ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 4/22 ojú ìwé 20-23
  • Nísinsìnyí, Mo Láyọ̀ Láti Wà Láàyè!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nísinsìnyí, Mo Láyọ̀ Láti Wà Láàyè!
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìfẹ́ Ọkàn fún Ohun Kan Tí Ó Sàn Jù
  • Fífẹ́ Láti Kú Lẹ́ẹ̀kan Sí I
  • Kíkojú Yánpọnyánrin Kan
  • Ìrọni Láti Gbẹ̀jẹ̀
  • Iṣẹ́ Abẹ—Ó Kẹ́sẹ Járí
  • Ìrànlọ́wọ́ Láti Ọ̀dọ Ẹgbẹ́ Ará Wa
  • Ìrètí Dídájú Kan Mú Mi Dúró
  • Kíkojú Ọ̀ràn Ìṣègùn Àìròtẹ́lẹ̀
    Jí!—1996
  • Mo Kún fun Ìmoore fun Itilẹhin Jehofa tí Kìí Kùnà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Òtítọ́ fún Mi ní Ìwàláàyè Mi Padà
    Jí!—1996
  • “Wàá Kàn Kú Dànù Ni!”
    Jí!—2000
Jí!—1997
g97 4/22 ojú ìwé 20-23

Nísinsìnyí, Mo Láyọ̀ Láti Wà Láàyè!

Dókítà náà béèrè pé: “O mọ̀ pé o máa kú, àbí o kò mọ̀?” Lọ́nà títakora, ikú ì bá ti jẹ́ ìdáǹdè tí mo fọkàn fẹ́ nígbà méjì ṣáájú. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí kọ́. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé.

A TỌ́ mi dàgbà ní Long Island, ìgbèríko New York, níbi tí bàbá mi ti jẹ́ gbajúmọ̀ awakọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àfidíje. Ó jẹ́ ẹni tí ó máa ń fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn ṣe nǹkan lọ́nà tí kò lábùkù, ìbánidíje ló sì ń mú inú rẹ̀ dùn. A kò lè sọ ohun tí yóò ṣe ṣáájú, kò sì ṣeé tẹ́ lọ́rùn. Ní ìhà kejì, Mọ́mì jẹ́ alálàáfíà, tí ń ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, bí Dádì sì ṣe ń wakọ̀ sáré ìdíje ń bà á lẹ́rù tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi lè máa wòran nígbà tí dádì bá ń díje.

Èmi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin ti kọ́ láti máa ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ nílé, ohun kan tí ó ti mọ́ Mọ́mì lára. Ṣùgbọ́n kò rọrùn. Gbogbo wa ni ẹ̀rù Dádì ń bà. Ó nípa lórí mi débi pé n kò ronú pé mo lè ṣe ohun kan lọ́nà títọ́ láé. Ọ̀wọ̀ ara ẹni mi túbọ̀ dín kù nígbà tí “ọ̀rẹ́” ìdílé wa kan fi ìbálòpọ̀ fòòró mi, nígbà tí mo wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà àṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà. Nígbà tí n kò lè kojú àwọn ìmọ̀lára mi, mo gbìyànjú láti pa ara mi. Ìyẹn ni ìgbà kíní tí mo rò pé ikú ì bá ti jẹ́ ìdáǹdè tí mo fọkàn fẹ́.

Mo nímọ̀lára pé n kò já mọ́ nǹkan kan, a kò fẹ́ràn mi, mo sì ní ìṣiṣẹ́gbòdì kan tí ó ní í ṣe pẹ̀lú oúnjẹ jíjẹ, tí ó máa ń wọ́pọ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́bìnrin tí iyì ara ẹni wọn kéré. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésí ayé wíwá ìmóríyá kiri, jíjẹ oògùn yó, ṣíṣe àgbèrè, àti ṣíṣẹ́ oyún—“ní wíwá ìfẹ́ kiri ní gbogbo ibi tí kò yẹ,” gẹ́gẹ́ bí ìlà orin kan ṣe lọ. Mo kó wọnú gígun alùpùpù kiri, wíwa ọkọ̀ sá eré ìdíje, àti mímòòkùn nínú omi nípa lílo ohun èèlò àfimí lábẹ́ omi, mo sì ń rin ìrìn àjò lọ sí Las Vegas láti lọ ta tẹ́tẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Mo tún wá ìrànwọ́ lọ sọ́dọ̀ aláfọ̀ṣẹ kan, mo sì lo ọpọ́n Ouija fún ìmóríyá, láìmọ àwọn ewu tí ó wà nínú bíbá ẹ̀mí lò.—Diutarónómì 18:10-12.

Ní àfikún, wíwá ìmóríyá kiri mú kí n lọ́wọ́ sí àwọn ìgbòkègbodò tí kò bófin mu bíi ṣíṣòwò oògùn olóró àti fífẹ́wọ́ nílé ìtajà. Bí mo ṣe ń wá ìfẹ́ àti ìtẹ́wọ́gbà kiri pẹ̀lú yọrí sí níní ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́kùnrin àti àfẹ́sọ́nà. Gbogbo kókó wọ̀nyí para pọ̀ di ọ̀nà ìgbésí ayé kan tí ó túbọ̀ léwu ju bí mo ti mọ̀ lọ.

Lálẹ́ ọjọ́ kan, lẹ́yìn mímu ọtí líle pọ̀ mọ́ oògùn líle níbi ìrọpo ọkọ àfidíje lójú ọ̀nà ìwakọ̀díje, mo fi ìwà òmùgọ̀ gba ọ̀rẹ́kùnrin mi láyè láti wà mí lọ sílé. Lẹ́yìn tí mo ti sùn wọra sórí àga iwájú ọkọ̀ náà, ní kedere, òun náà sùn wọra. Ipá ìkọlura kan ló ta mí jí. Mo fara pa púpọ̀, wọ́n sì gbà mí sílé ìwòsàn, ṣùgbọ́n mo kọ́fẹ pa dà níkẹyìn, àfi ti orúnkún mi ọ̀tún tí mo fi pa.

Ìfẹ́ Ọkàn fún Ohun Kan Tí Ó Sàn Jù

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, n kò mọrírì ìwàláàyè èmi fúnra mi, mo máa ń dàníyàn gidigidi nípa ààbò àti ẹ̀tọ́ àwọn ọmọdé àti ẹranko, àti nípa dídáàbò bo àyíká. Mo ń yán hànhàn fún ayé kan tí ó sàn jù, mo ń kópa alákitiyan nínú ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́, nínú ìgbìyànjú láti ṣèrànwọ́ láti ṣẹ̀dá ọ̀kan. Ìfẹ́ ọkàn fún ayé kan tí ó sàn jù yí ni ohun tí ó kọ́kọ́ fà mí mọ́ àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ mi kan, tí ó jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, máa ń sọ. Ó máa ń tọ́ka sí “ètò ìgbékalẹ̀ yí” lọ́nà tí ń fi ìjákulẹ̀ hàn, nígbàkigbà tí nǹkan kò bá lọ déédéé lẹ́nu iṣẹ́. Nígbà tí mo béèrè ohun tí ó ní lọ́kàn lọ́wọ́ rẹ̀, ó ṣàlàyé pé, lọ́jọ́ kan láìpẹ́, ìgbésí ayé yóò bọ́ lọ́wọ́ gbogbo hílàhílo. Níwọ̀n bí mo ti bọ̀wọ̀ fún un gidigidi, mo tẹ́tí sí i pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn púpọ̀.

Ó bani nínú jẹ́ pé a kò ríra mọ́, ṣùgbọ́n n kò fìgbà kankan gbàgbé àwọn ohun tí ó sọ. Mo mọ̀ pé lọ́jọ́ kan, mo ní láti ṣe ìyípadà kíkàmàmà nínú ọ̀nà ìgbésí ayé mi kí n lè tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Ṣùgbọ́n n kò múra tán. Síbẹ̀, mo máa ń sọ fún ẹni tí mo bá fojú sùn láti bá ṣègbéyàwó pé, lọ́jọ́ kan ṣáá, n óò di Ẹlẹ́rìí kan, bí wọn kò bá sì fẹ́ bẹ́ẹ̀, àkókò nìyí fún wa láti pínyà.

Àbáyọrí rẹ̀ ni pé, ọ̀rẹ́kùnrin tí mo ní kẹ́yìn fẹ́ láti mọ̀ sí i, ó sọ pé bí mo bá ní ọkàn ìfẹ́ bẹ́ẹ̀, òun pẹ̀lú lè ní in. Nítorí náà, a bẹ̀rẹ̀ sí í wá Àwọn Ẹlẹ́rìí. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n wá wa rí nígbà tí wọ́n ṣèbẹ̀wò sí ẹnu ọ̀nà iwájú ilé mi. A bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, ṣùgbọ́n níkẹyìn, ọ̀rẹ́kùnrin mi yàn láti ṣíwọ́ kíkẹ́kọ̀ọ́, ó sì pa dà sọ́dọ̀ ìyàwó rẹ̀.

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi kò lọ déédéé. Ó gbà mí lákòókò láti mọrírì ojú ìwòye Jèhófà nípa ìjẹ́mímọ́ ìwàláàyè. Bí ó ti wù kí ó rí, ní kété tí mo ṣàtúnṣe ìrònú mi, mo rí àìní náà láti fagi lé àwọn ìrìn àjò tí a ti máa ń fò bọ́ láti inú ọkọ̀ òfuurufú, tí a sì ń fara pidán lóríṣiríṣi kí a tó rọ̀ mọ́ okùn ààbò, kí n sì ṣíwọ́ mímu sìgá. Bí ìgbésí ayé ṣe wá túbọ̀ ń ṣeyebíye sí mi, mo ṣe tán láti gbé ìgbésí ayé tí ó fọkàn ẹni balẹ̀, kí n má sì fi ìwàláàyè mi wewu mọ́. Ní October 18, 1985, mo fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi fún Jèhófà hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi. N kò mọ pé láìpẹ́, ìwàláàyè mi yóò wà nínú ewu.

Fífẹ́ Láti Kú Lẹ́ẹ̀kan Sí I

Oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà—ní alẹ́ March 22, 1986—mo wà níwájú ilé mi, mo ń kó àwọn aṣọ tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ fọ̀ jáde nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mi, nígbà tí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan tí ń sáré àsápajúdé kọ lù mí, tí ó sì wọ́ mi tuuru ju 30 mítà lọ! Akọluni náà sá lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo fi orí pa, síbẹ̀ mo mọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní gbogbo àkókò náà.

Ní ìdojúbolẹ̀ láàárín ọ̀nà tí ó ṣókùnkùn kan, gbogbo ohun tí mo lè ronú rẹ̀ ni ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ti pé kí ọkọ̀ míràn tún kọ lù mí. Ìrora náà le gan-an, ó ju ohun tí mo lè mú mọ́ra lọ. Nítorí náà, mo ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kí ó jẹ́ kí n kú. (Jóòbù 14:13) Obìnrin kan tí ó jẹ́ nọ́ọ̀sì yọ síbẹ̀. Mo bẹ̀ ẹ́ pé kí ó bá mi tún àwọn ẹsẹ̀ mi tí ó ti rún gbé sípò bó ti yẹ. Ó ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì tilẹ̀ tún fi díẹ̀ lára aṣọ rẹ̀ ṣe báńdéèjì tí ó fi dá ẹ̀jẹ̀ tí ń dà láti ibi egungun tí ó fọ́ nínú ẹsẹ̀ kan. Wọ́n rí bàtà mi níbi tó jìn díẹ̀, ẹ̀jẹ̀ kún inú rẹ̀!

Àwọn tí ń kọjá lọ, láìmọ̀ pé ẹsẹ̀ ni mo fi rìn, ń béèrè ibi tí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mi wà. Láìmọ bí ó ṣe wọ́ mi jìnnà tó, mo rò pé mo ṣì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkọ̀ mi! Nígbà tí àwọn oníṣègùn dé, wọ́n rò pé n óò kú ni. Nítorí náà, wọ́n ké sí àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́, nítorí pé, ìfọkọ̀pànìyàn lè jẹ́ ìwà ọ̀daràn oníjìyà ikú. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n mú awakọ̀ náà. Wọ́n sàmì sí àgbègbè náà bí ibi ìṣẹ̀lẹ̀ ìwà ọ̀daràn kan, wọ́n sì gbẹ́sẹ̀ lé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí. Ilẹ̀kùn méjèèjì tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ kan tí já sọ nù.

Kíkojú Yánpọnyánrin Kan

Nígbà kan náà, nígbà tí mo dé ibùdó àdúgbò fún ìtọ́jú ìpalára tí ó kan iṣan, kódà nígbà tí wọ́n fi ohun èlò àfimí afẹ́fẹ́ oxygen bò mí nímú àti lẹ́nu, mo ń wí pé: “N kò fẹ́ ẹ̀jẹ̀, n kò fẹ́ ẹ̀jẹ̀. Mo jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà!” Ohun tí mo rántí kẹ́yìn ni ìmọ̀lára mi nígbà tí wọ́n ń gé aṣọ kúrò lára mi, mo sì ń gbọ́ tí àwọn agbo òṣìṣẹ́ ìtọ́jú ìpalára tí ó kan iṣan ń pàṣẹ lọ́nà tí ń fi ìmọ̀lára kánjúkánjú hàn.

Nígbà tí mo ta jí, ó yà mí lẹ́nu pé mo ṣì wà láàyè. Bí mo ti ń nímọ̀lára fúngbà díẹ̀ ni ìmọ̀lára mi ń lọ fúngbà díẹ̀. Nígbà kọ̀ọ̀kan tí mo bá ta jí, mo ń béèrè pé kí àwọn ẹbí mi kàn sí tọkọtaya tí ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inú àwọn mọ̀lẹ́bí mi kò dùn pé mo di Ẹlẹ́rìí, nítorí náà, kò ṣòro fún wọn láti “gbàgbé” láti kàn sí wọn. Ṣùgbọ́n n kò mẹ́nu kúrò—ohun àkọ́kọ́ tí mo ń béèrè nígbàkigbà tí mo bá yajú nìyẹn. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, àwíìyannu mi méso wá, nígbà tí mo sì ta jí lọ́jọ́ kan, wọ́n wà níbẹ̀. Ẹ wo irú ìtura tí ó jẹ́! Àwọn ènìyàn Jèhófà mọ ibi tí mo wà.

Bí ó ti wù kí ó rí, ayọ̀ mi kò wà pẹ́, nítorí ìwọ̀n ẹ̀jẹ̀ mi bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù, ara mi sì koná lala. Wọ́n yọ àwọn egungun tí wọ́n fura sí pé ó ń fa àìlera náà kúrò, wọ́n sì fi àwọn ọ̀pá mẹ́rin, tí wọ́n fi irin ṣe, tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ abẹ, sínú ẹsẹ̀ mi. Àmọ́ láìpẹ́, ara kíkóná lala náà tún pa dà wá, ẹsẹ̀ mi sì dúdú. Ó ti di egbò kíkẹ̀, ọ̀nà tí mo sì lè gbà là á já ni kí wọ́n gé ẹsẹ̀ náà kúrò.

Ìrọni Láti Gbẹ̀jẹ̀

Nítorí pé ìwọ̀n ẹ̀jẹ̀ ara mi ti lọ sílẹ̀ gan-an, wọ́n gbà pé iṣẹ́ abẹ kò lè ṣeé ṣe láìsí ìfàjẹ̀-sínilára. Wọ́n pe àwọn dókítà, nọ́ọ̀sì, mẹ́ńbà ìdílé, àti àwọn ọ̀rẹ́ mi àtijọ́ wá láti rọ̀ mí. Lẹ́yìn náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lẹ́nu ọ̀nà mi. Mo yọ́ ọ gbọ́ nígbà tí àwọn dókítà ń yọ́ ọ̀rọ̀ sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lẹ́nu ilẹ̀kùn mi, pé wọ́n ń wéwèé láti ṣe nǹkan kan, ṣùgbọ́n n kò mọ ohun tí ó jẹ́. Lọ́nà àrìnnàkore, Ẹlẹ́rìí kan tí ó wá bẹ̀ mí wò nígbà náà gbọ́ ìwéwèé náà láti gbìyànjú fipá fa ẹ̀jẹ̀ sí mi lára. Ó kàn sí àwọn Kristẹni alàgbà ládùúgbò lọ́gán, wọ́n sì wá ràn mí lọ́wọ́.

Wọ́n háyà oníṣègùn ọpọlọ kan láti ṣe ìdíyelé ipò tí mo wà ní ti èrò orí. Ó ṣe kedere pé, ète tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kí àwọn kà mí sí ẹni tí kò lè dá ìpinnu ṣe, kí awọn sì tipa bẹ́ẹ̀ fagi lé ìfẹ́ ọkàn mi. Ìwéwèé yìí kùnà. Lẹ́yìn náà ni wọ́n mú mẹ́ńbà ẹgbẹ́ àlùfáà kan, tí òun fúnra rẹ̀ ti gba ẹ̀jẹ̀ sára wá, kí ó lè wá mú un dá mi lójú pé gbígba ẹ̀jẹ̀ sára ṣètẹ́wọ́gbà. Níkẹyìn, àwọn mọ̀lẹ́bí mi wá àṣẹ ilé ẹjọ́ láti fa ẹ̀jẹ̀ sí mi lára tipátipá.

Ní nǹkan bí agogo méjì òru, agbo àwọn dókítà kan, akọ̀wé ayára-bí-àṣá kan láti ilé ẹjọ́, apínwèé-ìpẹ̀jọ́ kan, àwọn amòfin tí ń ṣojú ilé ìwòsàn náà, àti adájọ́ kan, wọ inú iyàrá tí mo ti ń gbàtọ́jú wá. Ìgbẹ́jọ́ kan ń lọ lọ́wọ́. A kò sọ fún mi tẹ́lẹ̀, kò sí Bíbélì, kò sí agbẹjọ́rò, a sì ti lo egbòogi ìpàrora fún mi gan-an. Kí ni àbájáde ìgbẹ́jọ́ náà? Adájọ́ náà fi àṣẹ ilé ẹjọ́ dù wọ́n, ó sọ pé ìdúróṣinṣin Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà túbọ̀ wọ òun lọ́kàn ju ti ìgbàkigbà rí lọ.

Ilé ìwòsàn kan ní Camden, New Jersey, gbà láti ṣètọ́jú mi. Nítorí pé inú bí àwọn aláṣẹ ilé ìwòsàn ní New York, wọ́n dáwọ́ gbogbo ìtọ́jú mi dúró, títí kan àwọn egbòogi apàrora. Wọ́n tún kọ̀ láti gba ọkọ̀ òfuurufú kékeré tí ó yẹ kí ó gbé mi lọ sí ilé ìwòsàn New Jersey náà láyè láti balẹ̀. Ọpẹ́ ni pé mo gúnlẹ̀ láyọ̀ lẹ́yìn wíwọ ọkọ̀ tí wọ́n fi ń gbé aláìsàn lọ síbẹ̀. Nígbà tí mo gúnlẹ̀, mo gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí mo mẹ́nu bà níbẹ̀rẹ̀ ìtàn yí pé: “O mọ̀ pé o máa kú, àbí o kò mọ̀?”

Iṣẹ́ Abẹ—Ó Kẹ́sẹ Járí

Ó rẹ̀ mí gan-an débi pé, nọ́ọ̀sì kan ní láti bá mi kọ àmì X sórí fọ́ọ̀mù ìjọ́hẹn láti jẹ́ kí a lè ṣe iṣẹ́ abẹ náà. Wọ́n ní láti gé ẹsẹ̀ mi ọ̀tún lókè orúnkún. Lẹ́yìn náà, ìwọ̀n ẹ̀jẹ̀ ara mi dín sí 2, àwọn dókítà sì lérò pé, ìpalára gidigidi yóò ti bá ọpọlọ mi. Ohun tó fà á ni pé, nígbà tí wọ́n ń pe “Virginia, Virginia”—orúkọ tí mo fi sórí ìwé tí wọ́n fi gbà mí sílé ìwòsàn ní etí mi, wọn kò gbọ́ ìdáhùn kankan. Ṣùgbọ́n nígbà tí mo gbọ́ tí ẹnì kan fẹ̀sọ̀ pe “Ginger, Ginger,” lẹ́yìn náà, mo la ojú mi, mo sì rí ọkùnrin kan tí n kò rí rí.

Bill Turpin wá láti ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àdúgbò kan ní New Jersey. Ó ti mọ orúkọ ìnagijẹ mi, Ginger—tí àwọn ènìyàn ti fi mọ̀ mí jálẹ̀ ìgbésí ayé mi—láti ọ̀dọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí ní New York. Ó wéwèé àwọn ìbéèrè tí mo lè dáhùn nípa wíwulẹ̀ ṣẹ́jú, níwọn bí mo ti ń lo ẹ̀rọ àfimí tí n kò sì lè lanu sọ̀rọ̀ rárá. Ó béèrè pé: “Ǹjẹ́ o fẹ́ kí n máa wá bẹ̀ ọ́ wò, kí n sì sọ fún Àwọn Ẹlẹ́rìí ní New York nípa rẹ?” Mo ṣẹ́jú láìmọye ìgbà láti fi hàn pé mo fara mọ́ ọn! Arákùnrin Turpin ti fẹ̀mí wewu nípa yíyọ́ wọ inú iyàrá mi, nítorí pé àwọn mọ̀lẹ́bí mi ti pàṣẹ pé n ko gbọ́dọ̀ gbàlejò Ẹlẹ́rìí kankan.

Lẹ́yìn tí mo ti lo oṣù mẹ́fà nílé ìwòsàn, ìwọ̀nba àwọn ohun àìgbọ́dọ̀máṣe ojoojúmọ́ ni mo lè ṣe fúnra mi, bíi kí n jẹun kí n sì fọ ẹnu mi. Níkẹyìn, mo gba ẹsẹ̀ àtọwọ́dá kan, ó sì ṣeé ṣe fún mi láti rìn kiri díẹ̀ ní lílo ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ kan. Nígbà tí mo kúrò nílé ìwòsàn ní September 1986, tí mo sì pa dà délé mi, òṣìṣẹ́ ìrànwọ́ ìlera kan gbé ọ̀dọ̀ mí fún nǹkan bí oṣù mẹ́fà míràn láti máa ràn mí lọ́wọ́.

Ìrànlọ́wọ́ Láti Ọ̀dọ Ẹgbẹ́ Ará Wa

Kí n tó pa dà délé pàápàá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í mọyì ohun tí jíjẹ́ apá kan ẹgbẹ́ ará Kristẹni túmọ̀ sí ní ti gidi. (Máàkù 10:29, 30) Kì í ṣe kìkì pé àwọn arákùnrin àti arábìnrin fi ìfẹ́ bójú tó àwọn àìní mi nípa ti ara nìkan ni, ṣùgbọ́n wọ́n tún bójú tó àwọn àìní mi nípa tẹ̀mí pẹ̀lú. Nípa ìrànwọ́ onífẹ̀ẹ́ wọn, ó ṣeé ṣe fún mi láti tún bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni, bí àkókò sì ti ń lọ, kí n nípìn-ín nínú ohun tí a ń pè ní iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.

Láàárín oṣù mélòó kan péré, wọ́n yanjú ẹjọ́ tí wọn pe awakọ̀ náà, tí ó sábà ń gba ọdún márùn-ún, ó kéré tán, kí wọ́n tó dá ìgbà tí wọn yóò gbọ́ ọ—sí ìyàlẹ́nu agbẹjọ́rò mi. Ìwọ̀nba owó tí mo gbà lórí ẹjọ́ náà mú kí ó ṣeé ṣe fún mi láti kó lọ sí ilé kan tí ó túbọ̀ ṣeé dé. Ní àfikún, mo ra ọkọ̀ kan tí ó ní ẹ̀rọ agbága-onítáyà-ròkè àti ìṣètò ìfọwọ́darí. Nípa bẹ́ẹ̀, ní 1988, mo wọ òtú àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé, ní lílo 1,000 wákàtí, ó kéré tán, nínú iṣẹ́ ìwàásù lọ́dún kọ̀ọ̀kan. Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, mo ti gbádùn ṣíṣiṣẹ́ ní àwọn àgbègbè ìpínlẹ̀ ní àwọn ìpínlẹ̀ Àríwá Dakota, Alabama, àti Kentucky. Mo ti fi ọkọ̀ mi rìn lé ní 150,000 kìlómítà, ọ̀pọ̀ jù lọ rẹ̀ sì jẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni.

Mo ti ní ọ̀pọ̀ ìrírí apanilẹ́rìn-ín nínú bí mo ṣe ń lo alùpùpù ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta mi tí ń lo iná mànàmáná. Mo ti yí ṣubú lórí rẹ̀ nígbà méjì tí mo ń bá àwọn ìyàwó alábòójútó àyíká ṣiṣẹ́. Lẹ́ẹ̀kan, ní Alabama, mo fàṣìṣe ronú pé mo lè gùn ún fo omi kékeré kan tí ń ṣàn térétéré síhà kejì, mo sì ṣubú lulẹ̀, ẹrẹ̀ sì bò mí. Síbẹ̀, lílo ọgbọ́n ìdẹ́rìn-ínpani àti ṣíṣàìro ara mi ju bí ó ti yẹ lọ ti ràn mí lọ́wọ́ láti máa ní ìṣarasíhùwà títọ̀nà nìṣó.

Ìrètí Dídájú Kan Mú Mi Dúró

Àwọn ìṣòro ìlera nígbà míràn máa ń fẹ́rẹ̀ẹ́ kọjá agbára. Nígbà méjì ni mo ti ní láti ṣíwọ́ ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn nítorí pé ó jọ pé ó di dandan kí a gé ẹsẹ̀ mi kejì. Ewu pé mo lè pàdánù ẹsẹ̀ mi ń ṣe lemọ́lemọ́ nísinsìnyí, mo sì ti wà lórí àga onítáyà pátápátá fún ọdún márùn-ún tó kọjá. Ní 1994, mo fi apá dá. Mo nílò ìrànlọ́wọ́ láti wẹ̀, láti wọṣọ, láti gbọ́únjẹ, àti láti tún ilé ṣe, àfi kí wọ́n sì máa gbé mi lọ síbikíbi. Síbẹ̀, nítorí ìrànwọ́ tí àwọn ará ń ṣe, ó ṣeé ṣe fún mi láti máa bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lọ la ìfàsẹ́yìn yí já.

Jálẹ̀jálẹ̀ ìgbésí ayé mi, mo wá ohun tí ó jọ ìmóríyá, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, mo mọ̀ pé àkókò amóríyá jù lọ ń bẹ níwájú. Ohun tí ń mú mi láyọ̀ láti wà láàyè nísinsìnyí ni ìdánilójú tí mo ní pé Ọlọ́run yóò wo gbogbo àìlera ìsinsìnyí sàn nínú ayé tuntun rẹ̀, tí ń yára wọlé bọ̀. (Aísáyà 35:4-6) Nínú ayé tuntun yẹn, mo ń fojú sọ́nà láti bá àwọn ẹja àbùùbùtán àti òbéjé lúwẹ̀ẹ́, kí n bá kìnnìún kan àti àwọn ọmọ rẹ̀ rìn kiri ní àwọn òkè ńláńlá, kí n sì ṣe nǹkan rírọrùn kan bíi rírìn ní etíkun kan. Fífojú inú wo ṣíṣe gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run dá wa láti gbádùn nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé yẹn ń mú inú mi dùn.—Bí Ginger Klauss ṣe sọ ọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Nígbà tí títa tẹ́tẹ́ jẹ́ apá kan ìgbésí ayé mi

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwọn ìlérí Ọlọ́run mú mi dúró

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́