Àrùn Ẹ̀gbà—Ohun Tó Ń Fà Á
ONÍMỌ̀ nípa ọpọlọ, Dókítà Vladimir Hachinski, ti Yunifásítì Western Ontario ní London, Kánádà, sọ pé: “Ọpọlọ ni ẹ̀yà ara tó ṣẹlẹgẹ́ jù.” Ọpọlọ, tó jẹ́ kìkì ìpín 2 nínú ọgọ́rùn-ún ìwọ̀n ara, ní sẹ́ẹ̀lì iṣan tó lé ní bílíọ̀nù mẹ́wàá, tí gbogbo wọn jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ láìdáwọ́dúró láti mú gbogbo ìrònú wa, ìyírapadà wa, àti ìmọ̀lára wa jáde. Níwọ̀n bí ọpọlọ ti gbára lé ìpèsè afẹ́fẹ́ oxygen àti èròjà glucose láti fún un lágbára, ìgbékalẹ̀ àwọn òpójẹ̀ dídíjú kan ń pèsè wọn fún un láìdáwọ́dúró.
Bí ó ti wù kí ó rí, bí apá kékeré kan nínú ọpọlọ bá ṣàìní afẹ́fẹ́ oxygen fún ìṣẹ́jú àáyá mélòó kan pàápàá, àwọn ìgbéṣẹ́ṣe iṣan ọpọlọ tó ṣẹlẹgẹ́ ń bà jẹ́. Bí èyí bá wà bẹ́ẹ̀ ju ìwọ̀n ìṣẹ́jú mélòó kan lọ, ó ń yọrí sí ìbàjẹ́ ọpọlọ, nítorí pé àwọn sẹ́ẹ̀lì ọpọlọ àti àwọn ìṣiṣẹ́ wọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí í kú. Ìṣẹ̀lẹ̀ yí ni a ń pè ní àìtó ẹ̀jẹ̀ ní apá kan ara, àìsí afẹ́fẹ́ oxygen tí òpójẹ̀ tó dí ń fà. Àwọn ìṣùpọ̀ ẹran ara ọpọlọ ń bà jẹ́ síwájú sí i nítorí àìsí afẹ́fẹ́ oxygen ń fa ìgbésẹ̀ alásokọ́ra aṣekúpani ti ìṣiṣẹ́ oníkẹ́míkà. Ó ń yọrí sí àrùn ẹ̀gbà. Àrùn ẹ̀gbà tún ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn iṣan ẹ̀jẹ̀ bá bẹ́, tó mú kí ẹ̀jẹ̀ máa tú sínú ọpọlọ jù, tó ń dí àwọn ipa ọ̀nà ìsokọ́ra. Èyí ń ṣèdíwọ́ fún gbígbé agbára oníkẹ́míkà àti agbára bíi mànàmáná lọ sínú àwọn iṣu ẹran ara, ó sì ń fa ìpalára fún ìṣùpọ̀ ẹran ara ọpọlọ.
Ìyọrísí Rẹ̀
Àrùn ẹ̀gbà ń yàtọ̀ síra, wọ́n sì lè nípa lórí ẹnì kọ̀ọ̀kan ní àwọn ọ̀nà tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé kà tán. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹni tí gbogbo ohun tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ìyọrísí àrùn ẹ̀gbà ń ṣe, àwọn ìyọrísí náà máa ń wà láti orí èyí tí kò le, tí kì í fi bẹ́ẹ̀ pàfiyèsí títí dé orí èyí tó le koko, tí a sì ń rí ìjẹ̀rora tó ń mú wá. Apá ibi tí àrùn ẹ̀gbà ti ṣẹlẹ̀ nínú ọpọlọ ló ń pinnu ẹ̀yà ara tí ó ń bà jẹ́.
Èyí tó wọ́pọ̀ ni àìlera apá àti ẹsẹ̀ lókè àti nísàlẹ̀, tàbí kí wọ́n tilẹ̀ rọ. Ní gbogbogbòò, èyí ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan ara, ẹ̀gbẹ́ tó wà ní ìhà kejì ibi tí àrùn ẹ̀gbà náà ti ṣẹlẹ̀ nínú ọpọlọ. Nípa bẹ́ẹ̀, bí ìbàjẹ́ náà bá jẹ́ ti ìhà ọ̀tún nínú ọpọlọ, ìhà òsì ẹni náà ni yóò rọ, bí ó bá sì jẹ́ ìhà òsì ọpọlọ ló bà jẹ́, ìhà ọ̀tún ẹni náà ni yóò rọ. Àwọn kan lè máa lo apá àti ẹsẹ̀ wọn nìṣó, kí wọ́n sì rí i pé àwọn iṣu ẹran ara wọn ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ débi tó fi jọ pé tapátẹsẹ̀ wọn ń dá ṣiṣẹ́ láyè ara wọn. Ẹni tó ṣẹlẹ̀ sí náà á wá dà bíi ṣẹ̀ṣẹ̀bẹ̀rẹ̀ eléré orí yìnyín kan tí ń dura. Dókítà David Levine, ti Ibùdó Ìṣègùn ní Yunifásítì New York, sọ pé: “Wọ́n ti pàdánù irú ìmọ̀lára tí ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ yálà wọ́n ń gbé apá àti ẹsẹ̀ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ àti ibi tí apá àti ẹsẹ̀ wọn wà nínú òfuurufú.”
Iye tí ó tó ìpín 15 nínú ọgọ́rùn-ún nínú àwọn tó yí i dá ń nírìírí ìkìmọ́lẹ̀, tí ń yọrí sí àwọn sáà tí wọn kì í lè ṣàkóso ìgbòkègbodò ara wọn, ó sì sábà ń ṣẹlẹ̀ ní àkókò tí wọn kò ní ìmọ̀lára. Bákan náà ni níní ìrora àti ìyípadà nínú níní ìmọ̀lára tún wọ́pọ̀. Ẹnì kan tó yí àrùn ẹ̀gbà dá, tí pajápajá máa ń mú léraléra lọ́wọ́ àti lẹ́sẹ̀ sọ pé: “Ní àwọn òru kan, ohun kan yóò kàn mí lẹ́sẹ̀, n óò sì ta jí, nítorí ńṣe ló ń dà bíi pé iná mànàmáná ló ń gbé mi lẹ́sẹ̀.”
Ìyọrísí àrùn ẹ̀gbà lè kan kí ojú máa rí nǹkan kan ṣoṣo lọ́nà méjì, kí gbígbé nǹkan mì sì di ìṣòro. Bí àwọn àgbègbè tí a ti ń mọ bí nǹkan ti rí nínú ẹnu àti ọ̀fun bá ti bà jẹ́, àwọn ipò tí ń tẹ́ni lógo síwájú sí i, bíi wíwatọ́, lè ṣẹlẹ̀ sí àwọn alárùn ẹ̀gbà. Ó lè pa èyíkéyìí nínú àwọn agbára ìmọ̀lára márààrún lára, kí ó fa àbùkù nínú ìríran, ìgbọ́ròó, ìgbóòórùn, ìtọ́wò, àti ìfọwọ́bà.
Àwọn Ìṣòro Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀
Finú wòye ara rẹ bí ẹni tí àwọn àjèjì méjì tó síngbọnlẹ̀ ń tọ̀ lẹ́yìn ní òpópó kan ti iná kò ti mọ́lẹ̀ rekete. Bí o ti wẹ̀yìn lo rí wọn, tí wọ́n ń sáré bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ. O gbìyànjú láti ké rara fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n ohùn rẹ kò là! Ǹjẹ́ o lè finú ro ìjákulẹ̀ pátápátá tí o máa ní nínú ipò yẹn? Ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ lára àwọn alárùn ẹ̀gbà nígbà tí ohùn wọn bá lọ lójijì nìyẹn.
Àìlèsọ èrò, ìmọ̀lára, ìrètí, àti ìbẹ̀rù jáde—dídi àjèjì lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ sí àwọn ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí—jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìyọrísí tí ń múni banú jẹ́ jù lọ tí àrùn ẹ̀gbà ń ní. Ẹnì kan tí ó yí àrùn ẹ̀gbà dá ṣàpèjúwe rẹ̀ báyìí: “Gbogbo ìgbà tí mo bá fẹ́ sọ̀rọ̀ ni ọ̀rọ̀ kì í jáde. Ó fipá mú mi láti dákẹ́, n kò sì lè tẹ̀ lé àṣẹ àfẹnusọ tàbí alákọsílẹ̀. Mo ń gbọ́ ọ̀rọ̀ . . . bíi pé àwọn ènìyàn tó wà yí mi ká ń fọ èdè àjèjì. N kò lóye èdè, n kò sì lè lò ó.”
Bí ó ti wù kí ó rí, Charles lóye gbogbo ohun tí a ń bá a sọ. Ṣùgbọ́n nípa dídáhùn, ó kọ ọ́ pé: “Mo ń ṣàkójọ àwọn ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ sọ, ṣùgbọ́n wọ́n máa ń dà rú, wọ́n sì ń ṣe ségesège bí mo bá ń sọ wọ́n. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, mo ń nímọ̀lára pé, mo kó sínú àhámọ́ nínú ara mi.” Nínú ìwé rẹ̀, Stroke: An Owner’s Manual, Arthur Josephs ṣàlàyé pé: “Nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀, ó lé ní ọgọ́rùn-ún iṣu ẹran ara tí a ń darí, tí a sì ń mú ṣiṣẹ́ pọ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ni àwọn ẹ̀ka tí ń mú ẹ̀yà ara ṣiṣẹ́ tó lé ní ọgọ́rùn-ún ní ìpíndọ́gba ń darí. . . . Ní ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan tí a bá fi sọ̀rọ̀, a nílò àràkanndá 140,000 ìgbòkègbodò ọpọlọ òun iṣu ẹran ara. Ó ha ṣeni ní kàyéfì kankan bí ìpalára tó bá bá apá kan ọpọlọ tí ń darí àwọn iṣu ẹran ara wọ̀nyí bá yọrí sí ìsọ̀rọ̀ tó ṣe ségesège bí?”
Ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ mérìíìírí dídíjú ní àgbègbè ọ̀rọ̀ sísọ nínú ọpọlọ ló jẹ́ ìyọrísí àrùn ẹ̀gbà. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan tí kò lè sọ̀rọ̀ lè kọrin. Ẹlòmíràn lè máa sọ̀rọ̀ láìròtì, nígbà tí kò fẹ́ sọ ọ́, tàbí lọ́nà míràn, ó lè máa sọ̀rọ̀ láìdánudúró. Àwọn mìíràn ń sọ àsọtúnsọ tàbí wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ lọ́nà tí kò yẹ, ní sísọ pé bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí wọ́n fẹ́ sọ pé bẹ́ẹ̀ kọ́, tàbí ní ìdà kejì. Àwọn kan ń mọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n fẹ́ sọ, ṣùgbọ́n ọpọlọ kò lè mú kí ẹnu, ètè, àti ahọ́n sọ wọ́n. Ọ̀rọ̀ wọn sì lè máa fà nítorí àwọn iṣu ẹran ara tó dẹ̀. Àwọn kan lè máa bú jáde láàárín ọ̀rọ̀.
Ìpalára mìíràn tí àrùn ẹ̀gbà lè ṣe ni bíba apá tí ń darí ìṣètò ìmọ̀lára nínú ọpọlọ jẹ́. Ìyọrísí rẹ̀ lè jẹ́ sísọ̀rọ̀ lọ́nà tí kò fi ìmọ̀lára kankan hàn. Ó sì lè jẹ́ ìṣòro lílóye bí ohùn àwọn ẹlòmíràn ṣe ń gbé ìmọ̀lára wọn yọ. Àwọn adènà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ bí èyí àti àwọn tí a ṣàpèjúwe wọn lókè lè dá ìyapa sílẹ̀ láàárín àwọn mọ̀lẹ́bí, bíi láàárín ọkọ àti aya. Georg wí pé: “Nítorí pé àrùn ẹ̀gbà ń kan ìrísí ojú àti ìfaraṣàpèjúwe, ní tòótọ́, ó ń kan gbogbo ànímọ́ ẹni, lójijì ni àjọṣe wa kò dán mọ́rán bíi ti àtijọ́ mọ́. Lójú mi, ńṣe ló jọ pé mo ní ìyàwó kan tó yàtọ̀ pátápátá, ẹnì kan tí mo gbọ́dọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í mọ̀.”
Àwọn Ìyípadà Ìmọ̀lára àti Àkópọ̀ Ìwà
Ìmọ̀lára tí ń yí pa dà láìyẹ, ìbújáde omijé tàbí ẹ̀rín, ìbínú àbíjù, èrò ìfura tí kò rí bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀, àti ìbànújẹ́ tí kò mọ níwọ̀n wulẹ̀ jẹ́ apá kan ìṣòro kíkàmàmà tí àwọn tí wọ́n yí àrùn ẹ̀gbà dá àti àwọn mọ̀lẹ́bí wọn lè máa bá yí ní ti ìmọ̀lára àti àkópọ̀ ìwà.
Alárùn ẹ̀gbà kan tí ń jẹ́ Gilbert sọ pé: “Nígbà kọ̀ọ̀kan, ìmọ̀lára máa ń bò mí mọ́lẹ̀, yálà kí ohun kan tí kò tó nǹkan máa pa mí lẹ́rìn-ín tàbí kí ó máa pa mí lẹ́kún. Nígbà míràn, tí mo bá rẹ́rìn-ín, ẹnì kan yóò béèrè pé, ‘Kí ló ń pa ọ́ lẹ́rìn-ín?’ n kò sì ní rí ohun sọ.” Èyí pẹ̀lú ìṣòro àìlèséraró àti títiro, mú kí Gilbert sọ pé: “Mo nímọ̀lára bíi pé ara mìíràn ni mo gbé wọ̀, bíi pé n kì í ṣe ara mi, pé kì í ṣe èmi kan náà kí àrùn ẹ̀gbà náà tó dé.”
Bí ó bá fi wà, ṣàṣà ènìyàn ló lè ṣàìní ìmọ̀lára tó dà rú nígbà tí wọ́n bá ní àbùkù ara tó yí ìrònú àti ara wọn pa dà. Hiroyuki, tí àrùn ẹ̀gbà tó ní fa ìdíwọ́ ọ̀rọ̀ sísọ fún, tó sì sọ ọ́ di arọ lápá kan, sọ pé: “Lẹ́yìn àkókò díẹ̀ pàápàá, n kò wulẹ̀ nímọ̀lára tó sàn jù. Ní mímọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí n má lè máa ṣiṣẹ́ mi bíi ti tẹ́lẹ̀, mo sọ̀rètí nù. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í dẹ́bi fún àwọn nǹkan àti àwọn ènìyàn, mo sì lérò pé àwọn ìmọ̀lára mi yóò bú jáde. N kò ṣe bí ọkùnrin.”
Àwọn alárùn ẹ̀gbà sábà máa ń ní ìbẹ̀rù àti hílàhílo. Ellen sọ pé: “Mo máa ń nímọ̀lára àìláàbò nígbà tí orí mi bá wúwo, tí ó lè jẹ́ àmì ìkìlọ̀ nípa àrùn ẹ̀gbà lọ́jọ́ iwájú. Ẹ̀rù máa ń bà mí gan-an bí mo bá gba ara mi láyè láti ronú lọ́nà òdì.” Ron ṣàlàyé hílàhílo tó ń bá fínra pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà ni dídé orí ìpinnu títọ́ máa ń fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé ṣe. Yíyanjú àwọn ìṣòro kéékèèké méjì tàbí mẹ́ta lẹ́ẹ̀kan náà ń já mi kulẹ̀. Mo ń yára gbàgbé nǹkan tó bẹ́ẹ̀ tí n kì í lè rántí àwọn ìpinnu tí mo ṣe láìpẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, mo ń ṣe àwọn àṣìṣe bíbanilẹ́rù, ó sì máa ń kójútì bá èmi àti àwọn ẹlòmíràn. Báwo ni ipò mi yóò ṣe rí lọ́dún díẹ̀ sí i? Ǹjẹ́ n óò lè báni sọ̀rọ̀ lọ́nà onílàákàyè tàbí ki n wa ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mọ́? Ǹjẹ́ n kò ní di ẹrù ìnira fún ìyàwó mi?
Ó Ń Kan Àwọn Mọ̀lẹ́bí Pẹ̀lú
Nígbà náà, a lè rí i pé àwọn alárùn ẹ̀gbà náà nìkan kọ́ ló ní ìyọrísí amúnibanújẹ́ láti kò lójú. Ó kan àwọn mọ̀lẹ́bí wọn pẹ̀lú. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, wọ́n ní láti kojú rírí ìbànújẹ́ ńlá ti ẹnì kan tó gbó ṣáṣá, tó sì dáńgájíá, tí ó wá ń jó rẹ̀yìn lójú wọn lójijì, tí ó wá bọ́ sí ipò ọmọ ọwọ́ kan tí kò lè dá ṣe ohunkóhun. Ó lè dabarú ipò ìbátan nítorí pé ó ṣeé ṣe kí àwọn mọ̀lẹ́bí ní láti máa kó ipa tí kò mọ́ wọn lára tẹ́lẹ̀.
Haruko sọ ipa bíbaninínújẹ́ náà báyìí: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ohun pàtàkì ni ọkọ mi kò lè rántí mọ́. Lójijì, a ní láti ti ilé iṣẹ́ tó ti ń bójú tó tẹ́lẹ̀ pa, kí a sì pàdánù ilé àti àwọn ohun ìní wa. Ohun tó dunni jù ni pé a kò lè bá ọkọ mi sọ̀rọ̀ fàlàlà mọ́, a kò sì lè gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́. Níwọ̀n bí kò ti mọ ìyàtọ̀ láàárín òru àti ọ̀sán mọ́, ó sábà máa ń ká àwọn aṣọ ìdáàbòbò tí a nílò lóru kúrò. Bí a tilẹ̀ mọ̀ pé àkókò kan yóò dé tí yóò wá dà bẹ́ẹ̀, ó ṣì ṣòro fún wa láti tẹ́wọ́ gba bí ipò rẹ̀ ti rí ní gidi. Ipò wa ti yí pa dà sẹ́yìn pátápátá, nítorí ní báyìí, èmi àti ọmọbìnrin mi ni alábòójútó ọkọ mi.”
Elaine Fantle Shimberg sọ nínú ìwé Strokes: What Families Should Know pé: “Ṣíṣètọ́jú alárùn ẹ̀gbà kan—bí ó ti wù kí o nífẹ̀ẹ́ wọn tó—lè tán ọ lókun nígbà míràn. Pákáǹleke àti àìgbọdọ̀máṣe náà kì í dẹwọ́.” Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ìtọ́jú àrà ọ̀tọ̀ tí àwọn mọ̀lẹ́bí kan ń pèsè lè ṣèpalára fún ìlera, ìmọ̀lára, àti ipò tẹ̀mí olùṣètọ́jú náà. Maria ṣàlàyé pé àrùn ẹ̀gbà tí ìyá rẹ̀ ní nípa lórí ìgbésí ayé òun gidigidi: “Mo ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀ lójoojúmọ́, mo sì ń gbìyànjú láti gbé e ró nípa tẹ̀mí, ní kíkàwé fún un àti gbígbàdúrà pẹ̀lú rẹ̀, lẹ́yìn náà, mo ń fún un ní ìfẹ́, ìgbánimọ́ra, àti ìfẹnukonu lọ́pọ̀ yanturu. Nígbà tí mo bá fi pa dà délé, ó ti ń rẹ̀ mí ní ti ìmọ̀lára—ní àwọn ọjọ́ mìíràn, ó ń rẹ̀ mí débi tí mo fi máa ń bì.”
Ohun tó ṣòro jù fún àwọn olùṣètọ́jú kan láti mú mọ́ra ni ìyípadà nínú ọ̀nà ìhùwà. Onímọ̀ nípa ìbátan ìhùwà, ọpọlọ àti ìrònú náà, Ọ̀mọ̀wé Ronald Calvanio, sọ fún Jí! pé: “Nígbà tí o bá ní àrùn kan tó nípa lórí ìṣiṣẹ́ apá tí ń ṣàkóso ìsopọ̀ ìgbòkègbodò iṣan nínú ọpọlọ—ìyẹn ni, bí ẹnì kan ṣe ń ronú, bó ṣe ń lo ìgbésí ayé rẹ̀, bó ṣe ń hùwà pa dà ní ti ìmọ̀lára—a ń sọ nípa ohun tí ẹni yẹn jẹ́ gan-an, nítorí náà, ní àwọn ọ̀nà kan, àwọn ìbàjẹ́ èrò orí tí ń ṣẹlẹ̀ ń yí ọ̀nà ìgbésí ayé ìdílé pa dà lọ́nà gbígbàfiyèsí gidigidi.” Yoshiko sọ pé: “Ó jọ pé ọkọ mi yí pa dà pátápátá lẹ́yìn àìsàn rẹ̀, ó máa ń bínú láìròtẹ́lẹ̀ nítorí àwọn nǹkan kéékèèké. Ní àwọn àkókò wọ̀nyẹn, mo ń di aláìláyọ̀ gan-an.”
Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tí kò sí nínú agbo ilé náà kì í mọ ìyípadà tó ṣẹlẹ̀ nínú àkópọ̀ ìwà náà. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn olùṣètọ́jú kan ń rò pé àwọn dá wà, wọ́n sì ń dá gbé ẹrù ìnira wọn. Midori sọ pé: “Àrùn ẹ̀gbà náà ti sọ ọkọ mi di aláàbọ̀ ara ní ti èrò orí àti ìmọ̀lára. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó nílò ìṣírí lọ́pọ̀lọpọ̀, kì í bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ó sì ń dá jìyà. Nítorí náà, ó kù sí mi lọ́wọ́ láti bójú tó àwọn ìmọ̀lára rẹ̀. Rírí àwọn ìmọ̀lára ọkọ mi lójoojúmọ́ ń dà mí láàmú, ó sì ń bà mí lẹ́rù lọ́pọ̀ ìgbà.”
Báwo ni ọ̀pọ̀ lára àwọn tó yí àrùn ẹ̀gbà dá àti àwọn mọ̀lẹ́bí wọn ṣe kojú àwọn ìyípadà tí àrùn ẹ̀gbà mú wọ inú ìgbésí ayé wọn? Ní àwọn ọ̀nà wo ni ọ̀kọ̀ọ̀kan wa lè gbà ṣètìlẹ́yìn fún àwọn tí ìyọrísí asọni-daláìlè-ṣeǹkan ti àrùn ẹ̀gbà ń pọ́n lójú? Àpilẹ̀kọ wa tó kàn yóò ṣàlàyé.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Àmì Ìkìlọ̀
• Àárẹ̀; pajápajá; tàbí ojú, apá, tàbí ẹsẹ̀ tó rọ ní ẹ̀gbẹ́ kan ara, tí gbogbo rẹ̀ ṣẹlẹ̀ lójijì
• Ìríran tó ṣú dùdù tàbí tó ṣe bàìbàì lójijì, ní pàtàkì, ní ojú kan; ìṣẹ̀lẹ̀ kí ojú máa rí nǹkan kan ṣoṣo lọ́nà méjì
• Ìṣòro ní sísọ gbólóhùn kéékèèké pàápàá, tàbí lílóye wọn
• Òòyì tàbí àìlèséraró tàbí àìlèmára-ṣiṣẹ́pọ̀, ní pàtàkì, bí àmì àrùn míràn bá tún bá a rìn
Àwọn Àmì Àrùn Tí Kò Wọ́pọ̀ Tó Bẹ́ẹ̀
• Ẹ̀fọ́rí lílekoko tó ṣẹlẹ̀ lójijì, tí a kò sì mọ ohun tó fà á—tí a sábà ń pè ní “ẹ̀fọ́rí tó tí ì burú jù”
• Ìrìndọ̀ àti ara gbígbóná kọjá ààlà lójijì—tó yàtọ̀ sí àìsàn tí fáírọ́ọ̀sì fà ní ti bó ṣe yára bẹ̀rẹ̀ (láàárín ìṣẹ́jú tàbí wákàtí kàkà kó jẹ́ láàárín ọjọ́ mélòó kan)
• Ìpàdánù ìmọ̀lára fúngbà díẹ̀ tàbí sáà ìmọ̀lára tó lọ sílẹ̀ (òòyì, ìdàrú ọkàn, àìperí, dídákú)
Má Ṣàìka Àwọn Àmì Àrùn Sí
Dókítà David Levine rọni pé, nígbà tí àwọn àmì àrùn bá fara hàn, kí ẹni náà “tètè lọ sí ẹ̀ka ìtọ́jú pàjáwìrì nílé ìwòsàn bí ó bá ti lè yára tó. Ẹ̀rí wà pé bí a bá ṣètọ́jú àrùn ẹ̀gbà láàárín wákàtí mélòó àkọ́kọ́, ìbàjẹ́ náà lè mọ níwọ̀n.”
Nígbà míràn, àwọn àmì àrùn náà lè fara hàn fúngbà díẹ̀, kí wọ́n sì pòórá. Ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ni a mọ̀ sí ìṣẹ̀lẹ̀ àìtó ẹ̀jẹ̀ ní àwọn apá kan ara fúngbà díẹ̀. Má ṣàìkàwọ́nsí, nítorí wọ́n lè jẹ́ atọ́ka fún àwọn ewu àrùn ẹ̀gbà lílekoko, àrùn ẹ̀gbà sì lè ṣẹlẹ̀ ní kíkún lẹ́yìn náà. Dókítà kan lè ṣètọ́jú àwọn ohun tó ń fà á, kí ó sì dín ewu ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn ẹ̀gbà lọ́jọ́ iwájú kù
A fà á yọ láti inú àwọn ìlànà tí Àjọ Orílẹ̀-Èdè fún Ìgbógunti-Àrùn-Ẹ̀gbà, Englewood, Colorado, U.S.A., pèsè.