Ohun 2—Máa Ṣìkẹ́ Ara Rẹ
“Kò sí ènìyàn kankan tí ó jẹ́ kórìíra ara òun fúnra rẹ̀; ṣùgbọ́n a máa bọ́ ọ, a sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀.”—Éfésù 5:29. Tó o bá ń fún ara rẹ ní àwọn nǹkan tí ara ń fẹ́, ó lè mú kí ìlera rẹ dára sí i.
◯ Máa sinmi dáadáa. “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílépa ẹ̀fúùfù.” (Oníwàásù 4:6) Kòókòó jàn-ánjàn-án tó kúnnú ayé báyìí kì í jẹ́ kí àwọn èèyàn ráyè sùn dáadáa. Àmọ́ oorun ṣe pàtàkì fún ìlera ẹ̀dá. Ìwádìí fi hàn pé, ara àti ọpọlọ wa máa ń tún ara rẹ̀ ṣe nígbà téèyàn bá sùn, èyí sì máa ń jẹ́ kéèyàn lè máa rántí nǹkan dáadáa kí ìṣesí rẹ̀ sì dára.
Oorun máa ń jẹ́ kí ara wa lè gbógun ti àìsàn, kò sì ní jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn àrùn bí, ìtọ̀ ṣúgà, rọpárọsẹ̀, àrùn ọkàn, jẹjẹrẹ, sísanra jọ̀kọ̀tọ̀, ìsoríkọ́, tó fi mọ́ àìsàn tó ń mú kí arúgbó máa ṣarán, kọlù wá. Dípò tí a ó fi máa lo àwọn nǹkan bíi dáyá, kaféènì tàbí àwọn nǹkan míì tó máa ń jẹ́ kí oorun dá lójú èèyàn, ńṣe ló yẹ́ ká wáyè láti sùn, bó tiẹ̀ ṣe díẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ti dàgbà ló yẹ kó máa sun oorun wákàtí méje sí mẹ́jọ lálaalẹ́, kí ojú wọn lè gún régé, kí ara wọn yá gágá kí wọ́n sì lè lókun nínú. Ó sì yẹ kí àwọn ọmọdé máa sùn jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìrònú àwọn ọ̀dọ́ tí kì í sùn dáadáa kì í fi bẹ́ẹ̀ já geere, wọ́n sì lè gbàgbé sùn lọ nígbà tí wọ́n bá ń wakọ̀.
Ó ṣe pàtàkì kéèyàn sùn dáadáa nígbà tó bá ń ṣàìsàn. Ara wa lè gbogun ti àwọn àìlera kan, irú bí ọ̀fìnkìn, téèyàn bá sùn dáadáa tó sì mu ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.
◯ Máa tọ́jú eyín rẹ. Máa fọ eyín rẹ, kó o sì máa yọ ìdọ̀tí tó há sí ẹ ní eyín lẹ́yìn tó o bá jẹun tan, ní pàtàkì jù lọ kó o tó lọ sùn, èyí kò ní jẹ́ kí eyín rẹ jẹrà, kò ní jẹ́ kí ẹran ìdí eyín rẹ bà jẹ́ tàbí kí eyín rẹ ká. Kò sí bí a ṣe máa gbádùn oúnjẹ tá à ń jẹ bí kò bá sí eyín lẹ́nu wa. Ìwádìí tí wọ́n ṣe nípa àwọn erin fi hàn pé, ebi ló máa ń pa wọ́n kú, kì í ṣe torí pé wọn ti darúgbó, ohun tó sì máa ń ṣẹlẹ̀ gan-an ni pé nígbà tí eyín erin bá ti ká dà nù, wọn kò ní lè jẹ nǹkan lẹ́nu dáadáa mọ́. Àwọn ọmọdé tí wọ́n bá ti kọ́ pé kí wọ́n máa fọ ẹnu wọn kí wọ́n sì máa yọ ìdọ̀tí tó há sí wọn ní eyín lẹ́yìn tí wọ́n bá jẹun tán máa ń ní ìlera tó dáa nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé àti jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn.
◯ Máa lọ ṣàyẹ̀wò ara rẹ lọ́dọ̀ dókítà. Ó máa ń gba pé kéèyàn lọ rí àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ dókítà nítorí àwọn àìlera kan. Téèyàn bá ti tètè mọ ohun tó ń ṣe é, kì í jẹ́ kéèyàn náwó jù. Torí náà, tó o bá rí i pé ara rẹ kò le dáadáa, wá bó o ṣe máa mọ ohun tó ń ṣe ẹ́ àti bó o ṣe máa mú un kúrò dípò tí wàá kàn fi máa lo oògùn láti rọ̀ ọ́ lójú.
Ṣíṣàyẹ̀wò ara ẹni déédéé lọ́dọ̀ àwọn dókítà tí ìjọba fọwọ́ sí lè jẹ́ ká bọ́ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ ìṣòro lílekoko, bí ìgbà tí aláboyún bá lọ gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ oníṣègùn.a Àmọ́, má gbàgbé pé àwọn dókítà kò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu o. Ìgbà tí Ọlọ́run bá sọ “ohun gbogbo di tuntun” la máa tó rí ìwòsàn onírúurú àìlera.—Ìṣípayá 21:4, 5.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà “Healthy Mothers, Healthy Babies,” nínú Jí! November 2009, lédè Gẹ̀ẹ́sì.