ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/03 ojú ìwé 3-4
  • Wíwà ní Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì Nínú Lílo Ìmọ̀ Iṣẹ́ Ẹ̀rọ Kọ̀ǹpútà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwà ní Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì Nínú Lílo Ìmọ̀ Iṣẹ́ Ẹ̀rọ Kọ̀ǹpútà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ohun Tó Lè Mú Kí Iṣẹ́ Ìtumọ̀ Èdè Rọrùn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Kí Ló Ń Fa Ìháragàgà fún Ìsọfúnni?
    Jí!—1998
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 12/03 ojú ìwé 3-4

Wíwà ní Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì Nínú Lílo Ìmọ̀ Iṣẹ́ Ẹ̀rọ Kọ̀ǹpútà

1 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn wọn níyà, nítorí pé “àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù.” (1 Kọ́r. 7:29) Bí òpin ètò ògbólógbòó yìí ti ń sún mọ́lé, ohun kánjúkánjú mà ni o láti máa ‘wá Ìjọba náà àti òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́,’ ká sì máa ‘ra àkókò tí ó rọgbọ padà’! Àkókò ṣeyebíye gan-an.—Mát. 6:33; Éfé. 5:15, 16.

2 Àwọn èèyàn máa ń sọ pé ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ máa ń dín àkókò kù gan-an. Bí àpẹẹrẹ, nípa wíwulẹ̀ tẹ bọ́tìnnì kan lára kọ̀ǹpútà, ẹni tó ń lò ó lè rí ọ̀pọ̀ jaburata ìsọfúnni lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì lójú ẹsẹ̀. Láàárín ìṣẹ́jú àáyá díẹ̀, kọ̀ǹpútà lè ṣe iṣẹ́ tí ì bá gbani ní ọ̀pọ̀ wákàtí tàbí ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ láti ṣe ní àwọn ọ̀nà mìíràn. Bí a bá lò ó bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, ohun èlò tó ń ranni lọ́wọ́ ni.

3 Ṣé Lóòótọ́ Ló Máa Dín Àkókò Kù?: Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ohun tí irú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ bẹ́ẹ̀ ń náni kì í ṣe kékeré rárá o, nítorí pé bó ṣe ń náni lówó ló tún ń gba àkókò. Ó lè gbani ní ọ̀pọ̀ wákàtí láti mọ bí a ṣe ń lo kọ̀ǹpútà fún ṣíṣe àwọn ohun kan. Síwájú sí i, ẹni tí kọ̀ǹpútà bá ti gbà lọ́kàn gidigidi lè máa fi àkókò tí ì bá lò fún àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù ṣòfò. A gbọ́dọ̀ wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, nípa fífi ìlànà tó wà nínú ọ̀rọ̀ ìṣílétí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ́kàn pé ká máa rìn “gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara [wa].”—Wo 1 Kọ́ríńtì 7:31.

4 Ọ̀pọ̀ àwọn ará tó ní èrò tó dára lọ́kàn ti fúnra wọn ṣe àwọn àkójọ ìlànà tí kọ̀ǹpútà fi ń ṣiṣẹ́ fún pípa àwọn àkọsílẹ̀ ìjọ mọ́. Ní tòótọ́, bó bá ṣe wu kálukú ló ṣe lè lo kọ̀ǹpútà rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, kò yẹ ká máa fi àwọn àkọsílẹ̀ ìjọ tí fọ́ọ̀mù wà fún pa mọ́ sórí kọ̀ǹpútà, nítorí pé àwọn ọmọdé tàbí àwọn ẹlòmíràn tí kò lẹ́tọ̀ọ́ láti rí irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ lè rí wọn. A ní láti fi gbogbo àkọsílẹ̀ ìjọ, irú bí àkọsílẹ̀ ìnáwó, káàdì Congregation’s Publisher Record [Àkọsílẹ̀ Ìròyìn Akéde Ìjọ] àtàwọn mìíràn bẹ́ẹ̀, pa mọ́ sórí àwọn fọ́ọ̀mù tí ètò àjọ náà pèsè, a kò sì gbọ́dọ̀ fi àwọn ìsọfúnni tó wà nínú àwọn fọ́ọ̀mù ìjọ wọ̀nyí pa mọ́ sórí kọ̀ǹpútà. Nípa báyìí, yóò ṣeé ṣe láti pa àwọn àkọsílẹ̀ tó jẹ́ àṣírí nípa ìjọ mọ́.

5 Àwọn alábòójútó tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ ní láti máa lo òye tí wọ́n bá ń yan iṣẹ́ fún àwọn ará nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Ó yẹ kí wọ́n máa ronú jinlẹ̀ nípa ìsọfúnni tí a fẹ́ bójú tó nínú iṣẹ́ kan ní pàtó. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, àwọn iṣẹ́ kan wà tó jẹ́ pé ó lè má ṣeé ṣe fún akẹ́kọ̀ọ́ èyíkéyìí láti bójú tó wọn. Ó yẹ kí àwọn alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ máa ṣàgbéyẹ̀wò ìdí tí a fi fẹ́ ṣe iṣẹ́ kan, kí wọ́n sì tún máa pe àfiyèsí sí bí ẹni tó fẹ́ bójú tó o ṣe tóótun sí àti irú ọ̀rọ̀ tó jẹ́. Kò yẹ kó jẹ́ pé ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà la máa jẹ́ kó ṣe àwọn ìpinnu wọ̀nyí.

6 Arákùnrin tí a bá yan iṣẹ́ kan fún láti bójú tó ní ìpàdé ìjọ kò ní láti dara dé ìsọfúnni tí ẹlòmíràn ti pèsè sílẹ̀, pàápàá ẹni tí kò mọ̀ rí, kìkì nítorí pé wọ́n ti fi sínú ètò orí kọ̀ǹpútà tí wọ́n fi ń ta ìsọfúnni látagbà, tí lílò ó kò sì ní jẹ́ kó ṣe ìsapá kankan. Àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú kì í kọjá àyè wọn nípa mímúra àsọyé Bíbélì tàbí àwọn iṣẹ́ kan nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé sílẹ̀, kí wọ́n wá fi sínú ètò orí kọ̀ǹpútà tá a fi ń ta ìsọfúnni látagbà kí àwọn ẹlòmíràn lè rí i lò. Àmọ́ o, ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà àti Watchtower Library on CD-ROM [Àkójọ Ìtẹ̀jáde Society Tá A Ṣe Sórí Ike Pẹlẹbẹ Tá À Ń Fi Kọ̀ǹpútà Lò] lè wúlò gan-an fún arákùnrin kan láti lò, níwọ̀n bí àwọn ohun èlò wọ̀nyí á ti mú kó ṣeé ṣe fún un láti ṣèwádìí tó gbéṣẹ́ láàárín ìwọ̀nba àkókò tó ní.

7 Ní ti ṣíṣe àdàkọ àwọn àkójọ ìlànà tí kọ̀ǹpútà fi ń ṣiṣẹ́ tí ẹnì kan ṣe fúnra rẹ̀, tàbí àwọn ìsọfúnni tí ẹnì kan ti ṣètò sílẹ̀ lórí kọ̀ǹpútà àti irú àwọn àkọsílẹ̀ mìíràn bẹ́ẹ̀ àti pípín wọn kiri láàárín àwọn arákùnrin, títí kan mímúra àwọn iṣẹ́ kan sílẹ̀ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn àti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti pípín in kiri nípa lílo àwọn ohun abánáṣiṣẹ́ tàbí lọ́nà mìíràn, ohun tó ti dára jù ni pé kí àwọn arákùnrin máa fúnra wọn múra iṣẹ́ wọn sílẹ̀, ní fífi àwọn ohun tó lè ṣàǹfààní fún àwọn ará tó wà nínú ìjọ sọ́kàn. (1 Tím. 4:13, 15) A kò gbọ́dọ̀ lo àǹfààní àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ará nínú ìjọ láé gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti pawó.

8 Ojú wo ló yẹ ká fi wo ṣíṣe ìpínkiri àwọn ìwé tí a ti fi kọ̀ǹpútà tẹ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ sí, irú bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a fà yọ nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tàbí ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ? Ohun tí ì bá dára jù lọ pé kí àwọn akéde ṣe ni pé kí wọ́n fúnra wọn kọ ọ̀rọ̀ ṣókí tàbí kí wọ́n sàmì sínú Bíbélì wọn àti sínú ìtẹ̀jáde tí à ń kà. Ní ìpàdé, lílo àwọn ìwé tí a ti tẹ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a fà yọ nínú ìtẹ̀jáde sí kò ní jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti máa lo Bíbélì fúnra rẹ̀ láti fi wá ẹsẹ Ìwé Mímọ́. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, wíwo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ nígbà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá ń lọ lọ́wọ́ tàbí ní ìpàdé ìjọ jẹ́ ara ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí à ń gbà, èyí tó ń mú wa gbára dì láti lè máa lo Bíbélì lọ́nà gbígbéṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Lọ́pọ̀ ìgbà, àti ní pàtàkì jù lọ nígbà tí a bá fẹ́ ka àyọkà tó gùn, kíka Bíbélì jáde tààràtà ló gbéṣẹ́ jù, pàápàá nígbà tí a bá rọ àwùjọ láti máa fi ojú bá kíkà náà lọ nínú Bíbélì tiwọn.

9 Àwọn Ewu Bíburú Jáì Mìíràn Tó Fara Sin: Gẹ́gẹ́ bí ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà ti August 1, 1993, ṣe sọ ní ojú ìwé 17, wíwá ìsọfúnni lọ síbi tí àwọn èèyàn ń fi ìsọfúnni sí nínú kọ̀ǹpútà lè jẹ́ kéèyàn kó sínú ewu tẹ̀mí tó burú jáì. Gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyànkéèyàn kan ṣe lè fi àkójọ ìsọfúnni kan tí wọ́n ń pè ní virus, tí wọ́n ṣe láti fi da àwọn ìsọfúnni tó wà lórí kọ̀ǹpútà rú tàbí láti fi bà wọ́n jẹ́, sí ibi tí a ti lè rí ìsọfúnni lórí kọ̀ǹpútà, bákan náà ló ṣe rọrùn fún àwọn apẹ̀yìndà, àwọn àlùfáà àtàwọn èèyàn tó ń wá ọ̀nà láti sọ àwọn ẹlòmíràn di oníwàkiwà tàbí láti mú wọn ṣìwà hù lọ́nà mìíràn láti fi àwọn èròǹgbà wọn tó lè ṣàkóbá fúnni síbẹ̀. Àwọn ibi tí a ti lè rí ìsọfúnni lórí kọ̀ǹpútà, kódà èyí tí a pè ní “JW Only” [Fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Nìkan] pàápàá, lè jẹ́ kí àwọn Kristẹni kó “ẹgbẹ́ búburú,” àyàfi bí a bá mójú tó o bó ṣe yẹ, tó sì jẹ́ pé kìkì àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà olóòótọ́ tí wọ́n dàgbà dénú nìkan ló ń lò ó. (1 Kọ́r. 15:33) Ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa ti gba àwọn ìròyìn kan pé irú àwọn ètò àdáni bẹ́ẹ̀ tó wà fún títa ìsọfúnni látagbà ni wọ́n ti lò fún míméfò nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí. Ìyẹn nìkan kọ́ o, wọ́n tún ń lò ó láti fúnni ní ìmọ̀ràn burúkú, láti tan òfófó àti ìsọfúnni èké kálẹ̀, láti gbin èrò tí kò tọ́ síni lọ́kàn, láti gbé ìbéèrè àti iyèméjì tó lè ṣàkóbá fún ìgbàgbọ́ àwọn kan dìde, àti láti tan àwọn àlàyé tí àwọn kan fúnra wọn ṣe lórí Ìwé Mímọ́ kálẹ̀. Béèyàn bá kọ́kọ́ rí àwọn ìsọfúnni kan, ó lè dà bíi pé wọ́n fani mọ́ra wọ́n sì ń lani lóye, síbẹ̀ ó ṣeé ṣe kí àwọn ohun tó lè pani lára fara sin sínú wọn. “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” làwọn Kristẹni gbára lé fún oúnjẹ tẹ̀mí tó bá àkókò mu àti fún ìlàlóye. (Wo Ilé-Ìṣọ́nà ti July 1, 1994, ojú ìwé 9 sí 11.) Ẹrù iṣẹ́ pàtàkì ló jẹ́ fún Kristẹni kọ̀ọ̀kan láti dáàbò bo ìgbàgbọ́ rẹ̀ kí ohunkóhun má bàa sọ ọ́ dìbàjẹ́. Ní pàtàkì jù lọ, ó tún ní láti mọ àwọn tí òún á máa bá kẹ́gbẹ́.—Mát. 24:45-47; 2 Jòh. 10, 11.

10 Àpilẹ̀kọ Ilé-Ìṣọ́nà yẹn kan náà sọ ìjẹ́pàtàkì bíbọ̀wọ̀ fún àwọn òfin ẹ̀tọ́ oníǹkan. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn iléeṣẹ́ tó ń pèsè àkójọ ìlànà tí kọ̀ǹpútà fi ń ṣiṣẹ́, tí wọ́n sì ń tà wọ́n, ló jẹ́ pé wọ́n máa ń ní ẹ̀tọ́ oníǹkan lórí wọn, wọ́n sì máa ń fúnni ní ìwé àṣẹ tó ń ṣàlàyé bí a ṣe lè lo àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ inú rẹ̀ lọ́nà tó bófin mu. Ìwé àṣẹ ọ̀hún sábà máa ń sọ pé ẹni tó rà á kò láṣẹ láti fún àwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀dà àkójọ ìlànà náà; àní, òfin ẹ̀tọ́ oníǹkan lágbàáyé fi hàn pé kò bófin mu láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn oníwọra ẹ̀dá ló máa ń rú òfin yìí láìwẹ̀yìn wò. Àmọ́, ó yẹ kí àwọn Kristẹni jẹ́ olóòótọ́ nínú ọ̀ràn òfin, kí wọ́n máa san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì.—Mát. 22:21; Róòmù 13:1.

11 Àwọn iléeṣẹ́ ńláńlá kan máa ń ta àwọn kọ̀ǹpútà tí àkójọ ìlànà tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ bá wọn wá, tí wọ́n sì ti fàṣẹ sí wọn. Àmọ́, àwọn ilé ìtajà kan tó ń ta kọ̀ǹpútà kì í pèsè ìwé àṣẹ nítorí pé ẹ̀dà àwọn àkójọ ìlànà tí wọ́n ń ṣe sínú kọ̀ǹpútà tí wọ́n ń tà kò bófin mu, èyí tó túmọ̀ sí pé ẹni tó bá rà á rú òfin nípa lílo àwọn àkójọ ìlànà náà. Níbàámu pẹ̀lú èyí, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ yẹra fún fífi àwọn ìsọfúnni tó ní ẹ̀tọ́ oníǹkan (irú bí àwọn ìtẹ̀jáde Society) sí ibi tí a ti lè rí ìsọfúnni lórí kọ̀ǹpútà tàbí mímú irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ níbẹ̀; bákan náà, wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe èyí láìgba ìyọ̀ǹda tó bófin mu látọ̀dọ̀ oníǹkan.—Héb. 13:18.

12 A gbọ́dọ̀ gbé àǹfààní tó wà nínú ohun èlò ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ èyíkéyìí yẹ̀ wò ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn ewu tó ṣeé ṣe kó wà nínú lílò ó. Gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ pé a lè lo tẹlifíṣọ̀n lọ́nà tó lè ṣeni láǹfààní, ipa búburú tó ń ní lórí aráyé lóde òní ti sún àwọn ọ̀mọ̀ràn inú ayé pàápàá láti máa kọminú gidigidi sí i. Kò síbi táwọn ètò orí kọ̀ǹpútà tá a fi ń ta ìsọfúnni látagbà kò dé lágbàáyé, wọ́n sì lè mú àìlóǹkà ìsọfúnni tó wúlò wá sínú ilé tàbí síbi iṣẹ́. Wọ́n máa ń pèsè àwọn ìsọfúnni tó wúlò gan-an fún àwọn iléeṣẹ́ aládàáni àtàwọn àjọ, àti fún àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan tó pọn dandan kí wọ́n gba ìsọfúnni tó bágbà mu nípa àwọn ohun tó lè ṣàǹfààní fún wọn tàbí fún iṣẹ́ wọn nínú ayé oníkìràkìtà táà ń gbé yìí. Lọ́wọ́ kan náà, àwọn ètò orí kọ̀ǹpútà tí wọ́n fi ń ta ìsọfúnni látagbà kún fún ọ̀pọ̀ ìṣòro, irú bí ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè, àwọn èròǹgbà nípa ìkórìíra tó lè dá ìpínyà sílẹ̀, àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìsọfúnni nípa béèyàn ṣe lè hu àwọn ìwà tí kò bójú mu àtàwọn ìwà bíburú jáì.

13 Nítorí náà, ọ̀pọ̀ ìdí pàtàkì ló wà tí Kristẹni kan fi gbọ́dọ̀ wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú lílo ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gbádùn àwọn ìtẹ̀jáde bí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun (Gẹ̀ẹ́sì), àwọn ìdìpọ̀ Insight àti ètò orí kọ̀ǹpútà kan tó wà fún wíwá ẹsẹ Ìwé Mímọ́, tó ń jẹ́ GetVerse, tí ètò àjọ náà ti ṣe sórí àwọn ike pẹlẹbẹ kékeré tó ń bá kọ̀ǹpútà ṣiṣẹ́. Àwọn mìíràn ti jàǹfààní nípa lílo Watchtower Library on CD-ROM èyí tó wúlò gan-an fún ṣíṣe ìwádìí síwájú sí i. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ohun èlò ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ kan wúlò, ẹni tó ń lo irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó ṣàǹfààní tún gbọ́dọ̀ máa wà lójú fò láti dáàbò bo ara rẹ̀ àtàwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ ohun èyíkéyìí tó lè nípa búburú lórí ẹni. A ní láti wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, débi pé lílo ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ lọ́nà tí kò lè pani lára pàápàá kò ní máa gba púpọ̀ lára àkókò wa tí a ti yà sí mímọ́, tàbí kó pín ọkàn wa níyà kúrò lára iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ fún wa àtàwọn góńgó wa.—Mát. 6:22; 28:19, 20.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́