Ó Wọ̀ Ọ́ Lọ́kàn
Gloria Adame kọ̀wé pé: “Mẹ́tàlá ni àwa ọmọ inú ìdílé wa, ọkùnrin mẹ́rin, obìnrin mẹ́sàn-án. Ọdún 1984 ni. Bàbá ti darí wálé sí Mexico, ó sì rí i pé, nígbà tí òun wà níbi tí òun ti ń ṣiṣẹ́ ní United States, ìdílé wa ti bẹ̀rẹ̀ sí í bá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò dùn mọ́ ọn nínú rárá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ta kò wá. Ó jọ pé bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọjá ni ọkàn-àyà rẹ̀ ń le sí i.
“A nífẹ̀ẹ́ bàbá wa púpọ̀, a sì fẹ́ kí ó jàǹfààní láti inú ìmọ̀ tí ń fúnni ní ìyè tí a ń rí gbà. Lójoojúmọ́, a ń gbàdúrà tìtaratìtara sí Jèhófà, a ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó ṣí ọ̀nà fún wa láti bá Bàbá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ètè Jèhófà. Jèhófà gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa nítorí pé ó fún wa ní ìgboyà láti máa kóra jọ pọ̀ nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, nínú iyàrá tí Bàbá ti máa ń wo tẹlifíṣọ̀n lálaalẹ́. Níbẹ̀ ni àwa ọmọbìnrin àti màmá mi ń pàdé pọ̀ láti ka ẹsẹ Bíbélì ojoojúmọ́.
“Màmá ló ń darí ìjíròrò náà, lẹ́yìn tí a bá sì ti ka àlàyé náà tán, a óò pín àdúrà gbà láàárín ara wa. Nígbà tí àbúrò wa kékeré, Marie, tó jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún péré bá ń gbàdúrà, ó máa ń fìtara bẹ Jèhófà pé: ‘Jèhófà, jọ̀wọ́ jẹ́ kí ọkàn-àyà Dádì rọ̀, kí òun náà lè di Ẹlẹ́rìí rẹ.’ Ó jọ pé Bàbá kì í tẹ́tí sí wa, nítorí pé ó máa ń yí ohun tẹlifíṣọ̀n náà sókè gan-an. Bí ó ti wù kí ó rí, bí àkókò ṣe ń lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í yí ohùn náà sílẹ̀, títí di alẹ́ ọjọ́ tí ó kúkú pa tẹlifíṣọ̀n náà gan-an.
“Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, bí a ti máa ń ṣe, Màmá béèrè ẹni tó kàn láti ka ẹsẹ náà. Ó yà wá lẹ́nu bí Bàbá ṣe wí pé: ‘Èmi ló kàn.’ Ẹnu yà wá, àmọ́ a kò sọ ohunkóhun. Màmá kò janpata, kò sì béèrè ìbéèrè kankan, ṣùgbọ́n ó mú ìwé pẹlẹbẹ náà, Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́, fún un. Lẹ́yìn tí Bàbá ti darí ìjíròrò ẹsẹ Bíbélì náà, Màmá béèrè ẹni tó kàn láti gbàdúrà. Bàbá wí pé: ‘Èmi ló kàn.’
“A kò lè sọ̀rọ̀. Láàárín àdúrà náà, a kò lè kápá ẹkún tó ń gbọ̀n wá mọ́. Bàbá pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún, ó sì bẹ Jèhófà pé kí ó dárí ji òun nítorí pé òun ti sọ̀rọ̀ òdì nípa Rẹ̀. Ó tún bẹ Màmá láti dárí ji òun nítorí pé òun ti ta kò wá.
“Nítorí náà, ní 1986, àtakò tí bàbá wa ń ṣe wá sópin. Ní 1990, ìdílé wa ṣí lọ sí Texas ní United States. Láìpẹ́, Bàbá ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó sì fi ẹ̀rí rẹ̀ hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi, bí méje nínú àwa ọmọbìnrin ti ṣe. A yan Bàbá sí ipò Kristẹni alàgbà ní April 1997. Títí di òní olónìí, ṣíṣàyẹ̀wò ẹsẹ Bíbélì lójoojúmọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé ṣe pàtàkì sí wa gidigidi, àdúrà sí Jèhófà sì jẹ́ ìpìlẹ̀ kan fún ìgbésí ayé ìdílé wa.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
1. Àwọn ọmọbìnrin mẹ́rin tí ń ṣe aṣáájú ọ̀nà ní Mexico. Marie ló wà níwájú
2. Juanita àti Isaac Adame, pẹ̀lú àwọn kan nínú àwọn ọmọ wọn. Gloria ló wà ní ìkángun lápá ọ̀tún