ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 1/22 ojú ìwé 3
  • Ìrora Tí Ó Wà Nínú Yíyọ̀ǹda Wọn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìrora Tí Ó Wà Nínú Yíyọ̀ǹda Wọn
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìṣòro Tí Àwọn Òbí Tó Ń Dá Tọ́mọ Ń Kojú Kò Níye
    Jí!—2002
  • Fífi Ayọ̀ Gbé Ilé Tí Ó Ṣófo
    Jí!—1998
  • Ẹ̀yin Òbí Ẹ Jẹ́ Àpẹẹrẹ Rere Fáwọn Ọmọ Yín
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ẹ̀yin Òbí—ẹ Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Tìfẹ́tìfẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 1/22 ojú ìwé 3

Ìrora Tí Ó Wà Nínú Yíyọ̀ǹda Wọn

“Ọjọ́ tí mo bí àkọ́bí ọmọ mi ni ọkọ mi ti kìlọ̀ fún mi—‘Olùfẹ́, ọmọ títọ́ jẹ́ iṣẹ́ yíyọ̀ǹda tí a fà gùn.’”—Ourselves and Our Children—A Book by and for Parents.

Ọ̀PỌ̀ òbí ni inú wọ́n dùn—ni wọ́n yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ pàápàá—nígbà tí wọ́n bí àkọ́bí wọn. Lójú gbogbo àìbáradé, kòókòó-jàn-ánjàn-án, ìrora, ìdààmú, àti hílàhílo tí ń tìdí jíjẹ́ òbí wá, àwọn ọmọ lè jẹ́ orísun ayọ̀. Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọdún sẹ́yìn, Bíbélì polongo pé: “Àwọn ọmọ jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ OLÚWA; ìbùkún gidi ni wọ́n.”—Orin Dáfídì 127:3, Today’s English Version.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Bíbélì tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ amúnironú-jinlẹ̀ yí pé: “Ọkùnrin yóò . . . fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Nítorí onírúurú ìdí, àwọn ọmọ tí wọ́n ti dàgbà sábà máa ń fi ilé sílẹ̀—láti lọ kàwé tàbí lọ dáwọ́ lé iṣẹ́ kan, láti lọ mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni wọn gbòòrò sí i, láti ṣègbéyàwó. Ṣùgbọ́n ìnira gbáà ni òótọ́ ọ̀rọ̀ yí jẹ́ fún àwọn òbí kan. Wọ́n jẹ́ kí ìlàkàkà àdánidá tí àwọn ọmọ wọn ní láti wà lómìnira mú wọn “nímọ̀lára pé a yájú sí àwọn, a ṣẹ̀ sí àwọn, a kójútì bá àwọn, a wu àwọn léwu tàbí a ta àwọn nù,” gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé kan ṣe sọ ọ́. Èyí sábà máa ń yọrí sí gbọ́nmisi-omi-òto àti pákáǹleke tí kì í tán bọ̀rọ̀ nínú ìdílé. Nípa kíkọ̀ láti gba kámú nípa ọjọ́ tí àwọn ọmọ wọn yóò fi ilé sílẹ̀, àwọn òbí kan kì í múra wọn sílẹ̀ fún ìgbésí ayé àgbàlagbà. Àtubọ̀tán irú ìdágunlá bẹ́ẹ̀ wá lè burú jáì: ó lè sọ wọ́n di àgbàlagbà tí kò múra sílẹ̀ láti ṣètọ́jú ilé; láti bójú tó ìdílé kan; tàbí láti ní iṣẹ́ lọ́wọ́, kí ó má sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

Ìrora ìpínyà lè nira ní pàtàkì nínú àwọn ìdílé olóbìíkan. Òbí kan tí ó jẹ́ anìkàntọ́mọ, tí ń jẹ́ Karen, sọ pé: “Kòríkòsùn ni èmi àti ọmọbìnrin mi; a ní ìdè ìbáṣọ̀rẹ́ gidi kan. Bí ìgbín fà, ìkarahun a tẹ̀ lé e ni ọ̀rọ̀ wa.” Ipò ìbátan kòríkòsùn láàárín òbí òun ọmọ wọ́pọ̀ ní àwọn ìdílé olóbìíkan. A gbà pé èrò pípàdánù irú ipò ìbátan kòríkòsùn bẹ́ẹ̀ lè múni banú jẹ́.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìwé Traits of a Healthy Family rán àwọn òbí létí pé: “Gbogbo ohun tí ìgbésí ayé ìdílé jẹ́ nìyẹn: títọ́ ọmọ ọwọ́ kan tí ó gbára léni di àgbàlagbà tí ó tójú bọ́.” Ó wá kìlọ̀ pé: “Àìlèyọ̀ǹda àwọn ọmọ ló ń tanná ran ọ̀pọ̀ ìṣòro tí ń dìde nínú ìdílé.”

Ìwọ ńkọ́? Ṣé òbí ni ọ́? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, o ha ti múra sílẹ̀ de ọjọ́ tí ìwọ yóò yọ̀ǹda àwọn ọmọ rẹ? Àwọn ọmọ rẹ sì ńkọ́? O ha ń múra wọn sílẹ̀ láti ṣàṣeyọrí ní àwọn nìkan bí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́