Iṣẹ́ Ìṣàtúntò Eyín—Kí Ni Ó Ní Nínú?
EYÍN rẹ ṣe pàtàkì! Wọ́n wúlò fún ọ nígbà tí o bá ń jẹun àti nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀, wọ́n tún kó ipa pàtàkì kan nínú ẹ̀rín músẹ́ tàbí ẹ̀rín kèékèé tí ó gún régé.
Àwọn eyín wọ́gọwọ̀gọ lè mú kí ó ṣòro láti jẹ oúnjẹ lẹ́nu, wọ́n lè dá kún àrùn ẹran ìdí eyín, wọ́n sì lè fa àìlèsọ̀rọ̀-dáadáa. Àwọn ògbógi tún ti ṣàkíyèsí pé àwọn eyín wọ́gọwọ̀gọ lè jẹ́ àbùkù tí ń fawọ́ aago àwọn kan sẹ́yìn láwùjọ, níwọ̀n bí wọ́n ti lè ní ìṣòro láti ṣàlàyé ara wọn fàlàlà nítorí wọ́n gbà gbọ́ pé eyín àwọn ti ba ẹ̀rín músẹ́ àwọn jẹ́.
Kí ni o lè ṣe bí àwọn eyín rẹ bá rí wọ́gọwọ̀gọ? Ta ní lè ràn ọ́ lọ́wọ́? Ní ọjọ́ orí wo? Irú ìtọ́jú wo ni o lè gbà? Yóò ha fa ìrora bí? O ha máa ń fìgbà gbogbo pọn dandan bí?
Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìtọ́jú Eyín
Ẹ̀ka iṣẹ́ ìtọ́jú eyín tí ń bójú tó irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ ni a ń pè ní iṣẹ́ ìṣàtúntò eyín. Ó ń ṣe àtúnṣe àìgúnrégé eyín.
Àwọn ohun wo ni lájorí iṣẹ́ ìṣàtúntò eyín? Ó ní ṣe pẹ̀lú mímọ àwọn ìṣòro àti dídènà wọn àti ṣíṣe àwọn ohun èlò ìṣàtúntò eyín.
Eyín tí ó wọ́ lù, tí ó rí wọ́gọwọ̀gọ, tí ó sì ta yọ ti jẹ́ ìṣòro fún àwọn ènìyàn ní ìgbà ìjímìjí pàápàá, ó kéré tán, àwọn ìgbìyànjú láti wá ìtọ́jú fún un ti wà láti ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Tiwa. Lọ́nà tó yani lẹ́nu, a ti rí àwọn ohun èlò ìṣàtúntò eyín ti ìjímìjí tí a ṣe dáradára nínú àwárí àwọn awalẹ̀pìtàn ilẹ̀ Gíríìkì àti Etruria.
Lónìí, ní apá ibi púpọ̀ jù lọ lágbàáyé, àwọn olùtọ́jú eyín, tí a ń pè ní aṣàtúntò-eyín, ń ṣètọ́jú àwọn ìṣòro tí ó ní ṣe pẹ̀lú eyín wọ́gọwọ̀gọ. Wọ́n ní láti mọ̀ nípa bí eyín ṣe ń hù àti ìdàgbàsókè rẹ̀ àti páárì àti àwọn iṣu ẹran ara àti ẹran ara tí ó yí i ká.
Ohun Tí Iṣẹ́ Ìṣàtúntò Eyín Ń Ṣe
A lè túmọ̀ iṣẹ́ ìṣàtúntò eyín bí “ẹ̀ka iṣẹ́ ìtọ́jú eyín tí ń rí sí àbójútó, ìmútọ́ àti àtúnṣe híhù àti gbígbó àwọn ìgbékalẹ̀ eyín òun ojú.” Ó ní nínú, “àtúnṣe ipò tí àwọn eyín wà sí ara wọn, àti àwọn egungun ojú nípa lílo ipá àti/tàbí mímì ín àti ìtúndarí àwọn ipá ìṣiṣẹ́ tí ó wà láàárín àpapọ̀ ìgbékalẹ̀ agbárí òun ojú.” Òtítọ́ ni èyí jẹ́ ìtumọ̀ tí ó kan òye iṣẹ́, àmọ́ ó péye.
Nítorí náà, nínú iṣẹ́ ìṣàtúntò eyín, a ń fi agbára mú àwọn eyín tàbí àwọn ohun tí ó yí wọn ká, tọ́. A ń ṣe èyí nípasẹ̀ ohun èlò tí ó bá ipò olúkúlùkù mu, tí ń ṣàtúnṣe àwọn ìṣòro pàtàkì tí agbàtọ́jú kọ̀ọ̀kan ní, tí ń ti eyín àti àwọn egungun pàápàá sí ipò tí ó yẹ kí wọ́n wà.
Àwọn sẹ́ẹ̀lì kan, tí a ń pè ní osteoclast àti àwọn sẹ́ẹ̀lì mìíràn tí a ń pè ní osteoblast, wà nínú egungun tí ó yí eyín ká. Ní àbáyọrí àwọn agbára tí àwọn ohun èlò ìṣàtúnṣe eyín ń ní, àwọn osteoclast ń ṣiṣẹ́ níbi tí agbára bá wà, kí àwọn ẹran ara elégungun lè dẹ̀. Àwọn egungun tuntun tí osteoblast mú jáde níbi tí ó fà ro ń dí àlàfo náà. Lọ́nà yìí, eyín náà ń sún díẹ̀díẹ̀.
Ó ha ń bára dé láti gbé ohun mìíràn tí wọ́n fi irin, ike, àti bóyá rọ́bà fífà pàápàá ṣe sẹ́nu fún ọ̀pọ̀ oṣù bí? Bí wọ́n bá gbé ohun èlò síni lẹ́nu tàbí tí wọ́n bá ṣàtúnṣe rẹ̀, ó lè kọ́kọ́ máà bára dé; àmọ́ tí ó bá pẹ́ díẹ̀, yóò mọ́ni lára. Lọ́rọ̀ ẹnu, ẹnikẹ́ni ni gbígbé ohun èlò ìṣàtúntò eyín sẹ́nu lè mọ́ lára.
Ìgbà Wo Ló Yẹ Kí A Tọ́jú Ẹnì Kan?
Kì í ṣe gbogbo ipò tí ó bá jọ pé ó ń fa àìlègé-ǹkanjẹ, tabí àìgúnrégé eyín, nígbà ọmọdé ni yóò máa bá a lọ títí di ìgbà tó bá dàgbà. Irú àwọn eyín kan tí kò bọ́ sípò máa ń ṣàtúnṣe ara wọn. Ní gidi, nígbà rírọ eyín, eyín tuntun tí ó hù lọ́wọ́ iwájú ẹnu sábà máa ń wọ́ lù, nítorí pé wọ́n tóbi ju eyín tí wọ́n ń gbapò rẹ̀ lọ.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí erìgì àkọ́kọ́ bá ká, tí erìgì tuntun sì hù rọ́pò rẹ̀, ìyàtọ̀ kan ń ṣẹlẹ̀ ní ibi tí eyín náà wà tẹ́lẹ̀. Bí ó ṣe ń lò àwọn eyín náà àti bí ìgbékalẹ̀ iṣu ẹran ara ṣe ń nípa lórí wọn tó, àwọn eyín náà lè wá to ara wọn. Nítorí náà, bí o bá jẹ́ òbí kan, má ṣe dààmú bí o bá ṣàkíyèsí pé ó jọ pé eyín àkọ́kọ́ tí ọmọ rẹ ń hù ṣe wọ́gọwọ̀gọ níbẹ̀rẹ̀. Ó yẹ kí aṣàtúntò eyín kan lè pinnu bí a bá ní láti ṣe ohunkóhun.
Èrò àwọn aṣàtúntò-eyín yàtọ̀ síra lórí ìgbà tó yẹ kí a tọ́jú àwọn ọmọ kéékèèké tí wọ́n ní ìṣòro náà. Àwọn kan sọ pé nígbà tí wọ́n bá ṣì kéré gan-an (ọdún 4 sí 6). Àwọn mìíràn sọ pé tí ó bá pẹ́ díẹ̀, tí ó bá sún mọ́ òpin ìgbà híhù nígbà ìbàlágà (ọdún 12 sí 15). Síbẹ̀, àwọn kan gbà pẹ̀lú àkókò kan tí ó wà láàárín méjèèjì.
Kì Í Ṣe fún Àwọn Ọmọdé Nìkan
Àmọ́, kì í ṣe àwọn ọmọdé nìkan ni iṣẹ́ ìṣàtúntò eyín wà fún. Eyín wọ́gọwọ̀gọ ń fa ìṣòro púpọ̀, kódà fún àwọn àgbàlagbà. Ọjọ́ orí rẹ kò dí àtúnṣe ìṣọwọ́rẹ́rìn-ín músẹ́ rẹ lọ́wọ́ bí àwọn eyín àti àwọn ìgbékalẹ̀ tí ń di eyín rẹ mú bá jíire.
Àwọn ìṣòro wo ni eyín wọ́gọwọ̀gọ ń fà? Ó kéré tán, oríṣi mẹ́ta: (1) àwọn ìṣòro tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìrísí; (2) àwọn ìṣòro ìṣiṣẹ́, tí ó kan ìṣòro nínú gbígbé páárì (ríro àti àìṣiṣẹ́-dáradára iṣu ẹran ara), ìṣòro jíjẹ nǹkan, àti ìṣòro pípe ọ̀rọ̀ àti sísọ ọ̀rọ̀; (3) ewu púpọ̀jù ti ìpalára nítorí eyín títayọ àti ewu púpọ̀jù ti àwọn àrùn abẹ́ eyín (àrùn ẹran ìdí eyín) àti ìjẹrà eyín àti àìlágbára òun ìbàjẹ́ tí àìgúnrégé eyín ń fà.
Ní àfikún, àwọn ògbógi kan ka àìgúnrégé eyín mọ́ àwọn ìṣòro tí ó wà nínú eegun ẹ̀yìn (ní pàtàkì níbi ọrùn) àti àwọn ìṣòro ìṣiṣẹ́ iṣu ẹran ara ní àwọn apá ibòmíràn nínú ara. Ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe ń tọ́jú wọn? Báwo sì ni ó ṣe ń pẹ́ tó?
Bí Ìtọ́jú Ṣe Ń Pẹ́ Tó àti Àwọn Ọ̀nà Tí A Ń Gbà Ṣe Wọ́n
Bí o bá nímọ̀lára pé yálà ìwọ tàbí ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ nílò aṣàtúntò-eyín kan, o gbọ́dọ̀ yan ọ̀kan tí o lè fọkàn tán. Bí ìtọ́jú ṣe pẹ́ tó yóò yàtọ̀ látàrí bí ìṣòro náà bá ṣe le tó àti ọ̀nà tí a gbà ṣe é, àmọ́ ó ṣeé ṣe kí ó gba oṣù bí mélòó kan, ó tilẹ̀ lè gba ọdún bí mélòó kan.
Kí nǹkan lè rọrùn, a lè pín àwọn ohun èlò ìtọ́jú sí ìsọ̀rí méjì: àwọn ohun èlò tí a lè yọ àti àwọn ohun èlò tí a kò lè yọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tí ń gbàtọ́jú náà lè yọ àwọn ohun èlò tí a lè yọ kúrò kí ó sì tún fi síbẹ̀ padà, àwọn ohun èlò tí a kò lè yọ ni a máa ń rẹ́ mọ́ eyín, tí ó sì máa ń ti eyín lọ́nà tí ó túbọ̀ díjú.
Ìwádìí ti tẹ̀ síwájú gan-an nínú ọ̀ràn nípa ẹwà, tí ó fi jẹ́ pé lónìí, ọ̀pọ̀ ohun èlò “tí ṣíṣe rẹ̀ bá ti àdánidá mu” ti wà. A kò lè rí àwọn kan nítorí pé àwọ̀ wọn bá ti eyín mu, àti àwọn mìíràn, tí a ṣe sí apá inú, síbi tí a mọ̀ sí àyè ìpèdè, ní ẹgbẹ́ ahọ́n, kò ṣeé rí. Irú àwọn ìlànà bẹ́ẹ̀ ni a ń pè ní ìṣàtúntò eyín lọ́nà tí a kò ní rí i.
Nínú àwọn ọ̀ràn tí ó ṣòro jù lọ, nígbà tí aṣàtúntò-eyín kò bá lè fi ohun èlò ìṣàtúntò eyín ṣe ohun tí a fẹ́ yọrí, ó tilẹ̀ lè wá ìrànlọ́wọ́ oníṣẹ́ abẹ kan tí ó mọ àwọn ìṣòro ẹnu àti ojú dunjú. Ó lè ṣe iṣẹ́ abẹ tí yóò fi sún àwọn egungun tí ó ṣàgbékalẹ̀ iwájú.
Lónìí, iṣẹ́ ìṣàtúntò eyín lè yanjú ọ̀pọ̀ lára àwọn àìní àwọn tí wọ́n ní ìṣòro eyín àti páárì, títí kan àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ọkàn láti rẹ́rìn-ín músẹ́ láìsí pé wọ́n ń kóra ró nítorí eyín wọn. Dájúdájú, yálà ẹnì kan pinnu láti lo ọ̀nà ìṣàtúntò eyín tàbí kò ní lò ó jẹ́ ìpinnu àdáṣe.
Ní báyìí ná, ìran ènìyàn ní láti máa bá àwọn àbùkù ara, tí a lè fi àwọn ohun èlò ìṣàtúnṣe mú kúrò, yí. Síbẹ̀síbẹ̀, a lè fojú sọ́nà fún ìgbà tí Ọlọ́run yóò mú gbogbo ohun tí àìpé ń fà, títí kan àwọn ti ẹnu, kúrò nínú ayé tuntun rẹ̀. Nígbà náà, nínú ètò tuntun ti ìlera pípé yẹn, olúkúlùkù wa yóò lè fi taratara fi ọ̀yàyà rẹ́rìn-ín músẹ́ sí ẹnikẹ́ni tí a bá pàdé.
Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò yẹn pé: “Gbogbo ilẹ̀ ayé ti sinmi, ó ti bọ́ lọ́wọ́ ìyọlẹ́nu. Àwọn ènìyàn ti tújú ká pẹ̀lú igbe ìdùnnú.” (Aísáyà 14:7) Dájúdájú, a óò fi ẹ̀rín músẹ́, tí ó gún régé kún irú ìtújúká àti igbe ayọ̀ bẹ́ẹ̀!
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àfihàn àwọn ohun èlò ìṣàtúntò eyín tí a pète láti (1) sún àwọn erìgì eyín sẹ́yìn àti (2) láti mú páárì dàgbà
1
2
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àwọn ohun ìṣàtúntò tí a pète láti ṣàtúnṣe àìwàdéédéé