ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 2/8 ojú ìwé 3
  • Àrùn Ẹ̀gbà!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àrùn Ẹ̀gbà!
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kíkojú Àwọn Ìyọrísí Rẹ̀
    Jí!—1998
  • Àrùn Ẹ̀gbà—Ohun Tó Ń Fà Á
    Jí!—1998
  • Ìjẹ́rìí Tó Fa Kíki Látẹnu Àwọn Ọ̀dọ́
    Jí!—2005
  • KÍ LO KÀ SÍ OJÚLÓWÓ ÀṢEYỌRÍ?
    Jí!—2014
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 2/8 ojú ìwé 3

Àrùn Ẹ̀gbà!

ÀRÙN ẹ̀gbà gbapò iwájú nínú àwọn ohun tí ń fa ikú, tí ó sì ń sọ àwọn ènìyàn daláàbọ̀ ara títí lọ, ní àwọn orílẹ̀-èdè onílé iṣẹ́ ẹ̀rọ ní ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ayé. Àwọn kan tún ń pè é ní orúkọ tó fi bí “ìkọlù ọpọlọ” ṣe ń ṣẹlẹ̀ lójijì hàn. Ní ìṣẹ́jú kan, ara ẹni náà lè yá gágá, ní ìṣẹ́jú tó tẹ̀ lé e, ó lè dà bíi pé ẹdùn àrá ló ta bà á—ìkọlù àrùn ẹ̀gbà lílekoko lè yí ìwàláàyè ẹnì kan pa dà lójijì, lọ́nà gbígbàfiyèsí. Nípa bíba apá kan ara ẹnì kan jẹ́ tipátipá, àti sísọ ẹni náà di arọpárọsẹ̀ láìláàánú, ó lè sọ ọ́ di aláìlèsọ̀rọ̀, kí ó sọ ìmọ̀lára rẹ̀ dahoro, kí ó yí irú ìwà ẹ̀dá àti agbára ìrònú rẹ̀ pa dà, kí ó sì gbé ìlàkàkà tó jọ pé kò lópin láti jèrè ìgbésí ayé wíwàdéédéé tí ẹni náà àti ìdílé rẹ̀ ti ní tẹ́lẹ̀ karí rẹ̀.

Ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀ràn Ellen Morgan.a Ní Wednesday, ara Ellen, ẹni ọdún 64, le koko, ó sì yá gágá. Ní Thursday, nígbà tí òun àti ọkọ rẹ̀ ń nájà, lójijì ni Ellen kò lè sọ̀rọ̀ mọ́, tí ojú rẹ̀ sì yí pa dà sí ìrísí búburú. Gbogbo ara rẹ̀ rọ̀ wọjọrọ, ó sì ń fì dùgbẹ̀dùgbẹ̀ bí ẹni ọtí ń pa. Àrùn ẹ̀gbà lílekoko ti kọ lu Ellen!

Lẹ́yìn ìkọlù àrùn ẹ̀gbà náà, Ellen di aláàbọ̀-ara tó bẹ́ẹ̀ tí kò tilẹ̀ lè ṣe àwọn ohun tó kéré jù, bíi wíwẹ ara rẹ̀ tàbí wíwọṣọ. Nítorí pé kò lè kọ̀wé, kò lè hunṣọ, kò sì lè ránṣọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún láìdábọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, àárẹ̀ sì ń mú un. Ní gbogbo àkókò yí, kò sí ohun kankan tó ba agbára ìrònú Ellen jẹ; bí ó ti wù kí ó rí, ara máa ń tì í nígbà tó bá rò pé àwọn ẹlòmíràn ń wo òun bí aláìlérò-lórí. Lẹ́yìn náà, Ellen ṣàlàyé pé: “Ṣàṣà ènìyàn ló mọ bí ìkàyà ìyípadà òjijì yí ṣe ń nípa lórí ẹni tó, ní ti ìmọ̀lára àti èrò orí. Mo fẹ́rẹ̀ẹ́ rò pé òun ni òpin ìwàláàyè mi bí ẹnì kan.”

Kí ló ń fa àrùn ẹ̀gbà? Ṣé bákan náà ló ṣe ń nípa lórí gbogbo ẹni tó bá kọ lù? Báwo ni àwọn tó ti là á já ṣe kojú àrùn yí? Báwo ni àwọn mọ̀lẹ́bí àwọn tó la àrùn ẹ̀gbà já ṣe ń kojú rẹ̀? Kí ni gbogbo wa lè ṣe láti ṣètìlẹ́yìn? Jí! ṣàgbéyẹ̀wò irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀, ó sì mú òye nípa ìgbésí ayé àwọn tó la àrùn ẹ̀gbà já àti àwọn mọ̀lẹ́bí wọn, tó bá wọn ṣàjọpín ìlàkàkà wọn, wá fún ọ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nítorí ìgbatẹnirò fún àwọn aláìlera náà àti àwọn mọ̀lẹ́bí wọn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́