránṣẹ́ lórí ẹ̀rọ. Nígbà tí èyí ní àyè pàtàkì tirẹ̀, kì í ṣe ìbánisọ̀rọ̀ gbígbámúṣé ní èrò ìtumọ̀ kíkún. Èé ṣe? Nítorí pé àwọn ènìyàn la ń bá fara rora, kì í ṣe àwọn ẹ̀rọ. Nígbà tí a bá ń fẹ̀rọ fúnni nísọfúnni, a kò lè rí ojú ẹni, kò sí ìfojúkojú tàbí ìfara-ṣàpèjúwe, tó sábà máa ń jẹ́ kí ìjíròrò nítumọ̀, tó sì ń fi ìmọ̀lára hàn. Nínú ìjíròrò ojúkojú, àwọn kókó wọ̀nyí ń ṣàfikún àwọn ọ̀rọ̀ tí a lò, wọ́n sì sábà ń mú kí ọ̀rọ̀ ṣe kedere. Kò sí èyíkéyìí nínú àwọn ohun iyebíye tí ń jẹ́ ká lóye wọ̀nyí lárọ̀ọ́wọ́tó nígbà tí a bá ń fi ẹ̀rọ fúnni nísọfúnni, kò tilẹ̀ sí lórí ẹ̀rọ tẹlifóònù alágbèérìn tó túbọ̀ ń gbajúmọ̀ sí i. Kódà, ìjíròrò ojúkojú pàápàá kò gbé ohun tó wà lọ́kàn ẹni tí ń sọ̀rọ̀ jáde gẹ́lẹ́ nígbà míràn. Olùgbọ́ lè gbọ́ ọ̀rọ̀ lọ́nà tirẹ̀, kí ó tú u palẹ̀ lọ́nà tirẹ̀, kí ó sì fún un ní ìtumọ̀ òdì. Ẹ wá wo bí ewu yìí yóò ti pọ̀ tó, nígbà tí a kò lè rí asọ̀rọ̀ náà!

Òtítọ́ kan tí ń múni kédàárò nínú ìgbésí ayé ni pé, àkókò púpọ̀ jù tí àwọn kan ń lò nídìí kọ̀ǹpútà àti tẹlifíṣọ̀n sábà máa ń sọ àwọn mẹ́ńbà ìdílé pàápàá di àjèjì sí ara wọn nínú ilé wọn gan-an.

Ṣé O Ti Gbọ́ Nípa Ìbẹ̀rù Ẹ̀rọ?

Ní ṣákálá, “ìbẹ̀rù ẹ̀rọ” túmọ̀ sí “ìbẹ̀rù ohun amáyédẹrùn tí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ń pèsè,” títí kan lílo kọ̀ǹpútà àti àwọn ohun abánáṣiṣẹ́ tó jọ ọ́. Àwọn kan gbà pé èyí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn hílàhílo wíwọ́pọ̀ jù tí sànmánì onísọfúnni mú wá. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé agbéròyìnjáde The Canberra Times, tí a gbé karí ìròyìn kan tí àjọ akóròyìnjọ Associated Press gbé jáde, kà pé: “Àwọn Ọ̀gá Àgbà Ilé Iṣẹ́ Ńláńlá Ilẹ̀ Japan Ń Bẹ̀rù Kọ̀ǹpútà.” Wọ́n sọ nípa olùdarí àgbà ilé iṣẹ́ ńlá kan ní Japan pé: “[Ó] ní agbára àti ipò. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ó jókòó ti kọ̀ǹpútà, ojora yóò sì mú un.” Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí a fi 880 ilé iṣẹ́ ńláńlá ní Japan ṣe ti fi hàn, ìpín 20 péré nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀gá àgbà wọn ló lè lo kọ̀ǹpútà.

Àwọn ìjábá ńláńlá bíi ti àìṣiṣẹ́ tẹlifóònù ní New York City lọ́dún 1991, tó da iṣẹ́ àwọn ibùdókọ̀ òfuurufú abẹ́lé rú fún ọ̀pọ̀ wákàtí ló ń túbọ̀ fún ìbẹ̀rù ẹ̀rọ lágbára sí i. Ìjàǹbá Ibùdó Agbára Átọ́míìkì Erékùṣù Three Mile ní United States, ní 1979 ńkọ́? Ó gba àwọn tí ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ ní ọ̀pọ̀ wákàtí iṣẹ́ àṣekára kí wọ́n tó lè lóye ohun tí àmì ìdágìrì tí kọ̀ǹpútà ń darí túmọ̀ sí.

Ìwọ̀nyí jẹ́ díẹ̀ lára àwọn àpẹẹrẹ bí ìmọ̀ ẹ̀rọ sànmánì onísọfúnni náà ṣe nípa gidigidi tó lórí ìran ènìyàn. Ọ̀mọ̀wé Frederick B. Cohen béèrè àwọn ìbéèrè amúnironú wọ̀nyí nínú ìwé rẹ̀ pé: “Ǹjẹ́ o ti lọ sí báńkì láìpẹ́ yìí bí? Bí àwọn kọ̀ǹpútà kò bá ṣiṣẹ́, ǹjẹ́ o lè rówó gbà? Ilé ìtajà ńlá ńkọ́? Wọ́n ha lè ṣírò ọjà tí o rà kí wọ́n sì gbowó lọ́wọ́ rẹ láìsí kọ̀ǹpútà wọn tí ń ṣiṣẹ́ náà bí?”

Bóyá ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú àwọn ipò àfinúrò wọ̀nyí lè bá ọ mu:

• Ó jọ pé bọ́tìnnì pọ̀ jù lórí ẹ̀rọ fídíò (VCR) rẹ tuntun nígbà tí o fẹ́ fi gba ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan sílẹ̀. Bóyá o kúkú ké sí ọmọ àbúrò rẹ tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án kó wá bá ọ tẹ bọ́tìnnì tó yẹ lórí VCR náà, tàbí o kúkú pinnu níkẹyìn pé o kò fi bẹ́ẹ̀ nílò ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà.

• O nílò owó ní pàjáwìrì. O wakọ̀ lọ sídìí ẹ̀rọ aṣírò owó adáṣiṣẹ́ tó sún mọ́ ọ jù, àmọ́ o wá rántí lójijì pé, nígbà tí o lò ó kẹ́yìn, ó dà rú mọ́ ọ lójú, tó fi jẹ́ pé bọ́tìnnì tí kò yẹ lo tẹ̀ nígbà náà.

• Tẹlifóònù ọ́fíìsì dún. Wọ́n ṣe àṣìṣe láti darí rẹ̀ sọ́dọ̀ rẹ. Ọ̀gá rẹ tó wà ní àjà tó wà lókè ló ni ìtẹ̀láago náà. Ọ̀nà tó rọrùn kan wà láti darí rẹ̀ sí àjà tó wà lókè náà, ṣùgbọ́n, nítorí tí kò dá ọ lójú, o pinnu pé kí òṣìṣẹ́ tí ń darí ìtẹniláago bá ọ darí rẹ̀.

• Àyè ìpèsè ìsọfúnni níbi ìwakọ̀ ọkọ̀ rẹ tuntun jọ ti ọkọ̀ òfuurufú ayára-bí-àṣá òde òní. Lójijì, iná pupa kan tàn, ìdààmú sì bá ọ nítorí o kò mọ ohun tí iná náà túmọ̀ sí. O wá ní láti ṣàyẹ̀wò ìwé ìtọ́ni kan tí àlàyé kíkún wà nínú rẹ̀.

Ìwọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ díẹ̀ nípa ìbẹ̀rù ẹ̀rọ. Ó lè dá wa lójú pé ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ yóò máa mú àwọn ohun èlò dídíjú sí i jáde, tí ó dájú pé àwọn ènìyàn ìran tó ti kọjá ì bá ti pè ní “iṣẹ́ ìyanu.” Ọ̀kọ̀ọ̀kan ohun àṣejáde tí a mú bágbà mu, tí ń gorí àtẹ, ló ń gba ìmọ̀ púpọ̀ sí i nípa lílò rẹ̀, bí a óò bá lò ó lọ́nà gbígbéṣẹ́. Àwọn ìwé ìtọ́ni, tí àwọn ògbóǹkangí fi àkànlò èdè wọn kọ,a ń fúnra wọn bani lẹ́rù nígbà tí wọ́n bá wulẹ̀ rò pé ẹni tí yóò lò ó náà lóye àṣàyàn èdè tí a fi kọ ọ́, ó sì ní àwọn ìmọ̀ àti òye iṣẹ́ kan.

Olùṣàgbékalẹ̀ àbá lórí ìsọfúnni náà, Paul Kaufman, ṣàkópọ̀ ọ̀ràn náà báyìí: “Àwùjọ wa ní èrò kan nípa ìsọfúnni, tó jẹ́ pé, bí ó tilẹ̀ fani mọ́ra, kò sèso rere níkẹyìn. . . . Ìdí kan ni pé a ti darí àfiyèsí púpọ̀ jù sórí kọ̀ǹpútà àti àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀, àfiyèsí kò sì pọ̀ tó lórí àwọn ènìyàn gan-an tí ń lo ìsọfúnni láti lóye àgbáyé, kí wọ́n sì ṣe àwọn ohun wíwúlò fún ẹnì kíní-kejì. . . . Ìṣòro náà kì í ṣe ti pé a ń bọlá fún kọ̀ǹpútà jù ṣùgbọ́n, ó jẹ́ ti pé a ń fojú tín-ínrín àwọn ẹ̀dá ènìyàn jù.” Ó jọ pé pípọkànpọ̀ sórí ìyìn tí a ó gbà nítorí fífi ìmọ̀ ẹ̀rọ mú àwọn ohun amáyédẹrùn kíkàmàmà jáde ti sábà máa ń fi àwọn ènìyàn sí ipò ìdààmú lórí ohun tó kàn, tí a óò mú jáde. Edward Mendelson wí pé: “Kò lè ṣeé ṣe láé fún àwọn alálàá ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ láti mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tó ṣeé ṣe yọrí àti ohun títóótun. Bí a bá lè ṣe ẹ̀rọ kan ti yóò ṣe iṣẹ́ dídíjú kan tó jọni lójú, nígbà náà, alálàá náà gbà pé iṣẹ́ náà tóótun láti ṣe.”

Gbígbójúfo ipa ti ẹ̀dá ènìyàn yí nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ti dá kún ìháragàgà fún ìsọfúnni lọ́nà lílékenkà.

Ìṣejáde Ha Sunwọ̀n Sí I Ní Gidi Bí?

Nígbà tí akọ̀ròyìn Paul Attewell ń kọ̀wé nínú ìwé agbéròyìnjáde The Australian, ó sọ nípa ìwádìí tí ó ṣe lórí iye àkókò àti owó tí a fi pa mọ́ ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́ nítorí ìlò kọ̀ǹpútà. Díẹ̀ lára àwọn kókó tí ó sọ ní kedere nìwọ̀nyí: “Láìka ọ̀pọ̀ ọdún tí a ti lò lórí àwọn ìgbékalẹ̀ ìlò kọ̀ǹpútà láti ṣe àwọn iṣẹ́ àbójútó àti láti dín ìnáwó kù sí, ọ̀pọ̀ yunifásítì àti kọ́lẹ́ẹ̀jì rí i pé iye àwọn òṣìṣẹ́ àbójútó wọn wulẹ̀ ń pọ̀ sí i ni. . . . Fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, àwọn tí ń ṣe kọ̀ǹpútà jáde ti sọ pé àwọn ohun èlò oníṣẹ́ ẹ̀rọ tí àwọn ń tà yóò mú àṣeyọrí ńláǹlà wá nínú ìṣejáde, tí yóò jẹ́ kí a lè ṣe àwọn iṣẹ́ àbójútó kan yọrí pẹ̀lú iye òṣìṣẹ́ tó dín kù gan-an, tó sì dín ìnáwó kù. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí a ti wá ń mọ̀, àwọn ohun amáyédẹrùn onísọfúnni ti yọrí sí àṣìlò ìsapá: a ń ṣe ọ̀pọ̀ ohun tuntun nípa lílo iye òṣìṣẹ́ kan náà tàbí tí ó pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ dípò kí àwọn òṣìṣẹ́ tí kò pọ̀ tó ti tẹ́lẹ̀ máa ṣe iṣẹ́ àtilẹ̀wá náà. Lọ́pọ̀ ìgbà, a kò fi owó kankan pa mọ́. Àpẹẹrẹ kan ní ti àṣìlò yí ni pé àwọn ènìyàn ń lo ohun amáyédẹrùn tí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ń pèsè láti mú kí ìrísí àwọn àkọsílẹ̀ túbọ̀ jojú ní gbèsè ju wíwulẹ̀ jẹ́ kí iṣẹ́ orí ìwé túbọ̀ yára kánkán.”

Ní báyìí, ó jọ pé ọ̀nà márosẹ̀ ìsọfúnni, tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ewu fún àwọn Kristẹni, ti di apá kan ọ̀nà ìgbésí ayé. Àmọ́, báwo ni a ṣe lè yẹra fún ìháragàgà fún ìsọfúnni—ó kéré tán, dé ìwọ̀n kan? A pèsè àwọn àbá gbígbéṣẹ́ mélòó kan nínú àpilẹ̀kọ kúkúrú tó kàn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àpẹẹrẹ àkànlò èdè kọ̀ǹpútà ni: log on, tó túmọ̀ sí “wọlé sínú ìlò ìgbékalẹ̀ ẹ̀rọ”; boot up, tó túmọ̀ sí “bẹ̀rẹ̀ tàbí mú ṣiṣẹ́”; portrait position, tó túmọ̀ sí “lóòró”; landscape position, tó túmọ̀ sí “nídùbúlẹ̀.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Àpọ̀jù Pàǹtírí Ìsọfúnni

“Gẹ́gẹ́ bí ìrírí tí gbogbo wa ń ní, àwùjọ ti túbọ̀ ń gọ̀ sí i láìdábọ̀. A ń fojú rí ìjẹgàba àwọn pàrùpárù ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n, àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí rédíò tí a wéwèé láti fa ìkórìíra, àwọn asọ̀rọ̀ lórí rédíò tí ń fi ọ̀rọ̀ rírùn ṣe fọ́nńté, àwọn ọ̀rọ̀ ìfiniṣẹ̀sín àti ti ìwà ipá tó bùáyà. Àwọn fíìmù túbọ̀ ń fi ìbálòpọ̀ hàn, wọ́n sì ń kún fún ìwà ipá. Ìpolówó túbọ̀ jẹ́ aláriwo, tí ń kógun tini, tó sì sábà máa ń jẹ́ èyí tí kò dùn mọ́ni . . . Ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ ń pọ̀ sí i, ọ̀rọ̀ ọmọlúwàbí sì ń dín kù. . . . Ohun tí àwọn mìíràn ti pè ní ‘yánpọnyánrin nínú ohun àgbélárugẹ ìdílé’ wa kan ìyípadà tegbòtigaga nínú ìsọfúnni ju bí ó ti kan àìlọ́wọ̀ fún ìṣètò ìdílé lọ́nà àdáyébá ní Hollywood lọ.”—Data Smog—Surviving the Information Glut, láti ọwọ́ David Shenk.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

Ọgbọ́n Ọ̀nà Àtijọ́ Náà

“Ọmọ mi, bí ìwọ bá fẹ́ gba ọ̀rọ̀ mi, kí ìwọ sì pa òfin mi mọ́ pẹ̀lú rẹ, tí ìwọ dẹtí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n, tí ìwọ sì fi ọkàn sí òye; àní bí ìwọ bá ń ké tọ ìmọ̀ lẹ́yìn, tí ìwọ sì gbé ohùn rẹ sókè fún òye; bí ìwọ bá ṣàfẹ́rí rẹ̀ bíi fàdákà, tí ìwọ sì ń wá a kiri bí ìṣúra tí a pa mọ́; nígbà náà ni ìwọ ó mọ ìbẹ̀rù Olúwa, ìwọ ó sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run. Nítorí Olúwa ní ń fi ọgbọ́n fúnni: láti ẹnu rẹ̀ jáde ni ìmọ̀ àti òye ti ń wá. Nígbà tí ọgbọ́n bá wọ inú rẹ lọ, tí ìmọ̀ sì dùn mọ́ ọkàn rẹ; ìmòye yóò pa ọ́ mọ́, òye yóò sì máa ṣọ́ ọ.”—Òwe 2:1-6, 10, 11

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

A ti fi àpọ̀jù ìsọfúnni wé gbígbìyànjú láti fi ìdérí ìka gbe omi láti ẹnu ẹ̀rọ omi panápaná

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́