Kí Ló Ṣẹlẹ̀ Sí Ẹ̀yà Apache?
TA NI a pè ní, “Ẹni tí ojú rẹ̀ le jù láyé”? Síbẹ̀, ta ni a mọ̀ nítorí ìgboyà àti ìmúratán rẹ̀ títayọ? Ẹni náà ni aṣáájú ẹ̀yà Apache tí ó túúbá fún Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun United States kẹ́yìn. Ó gbé nǹkan bí 80 ọdún láyé, ó sì kú ní 1909 ní Oklahoma, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ara Kristẹni ti Ìjọ Alátùn-únṣe ti Dutch. Ẹni náà ni Goyathlay (tí pípè rẹ̀ jẹ́ Goyahkla), tí a mọ̀ sí Geronimo, aṣáájú tí ó lágbára jù lọ tí ó kẹ́yìn fún ẹ̀yà Apache.
A gbọ́ pé wọ́n wá pè é ní Geronimo lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Mexico ké gbàjarè sí Jerome (Jerónimo) “Mímọ́” nítorí ìbẹ̀rù nígbà tí Goyathlay gbógun tì wọ́n. Ní nǹkan bí ọdún 1850, ikọ̀ ọmọ ogun ilẹ̀ Mexico pa àwọn obìnrin àti ọmọdé 25 tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà Apache tí wọ́n pàgọ́ sí ẹ̀yìn odi Janos, Mexico. Ìyá Geronimo, ìyàwó rẹ̀ kékeré, àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta wà lára wọn. A gbọ́ pé, “ní gbogbo ìyókù ìgbésí ayé Geronimo, ó kórìíra gbogbo àwọn ará Mexico.” Bí ìfẹ́ ọkàn àtigbẹ̀san ti ń tì í gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n, ó di ọ̀kan lára àwọn olóyè tí a bẹ̀rù jù lọ nínú ẹ̀yà Apache.
Ṣùgbọ́n kí ni a mọ̀ nípa àwọn Àmẹ́ríńdíà ẹ̀yà Apache, tí àwọn fíìmù Hollywood sábà máa ń fi hàn bí ọ̀dàlẹ̀? Ǹjẹ́ wọ́n ṣì wà láyé? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni wọ́n ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn, kí sì ni ìrètí wọn fún ọjọ́ ọ̀la?
“Àwọn Ẹkùn Ènìyàn”
A mọ àwọn ẹ̀yà Apache (tí ó ṣe kedere pé a mú orúkọ wọn láti inú ọ̀rọ̀ èdè Zuni náà, apachu, tí ó túmọ̀ sí “ọ̀tá”) bíi jagunjagun tí kì í bẹ̀rù, tí ó sì dáńgájíá. Jagunjagun olókìkí, tí ó bá àwọn Àmẹ́ríńdíà jà ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún náà, Ọ̀gágun George Crook, pè wọ́n ní “àwọn ẹkùn ènìyàn.” Síbẹ̀, ìwé kan sọ pé, “kò sí ìgbà kankan, lẹ́yìn ọdún 1500, tí gbogbo ẹ̀yà Apache lápapọ̀ lé ní ẹgbàáta.” Ṣùgbọ́n àwọn jagunjagun mélòó kan lè dá odindi ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀tá lọ́wọ́ kọ́ nínú ogun abẹ́lẹ̀!
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìwé kan nípa àwọn ẹ̀yà Apache sọ pé: “Ní ìyàtọ̀ sí èròǹgbà wíwọ́pọ̀ tí àwọn ará Sípéènì, Mexico, àti Amẹ́ríkà ṣẹ̀dá, àwọn ẹ̀yà Apache kì í ṣe aláìlọ́làjú, tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ, tí gbogbo ọ̀ràn wọn jẹ́ ogun ṣáá. Nítorí oúnjẹ nìkan ni a ṣe máa ń piyẹ́ ní àwọn àkókò tí nǹkan wọ́n wa. A kì í gbógun lemọ́lemọ́, àmọ́ ní gbogbogbòò, a ń wéwèé dáradára láti gbẹ̀san àìṣèdájọ́ òdodo lòdì sí wa.” Àwọn àìṣèdájọ́ òdodo wọ̀nyẹn sì pọ̀ jaburata!
Ohun àfihàn kan ní Ibi Àfihàn Ohun Ìṣẹ̀ǹbáyé Àwọn Ẹ̀yà Apache ti San Carlos, ní Peridot, Arizona, ṣàlàyé ìtàn àwọn ẹ̀yà Apache ní ojú ìwòye wọn pé: “Dídé tí àwọn ará ìta dé sí àgbègbè náà mú ìkóguntini àti ìyípadà wá. Ìwọ̀nba ọ̀wọ̀ tí kò tó nǹkan ni àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀dé ní fún àwọn ìtanmọ́ra tí a ní fún ilẹ̀ náà bí ọmọ onílẹ̀. Nínú ìsapá láti dáàbò bo àwọn àṣà ìbílẹ̀ àti ohun ìṣẹ̀ǹbáyé wa, àwọn baba ńlá wa jagun, wọ́n sì ṣẹ́gun ọ̀pọ̀ àwọn jagunjagun àti ará ilẹ̀ Sípéènì, Mexico, àti United States. Ṣùgbọ́n bí iye púpọ̀ rẹpẹtẹ àti ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé ti po àwọn baba ńlá wa àti àwọn baba baba ńlá wa rúurùu, níkẹyìn, ó di dandan fún wọn láti fara mọ́ àwọn ohun tí Ìjọba United States ń béèrè. Wọ́n fipá mú wa láti kọ ìgbésí ayé alákòókiri wa sílẹ̀ lákọ̀tán, kí á sì máa gbé àwọn ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀.” Ọ̀rọ̀ náà, ‘fipá mú wa láti máa gbé àwọn ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀’ fi ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ hàn nípa nǹkan bí ìdajì mílíọ̀nù kan àwọn olùgbé ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ (lára àwọn Àmẹ́ríńdíà tí iye wọ́n lé ní mílíọ̀nù méjì) lára ẹ̀yà 554 tí ó wà ní United States àti ẹgbẹ́ àwùjọ 633 tí ó wà káàkiri Kánádà. Àwọn ẹ̀yà Apache tó 50,000 níye.a
Àwọn Olùlàájá ní Àtètèkọ́ṣe
Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ògbóǹkangí nípa ìtàn àwọn Àmẹ́ríńdíà nígbà àtètèkọ́ṣe gba èrò náà pé àwọn ẹ̀yà wọn ní àtètèkọ́ṣe gba Ipadò Bering wá láti Éṣíà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí tàn lọ sí ìhà gúúsù àti ìhà ìlà oòrùn díẹ̀díẹ̀. Àwọn onímọ̀ èdè so èdè àwọn ẹ̀yà Apache mọ́ ti àwọn ènìyàn Alaska àti Kánádà tí ń sọ èdè Athapaskan. Thomas Mails kọ̀wé pé: “Àwọn ìdíyelé lọ́ọ́lọ́ọ́ ti tọ́ka sí ọdún 1000 sí 1500 Lẹ́yìn Ikú Olúwa Wa bí àkókò tí wọ́n dé Gúúsù Ìwọ̀ Oòrùn Amẹ́ríkà. Àwọn onímọ̀ nípa ẹ̀dá ènìyàn kò tí ì fẹnu ọ̀rọ̀ jóná nípa ọ̀nà náà gan-an tí wọ́n gbà àti bí wọ́n ṣe ṣí wọ̀ ibẹ̀ tó.”—The People Called Apache.
Ní àwọn ọ̀rúndún tí ó ṣáájú, àwọn ẹ̀yà Apache sábà ń rí jíjẹ àti mímu wọn nípa ṣíṣètò àwọn ẹgbẹ́ tí ń piyẹ́ àwọn ará Mexico ẹ̀yà Sípéènì tí wọ́n múlẹ̀ gbè wọ́n. Thomas Mails kọ̀wé pé: “Irú àwọn ìpiyẹ́ bẹ́ẹ̀ ń bá a lọ fún ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó igba ọdún, bẹ̀rẹ̀ láti nǹkan bíi 1690 tí ó sì ń bá a lọ títí di nǹkan bíi 1870. Àwọn ìpiyẹ́ náà kò yani lẹ́nu, nítorí pé Mexico jẹ́ ilé àkójọ ohun èlò púpọ̀ yanturu ní gidi.”
Àwọn Wo Ló Kọ́kọ́ Gé Irun Mọ́ Awọ Orí?
Ní ìyọrísí ìforígbárí tí ń ṣe lemọ́lemọ́ láàárín Mexico àti orílẹ̀-èdè àwọn ẹ̀yà Apache, ìjọba ìpínlẹ̀ Sonora ní Mexico “padà sórí ìlànà” fífúnnilẹ́bùn awọ orí tí a gé irun mọ́ “tí ilẹ̀ Sípéènì ń ṣe tẹ́lẹ̀ rí.” Kì í ṣe àwọn ará Sípéènì ló nìkàn dá èyí sílẹ̀—àwọn ará Britain àti ará Faransé ti ní àṣà yìí ní àtètèkọ́ṣe.
Nítorí àtigba ẹ̀bùn owó ni àwọn ará Mexico ṣe ń gé irun mọ́ awọ orí, nígbà mìíràn, kò ṣe nǹkan kan bóyá awọ orí tí a gé irun mọ́ náà jẹ́ ti ẹ̀yà Apache tàbí kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ní ọdún 1835, wọ́n gbé òfin kan nípa ẹ̀bùn awọ orí tí wọ́n gé irun mọ́, tí ó pèsè 100 owó peso fún ọ̀kọ̀ọ̀kan awọ orí jagunjagun tí a gé mọ́ irun, jáde ní Mexico. Ní ọdún méjì lẹ́yìn náà, ẹ̀bùn náà ní nínú, 50 owó peso fún awọ orí obìnrin kọ̀ọ̀kan tí wọ́n bá gé irun mọ́, àti owó peso 25 fún ti ọmọ kọ̀ọ̀kan! Nínú ìwé rẹ̀, The Conquest of Apacheria, Dan Thrapp kọ̀wé pé: “Ní ti gidi, ìlànà náà ń wá ìparun pátápátá, tí ó jẹ́ ẹ̀rí pé ìparun ẹ̀yà ta gbòǹgbò tí ó tàn kálẹ̀, kì í sì í ṣe ìhùmọ̀ òde òní ti orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo péré.” Ó ń bá a lọ pé: “Àwọn ẹ̀yà Apache fúnra wọn kì í gé irun mọ́ awọ orí.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Mails sọ pé, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ẹ̀yà Chiricahua máa ń gé irun mọ́ awọ orí—àmọ́ kì í ṣe nígbà gbogbo, “nítorí ìbẹ̀rù wọn nípa ikú àti iwin.” Ó fi kún un pé: “Wọ́n wulẹ̀ ń gé irun mọ́ awọ orí láti gbẹ̀san lẹ́yìn tí àwọn ará Mexico bẹ̀rẹ̀ sí í lo ọgbọ́n náà ni.”
Thrapp sọ pé àwọn awakùsà “sábà ń kóra jọ . . . láti lọ ṣọdẹ àwọn Àmẹ́ríńdíà. Nígbà tí wọ́n bá lè ká wọn mọ́, wọ́n ń pa gbogbo àwọn ọkùnrin wọn láìkùkan àti, nígbà mìíràn, wọ́n ń pa àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé láìkùkan. Bí ó ṣe sábà máa ń rí, àwọn Àmẹ́ríńdíà máa ń gbẹ̀san lára àwọn aláwọ̀ funfun àti àwọn ẹ̀yà mìíràn.”
Charles Lummis sọ pé bíbá àwọn ẹ̀yà Apache jà dé orí kókó kan tí ó fi ń ṣàǹfààní fún ìpínlẹ̀ Arizona, níwọ̀n bí “àwọn ogun tí àwọn ẹ̀yà Apache ń jà ti [já sí] pé ó lé ní mílíọ̀nù méjì dọ́là [tí] Ẹ̀ka Ọ̀ràn Ogun ń san láàárín àwọn ààlà ilẹ̀ Arizona lọ́dọọdún.” Thrapp sọ pé: “Àwọn alágbára tí wọ́n tún ya ènìyànkénìyàn kan wà tí wọn kò fẹ́ ìfọ̀kànbalẹ̀ fún àwọn ẹ̀yà Apache, nítorí pé nígbà tí ìfọ̀kànbalẹ̀ bá dé, owó tí ń wọlé déédéé tí ẹ̀ka ológun ń ná yóò pòórá.”
Àwọn Ilẹ̀ Tí A Yà Sọ́tọ̀ Ha Ni Ojútùú Rẹ̀ Bí?
Ìforígbárí tí ń ṣẹlẹ̀ látìgbàdégbà láàárín àwọn abulẹ̀dó aláwọ̀ funfun tí ń gbógun àti àwọn ẹ̀yà Apache tí ń gbé ibẹ̀ ṣokùnfà ojútùú tí ìjọba àpapọ̀ gbé wá láti lọ sé àwọn Àmẹ́ríńdíà mọ́ àwọn ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀—tí ó sábà ń jẹ́ ibi ilẹ̀ tí kò dára, tí wọ́n retí pé kí wọ́n ti làájá. Ní ọdún 1871 sí 1872, a dá àwọn ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ fún àwọn ẹ̀yà Apache sílẹ̀.
Láti ọdún 1872 sí 1876, àwọn Apache ẹ̀yà Chiricahua ní ilẹ̀ tiwọn tí a yà sọ́tọ̀. Àwọn alákòókiri tí ohunkóhun kò dí lọ́wọ́ láti máa kó kiri wọ̀nyí nímọ̀lára pé a sé àwọn mọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní ilẹ̀ tí ó jẹ́ 1,107,000 hẹ́kítà, tí ó wà fún nǹkan bí 400 sí 600 ènìyàn, àgbègbè tí ó gbẹ táútáú yìí kò jẹ́ kí wọ́n ní àyè tí ó pọ̀ tó láti rí oúnjẹ nípa ọdẹ ṣíṣe àti ṣíṣa èso. Ìjọba ní láti pèsè ìwọ̀n oúnjẹ ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún-kẹẹ̀ẹ́dógún láti dènà ebi.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn abulẹ̀dó rò pé Ilẹ̀ Tí A Yà Sọ́tọ̀ fún Ẹ̀yà Chiricahua náà jẹ́ ilẹ̀ tí kò lẹ́tù lójú àti pé àwọn ẹ̀yà Apache gbọ́dọ̀ gbájú mọ́ ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ kan ṣoṣo. Àránkàn tí àwọn abulẹ̀dó aláwọ̀ funfun ní pọ̀ sí i lẹ́yìn ikú olóyè tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún náà, Cochise, ní ọdún 1874. Wọ́n nílò ìdí kan tí wọ́n fi lè lé àwọn Apache ẹ̀yà Chiricahua kúrò lórí ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ náà. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? “Ní ọdún 1876, ohun bojúbojú kan ṣẹlẹ̀. Àwọn méjì kan tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà Chiricahua pa àwọn ọkùnrin méjì kan tí ń ta ọtí whiskey láìbófinmu nígbà tí wọ́n kọ̀ láti ta [whiskey] sí i. Kàkà kí àwọn aṣojú [ìjọba] tí ń bójú tó San Carlos tí a yà sọ́tọ̀ mú àwọn tí wọ́n fura sí, ńṣe ni wọ́n kó àwọn ọkùnrin adìhámọ́ra-ogun wá, wọ́n sì kó àwọn [ẹ̀yà] Chiricahua lọ sí San Carlos. Wọ́n sì ti Ilẹ̀ Tí A Yà Sọ́tọ̀ fún Ẹ̀yà Chiricahua náà pa.”
Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n ṣì gba àwọn Àmẹ́ríńdíà láyè láti máa rìn kiri fàlàlà kọjá ààlà ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ náà. Àwọn abulẹ̀dó aláwọ̀ funfun kò nífẹ̀ẹ́ sí ìgbésẹ̀ yẹn. “Ní híhùwà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí àwọn abulẹ̀dó náà béèrè fún, ìjọba ṣí àwọn Apache ti àwùjọ San Carlos, White Mountain, Cibecue, àti Tonto, àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwùjọ tí ó ní àwọn ẹ̀yà Apache ti Chiricahua nídìí lọ sí ibùjókòó ẹ̀ka San Carlos.”—Creation’s Journey—Native American Identity and Belief.
Lákòókò kan, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ẹ̀yà Yavapai, Chiricahua, àti àwọn ẹ̀yà Apache Ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ni a fi sí àhámọ́ lórí ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ náà. Èyí fa pákáǹleke àti ìfura, níwọ̀n bí díẹ̀ lára àwọn ẹ̀yà wọ̀nyí ti jẹ́ ọ̀tá fún ìgbà pípẹ́. Báwo ni wọ́n ṣe hùwà padà sí ìkálọ́wọ́kò tí a gbé kalẹ̀ lórí ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ náà? Ìdáhùn àwọn ẹ̀yà Apache ni pé, “Ó fi ìgbésí ayé wa lọ́nà àbínibí dù wá, ó fi ohun ti ara, èrò ìmọ̀lára, àti tẹ̀mí dù wá. Wọ́n ti gba òmìnira wa lọ́wọ́ wa.”
Síbẹ̀síbẹ̀, àwùjọ àwọn ẹ̀yà Chiricahua kan, tí olórí ogun tí ó lókìkí náà, Geronimo, ṣe aṣáájú wọn, sá kúrò ní ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ náà ní ọdún 1885, wọ́n sì sá lọ sí Mexico. Ọ̀gágun Nelson Miles kó nǹkan bí 5,000 ọmọ ogun àti àwọn 400 alamí ti ẹ̀yà Apache, ó sì lépa wọn—gbogbo wọn ń gbìyànjú láti ṣàwárí àwọn jagunjagun 16, obìnrin 12, àti àwọn ọmọdé 6 péré lákòókò yẹn!
Níkẹyìn, ní September 4, 1886, Geronimo túúbá. Ó fẹ́ láti padà sí Ilẹ̀ Tí A Yà Sọ́tọ̀ ní San Carlos. Ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀. Wọ́n sọ fún un pé, wọ́n ti kó gbogbo àwọn ẹ̀yà Apache tó wà níbẹ̀ lọ sí ìhà ìlà oòrùn, bí ẹlẹ́wọ̀n, lọ sí Florida, ibi tí òun pẹ̀lú yóò lọ. Ó fi èdè Apache sọ pé: “Łahn dádzaayú nahikai łeh niʹ nyelíí k’ehge,” tí ó túmọ̀ sí “Tẹ́lẹ̀ rí a ń káàkiri fàlàlà.” Geronimo onígbèéraga, tí ó sì lọ́gbọ́n àrékérekè, tí ó jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n ní báyìí, kò lè káàkiri fàlàlà mọ́.
Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n gbà á láyè láti lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, dé Fort Sill, Oklahoma, níbi tí ó kú sí ní 1909. Bíi ti ọ̀pọ̀ aṣáájú àwọn Àmẹ́ríńdíà, a fi ipá mú olóyè ẹ̀yà Apache yìí láti fara mọ́ àwọn ipò ìgbésí ayé líle tí ó wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n àti àwọn ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀.
Àwọn Ìṣòro Wo Ni Wọ́n Ní Lónìí?
Àwọn ẹ̀yà Apache ń gbé àwọn ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ bíi mélòó kan ní Arizona àti New Mexico. Jí! ṣèbẹ̀wò sí Ilẹ̀ Tí A Yà Sọ́tọ̀ ní San Carlos, ó sì fọ̀rọ̀ wá àwọn aṣáájú ẹ̀yà Apache mélòó kan lẹ́nu wò. Ìròyìn nípa ìbẹ̀wò yẹn ló tẹ̀ lé e yìí.
Láìpẹ́ tí a dé ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ náà ní ọjọ́ kan tí gbogbo nǹkan gbẹ táútáú, tí ó móoru ní oṣù May, Harrison Talgo àti ìyàwó rẹ̀ gbà wá tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Harrison, sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ kan, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ ga tó mítà méjì, tí ó ní irùngbọ̀n yẹ́úkẹ́, jẹ́ mẹ́ńbà ìgbìmọ̀ ẹ̀yà San Carlos. A bi í léèrè pé: “Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tí àwọn ẹ̀yà Apache ní lónìí?”
“A ń pàdánù àwọn ìlànà àṣà ìbílẹ̀ wa. Tẹlifíṣọ̀n ti ní ipa bíburú jáì, pàápàá jù lọ lórí àwọn ọ̀dọ́ wa. Àpẹẹrẹ kan ni pé wọn kì í kọ́ èdè wa. Ìṣòro pàtàkì mìíràn ni àìríṣẹ́ṣe, tí ń tó ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-ún ní àwọn àgbègbè kan. Òtítọ́ ni pé a ní àwọn ilé tẹ́tẹ́, àmọ́ wọn kò fún ọ̀pọ̀ lára àwọn ènìyàn wa níṣẹ́. Ohun tó burú níbẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ènìyàn wa ń lọ síbẹ̀ lọ fi ìwé owó ìrànwọ́ àpapọ̀ wọn, tí ó dúró fún owó ilé àti oúnjẹ wọn, ta tẹ́tẹ́ ni.”
Nígbà tí a bi Harrison léèrè nípa ìṣòro ìlera tí ẹ̀yà náà ń dojú kọ, kò lọ́ra láti dáhùn. Ó sọ pé: “Àtọ̀gbẹ. Ó lé ní ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ènìyàn wa tí wọ́n jẹ́ alárùn àtọ̀gbẹ. Ní àwọn àgbègbè kan, ó lé ní ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún.” Ó sọ pé ìṣòro pàtàkì mìíràn ni ìṣòro tí àwọn aláwọ̀ funfun gbé dé ní ohun tí ó lé ní 100 ọdún sẹ́yìn—ọtí. “Oògùn lílé pẹ̀lú ń nípa lórí àwọn ènìyàn wa.” Ẹ̀rí kedere nípa àwọn ìṣòro wọ̀nyí ni a rí lára àwọn àmì òpópó ní ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ náà, tí ó sọ pé: “Má Mùmukúmu—Ẹ Yẹra fún Oògùn Líle” àti, “Dáàbò Bo Ilẹ̀ Wa. Dáàbò Bo Ìlera Wa. Má Ṣe Ohun Àmúṣọrọ̀ Wa Báṣubàṣu.”
A béèrè bóyá àrùn AIDS ti dé inú ẹ̀yà náà. Pẹ̀lú ìríra tí ó hàn kedere, ó fèsì pé: “Ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ lọ̀ràn. Ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ ti ń wọ ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ náà díẹ̀díẹ̀. Tẹlifíṣọ̀n àti àwọn ìwà abèṣe àwọn aláwọ̀ funfun ti ń sọ díẹ̀ lára àwọn ọ̀dọ́ wa nínú ẹ̀yà Apache di aláìlágbára.”
A béèrè nípa bí ipò nǹkan ti yí padà ní ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ náà ní àwọn ọdún àìpẹ́. Harrison dáhùn pé: “Ní àwọn ọdún 1950, bí àwọn nǹkan ṣe jẹni lógún, tí wọ́n sì ń nípa lórí ẹni nìyí: Ìkíní ni ìsìn; ìkejì ni ìdílé; ìkẹta ni ẹ̀kọ́ ìwé; ìkẹrin ni ìfìtínà ojúgbà; àti èyí tí ó kẹ́yìn ni tẹlifíṣọ̀n. Lónìí, àtẹ̀yìn ló ti bẹ̀rẹ̀, tí tẹlifísọ̀n sì ní ipa tí ó gba iwájú. Ìfìtínà ojúgbà ni ipa tí ó lágbára ṣìkejì—ìfìtínà láti kọ àṣà Apache sílẹ̀, kí wọ́n sì tẹ̀ lé ipa ti Amẹ́ríkà tí ó gbòde. Ẹ̀kọ́ ìwé ló gba ipò kẹta, ọ̀pọ̀ lára àwọn Apache sì ń lo àǹfààní kọ́lẹ́ẹ̀jì tí ó ṣí sílẹ̀, àti pípọ̀ tí àwọn ilé ẹ̀kọ́ àti ilé ẹ̀kọ́ gíga tí ó wà ní ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ náà ń pọ̀ sí i.”
A béèrè pé: “Ipa ti ìdílé ńkọ́?”
“Ó ṣeni láàánú pé a ti rẹ ìdílé sílẹ̀ sí ipò kẹrin, ìsìn ló sì kẹ́yìn nísinsìnyí—yálà ó jẹ́ ìsìn ìbílẹ̀ wa tàbí ti àwọn aláwọ̀ funfun.”
“Kí ni èrò rẹ nípa àwọn ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù?”
“Inú wa kò dùn sí bí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ṣe ń gbìyànjú láti yí àwọn ènìyàn wa lọ́kàn padà kúrò nínú àwọn ìgbàgbọ́ ìbílẹ̀.b Àwọn ọmọlẹ́yìn Luther àti àwọn Kátólíìkì ti ní àwọn ibùdó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ṣọ́ọ̀ṣì níhìn-ín fún ohun tí ó lé ní 100 ọdún. Àwọn àwùjọ Pentecostal, tí wọ́n ń fi ìmọ̀lára fani mọ́ra, wà pẹ̀lú.
“A ní láti mú ìdánimọ̀ àṣà ìbílẹ̀ wa padà bọ̀ sípò nípasẹ̀ ìdílé, kí a sì padà sórí sísọ èdè Apache. Ní báyìí, a ti pàdánù rẹ̀.”
Ìlọsíwájú Ètò Ọrọ̀ Ajé Ẹ̀yà Apache
A ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ aláṣẹ ẹ̀yà Apache mìíràn, tí ó fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nípa ìfojúsọ́nà tí Ilẹ̀ Tí A Yà Sọ́tọ̀ ní San Carlos ní fún ètò ọrọ̀ ajé. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó ṣàlàyé pé kò rọrùn láti rí àwọn olùdókòwò láti wá ná owó púpọ̀ sórí àwọn ìdáwọ́lé iṣẹ́ níbẹ̀. Àpẹẹrẹ dáradára kan ni àdéhùn kan tí wọ́n bá ilé iṣẹ́ tẹlifóònù pàtàkì kan ṣe láti dá Ilé Iṣẹ́ Ìfìsọfúnni-Ránṣẹ́ ti Apache ní San Carlos sílẹ̀. Àjọ Ètò Ọrọ̀ Ajé Ìgbèríko ló fowó ṣètìlẹ́yìn rẹ̀, yóò sì jẹ́ kí iṣẹ́ túbọ̀ wà fún àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀yà Apache, yóò sì mú ètò tẹlifóònù ní ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ náà sunwọ̀n, kí ó sì gbòòrò sí i.
Aláṣẹ yìí tún sọ̀rọ̀ tìyangàntìyangàn nípa ẹ̀ka ìfọ̀dọ̀tí inú kíndìnrín tí wọn óò gbé kalẹ̀ ní ilé ìwòsàn tí ó wà ní ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ náà, tí yóò bójú tó ọ̀ràn ìṣègùn fínnífínní àti lọ́nà tí ó dára. Lẹ́yìn náà ni ó fi àwọn ìwéwèé tí ó wà fún àtúnṣe ìdàgbàsókè ibùdó ìṣòwò ní San Carlos, tí wọn óò bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ láìpẹ́, hàn wá. Ó ní ẹ̀mí pé nǹkan yóò dára lọ́jọ́ iwájú, àmọ́ ó tẹnu mọ́ ọn pé ẹ̀kọ́ ìwé gbọ́dọ̀ jẹ́ ìpìlẹ̀ rẹ̀. ‘Ẹ̀kọ́ ìwé túmọ̀ sí owó ọ̀yà tí ó gbé pẹ́ẹ́lí, tí ń yọrí sí níní àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé tí ó sàn jù.’
Àwọn obìnrin ẹ̀yà Apache lókìkí nítorí òye iṣẹ́ apẹ̀rẹ̀ híhun wọn. Ìwé atọ́nà arìnrìn-àjò afẹ́ kan sọ pé, “ọdẹ ṣíṣe, ẹja pípa, sísin ẹran, gẹdú gígé, ìwakùsà, ṣíṣe eré ìtura níta àti rírìnrìn-àjò afẹ́” ni lájorí ohun tí ń mú owó wọlé jù lọ nínú ètò ọrọ̀ ajé àdúgbò.
Àwọn ẹ̀yà Apache ń gbìyànjú láti wà ní ipò kan náà pẹ̀lú àwọn ìlú mìíràn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro tí ó wà níwájú wọn tóbi. Bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn, wọ́n fẹ́ ìdájọ́ òdodo, ọ̀wọ̀, àti ìgbésí ayé tí ó bójú mu.
Ìgbà Tí Ìdájọ́ Òdodo Tòótọ́ Yóò Borí
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn ẹ̀yà Apache láti sọ fún wọn nípa ayé tuntun tí Jèhófà Ọlọ́run ṣèlérí fún ilẹ̀ ayé wa, tí Bíbélì ṣàpèjúwe dáradára gan-an nínú ìwé Aísáyà pé: “Nítorí pé kíyè sí i, èmi yóò dá ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun; àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà. Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò ṣe làálàá lásán.”—Aísáyà 65:17, 21, 23; 2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:1-4.
Àkókò tí Jèhófà Ọlọ́run yóò gbégbèésẹ̀ láti fọ ayé mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìwà ìbàjẹ́, títí kan bíba ilẹ̀ ayé jẹ́, ti sún mọ́lé. (Wo Mátíù 24; Máàkù 13; Lúùkù 21.) Àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè, títí kan àwọn ilẹ̀ àwọn Àmẹ́ríńdíà, lè wá bù kún ara wọn nípa yíyíjú sí Ọlọ́run òtítọ́ náà, Jèhófà, nípasẹ̀ Kristi Jésù. (Jẹ́nẹ́sísì 22:17, 18) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pèsè ẹ̀kọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ fún ọlọ́kàntútù èyíkéyìí tí ó bá fẹ́ láti jogún ilẹ̀ ayé tí a mú bọ̀ sípò, tí ó sì ń fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.—Sáàmù 37:11, 19.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn Apache pín sí onírúurú ìsọ̀rí ẹgbẹ́ àwùjọ bí ẹ̀yà Apache Ìhà Ìwọ̀ Oòrùn, tí ó ní nínú, Tonto Ìhà Àríwá àti Ìhà Gúúsù, Mimbreño, àti Coyotero. Àwọn ti Ìhà Ìlà Oòrùn ni àwọn ẹ̀yà Apache ti Chiricahua, Mescalero, Jicarilla, Lipan, àti Kiowa. Ìpín sí ìsọ̀rí síwájú sí i ni ti àwọn ẹ̀yà Apache ti White Mountain àti àwọn ẹ̀yà Apache ti San Carlos. Lónìí, ní pàtàkì, àwọn ẹ̀yà wọ̀nyí ń gbé gúúsù ìlà oòrùn Arizona àti New Mexico.—Wo àwòrán ojú ìwé 15.
b Ẹ̀dà Jí! kan lọ́jọ iwájú yóò gbé àwọn ìgbàgbọ́ àti ìsìn àwọn Àmẹ́ríńdíà yẹ̀ wò.
[Àwòrán ilẹ̀/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ÀRÍWÁ AMẸ́RÍKÀ
Àgbègbè tí a mú tóbi lápá ọ̀tún
Ilẹ̀ Tí A Yà Sọ́tọ̀ fún Àwọn Ẹ̀yà Apache
ARIZONA
NEW MEXICO
Jicarilla
Fort Apache (White Mountain)
San Carlos
Mescalero
[Credit Line]
Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Geronimo
[Credit Line]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Arizona Historical Society/Tucson, AHS#78167
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Harrison Talgo, mẹ́ńbà ìgbìmọ̀ ẹ̀yà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Wọ́n sin Olóyè Cochise sí ibi olódi rẹ̀ náà, Chiricahua
Àwọn àwo fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ ti sátẹ́láìtì mú tẹlifíṣọ̀n wá sí ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ náà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Nígbà ìsìnkú àwọn ẹ̀yà Apache, àwọn mọ̀lẹ́bí ń to àwọn òkúta sẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ sàréè. Àwọn aṣọ múlọ́múlọ́ tí a ta sófuurufú dúró fún orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé