ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 1/8 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìmukúmu Ọtí ní Mexico
  • Ìsọfúnni fún Àwọn Tí Ń Wọkọ̀ Òfuurufú
  • Àwọn Ẹyẹ Ilẹ̀ Tokyo Tí Ń Ṣí Kiri
  • A Wu Àlùmọ́nì Àdánidá Léwu
  • Màríà Ló Kọ́kọ́ Rí Kristi Tí Ó Jíǹde Kẹ̀?
  • Ewu Ìgbà Ẹ̀ẹ̀rùn ní Ìhà Gúúsù
  • “Ìjẹ̀rora” Níbi Iṣẹ́
  • Ìkìlọ̀ Ìgbà Òtútù
  • Àwọn Irú Ọ̀wọ́ Tí A Wu Léwu—Bí Ìṣòro Náà Ṣe Gbilẹ̀ tó
    Jí!—1996
  • Ṣé Èèyàn Ń Pa Oúnjẹ Ara Rẹ̀ Run Ni?
    Jí!—2001
  • Àmujù Ọtí Lè Kó Bá Ìlera Rẹ
    Jí!—2005
  • Ìdáàbò Bò Ní Ìdojú Kọ Àkúrun
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 1/8 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Ìmukúmu Ọtí ní Mexico

Àwọn ìwádìí tí Àjọ Afẹ́dàáfẹ́re ní Mexico ṣe fi hàn pé, ní 1991, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rin àwọn ará Mexico tí wọ́n jẹ́ onímukúmu ọtí. Ṣùgbọ́n Ìwé agbéròyìnjáde El Universal sọ pé nígbà tí ó fi máa di 1997, iye wọn lè ti di ìlọ́po méjì. Ó fa ọ̀rọ̀ Àjọ Tí Ń Ran Àwọn Onímukúmu Ọtí Lọ́wọ́ Láti Jáwọ́ yọ pé, lára àwọn mílíọ̀nù mẹ́jọ onímukúmu ọtí ní Mexico, mílíọ̀nù mẹ́ta ní ń gbé Mexico City. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde El Universal ti sọ, ọ̀pọ̀ jù lọ lára ìwà ọ̀daràn tí ń ṣẹlẹ̀ ní Mexico ni wọ́n máa ń hù nígbà tí wọ́n bá ti mutí yó. Ìmukúmu ọtí ń fa sísá níbi iṣẹ́ àti àìṣe-dáradára ní ilé ẹ̀kọ́. José Manuel Castrejón, aṣojú Àjọ Tí Ń Gbógun Ti Ìsọdibárakú, sọ pé, “ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìwà ipá nínú ìdílé àti ìdá márùn-ún lára ìjàǹbá tí ń ṣẹlẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ló ní í ṣe gan-an pẹ̀lú mímu ọtí líle.”

Ìsọfúnni fún Àwọn Tí Ń Wọkọ̀ Òfuurufú

Wíwọ ọkọ̀ òfuurufú lọ sí ọ̀nà jíjìn máa ń kó pákáǹleke bá èrò orí àti ara, ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London sì dá àwọn àbá kan tí yóò mú ìṣòro náà fúyẹ́. Lára wọn ni “ṣíṣàìmu ọtí líle ṣùgbọ́n mímu ọtí ẹlẹ́rìndòdò tí ó pọ̀, jíjẹ àwọn oúnjẹ tí ń yára dà nínú, àti fífinúwòye pé o wà ní ibì kan tí o ti ń gbádùn.” Jíjókòó lójú kan fún àkókò pípẹ́ lè mú kí ẹsẹ̀ wú, ó sì lè mú kí aṣọ túbọ̀ fúnni. Nípa bẹ́ẹ̀, ìwé agbéròyìnjáde The Times sọ pé, “àwọn dókítà dábàá wíwọ aṣọ tí kò fún, bíbọ́ bàtà àti bíbéèrè fún ìjókòó tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi àbákọjá kí o lè máa dìde rìn léraléra lọ síhà ilé ìyàgbẹ́.” Kíká apá àti ẹsẹ̀ rẹ kò, àti nínà wọ́n lákòókò ìrìn àjò náà yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ kí o má baà ní ìṣòro ìlọkiri ẹ̀jẹ̀ nínú ara. Láti bá àárẹ̀ ọpọlọ òun ara jà, “àwọn tí ìrìn àjò ti mọ́ lára máa ń yí ìgbòkègbodò wọn ojoojúmọ́ pa dà ṣáájú kí wọ́n tó gbéra ìrìn àjò. Àwọn tí wọ́n fẹ́ lọ sí ìhà ìlà oòrùn ti máa ń tètè jí fún ọ̀sẹ̀ kan ṣáájú, àwọn tí wọ́n sì fẹ́ lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn ti máa ń pẹ́ kí wọ́n tó sùn.”

Àwọn Ẹyẹ Ilẹ̀ Tokyo Tí Ń Ṣí Kiri

Ìwé agbéròyìnjáde The Daily Yomiuri sọ pé, àwọn ẹyẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí í dáṣà lílọ àti bíbọ̀ láàárín àwọn ìlú ńlá àti àrọko ní Tokyo, Japan, lójoojúmọ́. Àwọn ògbógi nípa ẹyẹ sọ pé èyí bẹ̀rẹ̀ ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn nígbà tí iye àwọn ẹyẹ tó wà ní àwọn ọgbà ohun alààyè ní Tokyo àti ní àyíká àwọn tẹ́ńpìlì bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i tí ó fi di ọ̀ranyàn fún àwọn ẹyẹ láti lọ kọ́ ìtẹ́ wọn sí ibòmíràn. Ìgbà yẹn ni wọ́n wá rí ìdẹ̀ra tí ó wà nínú ìgbésí ayé ní àrọko. Síbẹ̀síbẹ̀, ohun kan tí wọ́n pàdánù ni oúnjẹ tí wọ́n gbádùn gan-an ní ìlú ńlá—oúnjẹ orí àkìtàn àti àjẹkù oúnjẹ tí àwọn ènìyàn dà nù. Ìwé agbéròyìnjáde The Daily Yomiuri sọ pé, wọ́n ṣẹ́pá ìṣòro yìí ní lílo “ṣíṣíkiri bíi ti àwọn òṣìṣẹ́ tí ń gbowó oṣù. Wọ́n ń fò lọ sí àárín ìlú ńlá láti wá oúnjẹ ní òwúrọ̀, lẹ́yìn náà, wọn ń pa dà sí àrọko ní ìrọ̀lẹ́.”

A Wu Àlùmọ́nì Àdánidá Léwu

◆ Àgbègbè àríwá ìlà oòrùn Íńdíà, tí ó ní ọ̀pọ̀ irúgbìn àti ẹranko, ti ṣàkọsílẹ̀ pé a ti ń wu 650 irú ọ̀wọ́ irúgbìn àti 70 irú ọ̀wọ́ ẹranko léwu nísinsìnyí. A ti tọ́ka sí ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká wọn ní ìpínlẹ̀ Meghalaya, ní ààlà ilẹ̀ Bangladesh, tí ó wà nínú ipò ẹlẹgẹ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ‘àgbègbè bíburú jáì’ 18 tí ìjónírúurú ohun alààyè ti wà nínú ewu. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Asian Age ti sọ, ní àfikún sí àwọn ohun mìíràn, ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká wọn ń kojú ìbàjẹ́ àti ìpẹran láìgbàṣẹ tí ẹ̀dá ènìyàn ń ṣe. A ka ìjónírúurú ohun alààyè ní àwọn ìpínlẹ̀ méje tí wọ́n wà ní ìhà àríwá ìlà oòrùn Íńdíà sí èyí tí ó túbọ̀ ṣẹlẹgẹ́ tí ó sì gba àfiyèsí ní ti àjọṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn ju bí ó ṣe rí ní àwọn apá ibòmíràn ní orílẹ̀-èdè náà lọ.

◆ Ní Ítálì, iye irú ọ̀wọ́ àti ìsọ̀rí ọ̀wọ́ àwọn irúgbìn tí a ń wu léwu pẹ̀lú ti ń pọ̀ sí i. Ní 1992, àwọn 458 ni a kà sí èyí tí a ń wu léwu, ṣùgbọ́n nígbà tí ó fi máa di 1997, iye yẹn ti lọ sókè sí 1,011. Ìwé agbéròyìnjáde Corriere della Sera ṣàlàyé pé: “Nǹkan bí ìdá méje lára àwọn onírúurú tí ó para pọ̀ jẹ́ ohun ọ̀gbìn ilẹ̀ Ítálì ni a ń wu léwu ní àwọn ọ̀nà kan, ó sì ti tó àwọn irú ọ̀wọ́ 29 tí wọ́n ti kú run láàárín àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn.” Ó lé ní 120 irú ọ̀wọ́ tí ó wà “nínú ewu bíburú jáì ti kíkú run láìpẹ́ láìjìnnà,” ó sì lè tó 150 tí irú ewu yẹn lè wu láìpẹ́. Lójú ti onímọ̀ nípa ewéko náà, Franco Pedrotti, láti Yunifásítì Camerino, “àwọn fígọ̀ wọ̀nyí fi ipò bíbanilẹ́rù kan hàn.” Irúgbìn kan kú run ní ibùgbé àdánidá rẹ̀ nígbà tí wọ́n fi àgbègbè ibì kan ṣoṣo tí ó ti máa ń hù ṣe pápá ìgbábọ́ọ̀lù.

◆ Ìwé agbéròyìnjáde Buenos Aires náà, Clarín, sọ pé, ní Ajẹntínà, 500 lára 2,500 irú ọ̀wọ́ ẹranko ibẹ̀ ló wà nínú ewu. Claudio Bertonatti, olùṣekòkárí ẹ̀ka ìpèsè ààbò ti Àjọ Agbówókalẹ̀ fún Ìtọ́jú Ẹranko Igbó sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé dídáàbòbo ìjónírúurú ohun alààyè jẹ́ ojútùú kan ṣoṣo tí ó lè mú àwọn ènìyàn wà láyọ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ àti lọ́jọ́ iwájú, ọ̀pọ̀ àwọn ẹranko ni wọ́n wà nínú ewu pípòórá.” Àwọn onírúurú ẹranko bí armadillo, jaguar, vicuña, ẹja àbùùbùtán, àti ìjàpá orí ilẹ̀ wà lára àwọn ẹranko tí a ń wu léwu ní Ajẹntínà. Ìròyìn náà sọ pé: “Láìka [òtítọ́ náà] pé a ka títà wọ́n léèwọ̀ sí, nǹkan bí 100,000 ìjàpá ni a ń tà lọ́dọọdún” ní Buenos Aires. Bertonatti sọ pé: “Ìran ènìyàn, tí ó yẹ kí ó lọ́kàn ìfẹ́ nínú dídáàbòbo orísun ọrọ̀ yí jù lọ, ló ń fa ọ̀pọ̀ ju lọ lára àwọn ewu tí ń sún ọ̀pọ̀ irú ọ̀wọ́ lọ sí bèbè àkúrun.”

Màríà Ló Kọ́kọ́ Rí Kristi Tí Ó Jíǹde Kẹ̀?

Póòpù John Paul Kejì ti fi ìtẹnumọ́ kéde pé, “ó tọ́ láti ronú pé Ìyá [Jésù, Màríà] ni ó ṣeé ṣe kí Jésù tí ó jí dìdé náà kọ́kọ́ fara hàn.” (L’Osservatore Romano) Èyíkéyìí lára àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin kò sọ pé ìyá Jésù wà ní ibojì Jésù nígbà tí wọ́n rí i pé ó ṣófo. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Póòpù sọ pé: “Báwo ni a ṣe lè yọ Wúndíà Alábùkúnfún náà, tí ó wà lára àwùjọ àwọn ọmọlẹ́yìn (cf. Ìṣe 1:14), kúrò lára àwọn tí wọ́n pàdé Ọmọkùnrin rẹ̀ tí ó ti ọ̀run wá lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀?” Póòpù lo onírúurú àwáwí láti gbìyànjú láti ṣàlàyé ìdí tí kò fi sí àkọsílẹ̀ kankan nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere nípa ìpàdé láàárín Jésù àti ìyá rẹ̀. Òtítọ́ náà ṣì wà pé ẹ̀mí mímọ́ kò mí sí àwọn òǹkọ̀wé Ìhìn Rere náà láti mẹ́nu kan irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn àkọsílẹ̀ àwọn apọ́sítélì kò mẹ́nu kàn án rárá.—Tímótì Kejì 3:16.

Ewu Ìgbà Ẹ̀ẹ̀rùn ní Ìhà Gúúsù

January jẹ́ ọ̀kan lára àwọn oṣù tí ooru máa ń mú jù lọ ní ìhà Gúúsù Ìlàjì Ayé. Ìwé ìròyìn FDA Consumer ṣàlàyé pé, nígbà tí ooru bá ń mú, ó ṣe pàtàkì láti pa ara ẹni mọ́ lọ́wọ́ ara gbígbóná janjan. Onímọ̀ nípa ẹṣẹ́ tí ń tú àwọn èròjà ara sínú ẹ̀jẹ̀ náà, Dókítà Elizabeth Koller, sọ pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ara gbígbóná janjan ń fa ọgọ́rọ̀ọ̀rún ikú lọ́dọọdún, ó ṣeé dènà pátápátá. Ara gbígbóná janjan lè ṣẹlẹ̀ nítorí fífara ṣiṣẹ́ jù nínú ooru, ṣùgbọ́n ó tún máa ń ṣe àwọn arúgbó tí wọn kò ní ẹ̀rọ amúlétutù, tí wọ́n sì ní àìlera pàtàkì kan, bí àtọ̀gbẹ tàbí àrùn ọkàn àyà. Ìwé ìròyìn FDA Consumer dábàá mímu omi púpọ̀—lítà kan láàárín wákàtí kan bí a bá ń ṣeré ìmárale—bí ìdíwọ̀n ooru ara bá lọ sókè. Bí a bá wà nínú oòrùn, kí a wọ ohun adènà ìpalára oòrùn, fìlà tí etí rẹ̀ fẹ̀, àti aṣọ tí kò fún. Bí o kò bá ní ẹ̀rọ amúlétutù, tí o sì wà nínú ewu ara gbígbóná janjan, “fi omi tútù ṣanra, máa fi omi wọ́n ara rẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, kí o sì máa jókòó síwájú fáànù. Bí o bá nímọ̀lára bí ẹni tó fẹ́ dá kú, ké sí àwọn olùtọ́jú aláìlera ní pàjáwìrì.” Dókítà Koller kìlọ̀ pé: “Bí ara ẹnì kan bá ń gbóná jù, ìwọ̀nba ìṣẹ́jú díẹ̀ ni o ní láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là.”

“Ìjẹ̀rora” Níbi Iṣẹ́

Olùṣèwádìí náà, Jack Rostron, ti Yunifásítì John Moores sọ pé: “Ẹ̀fọ́rí, àárẹ̀, àìrántí-nǹkan, àìríran-dáadáa, òòyì, ìṣòro mímí, ọyún adinilétí, etí híhó, [àti] àrùn awọ ara”—gbogbo rẹ̀ lè jẹ́ nítorí ìṣòro tí ń wá nítorí àwọn ipò inú ilé tí ń wuni léwu tàbí ìṣòro SBS. Ó sọ pé, ìṣòro SBS, tí Àjọ Ìlera Àgbáyé mọ̀ ní 1986, lè “yí ọ̀ràn ti ìsúni tí ó wà nínú lílọ sí ibi iṣẹ́ sí ohun kan tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ bá ìdánilóró dọ́gba.” Ìwé agbéròyìnjáde The Independent ti London sọ pé, àwọn ilé tí a kì í ṣí fèrèsé wọn, tí wọ́n ní ẹ̀rọ amúlétutù alápapọ̀ lè mú kí àwọn ohun aṣèbàjẹ́, bí àwọn gáàsì eléròjà onímájèlé àti àwọn ìdọ̀tí tí ń jáde lára ẹ̀rọ aṣàdàkọ ìwé àti ẹ̀rọ ìtẹ̀wé wà káàkiri. Láti yẹra fún ìṣòro SBS, a gbọ́dọ̀ máa nu àwọn ẹ̀rọ amúlétutù déédéé àti dáradára. Rostron sọ pé: “Bí a ṣe ń ṣiṣẹ́ sí máa ń sunwọ̀n sí i tí ìwọ̀nba àwọn ènìyàn bá ń lo àwọn ọ́fíìsì kéékèèké tí wọ́n máa ń ṣí fèrèsé wọn.”

Ìkìlọ̀ Ìgbà Òtútù

Ìwé agbéròyìnjáde The Toronto Star sọ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń jókòó síta nínú òtútù, àti afẹ́fẹ́ wà nínú ewu àrùn hypothermia, àìtó ìwọ̀n ooru ara lọ́nà líléwu. Ìròyìn náà sọ pé, èyí máa ń ṣẹlẹ̀ “nígbà tí ara bá ń yára pàdánù ooru ara ju bí ó ṣe lè mú jáde lọ,” ó fi kún un pé, “kò dìgbà tí ìwọ̀n ooru ara bá wà lábẹ́ oódo kí àrùn hypothermia to ṣeni.” Nígbà púpọ̀ ni ètò ìyíkẹ́míkà-padà ara àwọn àgbàlagbà kì í lè dá ìwọ̀n ooru ara tí wọ́n pàdánù pa dà. Àwọn àti àwọn ọmọdé ni wọ́n wà nínú ewu jù. Ìwé ìléwọ́ Wilderness First Aid Handbook sọ pé, bí ara ẹnì kan bá “tutù, tí omi dà sára rẹ̀, tí ó rẹ̀ ẹ́, tí ebi ń pa á, tí ó ń gbọ̀n, tí ó ń sọ pé nǹkan ń ṣe òun, tí kò sì gbádùn wíwà ní ìta,” ó lè wà nínú ewu àrùn hypothermia. A gbọ́dọ̀ gbé irú ẹni bẹ́ẹ̀ wọlé, kí a wọ aṣọ gbígbẹ fún un, kí a fún un ní oúnjẹ, àti ohun mímu, àmọ́ kí ó máà jẹ́ ọtí líle tàbí kaféènì. Bí kò bá sí àmì pé ara rẹ̀ ń yá, a gbọ́dọ̀ wá ìrànlọ́wọ́ oníṣègùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́