Kíkojú Àwọn Ìyọrísí Rẹ̀
BÍ Gilbert tó rọpá rọsẹ̀ ṣe wà nídùbúlẹ̀ nílé ìwòsàn kan, ó bi dókítà rẹ̀ léèrè pé: “Ǹjẹ́ mo tún lè pa dà máa lo apá àti ẹsẹ̀ mi mọ́?” Gilbert gbọ́ ìdáhùn tí ń peni níjà náà pé: “Bí o bá ṣe sapá tó ni o ṣe lè kọ́fẹ pa dà tó, tí yóò sì yá ọ tó.” Ó dáhùn pé: “Mo ti ṣe tán!” Ní ọmọ ọdún 65, ìtọ́jú onídàárayá pa pọ̀ pẹ̀lú ojú ìwòye onídàáni-lójú mú kí ó tẹ̀ síwájú láti orí lílo kẹ̀kẹ́ arọ dé orí rírọ̀ mọ́ kẹ̀kẹ́ àfirìn, lẹ́yìn náà, dé orí ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀, àti dé orí pípadà síbi iṣẹ́.
Àwọn olùṣèwádìí náà, Weiner, Lee, àti Bell sọ pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìmúbọ̀sípò lẹ́yìn àrùn ẹ̀gbà lóde òní ń ṣètìlẹ́yìn fún èrò náà pé bí àgbègbè kan nínú ọpọlọ bá bà jẹ́, àwọn àgbègbè míràn lè gba iṣẹ́ ẹran ara tó ní ìpalára náà ṣe. Ète kan tí ìtọ́jú wà fún ni láti mú agbára àwọn àgbègbè tí ọ̀ràn kò kàn nínú ọpọlọ dàgbà lọ́nà gbígbéṣẹ́, kí a sì pèsè ìsúnniṣe tí yóò fàyè gba ọpọlọ láti ṣe àtúntò àti ìmárabápòmu.” Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn kókó mìíràn wà tí ń nípa lórí ìkọ́fẹpadà, lára wọn ni ọ̀gangan ibi tí àrùn ẹ̀gbà náà kàn àti bí ó ti le tó, bí ara ẹni náà ti dá tó lápapọ̀, bí ìtọ́jú tí ó rí gbà ṣe dára tó, àti bí àwọn ẹlòmíràn ṣe ṣètìlẹ́yìn tó.
Ìtìlẹ́yìn Ìdílé àti Àwọn Ọ̀rẹ́
Erikka fi ọdún mẹ́ta ṣe àwọn ìgbòkègbodò ìkọ́fẹpadà, ó ń kọ́ láti máa rìn, kí ó sì lè lo ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ láti ṣe ohun tí ọwọ́ òsì tí kò wúlò mọ́ ì bá ṣe. Ó sọ nípa ohun tó mú kí ó lè borí pé: “Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé ọkọ mi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi dúró tì mí. Mímọ̀ pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi fún mi lókun, nígbà tí wọ́n sì ń fún mi níṣìírí pé kí n má juwọ́ sílẹ̀, ìyẹn sún mi gbégbèésẹ̀.”
Àwọn mọ̀lẹ́bí ń di alájùmọ̀ṣe nínú ìgbésẹ̀ ìkọ́fẹpadà àwọn olólùfẹ́ wọn. Ó pọn dandan kí wọ́n máa bi oníṣègùn léèrè ọ̀rọ̀, kí wọ́n sì máa kíyè sí àwọn ìtọ́jú tí wọ́n lè ní láti máa ṣe nìṣó nílé kí àwọn àṣeyọrí tí wọ́n ti ní má baà jò rẹ̀yìn. Sùúrù, inú rere, òye, àti ìfẹ́ni tí àwọn mọ̀lẹ́bí àti àwọn ọ̀rẹ́ ń fi hàn máa ń pèsè àyíká ìmọ̀lára ààbò tí wọ́n ti ní láti tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀rọ̀ sísọ, ìwé kíkà, àti àwọn òye iṣẹ́ ìgbésí ayé ojoojúmọ́ mìíràn.
Bí John ti ń gbìyànjú láti wà déédéé láàárín ìrọni àti ìkẹ́nibàjẹ́, ó ran ìyàwó rẹ̀, Ellen, lọ́wọ́ nídìí eré ìmárale àti ìtọ́jú. Ó ṣàpèjúwe ìsapá tí ìdílé rẹ̀ ṣe pé: “A kì í jẹ́ kí Ellen ri ara rẹ̀ sínú ìkáàánú-ara-ẹni. Nígbà kọ̀ọ̀kan, a máa ń le koko díẹ̀, ṣùgbọ́n a sábà máa ń rí sí i pé kò kọjá ààlà agbára rẹ̀, a sì ń ṣèrànlọ́wọ́. A lè yára pa ìmọ̀lára rẹ̀ lára, nítorí náà, mo ń sapá láti má ṣe fa másùnmáwo bá a.”
Bí olùṣètọ́jú ọ̀rọ̀ sísọ kan ṣe ń kọ́ Ellen láti máa sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, John ń ràn án lọ́wọ́. “Ṣíṣe àwọn nǹkan pa pọ̀ jẹ́ ọ̀nà kan láti fúnni ní ìṣírí, nítorí náà, a jọ ń ka Bíbélì sókè ketekete fún ara wa, èyí tí ó mú kí ìsọ̀rọ̀ rẹ̀ sunwọ̀n sí i. Bákan náà, bí a ti ń ṣe é díẹ̀díẹ̀ níbẹ̀rẹ̀, a ń lọ́wọ́ sí iṣẹ́ òjíṣẹ́, níwọ̀n bí a ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lọ́nà yí, ó ṣeé ṣe fún Ellen láti bá àwọn ẹlòmíràn ṣàjọpín ìrètí tí a ní nípa ọjọ́ ọ̀la. Èyí fúnra rẹ̀ jẹ́ ìtọ́jú kan fún Ellen.” Nígbà tí ó fi pé ọdún mẹ́ta, Ellen ti kọ́fẹ pa dà gidigidi.
A kò gbọ́dọ̀ gbójú fo ìṣírí àti okun tí àwọn ọ̀rẹ́ lè fi fúnni, nítorí wọ́n lè ní ipa kíkàmàmà lórí ìkọ́fẹpadà ẹni tó yí àrùn ẹ̀gbà dá. Ìwé àtìgbàdégbà lórí ìṣègùn náà, Stroke, ròyìn pé “a ti ṣàwárí pé ìtìlẹ́yìn” púpọ̀ “ní ti àjùmọ̀ṣe ń múni retí ìkọ́fẹpadà tó túbọ̀ yá kánkán àti ìwọ̀n ìmúsunwọ̀n gbogbogbòò púpọ̀ sí i, àní láàárín àwọn olùgbàtọ́jú tí àrùn ẹ̀gbà wọn le koko pàápàá.”
Bernie mọrírì ìtìlẹ́yìn tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣe fún un gan-an. Ó rán wa létí pé: “Ìbẹ̀wò àwọn ọ̀rẹ́ ṣe pàtàkì fúnni láti kojú ipò náà. Ohùn tó fi ìbánikẹ́dùn hàn àti ìṣarasíhùwà tó fi ìbìkítà hàn ń múni lára yá gágá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò gbọ́dọ̀ gbé gbogbo àfiyèsí karí àìlèṣeǹkan ẹni náà, sísọ̀rọ̀ nípa ìsunwọ̀n sí i èyíkéyìí ń fúnni níṣìírí gidigidi.” Kí ni gbogbo wa lè ṣe láti ṣètìlẹ́yìn fún àwọn tí ń kojú àwọn ìyọrísí àrùn ẹ̀gbà? Bernie dámọ̀ràn pé: “Fúnni lẹ́bùn òdòdó kan tàbí kí o ṣàjọpín èrò tàbí ìrírí kan láti inú Ìwé Mímọ́. Ìyẹn ti jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún mi gan-an.”
Melva, àgbàlagbà kan tó yí àrùn ẹ̀gbà dá, rí i pé ó ṣàǹfààní pé kí ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin rẹ̀ nípa tẹ̀mí gbàdúrà pẹ̀lú rẹ̀. Gilbert pẹ̀lú dámọ̀ràn èyí, ó ṣàlàyé pé: “Ó fi hàn pé o bìkítà tó ní gidi bí o bá gbàdúrà pẹ̀lú ẹnì kan.” Peter, tí àrùn ẹ̀gbà tó ṣe é bà lójú jẹ́, ń mọyì rẹ̀ gan-an nígbà tí àwọn ẹlòmíràn bá lóye ibi tí agbára rẹ̀ mọ, tí wọ́n sì lo àkókò láti kàwé fún un.
Bíbá ẹnì kan lọ síbi ìmúbọ̀sípò àti bíbá a bọ̀ tún jẹ́ ìṣe onífẹ̀ẹ́ kan. Rírí i dájú pé inú ilé alárùn ẹ̀gbà náà ní ààbò tún pọn dandan pẹ̀lú. Nígbà tí ẹnì kan kò bá lè séra ró láìgbọ̀n, ó máa ń dojú kọ ewu ṣíṣubú léraléra. Bí àpẹẹrẹ, Gilbert mọrírì ìrànlọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ kan, tí wọ́n gbé ọ̀pá àdìmú gbọọrọ kan sí ilé ìwẹ̀ rẹ̀ fún ààbò, ní àfikún sí àwọn ohun mìíràn tí wọ́n ṣe.
Kíkọ́ Láti Ṣètìlẹ́yìn
Ìmọ̀lára tí kò dúró sójú kan àti ìtẹ̀sí láti sunkún lè kótìjú bá alárùn ẹ̀gbà náà, kí ó sì da àwọn òǹwòran tí wọ́n lè ṣàìmọ ohun tí wọ́n lè ṣe lọ́kàn rú. Bí ó ti wù kí ó rí, nípa kíkọ́ láti ṣètìlẹ́yìn, àwọn ọ̀rẹ́ lè gba alárùn ẹ̀gbà náà sílẹ̀ lọ́wọ́ ìmọ̀lára ìnìkanwà tí ó lè yọrí sí. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn àkókò tí ẹkún ń gbọnni ń dín kù. Àmọ́, nígbà tí ẹkún bá gbọ̀n ọ́, fọkàn balẹ̀, kí o sì dúró ti ẹni náà, kí o sì máa sọ ohun tí yóò wù ọ́ láti máa gbọ́ ká ní ìwọ ni o wà ní ipò rẹ̀, tí òun sì wà ni ipò rẹ.
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ní ìfẹ́ bíi ti Ọlọ́run fún àwọn tí àbùkù ara wọn lè ti yí ànímọ́ bí o ti mọ̀ wọ́n tẹ́lẹ̀ pa dà. Wọ́n ń fòye mọ ìmọ̀lára rẹ, ìyẹn sì ń nípa lórí bí wọ́n ṣe ń hùwà pa dà sí ọ. Erikka sọ pé: “Mo lè ṣàìrí bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ láé. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tó gbọ́dọ̀ retí ìyẹn lọ́dọ̀ alárùn ẹ̀gbà kan. Àwọn mọ̀lẹ́bí àti àwọn ọ̀rẹ́ gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ láti nífẹ̀ẹ́ ẹni náà ní ipò tí ó bá wà. Bí wọ́n bá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àkópọ̀ ìwà rẹ̀, wọn yóò rí i pé àwọn ànímọ́ fífanimọ́ra jù lọ àtẹ̀yìnwá ṣì wà níbẹ̀.”
Iyì ara ẹni máa ń lọ sílẹ̀ nígbà tí ẹnì kan kò bá lè sọ̀rọ̀ tàbí tí a kò lè lóye rẹ̀. Àwọn ọ̀rẹ́ lè fìdí bí àwọn tí ìpalára bá agbára ìsọ̀rọ̀ wọn ṣe níye lórí tó múlẹ̀ nípa sísapá láti bá wọn sọ̀rọ̀. Takashi wí pé: “Èrò mi àti ìmọ̀lára mi nínú ọkàn mi kò tí ì yí pa dà. Bí ó ti wu kí ó rí, àwọn ènìyàn ń yẹra fún mi nítorí wọn kò lè bá mi jíròrò bí ó ṣe yẹ kí ó rí. Ó ṣòro fún mi láti kàn sí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n nígbà tí ẹnì kan bá wá bá mi sọ̀rọ̀, ó máa ń jẹ́ ìṣírí kíkàmàmà, ó sì ń mú kí n láyọ̀ gidi gan-an!”
Àwọn ìlànà díẹ̀ tí ó lè ran gbogbo wa lọ́wọ́ láti ṣètìlẹ́yìn fún àwọn tó ní àbùkù agbára ìsọ̀rọ̀, kí a sì fún wọn níṣìírí, ni a tò lẹ́sẹẹsẹ wọ̀nyí.
Ọ̀pọ̀ jù lọ àrùn ẹ̀gbà kì í nípa lórí làákàyè. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tí wọ́n yí àrùn ẹ̀gbà dá ni ọpọlọ wọn máa ń dá ṣáṣá, bí ó tilẹ̀ lè ṣòro láti lóye ohun tí wọ́n ń sọ. Má ṣe bá wọn sọ̀rọ̀ bí ẹni tí kò lóye púpọ̀ tó tàbí bí ọmọdé. Máa bu iyì fún wọn.
Fi sùúrù gbọ́ wọn. Ó lè gbà wọ́n lákòókò láti ṣàtúntò èrò tàbí láti parí ọ̀rọ̀, àpólà ọ̀rọ̀, tàbí gbólóhùn kan. Rántí pé olùtẹ́tísíni tó bìkítà jù kì í kánjú láti gbọ́rọ̀.
Bí kò bá yé ọ, má ṣe díbọ́n pé ó yé ọ. Fi inú rere jẹ́wọ́ pé: “Jọ̀wọ́. Ó jọ pé kò yé mi. Jẹ́ kí a tún gbìyànjú rẹ̀ nígbà míràn.”
Máa sọ̀rọ̀ ketekete láìkánjú, kí ohùn rẹ sì wà bí ó ti sábà máa ń wà.
Máa lo àwọn gbólóhùn tí kò gùn àti àwọn ọ̀rọ̀ tó wọ́pọ̀.
Máa béèrè àwọn ìbéèrè tí a lè dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí o sì máa fúnni níṣìírí láti dáhùn. Fi sọ́kàn pé ó lè ṣòro fún wọn láti lóye ohun tí o ń sọ.
Má ṣe jẹ́ kí ariwo pọ̀ láyìíká.
Kíkojú Ipò Náà, Pẹ̀lú Ìtìlẹ́yìn Onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà
Nígbà tí ó ṣe pàtàkì láti mọ ohun tí ó fa àrùn ẹ̀gbà, nítorí tí ìyẹn ń mú kí o gbégbèésẹ̀, ó sì ń dín ewu níní àrùn ẹ̀gbà lọ́jọ́ iwájú kù, ó tún ṣe pàtàkì láti kápá ìbẹ̀rù tí ń bá a rìn. Ellen wí pé: “Ọrọ̀ Ọlọ́run Nínú Aísáyà 41:10 ń tù mí nínú ní pàtàkì. Níbẹ̀ ló ti sọ pé: ‘Ìwọ má bẹ̀rù; nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ; má fòyà; nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ: èmi yóò fún ọ ní okun; ní tòótọ́, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́; ní tòótọ́, èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi gbé ọ́ sókè.’ Jèhófà ti jẹ́ ẹni gidi sí mi, ó ń mú kí n má bẹ̀rù.”
Bíbélì tún ran Anand pẹ̀lú lọ́wọ́ láti kojú ìmọ̀lára àìnírètí tó ní: “Ó fún mi ní ìtìlẹ́yìn púpọ̀, nítorí ó ń ta mí jí, ó sì ń sọ mí dọ̀tun léraléra.” Ìṣòro ti Hiroyuki ni bí ó ṣe lè jàǹfààní láti inú Ìwé Mímọ́, nítorí pé kò lè pọkàn pọ̀. Ó wí pé: “Mo rí ìtùnú láti inú fífetí sí kíka Bíbélì lórí kásẹ́ẹ̀tì.”
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wí pé: “Nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.” (Kọ́ríńtì Kejì 12:10) Ẹ̀mí Jèhófà ló ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí ohun tí kò lè ṣe fúnra rẹ̀. Àwọn tí wọ́n yí àrùn ẹ̀gbà dá pẹ̀lú lè gbára lé Jèhófà láti fún wọn ní okun tẹ̀mí. Erikka sọ pé: “Nígbà tí ara wa le, tí a sì ń lo okun tiwa láti ṣe àwọn nǹkan, a lè máà fún Jèhófà láǹfààní púpọ̀ láti ràn wá lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n àìlera mi ti mú ki n lè fún ipò ìbátan mi pẹ̀lú rẹ̀ lókun lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ kan.”
Àwọn Olùṣètọ́jú Ń Rí Ìtìlẹ́yìn Gbà
Àwọn olùṣètọ́jú nílò ìtìlẹ́yìn nínú iṣẹ́ wọn tó ṣe kókó. Ibo ni wọ́n lè yíjú sí fún ìtìlẹ́yìn? Ibì kan ni inú ìdílé. Mẹ́ńbà kọ̀ọ̀kan ló yẹ kó kópa nínú ẹrù ìṣàbójútó. Yoshiko sọ nípa bí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ṣe ṣètìlẹ́yìn ní ti ìmọ̀lára pé: “Wọ́n máa ń fetí sí àwọn ìṣòro mi bíi pé tiwọn ni.” Ó yẹ kí àwọn mọ̀lẹ́bí gba gbogbo ìsọfúnni tí wọ́n bá lè rí gbà kí wọ́n lè kọ́ bí wọ́n ṣe lè bójú tó alárùn ẹ̀gbà kan, àti bí wọ́n ṣe lè hùwà lójú ìyípadà tó ń dé bá ìhùwàsí olólùfẹ́ wọn.
Ta ló tún lè ṣètìlẹ́yìn fún àwọn olùṣètọ́jú? David àti ìdílé rẹ̀ wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ ìdílé wọn tẹ̀mí nínú ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí Victor: “Wọ́n gbégbèésẹ̀ nípa àìní wa. Ní pípààrọ̀ ara wọn, wọ́n ń wá dúró ti Victor, wọ́n sì ń sùn lọ́dọ̀ wa láti bá wa ṣètọ́jú rẹ̀ ní gbogbo òru.”
Gbogbo olùṣètọ́jú ló fẹ́ láti nímọ̀lára ìfẹ́ ọlọ́yàyà àti ìtìlẹ́yìn ìdílé rẹ̀ tẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ó lè ṣòro fún àwọn kan láti béèrè fún ìrànlọ́wọ́. Haruko sọ pé: “A sábà ń sọ fún mi pé: ‘Bí o bá nílò ìrànwọ́ fún ohunkóhun, má ṣe lọ́ra láti jẹ́ kí a mọ̀.’ Ṣùgbọ́n ní mímọ bí ọwọ́ olúkúlùkù ṣe dí tó, ó ni mí lára láti béèrè fún ìrànlọ́wọ́. Ǹ bá mọrírì rẹ̀ gan-an bí àwọn ènìyàn bá lè ṣèrànwọ́ gúnmọ́: ‘Mo lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti tún ilé ṣe. Ọjọ́ wo ni o fẹ́ kí n wá ṣe é?’ ‘Mo lè bá ọ ra nǹkan lọ́jà, ṣé kí n wá nísinsìnyí?’”
Ìyàwó Kenji ní àrùn ẹ̀gbà; bí ó ti wù kí ó rí, Kenji lè ṣe ìrànwọ́ tó nílò fún un. Ó rí i pé òun lè kó àwọn ẹrù ìnira òun lé Jèhófà nípasẹ̀ àdúrà. Níkẹyìn, ìyàwó rẹ̀ kò lè sọ̀rọ̀ mọ́, Kenji sì tipa bẹ́ẹ̀ pàdánù ẹnì kan tí ó ti ń bá sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n ó ń ka Bíbélì lójoojúmọ́. Ó wí pé: “Ó mú mi rántí ìtọ́jú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí Jèhófà ń fún àwọn tí ẹ̀mí wọn wó palẹ̀, èyí sì ti mú kí n má di ẹni tó ń sorí kọ́ tàbí tó ń nímọ̀lára ìnìkanwà.”
Gbígbáralé ẹ̀mí Jèhófà lè ṣèrànwọ́ nígbà tí ó bá jọ pé àwọn ìmọ̀lára wa fẹ́ bò wá mọ́lẹ̀. Yoshiko, tí ń kojú ìyípadà nínú ìwà ọkọ rẹ̀ àti ìrunú ọkọ rẹ̀ tí àrùn ẹ̀gbà ti ṣe sẹ́yìn, sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, mo ń nímọ̀lára pé a ń fipá mú mi láti fi gbogbo agbára mi ké rara. Ní irú àkókò bẹ́ẹ̀, mo sábà máa ń gbàdúrà sí Jèhófà, ẹ̀mí rẹ̀ sì ń fún mi ní ìbàlẹ̀ ọkàn.” Ní mímọrírì bí Jèhófà ṣe dúró tì í, kò jẹ́ kí ohunkóhun ṣèdíwọ́ fún ọ̀nà ìgbésí ayé Kristẹni rẹ̀. Ó ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé, ó ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó sì ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Yoshiko sọ pé: “Nípa ṣíṣe ipa tèmi, mo mọ̀ dájú pé Jèhófà kì yóò kọ̀ mí sílẹ̀.”
Nígbà tí a bá wà nínú hílàhílo, Jèhófà wà níbẹ̀ láti gbọ́ wa. Midori, tí ọkọ rẹ̀ yí àrùn ẹ̀gbà dá, ń ní ìtùnú nínú òtítọ́ náà pé, lọ́nà àfiṣàpẹẹrẹ, Jèhófà ti fi gbogbo omijé tí òun ti dà sínú “ìgò” rẹ̀. (Orin Dáfídì 56:8) Ó ń rántí àwọn ọ̀rọ̀ Jésù pé: “Ẹ má ṣe ṣàníyàn láé nípa ọ̀la.” Ó wí pé: “Mo ti pinnu lọ́kàn mi láti mú sùúrù títí tí ayé tuntun náà yóò fi dé.”—Mátíù 6:31-34.
Kíkojú Àwọn Ààlà Tí Kò Mọ Níwọ̀n
Òtítọ́ ni pé nígbà ìmúbọ̀sípò wọn, àwọn kan ń kọ́fẹ pa dà lọ́nà tó gbàfiyèsí, ṣùgbọ́n àṣeyọrí kékeré làwọn kan ń ṣe ní jíjèrè agbára ìṣe tí wọ́n ní ṣáájú àrùn ẹ̀gbà náà. Kí ló lè ran àwọn tí a mẹ́nu bà kẹ́yìn yí lọ́wọ́ láti kojú ìpèníjà ti títẹ́wọ́gba ààlà ohun tí wọ́n lè ṣe, bí ó ti wù kí ó pọ̀, kí ó sì wà pẹ́ tó?
Bernie, tí àrùn ẹ̀gbà sọ di ẹni tí kò lè rìn kiri púpọ̀, dáhùn pé: “Ayọ̀ tí mo ní nínú ìrètí ìwàláàyè ayérayé nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé tí ń bọ̀ àti àdúrà sí Bàbá mi ọ̀run, Jèhófà, ló ràn mí lọ́wọ́ láti fọkàn balẹ̀ tẹ́wọ́ gba ààlà mi.”
Ìrètí yẹn ran Erikka àti ọkọ rẹ̀, Georg, lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba ibi tí ààlà rẹ̀ mọ kí wọ́n sì máa gbádùn ìgbésí ayé síbẹ̀. Georg ṣàlàyé pé: “A ní ìlérí Ọlọ́run láti ṣèmúláradá pátápátá lọ́jọ́ kan. Nítorí náà, a kò kó gbogbo àfiyèsí lé orí àbùkù ara náà. Ní tòótọ́, a ṣì ń ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe nítorí ìlera Erikka. Ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe láti kọ́ láti máa gbé ayé pẹ̀lú àwọn iṣu ẹran ara tí a kò lè ṣàkóso lọ́nà pípéye, kí a sì pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tó túbọ̀ gbámúṣé.”—Aísáyà 33:24; 35:5, 6; Ìṣípayá 21:4.
Nínú àwọn ọ̀ràn tí ìkọ́fẹpadà bá ti mọ níwọ̀n, ìtìlẹ́yìn ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́ túbọ̀ ṣe pàtàkì. Wọ́n lè ran aláìsàn náà lọ́wọ́ láti mú un mọ́ra títí di àkókò tí Ọlọ́run yóò ṣàtúnṣe gbogbo àìlera.
Mímọ̀ pé ọjọ́ ọ̀la amọ́kànyọ̀ kan wà fún àwọn alárùn ẹ̀gbà àti àwọn mọ̀lẹ́bí wọn, nígbà tí wọn yóò ní ìlera pa dà ń mú kí wọ́n lè kojú ipò ìwàláàyè bó ṣe wà lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan. Wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ fi sùúrù dúró de ìtura lọ́wọ́ gbogbo ìjìyà, nínú ayé tuntun ti Ọlọ́run, tí yóò dé láìpẹ́. (Jeremáyà 29:11; Pétérù Kejì 3:13) Ní báyìí ná, gbogbo àwọn tó bá yíjú sí Jèhófà lè ní ìdánilójú pé nísinsìnyí pàápàá, yóò ràn wọ́n lọ́wọ́, yóò sì tì wọ́n lẹ́yìn ní kíkojú ipa tí àrùn ẹ̀gbà lè ní.—Orin Dáfídì 33:22; 55:22.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]
Àwọn mọ̀lẹ́bí àti ọ̀rẹ́ lè ran aláìsàn náà lọ́wọ́ láti fara dà á títí tí àkókò tí Ọlọ́run yàn láti yanjú gbogbo àìlera yóò fi dé
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Dídènà Àrùn Ẹ̀gbà
DÓKÍTÀ David Levine sọ pé: “Ọ̀nà tó dára jù láti kojú àrùn ẹ̀gbà ni gbígbìyànjú láti dènà rẹ̀.” Kókó abájọ tó sì gbapò kíní ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àrùn ẹ̀gbà tó pọ̀ jù lọ ni ẹ̀jẹ̀ ríru.
Ní ti ọ̀pọ̀ ènìyàn, ẹ̀jẹ̀ ríru ṣeé dènà nípa jíjẹ oúnjẹ tó ní ọ̀pọ̀ èròjà potassium nínú, tí iyọ̀, ògidì ọ̀rá, àti èròjà cholesterol inú rẹ̀ sì kéré. Dídín ọtí líle tí a ń mu kù pẹ̀lú ṣe pàtàkì. Ètò eré ìmárale déédéé tó bá ọjọ́ orí àti ipò ìlera ẹni mu lè ṣèrànwọ́ láti dín ìwọ̀n ìsanra kù, ó sì lè yọrí sí dídín ìwọ̀n ìfúnpá kù. A lè ní láti lo egbòogi—lábẹ́ àbójútó dókítà kan, níwọ̀n bí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ egbòogi ti wà.
Àrùn òpójẹ̀ tí n gbẹ́jẹ̀ lọ sí orí máa ń dí ọ̀nà ìpèsè ẹ̀jẹ̀ fún ọpọlọ, ó sì jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ohun ti ń fa àrùn ẹ̀gbà. Ní sísinmilé bí ó bá ṣe dí tó, a lè gbani nímọ̀ràn láti ṣe iṣẹ́ abẹ tí a mọ̀ sí iṣẹ́ abẹ ìmúkúrò ìtẹ́nú òpójẹ̀ tí ń gbẹ́jẹ̀ lọ sí orí, láti la ọ̀nà inú òpójẹ̀ tó dí náà. Ìwádìí ti fi hàn pé àwọn ènìyàn tí ń ní àmì àrùn, tí òpójẹ̀ wọn sì dí gan-an, jàǹfààní iṣẹ́ abẹ pa pọ̀ mọ́ ìtọ́jú ìṣègùn. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìṣòro tó tan mọ́ iṣẹ́ abẹ náà lè yọjú, nítorí náà, a ní láti ṣàgbéyẹ̀wò rẹ̀ tìṣọ́ratìṣọ́ra.
Àrùn ọkàn àyà lè dá kún ewu àrùn ẹ̀gbà. A lè ṣèwòsàn ìsúnkì ségesège nínú òpójẹ̀ ọkàn àyà (àìṣedéédéé ìlùkìkì ọkàn àyà), tí ó lè mú kí ẹ̀jẹ̀ dì kí ó sì lọ sínú ọpọlọ, nípa lílo àwọn egbòogi tí kì í jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ dì. Àwọn àrùn ọkàn àyà míràn lè gba iṣẹ́ abẹ àti egbòogi láti dín àrùn ẹ̀gbà kù. Àrùn àtọ̀gbẹ ló máa ń fa ìpín púpọ̀ jù nínú ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn ẹ̀gbà, nítorí náà, kíkápá rẹ̀ ń ṣèrànwọ́ láti dènà àrùn ẹ̀gbà.
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àìtó ẹ̀jẹ̀ ní àwọn apá kan ara fúngbà díẹ̀ jẹ́ ìkìlọ̀ kedere pé àrùn ẹ̀gbà ń bọ̀. Rí i dájú pé o kò ṣàìkà wọ́n sí. Lọ rí oníṣègùn rẹ, ki o sì wá nǹkan ṣe nípa àwọn ohun tó ń fà á, nítorí pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àìtó ẹ̀jẹ̀ ní àwọn apá kan ara fúngbà díẹ̀ máa ń sọ ewu àrùn ẹ̀gbà di púpọ̀ ní ìlọ́po-ìlọ́po.
Ìgbésí ayé oníwọ̀ntúnwọ̀nsì tó gbámúṣé lè dá kún dídènà àrùn ẹ̀gbà lọ́nà púpọ̀. Jíjẹ oúnjẹ tí èròjà rẹ̀ pé àti ṣíṣe eré ìmárale déédéé pẹ̀lú jíjẹ́ kí ọtí líle tí a ń mu kéré gan-an àti ṣíṣàìmusìgá lè ṣèrànwọ́ láti jẹ́ kí àwọn òpójẹ̀ lera, wọ́n sì lè gbé àwọn ìyípadà gbígbámúṣé nínú àwọn tó tilẹ̀ ti ní ìpalára lárugẹ. Bí àwọn ìwádìí ṣe fi hàn, ṣíṣàfikún àwọn èso àti ẹ̀fọ́ àti oúnjẹ oníhóró tí a ń jẹ ti ṣèrànwọ́ láti dín ewu àrùn ẹ̀gbà kù.