Fífi Ayọ̀ Gbé Ilé Tí Ó Ṣófo
ÒBÍ kan sọ pé: “Bí ó ti wù kí a múra sílẹ̀ tó, ìpínyà pátápátá náà máa ń fa ìjayà fún púpọ̀ lára wa.” Òtítọ́ ni, bí ó ti wù kí fífi ilé sílẹ̀ ọmọ kan má ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ tó, tí ó bá ṣẹlẹ̀ ní gidi, kíkojú rẹ̀ lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn. Bàbá kan sọ nípa bí òun ṣe hùwà pa dà lẹ́yìn tí ó dá gbére fún ọmọ rẹ̀ pé: “Fún ìgbà àkọ́kọ́ láyé mi . . . , mo kàn ń sunkún ṣáá ni.”
Fún ọ̀pọ̀ òbí, fífi tí àwọn ọmọ wọn fi ilé sílẹ̀ fi wọ́n sí ipò ìwàlófìfo ńlá kan nínú ìgbésí ayé wọn—ọgbẹ́ ṣíṣísílẹ̀ kan. Bí wọn kò ṣe lè ní ìfarakanra ojoojúmọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, àwọn kan nírìírí ìmọ̀lára ìnìkanwà, ẹ̀dùn ọkàn, àti àdánù gidigidi. Ó sì lè máà jẹ́ àwọn òbí nìkan ni wọ́n ní ìṣòro láti mú ara bá ipò náà mu. Tọkọtaya kan tí a ń pè ní Edward àti Avril rán wa létí pé: “Bí àwọn ọmọ mìíràn bá ṣì wà nílé, àwọn pẹ̀lú yóò máa nímọ̀lára àdánù náà.” Kí wá ni ìmọ̀ràn tọkọtaya yìí? “Lo àkókò pẹ̀lú wọn, sì fòye hàn. Èyí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú ara bá ipò náà mu.”
Bẹ́ẹ̀ ni, ìgbòkègbodò ìgbésí ayé ń bá a lọ. Bí o bá ní láti bójú tó àwọn ọmọ rẹ yòó kù—kí a má sọ nípa iṣẹ́ rẹ tàbí àwọn iṣẹ́ ilé—o kò lè jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn dí ọ lọ́wọ́. Nítorí náà, jẹ́ kí a wo àwọn ọ̀nà kan tí o lè gbà rí ayọ̀ nígbà tí àwọn ọmọ rẹ ń fi ilé sílẹ̀.
Fiyè sí Ìhà Dídára Rẹ̀
Dájúdájú, bí inú rẹ bá bà jẹ́ tàbí tí o nímọ̀lára ìnìkanwà, tí o sì ní láti sunkún tàbí láti ṣàlàyé bí ìmọ̀lára rẹ ṣe rí fún ọ̀rẹ́ kan tí ó lẹ́mìí ìbánikẹ́dùn, ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nàkọnà. Bíbélì sọ pé: “Ìbìnújẹ́ ní àyà ènìyàn ní í dorí rẹ̀ kodò; ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere ní í mú un yọ̀.” (Òwe 12:25) Nígbà míràn, àwọn ẹlòmíràn lè sọ èrò tuntun fúnni nípa àwọn nǹkan. Fún àpẹẹrẹ, tọkọtaya kan tí a ń pè ní Waldemar àti Marianne dámọ̀ràn pé: “Má ṣe wo ọ̀ràn náà bí àdánù, àmọ́ wò ó bíi góńgó kan tí a lépa, tí ó sì yọrí sí rere.” Ẹ wo irú ojú títọ̀nà tí a fi ń wo nǹkan tí èyí jẹ́! Tọkọtaya kan tí a ń pè ní Rudolf àti Hilde sọ pé: “Inú wa dùn pé a lè tọ́ àwọn ọmọkùnrin wa dàgbà di ẹni tí ó ṣeé fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́.”
Ẹ ha ti gbìyànjú láti tọ́ ọmọ yín “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà” bí? (Éfésù 6:4) Kódà, bí ẹ bá ti ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ṣì lè ṣàníyàn nípa fífi ilé sílẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, fún àwọn tí wọ́n tọ́ ọmọ wọn lọ́nà yẹn, ohun tí Bíbélì mú dá wọn lójú ni pé, “nígbà tí ó bá sì dàgbà tán, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.” (Òwe 22:6) Kò ha tẹ́ yín lọ́rùn gan-an láti rí i pé ọmọ yín ti ṣàmúlò ẹ̀kọ́ tí ẹ kọ́ ọ? Àpọ́sítélì Jòhánù sọ nípa àwọn ìdílé rẹ̀ nípa tẹ̀mí pé: “Èmi kò ní èrèdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ìṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.” (Jòhánù Kẹta 4) Bóyá ìwọ pẹ̀lú lè ní èrò kan náà nípa ọmọ rẹ.
Òtítọ́ ni pé kì í ṣe gbogbo ọmọ ní ń ṣàmúlò ẹ̀kọ́ tí a fi kọ́ wọn lọ́nà ti Kristẹni. Bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀ nínú ọ̀ràn ọmọ rẹ tó ti dàgbà, kò túmọ̀ sí pé o kò ṣàṣeyọrí bí òbí kan. Má ṣe bu ẹnu àtẹ́ lu ara rẹ láìnídìí bí o ti sa gbogbo ipá rẹ láti tọ́ ọ dàgbà lọ́nà oníwà bí Ọlọ́run. Mọ̀ pé gẹ́gẹ́ bí àgbàlagbà kan, ọmọ rẹ yóò ru ẹrù tirẹ̀ fúnra rẹ̀ níwájú Ọlọ́run. (Gálátíà 6:5) Ní ìrètí náà pé, bóyá bí àkókò ti ń lọ, yóò tún ronú nípa àwọn yíyàn rẹ̀, pé “ọfà” náà yóò sì lọ sí ibi tí a darí rẹ̀ sí níkẹyìn.—Orin Dáfídì 127:4.
Òbí Ṣì Ni Ọ́!
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lílọ tí ọmọ rẹ lọ ń fi ìyípadà gbígbàfiyèsí kan hàn, kò túmọ̀ sí pé iṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí òbí ti tán. Ògbóǹtagí olùtọ́jú àrùn ọpọlọ náà, Howard Halpern, sọ pé: “Ìwọ lo ṣì jẹ́ òbí títí di ọjọ́ ikú rẹ, àmọ́ a ní láti ṣàtúnṣe sí pípèsèfúnni àti kíkọ́nilẹ́kọ̀ọ́.”
Bíbélì ti sọ tipẹ́tipẹ́ pé kìkì nítorí pé ọmọ kan ti dàgbà kò fòpin sí iṣẹ́ títọ́ ọmọ. Òwe 23:22 sọ pé: “Fetí sí ti bàbá rẹ tí ó bí ọ, má sì ṣe gan ìyá rẹ, nígbà tí ó bá gbó.” Bẹ́ẹ̀ ni, kódà nígbà tí àwọn òbí bá ti “gbó,” tí àwọn ọmọ wọn sì ti dàgbà, àwọn òbí ṣì lè jẹ́ ipa ìdarí pàtàkì nínú ìgbésí ayé àwọn ọmọ wọn. Dájúdájú, a ní láti ṣe àwọn àtúnṣe díẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ ní láti máa ṣàtúnṣe gbogbo ọ̀nà tí ẹ ń gbà bára lò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀tun, kí wọ́n sì tẹ́ni lọ́rùn. Nítorí náà, nísinsìnyí tí àwọn ọmọ rẹ ti dàgbà, sapá láti bá wọn lò bí àgbàlagbà. Ó dùn mọ́ni pé àwọn ìwádìí fi hàn pé ipò ìbátan òbí sí ọmọ sábà máa ń sunwọ̀n sí i gbàrà tí àwọn ọmọ bá fi ilé sílẹ̀! Bí àwọn ọmọ ti ń fojú winá pákáǹleke tí ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́ láyé, wọ́n sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ sí í rí àwọn òbí wọn pẹ̀lú ojú ìwòye tuntun. Ọkùnrin ará Germany kan tí a ń pè ní Hartmut sọ pé: “Nígbà yí ni mo wá lóye àwọn òbí mi dáradára, mo sì mọ ìdí tí wọ́n fi ṣe nǹkan lọ́nà tí wọ́n gbà ṣe é nígbà yẹn.”
Yẹra fún Yíyọjúràn
Bí ó ti wù kí ó rí, ẹ lè ba ohun púpọ̀ jẹ́ bí ẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí í yọjúràn sí ìgbésí ayé ara ẹni ọmọ yín tí ó ti dàgbà. (Fi wé Tímótì Kíní 5:13.) Abilékọ kan tí pákáǹleke ń fojú rẹ̀ rí màbo lọ́dọ̀ àwọn àna rẹ̀ kédàárò pé: “A nífẹ̀ẹ́ wọn, àmọ́ a wulẹ̀ fẹ́ gbé ìgbésí ayé tiwa, kí a sì ṣe àwọn ìpinnu wa fúnra wa.” Dájúdájú, òbí kan tí ó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ kì yóò jókòó tẹtẹrẹ kí ó máa wò ó kí ọmọ rẹ̀ tí ó ti dàgbà máa jìyà jewé iyá. Ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà ó dára gan-an láti yẹra fún fífún wọn ní ìmọ̀ràn tí wọn kò béèrè fún, láìka bí ó ṣe lọ́gbọ́n nínú tó tàbí bí ó ṣe ṣàǹfààní tó sí. Ní pàtàkì ni èyí jẹ́ òtítọ́ lẹ́yìn tí ọmọ kan bá ti ṣègbéyàwó.
Jí! fúnni ní ìmọ̀ràn ní 1983 pé: “Tẹ́wọ́ gba ipò rẹ tí ó yí pa dà. O fi iṣẹ́ rẹ ti jíjẹ́ ìyá tí ń tọ́jú ọmọ sílẹ̀ nígbà tí ọmọ jòjòló náà di àfànítẹ̀tẹ́. Bákan náà, o gbọ́dọ̀ wá ṣíwọ́ iṣẹ́ àbójútó tí o nífẹ̀ẹ́ sí náà láti wá gba ipò agbaninímọ̀ràn. Ṣíṣe ìpinnu fún ọmọ rẹ ní àsìkò yí nínú ìgbésí ayé wọn kò ní bójú mu bí kò ti ní bójú mu láti tún máa fọwọ́ gbá ẹ̀yìn rẹ̀ pẹ́pẹ́ kí ó lè gùfẹ̀ oúnjẹ tàbí láti máa fún un lọ́mú. Gẹ́gẹ́ bí olùfúnni-nímọ̀ràn, o ní àwọn ààlà pàtó kan. Kò tún ṣeé ṣe fún ọ mọ́ láti pàṣẹ fún wọn bí òbí lọ́nà tí ó gbéṣẹ́. (‘Ṣe é nítorí pé mo sọ bẹ́ẹ̀.’) Ọ̀wọ̀ gbọ́dọ̀ wà fún ipò àgbà tí ọmọ rẹ wà.”a
O lè má fara mọ́ gbogbo ìpinnu tí ọmọ rẹ àti ẹnìkejì rẹ̀ nínú ìgbéyàwó ṣe. Àmọ́ ọ̀wọ̀ fún ìjẹ́mímọ́ ìgbéyàwó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rẹ àníyàn rẹ sílẹ̀, kí o sì yé yọjúràn láìnídìí. Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, ó máa ń dára jù lọ láti jẹ́ kí àwọn ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ tọkọtaya yanjú ìṣòro wọn fúnra wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, o ń kóra rẹ sínú ewu kí ọkọ ọmọ rẹ tàbí aya ọmọ rẹ, tí ara lè máa kan nítorí àríwísí ní àkókò ẹlẹgẹ́ tí ó wà nínú ìgbéyàwó, máa gbó ọ lẹ́nu láìnídìí nígbà tí o bá ń fún un nímọ̀ràn tí kò fẹ́. Àpilẹ̀kọ Jí! tí a mẹ́nu kàn níṣàájú gbani nímọ̀ràn síwájú sí i pé: “Tẹ ẹ̀mí ìsúnniṣe náà láti máa gbà wọ́n ní ìmọ̀ràn tí wọn kò béèrè fún, tí kò lópin rì, èyí tí ó lè sọ ọkọ ọmọ tàbí ìyàwó ọmọ di ọ̀tá ẹni.” Jẹ́ alátìlẹ́yìn—máà jẹ́ adarí-ẹni. Nípa níní ipò ìbátan rere, o ń mú kí ó túbọ̀ rọrùn fún ọmọ rẹ láti tọ̀ ọ́ wá bí ó bá nílò àmọ̀ràn ní ti gidi.
Sọ Ìdè Ìgbéyàwó Dọ̀tun
Fún ọ̀pọ̀ tọkọtaya, ilé tí ó ṣófo náà lè tún ṣí àyè ìsọdipúpọ̀ ayọ̀ ìdílé sílẹ̀. Àkókò àti ìsapá tí a ń lò láti tọ́ ọmọ lọ́nà tí ó kẹ́sẹ járí lè boni mọ́lẹ̀ pátápátá tí àwọn tọkọtaya fi ń pa ipò ìbátan tiwọn tì. Ìyàwó kan sọ pé: “Nísinsìnyí tí àwọn ọmọ ti fi ilé sílẹ̀, èmi àti Konrad ń gbìyànjú láti tún pa dà di ojúlùmọ̀ ara wa.”
Bí ẹ ti bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹrù iṣẹ́ títọ́ ọmọ lójoojúmọ́, ẹ lè wá ní àkókò púpọ̀ fún ara yín nísinsìnyí. Òbí kan sọ pé: “Àkókò ọwọ́dilẹ̀ tuntun tí a wá ní yìí . . . ń jẹ́ kí a lè fi iyè púpọ̀ sórí ẹni tí a jẹ́, láti pọkàn pọ̀ sórí mímọ púpọ̀ sí i nípa ipò ìbátan wa, àti láti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ohun tí ń kúnjú àwọn àìní wa.” Ó fi kún un pé: “Ó jẹ́ àkókò tí a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun tuntun, tí a sì ń dàgbà lọ́nà yíyanilẹ́nu, bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé irú àkókò bẹ́ẹ̀ lè má fini lọ́kàn balẹ̀, ó tún ń runi sókè.”
Àwọn tọkọtaya kan tún ní òmìnira tí ó pọ̀ sí i ní ti ètò ìnáwó. Wọ́n lè wá bẹ̀rẹ̀ sí í mú iṣẹ́ àṣepawọ́ àti iṣẹ́ ìgbésí ayé tí wọ́n ti pa tì ṣe. Lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọ̀pọ̀ tọkọtaya ní ń lo òmìnira tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ní láti lépa àwọn ire tẹ̀mí. Bàbá kan tí a ń pè ní Hermann ṣàlàyé pé lẹ́yìn tí àwọn ọmọ òun fi ilé sílẹ̀, òun àti ìyàwó òun yíjú sí pípadàbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Yíyọ̀ǹda Tí Àwọn Òbí Anìkàntọ́mọ Ń Yọ̀ǹda Wọn
Mímú ara bá ipò ilé tí ó ṣófo náà mu lè ṣòro ní pàtàkì fún àwọn òbí anìkàntọ́mọ. Rebecca, tí ó jẹ́ ìyá anìkàntọ́mọ tí ó ní ọmọ méjì, ṣàlàyé pé: “Bí àwọn ọmọ wa bá lọ, a kò ní ọkọ tí yóò wà pẹ̀lú wa, tí yóò sì fìfẹ́ hàn sí wa.” Òbí anìkàntọ́mọ lè ti rí i pé àwọn ọmọ òun ti jẹ́ orísun ìtìlẹ́yìn ti èrò ìmọ̀lára. Bí wọ́n bá sì ń dá nínú owó tí ìdílé ń ná, lílọ wọn tún lè fa ìṣòro owó.
Àwọn díẹ̀ rọ́nà gbé e gbà láti mú nǹkan sunwọ̀n sí i ní ti ọ̀ràn ìnáwó nípa fíforúkọsílẹ̀ fún àwọn ètò ẹ̀kọ́ṣẹ́ tàbí àwọn ìlà ẹ̀kọ́ onígbàkúkúrú ní ilé ẹ̀kọ́. Ṣùgbọ́n báwo ni ènìyàn ṣe lè mú àlàfo ìdáwà kúrò? Òbí kan tí ó jẹ́ anìkàntọ́mọ, sọ pé: “Ohun tí ó ràn mí lọ́wọ́ ni wíwá nǹkan ṣe. Ó lè jẹ́ kíka Bíbélì, títún ilé mi ṣe, tàbí wíwulẹ̀ rìn kúṣẹ́kúṣẹ́ tàbí sísáré. Àmọ́ ọ̀nà tí ó ṣàǹfààní jù lọ tí mo fi ṣẹ́gun ìdáwà ni bíbá ọ̀rẹ́ kan tí ó jẹ́ ẹni tẹ̀mí sọ̀rọ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, “gbòòrò síwájú,” kí o sì wá ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tuntun, tí ó sì ń mú ìtẹ́lọ́rùn wá. (Kọ́ríńtì Kejì 6:13) Bí o bá nímọ̀lára ìpòrúurùu, ‘tẹpẹlẹ mọ́ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ àti àdúrà.’ (Tímótì Kíní 5:5) Ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò fún ọ ní okun, yóò sì tì ọ́ lẹ́yìn la àkókò ìmárabápòmu tí ó le koko yìí já.
Fífi Ayọ̀ Yọ̀ǹda Wọn
Ohun yòó wù kí ipò rẹ jẹ́, mọ̀ pé ìgbésí ayé kò ní dópin tí àwọn ọmọ bá fi ilé sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìdè ìdílé kò ní tú. Ìfẹ́ gidi tí a ṣàpèjúwe nínú Bíbélì lágbára tó láti so àwọn ènìyàn pọ̀, kódà bí wọ́n bá jìnnà síra gan-an. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán wa létí pé ìfẹ́ “a máa mú ohun gbogbo mọ́ra. Ìfẹ́ kì í kùnà láé.” (Kọ́ríńtì Kíní 13:7, 8) Kìkì nítorí pé àwọn ọmọ yín fi ilé sílẹ̀ kì yóò mú kí ìfẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan tí ẹ ti mú dàgbà nínú ìdílé yín kùnà.
Lọ́nà tí ó dùn mọ́ni, nígbà tí ìkìmọ́lẹ̀ wíwà lọ́nà jíjìn àti àárò ilé bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn ọmọ tàbí nígbà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í nímọ̀lára másùnmáwo ìkìmọ́lẹ̀ ọ̀ràn ìnáwó, àwọn ni wọ́n sábà máa ń kọ́kọ́ kàn sí ilé. Hans àti Ingrid dámọ̀ràn pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ mọ̀ pé ìgbàkigbà tí wọ́n bá fẹ́ ni wọ́n lè wá sọ́dọ̀ yín.” Ṣíṣèbẹ̀wò déédéé, kíkọ lẹ́tà, tàbí títẹ̀ wọ́n láago lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan yóò ràn yín lọ́wọ́ láti máa gbúròó wọn. “Ẹ lọ́kàn ìfẹ́ nínú ohun tí wọ́n ń ṣe láìṣe pé ẹ ń tojú bọ ọ̀ràn wọn,” bí Jack àti Nora ṣe sọ ọ́ nìyẹn.
Nígbà tí àwọn ọmọ bá fi ilé sílẹ̀, ìgbésí ayé yín yóò yí pa dà. Àmọ́ ìgbésí ayé nínú ilé tí ó ṣófo lè mú kí ọwọ́ dí, kí ó kún fún ìgbòkègbodò, kí ó sì tẹ́ni lọ́rùn. Bákan náà, ọ̀nà tí ẹ ń gbà bá àwọn ọmọ yín lò yóò yí pa dà. Síbẹ̀, ó ṣì lè jẹ́ ipò ìbátan aláyọ̀, tí ó sì ń fúnni ní ìtẹ́lọ́rùn. Ọ̀jọ̀gbọ́n Geoffrey Leigh àti Gary Peterson sọ pé: “Gbígbé níbi tí a kò ti sí lábẹ́ àwọn òbí kò fi hàn pé ìfẹ́, ìṣòtítọ́, tàbí ọ̀wọ̀ tí a ní fún àwọn òbí dín kù. . . . Ní gidi, àwọn ìdè ìdílé tí ó lágbára sábà máa ń wà jálẹ̀ ìgbésí ayé síbẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, o kò ní ṣíwọ́ nínífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ láé, o kò sì ní ṣíwọ́ jíjẹ́ òbí wọn. Àti nítorí pé o ti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ tó láti jẹ́ kí wọ́n lọ, o kò tí ì pàdánù wọn ní ti gidi.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “A Kii Jawọ Kuro Ninu Jijẹ Obi Lae,” nínú Jí!, ìtẹ̀jáde July 8, 1983.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]
“Fún ìgbà àkọ́kọ́ láyé mi . . . , mo kàn ń sunkún ṣáá ni”
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àbá Kan fún Àwọn Ọmọ Tí Wọ́n Ti Dàgbà—Ẹ Ran Àwọn Òbí Lọ́wọ́ Láti Yọ̀ǹda Yín
Fífi ilé sílẹ̀ sábà máa ń rọrùn láti kojú ju dídi ẹni tí a fi sílé lọ. Nítorí náà, bí o ti ń dunnú nípa òmìnira àti ipò àgbàlagbà rẹ, fi inú rere àti òye hàn sí àwọn òbí rẹ bí wọ́n bá ní ìṣòro láti mú ara wọn bá ipò mu. Mú ìfẹ́ àti ìfẹ́ni rẹ tí kò dáwọ́ dúró dá wọn lójú. Lẹ́tà kékeré kan, ẹ̀bùn àìròtẹ́lẹ̀ kan, tàbí ìtẹniláago ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ kan lè ṣe púpọ̀ láti mú inú òbí kan tí ó sorí kọ́ dùn! Máa fi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì-pàtàkì nínú ìgbésí ayé rẹ tó wọn létí. Èyí ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìdè ìdílé ṣì lágbára.
Bí o ti ń kojú pákáǹleke ìgbésí ayé bí àgbàlagbà, bóyá ìwọ yóò mọrírì ohun tí àwọn òbí rẹ là kọjá láti tọ́jú rẹ dàgbà ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Bóyá èyí yóò sún ọ láti wí fún àwọn òbí rẹ pé: “Mo dúpẹ́ fún gbogbo ohun tí ẹ ti ṣe fún mi!”