ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 2/8 ojú ìwé 29
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Nísinsìnyí, Mo Láyọ̀ Láti Wà Láàyè!
    Jí!—1997
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1998
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1998
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 2/8 ojú ìwé 29

Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Ìsìn àti Ogun Mo ń kọ̀wé láti fi ìmọrírì mi hàn fún ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ tí ó kún fún ìsọfúnni nípa ìsìn nínú ogun. (April 22, 1997) Àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́, “Pípànìyàn Lórúkọ Ọlọ́run,” gba àfiyèsí mi gan-an. Ó mọ níwọ̀n, ó sì sọ ojú abẹ níkòó, ní pàtàkì nígbà tí ó ń ṣàlàyé ohun tó fà á tí Jèhófà Ọlọ́run fi fọwọ́ sí i pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa àwọn ọmọ Kénáánì láyé àtijọ́.

S. J., United States

Ìtàn Ginger Klauss Ẹ jẹ́ kí ń sọ bí ìrírí Ginger Klauss náà, “Nísinsìnyí, Mo Láyọ̀ Láti Wà Láàyè!” (April 22, 1997), ṣe fún mi níṣìírí tó. Bíi tirẹ̀, èmi pẹ̀lú ro ara mi pin, mo nímọ̀lára pé n kò já mọ́ nǹkan kan, a kò sì nífẹ̀ẹ́ mi. Nítorí pé n kò lè kojú àwọn èrò ìmọ̀lára wọ̀nyẹn, pẹ̀lú omijé lójú ni mo máa ń sọ fún Ọlọ́run lójoojúmọ́ pé mo fẹ́ láti kú. Mo ka ikú sí ìdásílẹ̀ tí n óò fi ayọ̀ gbà. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, mo gbàdúrà pé, “Bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ rẹ, jọ̀wọ́ fún mi ní ìṣírí láti wà láàyè.” Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí mo gbàdúrà bẹ́ẹ̀ tán, ìtẹ̀jáde Jí! yìí tẹ̀ mí lọ́wọ́. Nígbà tí mo rí àpilẹ̀kọ yìí, ọkàn mi sọ pé Ọlọ́run ti dáhùn àdúrà mi. Mo kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ọ̀ràn Ginger pé níní ànímọ́ ìdẹ́rìn-ínpani, kí n má sì ro ara mi ju bó ti yẹ lọ lè ràn mí lọ́wọ́ láti máa ní ojú ìwòye pé nǹkan yóò dára nìṣó. Mo lè sọ dájúdájú pé ìwé ìròyìn yìí ní pàtàkì ti sún mi fẹ́ láti wà láàyè.

M. K., Japan

Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ parí kíka àpilẹ̀kọ náà ní ìgbà kẹfà ni, n óò sì tún máa kà á! Ọmọ ọdún 21 ni mí, mo sì jẹ́ ajíhìnrere alákòókò kíkún. Mo kan sáárá sí Ginger Klauss gan-an fún ìtara tí ó ní fún iṣẹ́ ìwàásù bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé orí àga arọ ló ń gbé. Ìrírí rẹ̀ sún mi láti sa gbogbo ipá mi láti sin Jèhófà.

S. Z., Ítálì

Ọpẹ́ mi kò lópin fún ìrírí arùmọ̀lára-sókè náà. Nítorí ìjoro iṣan, orí bẹ́ẹ̀dì ni mo ń gbé fún ọ̀pọ̀ àkókò lójoojúmọ́, ó sì máa ń ṣòro gan-an fún mi láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù lórí kẹ̀kẹ́ arọ. Ìrírí Ginger fún mi níṣìírí gan-an, ó sì ràn mí lọ́wọ́ láti kojú àwọn àkókò tí mo sorí kọ́ díẹ̀ wọ̀nyẹn nítorí àìlera mi.

M. R., Ítálì

Èrèdí Ṣíṣàìsàn Tó Bẹ́ẹ̀? Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Èé Ṣe Tí Mo Fi Ń Ṣàìsàn Tó Bẹ́ẹ̀?” (April 22, 1997) Ọmọ ọdún 21 ni mí, mo sì ní àrùn fòníkúfọ̀larùn. Mo lóye ìmọ̀lára àwọn ọ̀dọ́ tí a kọ sínú àpilẹ̀kọ yìí. Mo sábà máa ń ṣe kàyéfì bí mo bá lè rí ẹnikẹ́ni tí yóò nífẹ̀ẹ́ mi, tí yóò sì fẹ́ láti fi mí ṣe aya bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ní àìlera yìí. Ṣùgbọ́n àpilẹ̀kọ yín ràn mí lọ́wọ́ nítorí pé mo ti wá mọ̀ nísinsìnyí pé èmi nìkan kọ́ ni mo ń ní irú ìmọ̀lára yìí.

D. R., United States

Ọ̀rẹ́ Tí Kò Ṣeé Yà Nípa Ẹ ṣeun fún ìrírí Anne-Marie Evaldsson. (April 22, 1997) Mo kan sáárá sí arábìnrin yìí nítorí ọ̀nà tí ó ń gbà tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí láìka pé ó ní àbùkù ara sí. Àkọsílẹ̀ náà mú mi ronú. Ọ̀pọ̀ lára àwa kò mọyì ohun tí a fún wa láti lò nínú sísin Jèhófà. N óò fẹ́ láti gbóríyìn fún arábìnrin náà àti ọ̀rẹ́ adúrótini rẹ̀. Ẹ wo irú àpẹẹrẹ rere tí èyí jẹ́!

R. A., Ecuador

Láti mọ̀ pé ẹni tí ojú rẹ̀ fọ́ ń ṣiṣẹ́, ó ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé, ó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni lọ́sọ̀ọ̀ṣẹ̀ ń fúnni níṣìírí gidigidi. Ó mú mi nímọ̀lára pé sísa gbogbo ipá mi nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, fífi í sí ipò kíní, yẹ fún ìsapá náà. Ìníyelórí ìríran nípa tẹ̀mí ta yọ lọ́lá ní tòótọ́. N óò máa rántí Anne-Marie Evaldsson pẹ̀lú ìfẹ́ jíjinlẹ̀ àti ìmọrírì.

J. O., Nàìjíríà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́